Jẹ́ Onítara Fún Ilé Jèhófà!
Jẹ́ Onítara Fún Ilé Jèhófà!
“Ìtara fún ilé rẹ yóò jẹ mí run.”—JÒH. 2:17.
1, 2. Kí ni Jésù ṣe nínú tẹ́ńpìlì lọ́dún 30 Sànmánì Kristẹni, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
FOJÚ inú yàwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìrékọjá lọ́dún 30 Sànmánì Kristẹni. Oṣù mẹ́fà ṣáájú àkókò yìí ni Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ní báyìí, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù. Nínú Àgbàlá Àwọn Kèfèrí tó wà nínú tẹ́ńpìlì, Jésù “rí àwọn tí ń ta màlúù àti àgùntàn àti àdàbà àti àwọn onípàṣípààrọ̀ owó lórí ìjókòó wọn.” Ó wá fi àwọn ìjàrá ṣe pàṣán, ó sì fi lé gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n ń tà níbẹ̀ dà nù, àwọn tó ń tà á sì tẹ̀ lé wọn. Jésù tún da owó àwọn tó ń pààrọ̀ owó nù, ó sì sojú àwọn tábìlì wọn dé. Ó wá pàṣẹ fáwọn tó ń ta àdàbà pé kí wọ́n kó wọn jáde.—Jòh. 2:13-16.
2 Ohun tí Jésù ṣe yìí fi hàn pé ó ka tẹ́ńpìlì sí pàtàkì. Ó pàṣẹ fáwọn tó ń ṣòwò níbẹ̀ pé: “Ẹ dẹ́kun sísọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà!” Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ń wo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, wọ́n rántí ọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà, Dáfídì, kọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò yẹn pé: “Ìtara fún ilé rẹ yóò jẹ mí run.”—Jòh. 2:16, 17; Sm. 69:9.
3. (a) Kí ni ìtara? (b) Ìbéèrè wo la lè bi ara wa?
3 Ohun tó mú kí Jésù ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó bìkítà, ó sì ní ìtara fún ilé Ọlọ́run. Ìtara túmọ̀ sí pé “kéèyàn máa hára gàgà fún nǹkan, kéèyàn sì nífẹ̀ẹ́ láti jẹ́ kọ́wọ́ òun tẹ nǹkan ọ̀hún.” Ní ọ̀rúndún kọkànlélógún tá a wà yìí, àwọn Kristẹni tó lé ní mílíọ̀nù méje ló ń fi hàn pé àwọn ní ìtara fún ilé Ọlọ́run. Àmọ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan lè bi ara ẹ̀ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi kún ìtara tí mo ní fún ilé Jèhófà?’ Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ohun tí ilé Ọlọ́run túmọ̀ sí lóde òní. Lẹ́yìn náà, a óò wá gbé àwọn àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò nínú Bíbélì, nípa àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó nítara fún ilé Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ wọn wà lákọọ́lẹ̀ “fún ìtọ́ni wa” ó sì lè mú ká túbọ̀ fi kún ìtara wa.—Róòmù 15:4.
Ilé Ọlọ́run Láyé Ọjọ́un àti Lóde Òní
4. Kí ni wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́?
4 Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni ilé Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà kì í gbébẹ̀. Torí ó sọ pé: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ilẹ̀ ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Ibo wá ni ilé tí ẹ lè kọ́ fún mi wà, ibo sì wá ni ibi tí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún mi?” (Aísá. 66:1) Síbẹ̀ náà, tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ nígbà ayé Sólómọ́nì jẹ́ ojúkò ìjọsìn Jèhófà, wọ́n sì tún máa ń gbàdúrà níbẹ̀.—1 Ọba 8:27-30.
5. Kí ni jíjọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì ṣàpẹẹrẹ lóde òní?
5 Lóde òní, ilé Jèhófà kì í ṣe ilé ràgàjì tí wọ́n fi òkúta kọ́ ní Jerúsálẹ́mù tàbí níbòmíì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ètò tí Ọlọ́run ṣe ká bàa lè máa jọ́sìn rẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi. Gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ló ń fi ìṣọ̀kan sin Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà.—Aísá. 60:4, 8, 13; Ìṣe 17:24; Héb. 8:5; 9:24.
