Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Kọ́ni Pẹ̀lú Ìfẹ́
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Kọ́ni Pẹ̀lú Ìfẹ́
“Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.”—JÒH. 7:46.
1. Báwo ni ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni ṣe rí lára àwọn èèyàn?
FOJÚ inú wo bí ayọ̀ ẹ á ṣe pọ̀ tó ká sọ pé o fetí ara ẹ gbọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Jésù! Bíbélì sọ bí ọ̀rọ̀ Jésù ṣe rí lára àwọn èèyàn tó bá sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ nípa àwọn ará ìlú Jésù pé ‘ẹnu bẹ̀rẹ̀ sí í yà wọ́n nítorí àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin tó ń jáde láti ẹnu rẹ̀.’ Nígbà tí Mátíù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó gbọ́ ìwàásù Jésù lórí òkè, ó ní “háà . . . ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” Jòhánù sọ pé, ńṣe làwọn ọmọ ogun tí wọ́n rán láti wá fàṣẹ ọba mú Jésù pa dà lọ́wọ́ òfo, tí wọ́n sì lọ jíṣẹ́ fáwọn tó rán wọn pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.”—Lúùkù 4:22; Mát. 7:28; Jòh. 7:46.
2. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà kọ́ni?
2 Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an làwọn ọmọ ogun yẹn sọ. Òótọ́ ni pé kò tíì sí Olùkọ́ tó dà bíi Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ̀kọ́ ẹ̀ kò lọ́jú pọ̀, ó rọrùn láti lóye, ó sì bọ́gbọ́n mu. Ó máa ń lo àwọn àpèjúwe àtàwọn ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́. Ó mọ bó ṣe lè jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ wọ onírúurú èèyàn lọ́kàn, yálà àwọn tó lẹ́nu láwùjọ tàbí gbáàtúù. Ẹ̀kọ́ ẹ̀ rọrùn láti lóye, síbẹ̀ kò lábùlà. Àmọ́, àwọn nǹkan yìí nìkan kọ́ ló sọ Jésù di Olùkọ́ tó ju gbogbo olùkọ́ lọ láyé.
Ìfẹ́ Ni Ànímọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ
3. Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, báwo ni Jésù ṣe yàtọ̀ sáwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀?
3 Kò sí àní-àní pé àwọn onílàákàyè tó ní ìmọ̀ tó sì mọ bá a ṣe ń kọ́ni wà láàárín àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí. Àmọ́, kí ló mú kí ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni yàtọ̀ sí ti wọn? Àwọn aṣáájú ìsìn nígbà yẹn ò nífẹ̀ẹ́ àwọn gbáàtúù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n tẹ́ńbẹ́lú wọn, tí wọ́n sì ń wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí “ẹni ègún.” (Jòh. 7:49) Àmọ́ ti Jésù yàtọ̀, àánú àwọn èèyàn ṣe é torí “a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Jésù kóni mọ́ra, ó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn, ó sì nínúure. Síwájú sí i, àwọn aṣáájú ìsìn yẹn ò ní ìfẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run. (Jòh. 5:42) Àmọ́, Jésù nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀, ó sì fẹ́ máa ṣe ohun tó wù ú. Àwọn aṣáájú ìsìn yẹn máa ń lọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run po láti tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn, àmọ́ Jésù nífẹ̀ẹ́ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” ó fi kọ́ni, ó ṣàlàyé ẹ̀, ó gbèjà ẹ̀, ó sì gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. (Lúùkù 11:28) Ìyẹn ló jẹ́ kí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn nínú ohun tó fi kọ́ni, bó ṣe bá àwọn èèyàn lò àti bó ṣe kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.
4, 5. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa kọ́ni pẹ̀lú ìfẹ́? (b) Tá a bá ń kọ́ni, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ ohun tá a fẹ́ kọ́ni àti bá a ṣe lè kọ́ni?
