Báwo Lo Ṣe Lè Máa Fi Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù Lọ?
Báwo Lo Ṣe Lè Máa Fi Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù Lọ?
ǸJẸ́ ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá ọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rí, tó mú kíṣẹ́ náà sú ọ tó sì ń ṣe ọ́ bíi kó o ṣíwọ́? Àwọn nǹkan bí àtakò lílekoko, ìdààmú, àìlera, ọ̀rọ̀ àìdáa látọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ ẹni tàbí ìrònú pé àwọn èèyàn ò fetí sí ìwàásù wa, lè fẹ́ mú ká rẹ̀wẹ̀sì lẹ́nu iṣẹ́ náà. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù. Ó fara da àwọn ìdánwò tó le koko jù lọ “nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀.” (Héb. 12:2) Ó mọ̀ pé tóun bá fi lè jẹ́ kó hàn gbangba pé irọ́ gbuu ni gbogbo ẹ̀sùn tí ọ̀tá fi kan Jèhófà Ọlọ́run, inú Jèhófà yóò dùn.—Òwe 27:11.
Tí ìwọ náà bá ń fi ìfaradà ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ, wàá lè mú inú Jèhófà dùn. Àmọ́, bí àwọn ìṣòro kan bá wá fẹ́ tán ọ lókun lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù yìí ńkọ́? Wo Arábìnrin Krystyna tó jẹ́ àgbàlagbà, tí àìsàn sì ń bá fínra. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń rẹ̀ mí tí gbogbo nǹkan á sì tojú sú mi. Àwọn ìṣòro ọjọ́ ogbó tí mo ní, irú bí àìlera àti àníyàn nípa ọ̀ràn ìgbésí ayé, máa ń mú mi rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.” Báwo lo ṣe lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ láìka irú àwọn ìṣòro yìí sí?
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì
Tí akéde Ìjọba Ọlọ́run kan bá ń gbìyànjú láti ní irú ẹ̀mí táwọn wòlíì ìgbàanì ní, yóò lè máa fi ìfaradà ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí lọ. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ wòlíì Jeremáyà. Nígbà tí Ọlọ́run yàn án láti ṣe iṣẹ́ wòlíì, ó kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀. Síbẹ̀, nítorí pé Jeremáyà gbára lé Ọlọ́run pátápátá, ogójì ọdún ló fi fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ líle tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́.—Jer. 1:6; 20:7-11.
Àpẹẹrẹ Jeremáyà jẹ́ ìṣírí fún Arákùnrin Henryk. Ó ní: “Láti nǹkan tó ju àádọ́rin ọdún lọ tí mo ti ń bá iṣẹ́ ìwàásù bọ̀, àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń bá mi torí báwọn èèyàn ṣe máa ń ṣe sí wa, ìyẹn bí wọ́n ṣe máa ń tẹ́ńbẹ́lú ẹni tàbí bí wọ́n ṣe máa ń dágunlá. Nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, mo máa ń rán ara mi létí àpẹẹrẹ Jeremáyà. Ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà àti àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun pẹ̀lú Jèhófà mú kó lè máa bá iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ lọ.” (Jer. 1:17) Àpẹẹrẹ Jeremáyà tún jẹ́ ìṣírí fún Arákùnrin Rafał pẹ̀lú. Ó ní: “Ọlọ́run ni Jeremáyà gbára lé, dípò táá fi jẹ́ kí ọ̀ràn ara rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ gbà á lọ́kàn. Ó ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ láìṣojo bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn kógun tì í. Ìyẹn ni mo máa ń fi sọ́kàn.”
Wòlíì míì tí àpẹẹrẹ tirẹ̀ tún ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti máa fi ìfaradà ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ ni Aísáyà. Jèhófà sọ fún un pé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ̀ kò ní fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Mú kí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́, sì mú kí etí wọn gan-an gíràn-án.” Ṣé pé asán ni iṣẹ́ Aísáyà máa já sí? Rárá o, kò ní já sásán lójú Ọlọ́run! Nígbà tí Ọlọ́run yan Aísáyà ní wòlíì, bó ṣe dáhùn rèé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8-10) Aísáyà kò kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un. Ṣé irú ọwọ́ bẹ́ẹ̀ nìwọ náà fi mú iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run pàṣẹ pé ká máa ṣe?
