Bá A Ṣe Lè Rí Ìṣúra Tá A Rọra Fi Pa Mọ́ Sínú Kristi
Bá A Ṣe Lè Rí Ìṣúra Tá A Rọra Fi Pa Mọ́ Sínú Kristi
“Inú rẹ̀ ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí.”—KÓL. 2:3.
1, 2. (a) Kí ni wọ́n ṣàwárí lọ́dún 1922, ibo sì ni wọ́n wà báyìí? (b) Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ gbogbo èèyàn pé kí wọ́n ṣe?
ÀWỌN ìwé ìròyìn sábà máa ń gbé ìròyìn jáde nípa àwọn ìṣúra tó fara sin táwọn èèyàn ṣàwárí. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1922, lẹ́yìn tí awalẹ̀pìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Howard Carter ti ṣe wàhálà pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára nínú ipò tí kò bára dé, fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó ṣàwárí ohun kan tó pabanbarì. Ó rí ibojì Fáráò tó ń jẹ́ Tutankhamen, tí kò yingin, tó kún fún àwọn nǹkan iyebíye tó tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000].
2 Pẹ̀lú báwọn nǹkan tí Ọ̀gbẹ́ni Carter rí ṣe gbàfiyèsí tó, ilé tí wọ́n ń kó nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé sí ni ọ̀pọ̀ lára ẹ̀ wà báyìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lè máa fi àwọn nǹkan yẹn sọ̀tàn tàbí kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe jojú ní gbèsè tó, síbẹ̀ wọn ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé wa. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká wá ìṣúra tó máa nípa gidi lórí ìgbésí ayé wa. Gbogbo èèyàn ni ìkésíni náà wà fún, èrè tá a sì máa rí níbẹ̀ pọ̀ ju èyí tá a máa rí nínú ìṣúra ti ara lọ.—Ka Òwe 2:1-6.
3. Àwọn ọ̀nà wo ni ìṣúra tí Jèhófà rọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n wá gbà ṣàǹfààní?
3 Ronú lórí báwọn ìṣúra tí Jèhófà rọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n wá ti ṣeyebíye tó. Lára àwọn ìṣúra yẹn ni “ìbẹ̀rù Jèhófà,” èyí tó lè jẹ́ ààbò fún wa, tó sì lè pa wá mọ́ láwọn àkókò líle koko tá a wà yìí. (Sm. 19:9) Béèyàn bá wá “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an,” èyí á jẹ́ kéèyàn ní iyì tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé, ìyẹn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹni Gíga Jù Lọ. Síwájú sí i, ìṣúra tí Ọlọ́run ń pèsè, ìyẹn ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye, á jẹ́ ká lè máa yanjú àwọn ìṣòro àti àníyàn tá à ń ní lójoojúmọ́. (Òwe 9:10, 11) Báwo la ṣe lè rí àwọn ìṣúra iyebíye yìí?
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Wá Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí?
4. Báwo la ṣe lè rí àwọn ìṣúra tẹ̀mí tí Ọlọ́run ṣèlérí?
4 Ọ̀rọ̀ tiwa kò dà bíi tàwọn awalẹ̀pìtàn àtàwọn olùṣàwárí tó jẹ́ pé wọ́n ní láti wá ibi gbogbo kí wọ́n tó lè rí ìṣúra tí wọ́n ń wá, a mọ ibi pàtó tá a ti lè rí àwọn ìṣúra tẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dà bí àwòrán tó ń tọ́ka sí ibi tí ìṣúra wà, máa ń darí wa síbi pàtó tá a ti lè rí àwọn ìṣúra tí Ọlọ́run ṣèlérí. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa Kristi, ó ní: “Inú rẹ̀ ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí.” (Kól. 2:3) Bá a ṣe ń ka ọ̀rọ̀ yẹn, a lè béèrè pé: ‘Kí nìdí tó fi yẹ ká wá àwọn ìṣúra wọ̀nyẹn? Báwo la ṣe fi wọ́n “pa mọ́” sínú Kristi? Báwo la sì ṣe lè rí wọn?’ Ká lè rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì yìí.
5. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé nípa ìṣúra tẹ̀mí?
5 Àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè ni Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ yẹn sí. Ó sọ fún wọn pé, òun ń làkàkà nítorí wọn ká ‘lè tu ọkàn-àyà wọn nínú àti pé ká lè so wọ́n pọ̀ ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́.’ (Ka Kólósè 2:1, 2.) Kí nìdí tó fi ń ṣàníyàn? Ó ṣe kedere pé, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn ará tó wà nílùú Kólósè tó ń gbé ìmọ̀ ọgbọ́n orí ilẹ̀ Gíríìsì lárugẹ tàbí tí wọ́n ń sọ pé kí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í pa Òfin Mósè mọ́ lè ti nípa lórí àwọn ará yòókù. Ó wá fún àwọn ará ní ìkìlọ̀ tó lágbára yìí pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kól. 2:8.