4 Àwa ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi, a fẹ́ láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti nínú ìgbésí ayé wa. (1 Pét. 2:21) Torí náà, bá a ṣe fẹ́ gbin ẹ̀kọ́ Bíbélì sáwọn èèyàn lọ́kàn nìkan kọ́ là ń wá, a tún fẹ́ máa fi àwọn ànímọ́ Jèhófà hàn, ní pàtàkì ìfẹ́. Yálà a ní ìmọ̀ tó pọ̀ tàbí díẹ̀, bóyá a mọ bá a ṣe lè kọ́ni dáadáa tàbí a ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ ọ́n, iṣẹ́ kékeré kọ́ ni ìfẹ́ tá a bá fi hàn sáwọn tá à ń wàásù fún máa ṣe láti jẹ́ kí ohun tá à ń sọ wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Tá a bá fẹ́ kọ́rọ̀ wa máa wọni lọ́kàn lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká máa kọ́ni pẹ̀lú ìfẹ́.
5 Téèyàn bá fẹ́ di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́, ó gbọ́dọ̀ mọ ohun tó fẹ́ kọ́ni, kó sì mọ bó ṣe lè kọ́ni lọ́nà táá fi wọni lọ́kàn. Jésù ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè ṣe àwọn nǹkan yìí. Bákan náà lónìí, Jèhófà ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun kan náà. (Ka Aísáyà 54:13; Lúùkù 12:42.) Síbẹ̀síbẹ̀, ó yẹ ká jẹ́ kí ohun tá à ń kọ́ni tọkàn wa wá, kó má jẹ́ ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán. Bá a bá mọ ohun tá a fẹ́ fi kọ́ni, tá a mọ bá a ṣe fẹ́ fi kọ́ni, tá a sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń kọ́, inú wa á dùn, ọ̀rọ̀ wa á sì yé àwọn tá à ń kọ́. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fìfẹ́ hàn nígbà tá a bá ń kọ́ni? Báwo ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe ṣe é? Ẹ jẹ́ ká gbé e yẹ̀ wò.
A Gbọ́dọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
6. Báwo la ṣe máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tá a fẹ́ràn?
6 Ó máa ń wù wá láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a fẹ́ràn. Nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a fẹ́ràn, àwọn èèyàn máa ń rí bí ayọ̀ wa àti ìtara wa ṣe pọ̀ tó. Àgàgà nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tá a fẹ́ràn. Ó máa ń yá wa lára láti sọ ohun tá a mọ̀ nípa ẹni náà fáwọn èèyàn. A máa ń yìn ín, a máa ń bọlá fún un, a sì máa ń gbèjà ẹ̀. À ń ṣe gbogbo èyí torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ onítọ̀hún, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ànímọ́ ẹ̀ bíi tiwa.
7. Kí ni ìfẹ́ tí Jésù ní fún Ọlọ́run ràn án lọ́wọ́ láti ṣe?
7 Ká tó lè mú káwọn èèyàn fẹ́ràn Jèhófà, àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n, ká sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó ṣe tán, ìfẹ́ fún Ọlọ́run ló ń mú kéèyàn ṣe ìsìn tòótọ́. (Mát. 22:36-38) Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ lórí èyí. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà, èrò inú, ọkàn àti okun ẹ̀. Torí pé Jésù ti gbé pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀run fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún, ó mọ̀ ọ́n láìkù síbì kan. Kí wá ni àbájáde èyí? Jésù sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” (Jòh. 14:31) Ìfẹ́ yẹn sì hàn nínú gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀. Òun ló ràn án lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run nígbà gbogbo. (Jòh. 8:29) Òun ló jẹ́ kó gégùn-ún fáwọn alágàbàgebè aṣáájú ìsìn tí wọ́n sọ pé Ọlọ́run làwọn ń ṣojú fún. Ó tún jẹ́ kó sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
8. Kí ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe?
8 Bíi ti Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, èyí sì jẹ́ kí wọ́n wàásù ìhìn rere náà pẹ̀lú ìgboyà àti ìtara. Láìka báwọn aṣáájú ìsìn ṣe ta kò wọ́n sí, wọ́n wàásù yíká gbogbo ìlú Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò lè ṣíwọ́ wíwàásù nípa àwọn ohun tí wọ́n ti rí àtàwọn ohun tí wọ́n ti gbọ́. (Ìṣe 4:20; 5:28) Ó dá wọn lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn, á sì bù kún àwọn, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́! Torí pé, kò tíì pé ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn ikú Jésù tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé àwọn ti wàásù ìhìn rere “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kól. 1:23.