Tá a bá fẹ́ ṣe bíi ti Aísáyà, tá a fẹ́ máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ pẹ̀lú gbogbo báwọn èèyàn ò ṣe fẹ́ gbọ́ wa, a ò ní máa ro ti àìdáa táwọn èèyàn ń ṣe sí wa. Ohun tí Rafał ń ṣe láti fi borí ìrẹ̀wẹ̀sì nìyẹn. Ó ní: “Ṣe ni mo máa ń gbìyànjú láti mọ́kàn kúrò lórí ọ̀rọ̀ tí kò dáa táwọn èèyàn bá sọ. Tá a bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ohun tó bá wu àwọn tó wà níbẹ̀ ni wọ́n lè ṣe nípa ọ̀rọ̀ ìwàásù wa.” Arábìnrin Anna náà sọ tirẹ̀ pé: “N kì í jẹ́ kí èrò nípa ohun tí kò dùn mọ́ni tàbí tó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni dúró lọ́kàn mi rárá. Ohun tó ń jẹ́ kí n lè ṣe é ni pé mo máa ń gbàdúrà mo sì ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ kí n tó lọ sóde ẹ̀rí. Kíá ni èròkerò tó bá fẹ́ wá sí mi lọ́kàn sì máa ń pòórá.”
Àárín àwọn Júù olóríkunkun tó wà nígbèkùn ní Bábílónì ni Ìsíkíẹ́lì ti ṣe iṣẹ́ tirẹ̀. (Ìsík. 2:6) Ká ní wòlíì Ìsíkíẹ́lì kò sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn náà ni, tàbí ká ní ẹni burúkú kan kú láìjẹ́ pé ó gbọ́ ìkìlọ̀ látẹnu rẹ̀ ni, Ìsíkíẹ́lì ni ì bá jẹ̀bi ikú onítọ̀hún. Jèhófà sọ fún un pé: “Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni èmi yóò béèrè padà ní ọwọ́ rẹ.”—Ìsík. 3:17, 18.
Irú ẹ̀mí tí Ìsíkíẹ́lì ní yẹn gan-an ni Arákùnrin Henryk gbìyànjú láti ní. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ kí ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo. Ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣeyebíye, ó sì wà nínú ewu.” (Ìṣe 20:26, 27) Bọ́rọ̀ náà sì ṣe rí nìyẹn lára Arákùnrin Zbigniew. Ó ní: “Ìsíkíẹ́lì ní láti máa bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ láìwo ohun táwọn èèyàn ń rò. Èyí jẹ́ kí èmi náà máa fi ojú tí Ẹlẹ́dàá fi ń wo iṣẹ́ ìwàásù wò ó.”
Ìwọ Nìkan Kọ́ Lò Ń Ṣe Iṣẹ́ Náà
Nígbà tó o bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, mọ̀ dájú pé ìwọ nìkan kọ́ lò ń ṣe iṣẹ́ náà. Àwa náà lè sọ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, pé: “Àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:9) Arábìnrin Krystyna, tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń bá òun lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, sọ pé: “Ìyẹn ló fi jẹ́ pé mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó fún mi lókun. Kò sì já mi kulẹ̀ rí.” Dájúdájú, a nílò ìtìlẹyìn ẹ̀mí Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa!—Sek. 4:6.
Nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ ká lè gbé àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ “èso ti ẹ̀mí” yọ. (Gál. 5:22, 23) Èyí sì ń jẹ́ ká lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ, láìfi ohunkóhun táwọn èèyàn ṣe pè. Arákùnrin Henryk sọ pé: “Kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ń jẹ́ kí ìwà mi túbọ̀ máa dára sí i. Mo ti dẹni tó ń ní sùúrù, tó ń gba tẹni rò àtẹni tí kì í tètè sọ̀rètí nù.” Tó o bá ń fi ìfaradà ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó láìfi ti onírúurú ìṣòro pè, wàá lè dẹni tó túbọ̀ ń ní àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ èso tẹ̀mí.
Àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà ń lò láti fi darí iṣẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. (Ìṣí. 14:6) Bíbélì sì fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì tí Jèhófà ń lò yìí pọ̀ tó “ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún.” (Ìṣí. 5:11) Àwọn áńgẹ́lì yìí, tó wà lábẹ́ àbójútó Jésù, máa ń ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn. Ǹjẹ́ o máa ń fìyẹn sọ́kàn nígbàkigbà tó o bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
Anna sọ pé: “Bí mo bá ti ń ronú nípa rẹ̀ pé àwọn áńgẹ́lì máa ń wà pẹ̀lú wa lóde ẹ̀rí, ó máa ń fún mi níṣìírí gidi. Mo mọrírì bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń darí wọn láti máa tì wá lẹ́yìn.” Àǹfààní ńlá ló mà jẹ́ o, pé à ń bá àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ṣiṣẹ́ pọ̀!
Tá a bá tún wo àwọn tá a jọ jẹ́ akéde Ìjọba Ọlọ́run náà ńkọ́? Ìbùkún ńlá ló jẹ́ pé a wà lára ogunlọ́gọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́. Kò sí àní-àní pé wàá ti rí i pé òótọ́ lohun tó wà nínú òwe inú Bíbélì yìí, pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.”—Òwe 27:17.