6. Àwọn ọba Júdà wo ló fìtara tó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn fún ìjọsìn tòótọ́?
6 Lẹ́yìn tí wọ́n pín ìjọba Ísírẹ́lì sí méjì, lọ́dún 997 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, mẹ́rin lára àwọn ọba mọ́kàndínlógún [19] tó ṣàkóso ní Júdà, ìyẹn ìjọba ti apá gúúsù, ló fìtara tó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn fún ìjọsìn tòótọ́. Àwọn ni Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà àti Jòsáyà. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ wọn?
Ìjọsìn Àtọkànwá Máa Ń Mú Ìbùkún Wá
7, 8. (a) Irú iṣẹ́ ìsìn wo ni Jèhófà máa ń bù kún? (b) Ẹ̀kọ́ tó ń kini nílọ̀ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tí Ásà Ọba ṣe?
7 Nígbà ìṣàkóso Ásà Ọba, Jèhófà gbé àwọn wòlíì kan dìde láti máa tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa pé Ásà fetí sí wòlíì Asaráyà, tó jẹ́ ọmọ Ódédì. (Ka 2 Kíróníkà 15:1-8.) Àwọn àtúnṣe tí Ásà ṣe mú káwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà wà níṣọ̀kan, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó wà lábẹ́ ìjọba Ísírẹ́lì, tó wá síbi àpéjọ ńlá kan tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù. Gbogbo wọn ló pinnu pé àwọn á máa fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà. A kà pé: “Wọ́n fi ohùn rara àti igbe ìdùnnú àti kàkàkí àti ìwo búra fún Jèhófà. Gbogbo Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ lórí ohun tí wọ́n ṣe ìbúra lé; nítorí pé gbogbo ọkàn-àyà wọn ni wọ́n fi búra àti pé ìdùnnú kíkún níhà ọ̀dọ̀ wọn ni wọ́n fi wá a, tí ó fi jẹ́ kí wọ́n rí òun; Jèhófà sì ń bá a lọ láti fún wọn ní ìsinmi yí ká.” (2 Kíró. 15:9-15) Ó dájú pé Jèhófà á bù kún àwa náà tá a bá fi tọkàntọkàn sìn ín.—Máàkù 12:30.
8 Àmọ́ ó dunni pé, nígbà tó yá Ásà bínú gan-an torí pé Hánáánì aríran bá a wí. (2 Kíró. 16:7-10) Báwo làwa náà ṣe máa ń ṣe tí Jèhófà bá fún wa nímọ̀ràn tàbí tó tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ àwọn alàgbà nínú ìjọ? Ṣé a tètè máa ń ṣiṣẹ́ lórí ìbáwí tó dá lórí Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fún wa, tá a sì máa ń yàgò fún dídi kùnrùngbùn?
9. Kí ló kó ìpayà bá Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn Júdà, kí sì ni wọ́n ṣe?
9 Jèhóṣáfátì ṣàkóso ní Júdà láàárín ọ̀rúndún kẹwàá ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Orílẹ̀-èdè Ámónì, Móábù àtàwọn èèyàn ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì para pọ̀ láti gbéjà ko Jèhóṣáfátì àti gbogbo ilẹ̀ Júdà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ba ọba náà, kí ló ṣe? Òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, títí kan àwọn ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn, wá sí ilé Jèhófà láti gbàdúrà. (Ka 2 Kíróníkà 20:3-6.) Níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì sọ nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì, Jèhóṣáfátì bẹ Jèhófà pé: “Ìwọ Ọlọ́run wa, ìwọ kì yóò ha mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún lé wọn lórí? Nítorí pé kò sí agbára kankan nínú wa níwájú ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí tí ń bọ̀ wá gbéjà kò wá; àwa alára kò sì mọ ohun tí à bá ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.” (2 Kíró. 20:12, 13) Lẹ́yìn tí Jèhóṣáfátì ti gbàdúrà tán “ní àárín ìjọ,” ẹ̀mí Jèhófà wá sún Jahasíẹ́lì, ọmọ Léfì kan láti sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú tó fi gbogbo àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀.—Ka 2 Kíróníkà 20:14-17.