6. Kí nìdí to fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù?
6 Lóde òní, àwa náà máa ń dojú kọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ Sátánì àti ètò rẹ̀. Ìmọ̀ ọgbọ́n orí, tó fi mọ́ èrò táwọn èèyàn gbà pé ó tọ̀nà àti ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ló ń darí ìrònú, ìwà, ọ̀nà ìgbésí ayé àtohun táwọn èèyàn ń lépa. Ìsìn èké tún ń kó ipa tó pọ̀ jù nínú ọ̀pọ̀ ayẹyẹ ọdọọdún. Àwọn ohun tí wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n, eré orí ìtàgé, orin àtàwọn eré ìnàjú míì máa ń gbé ìfẹ́ ti ara lárugẹ, bákan náà ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń jáde lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì jẹ́ ewu fún tàgbàtèwe. Tá a bá ń rí àwọn nǹkan yìí àtàwọn àṣà ayé míì nígbà gbogbo, ó lè nípa lórí ìrònú wa àti ìṣesí wa sí ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń pèsè, ká sì wá tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tí kò di ìyè tòótọ́ mú gírígírí mọ́. (Ka 1 Tímótì 6:17-19.) Ní kedere, a ní láti mọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ká sì fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò tá ò bá fẹ́ kó sínú pàkúté Sátánì.
7. Ohun méjì wo ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó máa ran àwọn ará Kólósè lọ́wọ́?
7 Tá a bá tún ronú lórí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Kólósè, àá rí i pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó wá sọ ohun méjì tó lè tù wọ́n nínú, táá sì jẹ́ kí wọ́n wà níṣọ̀kan nínú ìfẹ́. Lákọ̀ọ́kọ́, ó sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú òye wọn.” Ó gbọ́dọ̀ dá wọn lójú pé òye tó tọ̀nà làwọ́n ní nípa Ìwé Mímọ́, kí ìgbàgbọ́ wọn bàa lè fìdí múlẹ̀ gbọin. (Héb. 11:1) Lẹ́yìn náà, ó sọ̀rọ̀ nípa “ìmọ̀ pípéye nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ Ọlọ́run.” Wọ́n ní láti jẹ́ kí òye wọn kọjá ohun téèyàn máa ń kọ́kọ́ mọ̀ nínú ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ ní òye tó ṣe kedere nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run. (Héb. 5:13, 14) Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn tó dáa lèyí jẹ́ fáwọn ará Kólósè àtàwa náà lóde òní! Nígbà náà, báwo la ṣe lè ní irú ìdánilójú àti ìmọ̀ pípéye bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jésù Kristi pé: “Inú rẹ̀ ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí,” jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe.
Àwọn Ìṣúra Tá A Fi ‘Pa Mọ́ Sínú’ Kristi
8. Ṣàlàyé ohun tí ọ̀rọ̀ náà, fi ‘pa mọ́ sínú’ Kristi túmọ̀ sí.
8 Tá a bá sọ pé gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ìmọ̀ la fi ‘pa mọ́ sínú’ Kristi, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó wà níbi tọ́wọ́ ẹnikẹ́ni kò ti lè tó o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé, ká tó lè rí ìṣúra yìí, a gbọ́dọ̀ sapá gan-an, ká sì darí àfiyèsí wa sọ́dọ̀ Jésù Kristi. Èyí bá ohun tí Jésù sọ nípa ara rẹ̀ mu pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòh. 14:6) Torí náà, ká tó lè ní ìmọ̀ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ gba ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà tí Jésù ń pèsè.
9. Ipò wo ni Ọlọ́run fi Jésù sí?
9 Yàtọ̀ sí pé Jésù ni “ọ̀nà,” ó tún sọ pé òun ni “òtítọ́ àti ìyè.” Èyí fi hàn pé ipa tó kó ju pé ó kàn jẹ́ ọ̀nà tá a lè gbà dé ọ̀dọ̀ Bàbá. Jésù tún kó ipa pàtàkì nínú bá a ṣe lè dẹni tó lóye òtítọ́ Bíbélì àti bá a ṣe lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ká sòótọ́, àwọn ìṣúra tẹ̀mí tí kò láfiwé la fi pa mọ́ sínú Jésù, èyí tó wà nípamọ́ fún àwọn tó ń fẹ̀sọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti ṣàwárí. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìṣúra yìí, tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwàláàyè wa ọjọ́ iwájú àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run.