Bíbá àwọn ará míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí máa ń jẹ́ ká láǹfààní ńlá láti rí àwọn ọ̀nà míì tó múná dóko tá a tún lè gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Arábìnrin Elżbieta sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá akéde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ láǹfààní láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ará ìjọ àtàwọn èèyàn tá a bá bá pàdé lóde ẹ̀rí.” Ìwọ náà gbìyànjú láti máa bá akéde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Yóò jẹ́ kó o lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí lọ́nà tó lárinrin.
Máa Tọ́jú Ara Rẹ Dáadáa
Láti lè máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó, a ní láti ṣètò ìgbòkègbodò wa dáadáa, ká ṣètò ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó ń lọ déédéé, ká sì rí i pé à ń sinmi dáadáa. Ní kúkúrú, ńṣe ni ká fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà ká sì máa tọ́jú ara wa dáadáa.
Bíbélì sọ pé: “Ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” (Òwe 21:5) Arákùnrin Zygmunt, tó ti dẹni ọdún méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] báyìí, sọ pé: “Bí mo ṣe fètò sí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn ń jẹ́ kí n lè ṣàṣeyọrí tó pọ̀. Mo fara balẹ̀ ṣètò àkókò mi kí n lè rí àkókò tó pọ̀ tó láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù.”
Ọ̀nà kan téèyàn ń gbà gbára dì fún iṣẹ́ ìwàásù ni pé kéèyàn ní òye Ìwé Mímọ́ dáadáa. Gẹ́gẹ́ bó ti ṣe pàtàkì pé ká máa jẹ oúnjẹ kí ara wa lè le, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣe pàtàkì pé ká máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé láti lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, tá a sì ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” a óò lókun tá a ó fi máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa.—Mát. 24:45-47.
Arábìnrin Elżbieta ṣe àyípadà pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé rẹ̀, kó lè túbọ̀ ráyè máa ṣe iṣẹ́
ìwàásù dáadáa. Ó ní: “Mo ti dín àkókò ti mo fi ń wo tẹlifíṣọ̀n kù gan-an kí n lè túbọ̀ máa ráyè múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà tí mo bá ń ka Bíbélì lálẹ́, mo máa ń ronú nípa àwọn tí mò ń bá pàdé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù. Mo sì máa ń wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti àpilẹ̀kọ táá lè ràn wọ́n lọ́wọ́.”Tó o bá ń sinmi tó bó ṣe yẹ, wàá lè máa lágbára dáadáa, èyí á sì jẹ́ kó o lè máa kópa tó kún rẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Àmọ́ tí eré ìnàjú bá pọ̀ jù lọ́rọ̀ ẹni, èèyàn kì í lè kópa tó bó ṣe yẹ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Akéde onítara kan tó ń jẹ́ Andrzej sọ pé: “Téèyàn kì í bá fún ara ní ìsinmi, ó máa ń jẹ́ kó rẹni jù, téèyàn ò bá sì ṣọ́ra, ìrẹ̀wẹ̀sì á dé. Mo máa ń rí i dájú pé mo fún ara mi ní ìsinmi dáadáa kí n má bàa rẹ̀wẹ̀sì.”—Oníw. 4:6.
Bó ti wù ká sapá tó, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò ní gba ìhìn rere. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé Jèhófà kò ní gbàgbé iṣẹ́ wa láéláé. (Héb. 6:10) Kódà bí ọ̀pọ̀ èèyàn ò bá tiẹ̀ dá wa lóhùn nígbà tá a dé ọ̀dọ́ wọn, wọ́n ṣì lè máa sọ̀rọ̀ nípa wíwá tá a wá síbẹ̀ lẹ́yìn tá a bá kúrò nílé wọn. Ó lè wá dà bí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Ìsíkíẹ́lì, ó ní: “Ó dájú pé [àwọn èèyàn náà] yóò mọ̀ . . . pé wòlíì kan wà ní àárín wọn.” (Ìsík. 2:5) Lóòótọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kò rọrùn, àmọ́ à ń jàǹfààní tó pọ̀ látinú rẹ̀, àwọn èèyàn tó ń fetí sí i náà sì ń jàǹfààní rẹ̀.
Arákùnrin Zygmunt sọ pé: “Ńṣe ni kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ń jẹ́ ká lè gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, ká sì máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa.” Ohun tí Arákùnrin Andrzej náà sọ ni pé: “Àǹfààní gidi ló jẹ́ pé à ń kópa nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí. Iṣẹ́ ta ò ní pa dà ṣe mọ́ láé lọ́nà tó gbòòrò tó yìí àti lábẹ́ irú ipò tá a wà yìí ni.” Lónìí, ìwọ náà lè jèrè lọ́pọ̀ yanturu tó o bá ń fi ìfaradà ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà lọ.—2 Kọ́r. 4:1, 2.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Tá a bá fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà tá a sì ń tọ́jú ara wa dáadáa, àá lè máa fi ìfaradà ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà lọ