10. (a) Báwo ni Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn Júdà ṣe rí ìtọ́sọ́nà gbà? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń fún wa lónìí?
10 Nígbà yẹn, Jahasíẹ́lì ni Jèhófà lò láti tọ́ Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn Júdà sọ́nà. Lónìí, ẹrú olóòótọ́ àti olóye ni Jèhófà ń lò láti pèsè ìtùnú àti ìtọ́sọ́nà fún wa. Dájúdájú, ó yẹ ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn, torí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó wa, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lórí ìtọ́ni tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà bá pèsè.—Mát. 24:45; 1 Tẹs. 5:12, 13.
11, 12. Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn Júdà?
11 Bí Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn rẹ̀ ṣe kóra jọ láti wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ẹ jẹ́ káwa náà máa pé jọ déédéé sáwọn ìpàdé ìjọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a wà nínú ìṣòro kan tó le, tá ò sì mọ ohun tó yẹ ká ṣe, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn Júdà, ká tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà pẹ̀lú ìgbọ́kànlé. (Òwe 3:5, 6; Fílí. 4:6, 7) Kódà, tó bá jẹ́ pé ńṣe la dánìkan wà, àdúrà wa sí Jèhófà á jẹ́ ká wà níṣọ̀kan pẹ̀lú “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará [wa] nínú ayé.”—1 Pét.5:9.
12 Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn ẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run fún wọn nípasẹ̀ Jahasíẹ́lì. Kí nìyẹn yọrí sí? Wọ́n ṣẹ́gun, wọ́n sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú “ayọ̀ yíyọ̀” àti pẹ̀lú “àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti pẹ̀lú háàpù àti kàkàkí sí ilé Jèhófà.” (2 Kíró. 20:27, 28) Àwa náà máa ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà fún wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀, a sì máa ń jùmọ̀ yìn ín.
Máa Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ibi Ìjọsìn Wa
13. Iṣẹ́ wo ni Hesekáyà dáwọ́ lé níbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀?
13 Ní oṣù àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí Hesekáyà bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso, ó fi bí ìtara rẹ̀ fún ìjọsìn Jèhófà ṣe tó hàn, nígbà tó tún tẹ́ńpìlì ṣí, tó sì tún un ṣe. Ó ṣètò pé káwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì fọ ilé Ọlọ́run mọ́. Wọ́n sì ṣe é fún ọjọ́ mẹ́rìndínlógún. (Ka 2 Kíróníkà 29:16-18.) Ohun tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ ká rántí àbójútó àti àtúnṣe tá a máa ń ṣe láti mú kí àwọn ibi tá a ti ń ṣe ìpàdé wà nípò tó fi hàn pé a ní ìtara fún ìjọsìn Jèhófà. Ó ṣe tán, a máa ń gbọ́ ìrírí to fi hàn pé ìtara àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà máa ń wú àwọn èèyàn lórí! Ó dájú pé, ipa tí wọ́n ń sà máa ń mú ìyìn bá Jèhófà.
14, 15. Iṣẹ́ wo ló ti mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà lóde òní? Sọ àpẹẹrẹ.
14 Ní ìlú kan ní àríwá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ọ̀gbẹ́ni kan kò fẹ́ kí wọ́n ṣàtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ẹ̀. Àmọ́ àwọn arákùnrin náà ò bá a janpata. Wọ́n rí i pé ògiri tó pààlà sáàárín ilé ọkùnrin yẹn àti Gbọ̀ngàn Ìjọba nílò àtúnṣe, wọ́n sì gbà láti tún un ṣe láìgba owó kankan. Wọ́n ṣiṣẹ́ kára, kódà wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tún gbogbo ògiri náà ṣe tán. Wọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ náà dáadáa débi pé ọ̀gbẹ́ni yẹn yí èrò ẹ̀ pa dà. Ní báyìí òun ló ń ṣọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà.