10. Kí la lè kọ́ nípa Jésù látinú Kólósè 1:19 àti 2:9?
10 “Nínú rẹ̀ ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ànímọ́ Ọlọ́run ń gbé gẹ́gẹ́ bí ara kan.” (Kól. 1:19; 2:9) Torí pé Jésù ti gbé lọ́run pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe ju bí ẹnikẹ́ni ṣe lè mọ̀ ọ́n lọ. Ní gbogbo àkókò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí Baba rẹ̀ kọ́ ọ, ó sì lo àwọn ànímọ́ tí Baba rẹ̀ kọ́ ọ nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lè sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòh. 14:9) Gbogbo ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run ló wà nípamọ́ tàbí ká sọ pé ó ń gbé inú Kristi, kò sì sí ọ̀nà tá a lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, bí kò ṣe nípa fífara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ gbogbo ohun tá a bá lè kọ́ nípa Jésù.
11. Ìsopọ̀ wo ló wà láàárín Jésù àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?
11 “Jíjẹ́rìí Jésù ni ohun tí ń mí sí ìsọtẹ́lẹ̀.” (Ìṣí. 19:10) Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé Jésù ni òpómúléró nínú mímú kí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì nímùúṣẹ. Ìgbà tá a bá mọ ipa tí Jésù kó nínú Ìjọba Mèsáyà nìkan la máa tó lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì lọ́nà tó péye, bẹ̀rẹ̀ látorí àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, títí dórí àwọn ìran alásọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣípayá. Èyí jẹ́ ká mọ ìdí tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fi rú àwọn tí kò gbà pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí lójú. Ó tún jẹ́ ká mọ ìdí tí àwọn tí kò mọyì Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, èyí tó ní ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà nínú, fi ka Jésù sí ọkùnrin kan tó kàn ṣàrà ọ̀tọ̀ ṣá. Ìmọ̀ nípa Jésù ń jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run mọ ìtúmọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí kò tíì nímùúṣẹ.—2 Kọ́r. 1:20.
12, 13. (a) Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé”? (b) Lẹ́yìn táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ti kúrò nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí, iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wo ni wọ́n ní?
12 “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Ka Jòhánù 8:12; 9:5.) Tipẹ́tipẹ́ kí wọ́n tó bí Jésù, wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ní ti àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ibú òjìji, àní ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.” (Aísá. 9:2) Àpọ́sítélì Mátíù sọ pé Jésù mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó wá ní: “Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mát. 4:16, 17) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù jẹ́ káwọn èèyàn lóye òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì rí ìtúsílẹ̀ gbà kúrò ní oko ẹrú àwọn ẹ̀kọ́ èké. Jésù sọ pé: “Èmi ti wá gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ sínú ayé, kí olúkúlùkù ẹni tí ń ní ìgbàgbọ́ nínú mi má bàa wà nínú òkùnkùn.”—Jòh. 1:3-5; 12:46.
13 Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Nítorí pé ẹ jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ìmọ́lẹ̀ nísinsìnyí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa. Ẹ máa bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.” (Éfé. 5:8) Torí pé àwọn Kristẹni ti kúrò nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí, àìgbọ́dọ̀máṣe ló jẹ́ fún wọn láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀. Èyí bá ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú Ìwàásù Orí Òkè mu, nígbà tó sọ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 5:16) Ǹjẹ́ ìwọ náà mọrírì ìṣúra tẹ̀mí tó o ti rí nínú Jésù, débi tí wàá fi lè sọ nípa rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ àti nípa ìwà Kristẹni tó ò ń hù?
14, 15. (a) Báwo ni wọ́n ṣe lo àgùntàn àtàwọn ẹran míì nínú ìjọsìn tòótọ́ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì? (b) Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ ìṣúra tí kò láfiwé nínú ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run”?
14 Jésù ni “ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run.” (Jòh. 1:29, 36) Nínú Bíbélì látòkèdélẹ̀, àgùntàn ṣe pàtàkì gan-an téèyàn bá fẹ́ rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà àti téèyàn bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Ábúráhámù ti fi hàn pé òun ṣe tán láti fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ, ó gbọ́ ohùn kan tó sọ pé kò gbọ́dọ̀ pa ọmọ náà, Ọlọ́run wá pèsè àgbò kan, ìyẹn akọ àgùntàn, láti fi rọ́pò rẹ̀. (Jẹ́n. 22:12, 13) Nígbà ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nílẹ̀ Íjíbítì, àgùntàn tún wúlò gan-an, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, “Ìrékọjá Jèhófà” ni wọ́n fi ṣe. (Ẹ́kís. 12:1-13) Bákan náà, Òfin Mósè fàyè gba fífi onírúurú ẹran, títí kan àgùntàn àti ewúrẹ́ rúbọ.—Ẹ́kís. 29:38-42; Léf. 5:6, 7.