15 Àwa èèyàn Jèhófà ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ kárí ayé. Àwọn ará ìjọ máa ń ti àwọn òṣìṣẹ́ káyé lẹ́yìn nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ilé Bẹ́tẹ́lì. Arákùnrin Sam, jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ tó já fáfá nípa ẹ̀rọ tó ń mú kí ilé móoru, èyí tó ń gbé afẹ́fẹ́ wọlé àti ẹ̀rọ amúlétutù. Òun àti Rúùtù ìyàwó ẹ̀ ti rìnrìn àjò lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní ilẹ̀ Yúróòpù àti Áfíríkà láti ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé. Wọ́n tún máa ń bá àwọn ará jáde òde ẹ̀rí níbikíbi tí wọ́n bá lọ. Arákùnrin Sam sọ ohun tó mú kó máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé bẹ́ẹ̀ láti orílẹ̀ èdè kan sí òmíràn, ó ní: “Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì nílùú wa àtàwọn tó ń sìn nílẹ̀ òkèèrè ló fún mi níṣìírí. Ìtara àti ayọ̀ tí wọ́n ní ló mú kí n máa ṣiṣẹ́ sìn lọ́nà yìí.”
Tẹ̀ Lé Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run
16, 17. Ìgbòkègbodò àkànṣe wo làwa èèyàn Ọlọ́run ti fìtara lọ́wọ́ sí, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
16 Yàtọ̀ sí pé Hesekáyà ṣàtúnṣe tẹ́ńpìlì, ó tún mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣayẹyẹ Ìrékọjá tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún pa dà, èyí tí Jèhófà pa láṣẹ fún wọn. (Ka 2 Kíróníkà 30:1, 4, 5.) Hesekáyà àtàwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ké sí gbogbo orílẹ̀-èdè náà, títí kan àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba àríwá síbi ayẹyẹ náà. Àwọn sárésáré sì mú lẹ́tà ìkésíni lọ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà.—2 Kíró. 30:6-9.
17 Àwa náà ti lọ́wọ́ nínú irú àwọn nǹkan báyìí láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. A ti lo àwọn ìwé ìkésíni tó fani mọ́ra láti pe àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa láti wá síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ní ìgbọràn sí àṣẹ Jésù. (Lúùkù 22:19, 20) Àwọn ìtọ́ni tá a máa ń gbà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ràn wá lọ́wọ́ láti máa fìtara lọ́wọ́ sí iṣẹ́ yìí. Jèhófà sì ti bù kún ìsapá wa gan-an ni! Lọ́dún tó kọjá, àwa bíi mílíọ̀nù méje la pín ìwé ìkésíni, àwọn tó sì wá síbi Ìrántí Ikú Kristi fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjìdínlógún [17,790,631].
18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o ní ìtara fún ìjọsìn tòótọ́?
18 Bíbélì sọ nípa Hesekáyà pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ó gbẹ́kẹ̀ lé; lẹ́yìn rẹ̀, kò tún wá sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ nínú gbogbo ọba Júdà, àní àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ pàápàá. Ó sì ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà. Kò yà kúrò nínú títọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè.” (2 Ọba 18:5, 6) Ẹ jẹ́ káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ìtara tá a ní fún ilé Ọlọ́run á jẹ́ ká máa “bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà” a ó sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.—Diu. 30:16.
Máa Tẹ̀ Lé Ìtọ́sọ́nà Láìjáfara
19. Ìsapá wo la máa ń fìtara ṣe lákòókò Ìrántí Ikú Kristi?
19 Nígbà tí Jòsáyà ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba, òun náà ṣètò ayẹyẹ Ìrékọjá, ó sì ṣe ìmúrasílẹ̀ débi tó lápẹẹrẹ. (2 Ọba 23:21-23; 2 Kíró. 35:1-19) Àwa náà máa ń múra sílẹ̀ dáadáa fún àpéjọ àgbègbè, àyíká àti àkànṣe títí kan Ìrántí Ikú Kristi. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ará kan tiẹ̀ máa ń fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n bàa lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Bákan náà, àwọn alàgbà onítara máa ń rí i pé wọn ò gbójú fo ẹnikẹ́ni nínú ìjọ. Wọ́n máa ń ran àwọn àgbàlagbà àtàwọn tara wọn ò le lọ́wọ́ kí wọ́n lè wà níbẹ̀.
20. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣàkóso Jòsáyà Ọba, kí ló sì ṣe? (b) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́?
20 Lásìkò tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò, tí Jòsáyà Ọba ṣètò, Hilikáyà Àlùfáà Àgbà “rí ìwé òfin Jèhófà láti ọwọ́ Mósè.” Ó mú ìwé náà fún Ṣáfánì akọ̀wé ọba, ìyẹn wá kà á fún Jòsáyà. (Ka 2 Kíróníkà 34:14-18.) Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìbànújẹ́ sorí ọba kodò, ó sì fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, lẹ́yìn náà ó pàṣẹ fáwọn ọkùnrin náà pé kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà. Ọlọ́run wá tipasẹ̀ wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Húlídà bẹnu àtẹ́ lu àwọn àṣà ìjọsìn kan tí wọ́n ń ṣe ní Júdà. Àmọ́, Jèhófà ò gbójú fo ipa tí Jòsáyà sà láti mú ìbọ̀rìṣà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì rí ojú rere rẹ̀ láìkà ti àjálù tí wọ́n sọ pé ó máa wá sórí ìlú náà lápapọ̀. (2 Kíró. 34:19-28) Kí la lè rí kọ́ nínú èyí? Ó dájú pé ohun tí Jòsáyà ṣe làwa náà fẹ́ ṣe. A fẹ́ máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà láìjáfara, ká sì máa ronú lórí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tá a bá fàyè gba ìpẹ̀yìndà tàbí tá a di aláìṣòótọ́ nínú ìjọsìn wa. Ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa bá a ṣe ń fìtara ṣe ìjọsìn tòótọ́, á sì tẹ́wọ́ gbà wá, bó ṣe tẹ́wọ́ gba Jòsáyà.
21, 22. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìtara fún ilé Jèhófà? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
21 Àwọn ọba Júdà mẹ́rin tá a gbé ọ̀rọ̀ wọn yẹ̀ wò náà, Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà àti Jòsáyà, jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa tó bá dọ̀rọ̀ jíjẹ́ onítara fún ilé Ọlọ́run àti ìjọsìn rẹ̀. Ìtara gbọ́dọ̀ sún àwa náà láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì lo ara wa tokuntokun fún ìjọsìn rẹ̀. Kò sí àní-àní pé ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ tá a bá ń ṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, tá a mọyì àbójútó onífẹ̀ẹ́ àti ìtọ́ni tá à ń rí gbà nípasẹ̀ ìjọ àti látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, ìyẹn á sì jẹ́ ká láyọ̀.
22 Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó sì máa fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti máa fìtara sin Baba wa onífẹ̀ẹ́. A tún máa ṣàgbéyẹ̀wò bá a ṣe lè yẹra fún ọ̀kan lára ọ̀nà tó burú jù lọ tí Sátánì ń gbà ti èèyàn dẹ́ṣẹ̀. Bá a ṣe ń fìtara tẹ̀ lé gbogbo ìránnilétí látọ̀dọ̀ Jèhófà, àpẹẹrẹ Jésù, tó jẹ́ Ọmọ Jèhófà, là ń tẹ̀ lé, ẹni tá a sọ nípa rẹ̀ pé: “Ògédé ìtara fún ilé rẹ ti jẹ mí run.”—Sm. 69:9; 119:111, 129; 1 Pét. 2:21.
Ǹjẹ́ O Rántí
• Irú iṣẹ́ ìsìn wo ni Jèhófà máa ń bù kún, kí sì nìdí?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé?
• Báwo ni ìtara ṣe lè mú ká máa ṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Báwo ni Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà àti Jòsáyà ṣe fi hàn pé àwọn ní ìtara fún ilé Jèhófà?