15 Kò sí èyíkéyìí lára àwọn ẹbọ wọ̀nyẹn téèyàn rú tó lè mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú títí láé. (Héb. 10:1-4) Àmọ́, Jésù ni “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” Òtítọ́ yìí nìkan sọ Jésù di ìṣúra kan tó níye lórí ju ìṣúra tara èyíkéyìí téèyàn lè rí lọ. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà, ká sì máa lo ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè àgbàyanu yẹn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa rí ìbùkún kíkọyọyọ àti èrè ńlá gbà, ìyẹn ògo àti ọlá wíwà pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run èyí tó wà fún “agbo kékeré” àti ìyè ayérayé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé fún àwọn “àgùntàn mìíràn.”—Lúùkù 12:32; Jòh. 6:40, 47; 10:16.
16, 17. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí “Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa”?
16 Jésù ni “Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa” (Ka Hébérù 12:1, 2.) Nínú ìwé Hébérù orí 11, a rí àsọyé tó wọni lọ́kàn lórí ìgbàgbọ́ tí Pọ́ọ̀lù sọ, èyí tó ní nínú ohun tí ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí àti orúkọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ìgbàgbọ́, àwọn bíi Nóà, Ábúráhámù, Sárà àti Ráhábù. Èyí ló mú kí Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù.” Kí nìdí?
17 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin olóòótọ́ tórúkọ wọn wà nínú ìwé Hébérù orí 11 ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, wọn ò mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa mú àwọn ìlérí wọ̀nyẹn ṣẹ nípasẹ̀ Mèsáyà àti Ìjọba rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn ò kún tó. Kódà àwọn tí Jèhófà lò láti kọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà kò mọ ìtúmọ̀ ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. (1 Pét. 1:10-12) Ipasẹ̀ Jésù nìkan la lè gbà sọ ìgbàgbọ́ di pípé tàbí sọ ọ́ di ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní òye kíkún, ká sì mọ ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí “Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa”!
Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Wíwá Kiri
18, 19. (a) Sọ àwọn ìṣúra tẹ̀mí míì tá a fi pa mọ́ sínú Kristi. (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bá a nìṣó ní wíwá ìṣúra tẹ̀mí nínú Jésù?
18 A ti gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ipa pàtàkì tí Jésù kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ láti gba aráyé là. Àmọ́, ó ṣì ku àwọn ìṣúra tẹ̀mí míì tá a fi pa mọ́ sínú Kristi. Inú wa á dùn tá a bá rí i, àǹfààní ló sì máa jẹ́ fún wa. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pétérù pe Jésù ní “Olórí Aṣojú ìyè” àti “ìràwọ̀ ojúmọ́” tó ń yọ. (Ìṣe 3:15; 5:31; 2 Pét. 1:19) Bákan náà, Bíbélì pe Jésù ní “Àmín.” (Ìṣí. 3:14) Ṣé o mọ ìtúmọ̀ àwọn ipò yìí àti ìjẹ́pàtàkì wọn? Jésù sọ pé, “ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí.”—Mát. 7:7.
19 Kò sí ẹlòmíì nínú ìtàn tí ìgbésí ayé rẹ̀ ní ìtúmọ̀, tó sì ní í ṣe pẹ̀lú ire wa ayérayé bíi Jésù. Inú rẹ̀ la ti lè rí àwọn ìṣúra tẹ̀mí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo àwọn tó bá ń fi tọkàntọkàn wá a. Àdúrà wa ni pé kó o rí ayọ̀ àti ìbùkún bó o ṣe ń wá àwọn ìṣúra tí ‘a rọra fi pa mọ́ sínú’ Kristi.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ìṣúra wo la rọ àwọn Kristẹni láti máa wá?
• Kí nìdí tí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Kólósè ṣì fi wúlò fún wa lóde òní?
• Sọ díẹ̀ lára àwọn ìṣúra tá a ‘fi pa mọ́’ sínú Kristi, kó o sì ṣàlàyé wọn.
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Bíbélì dà bí àwòrán atọ́nà tó ń darí wa sí ìṣúra tá a ‘rọra fi pa mọ́ sínú’ Kristi