9. Báwo la ṣe lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run lágbára sí i?
9 Tá a bá fẹ́ di olùkọ́ tí ọ̀rọ̀ ẹ̀ ń wọni lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ rí i pé à ń bá a nìṣó láti mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run lágbára sí i. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà. A tún ń mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run lágbára sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kíka àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì àti nípa lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni. Bí ìmọ̀ wa nípa Ọlọ́run bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tá a ní fún un ṣe máa pọ̀ sí i. Bá a sì ṣe ń fìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, àwọn èèyàn á máa rí i, èyí á sì fà wọ́n sún mọ́ Jèhófà.—Ka Sáàmù 104:33, 34.
A Gbọ́dọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Ohun Tá À Ń Kọ́ni
10. Kí ló ń sọni di olùkọ́ tó dáńgájíá?
10 Ohun tó ń sọ ẹnì kan di olùkọ́ tó dáńgájíá ni pé kó nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́ni. Ó gbọ́dọ̀ gbà pé òótọ́ lòun ń kọ́ni, pé ó ṣe pàtàkì, ó sì ṣeyebíye. Tí olùkọ́ bá fọwọ́ pàtàkì mú ohun tó ń kọ́ni, àwọn èèyàn á rí i nínú bó ṣe ń fìtara sọ̀rọ̀, èyí sì máa ń nípa tó dáa lórí àwọn tó ń kọ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí olùkọ́ kan ò bá mọyì ohun tóun fúnra ẹ̀ ń kọ́ni, báwo ló ṣe máa retí pé káwọn tó ń kọ́ fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan ọ̀hún? Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ipa kékeré kọ́ ni àpẹẹrẹ rẹ máa ní lórí àwọn èèyàn. Jésù sọ pé: “Gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.”—Lúùkù 6:40.
11. Kí nìdí tí Jésù fi nífẹ̀ẹ́ ohun tó fi kọ́ni?
11 Jésù nífẹ̀ẹ́ ohun tó fi kọ́ni? Ó mọ̀ pé òun ní ohun iyebíye tó yẹ káwọn èèyàn mọ̀, ìyẹn òtítọ́ nípa Baba rẹ̀ ọ̀run, tó jẹ́ “àsọjáde Ọlọ́run” àti “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:34; 6:68) Bí ìmọ́lẹ̀ tó lágbára, òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ni tú àṣírí ohun tí kò dáa, ó sì tànmọ́lẹ̀ sí ohun rere. Èyí mú ìtùnú àti ìrètí bá àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn táwọn aṣáájú ìsìn èké ti ṣì lọ́nà, tí Èṣù sì ń pọ́n lójú. (Ìṣe 10:38) Kì í ṣe nínú ohun tí Jésù kọ́ni nìkan ni ìfẹ́ tó ní sí òtítọ́ ti fara hàn, ó tún hàn nínú gbogbo ohun tó ṣe.
12. Báwo ni kíkéde ìhìn rere ṣe rí lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù?
12 Bíi ti Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ nípa Jèhófà àti Kristi, wọ́n sì mọyì ẹ̀ débi pé àwọn alátakò ò lè dá wọn dúró wíwàásù nípa rẹ̀ fáwọn èèyàn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù pé: “Ìháragàgà wà ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láti polongo ìhìn rere . . . Nítorí èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́.” (Róòmù 1:15, 16) Pọ́ọ̀lù kà á sí ohun iyì láti polongo òtítọ́. Ó kọ̀wé pé: “Èmi, . . . ni a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí fún, pé kí n polongo ìhìn rere nípa àwọn ọrọ̀ tí kò ṣeé díwọ̀n ti Kristi fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Éfé. 3:8) Kò ṣòro rárá láti fojú inú wo bí ìtara Pọ́ọ̀lù á ṣe pọ̀ tó nígbà tó ń kọ́ni nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe.
13. Àwọn ìdí wo ló wà tó fí yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ìhìn rere?
13 Ìhìn rere tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló jẹ́ ká mọ Ẹlẹ́dàá, tó sì jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Ìhìn rere yìí fún wa láwọn ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé, ó sì lágbára láti yí ìgbésí ayé wa pa dà, láti fún wa nírètí àti láti fún wa lókun lákòókò ìṣòro. Síwájú sí i, ó fọ̀nà ìgbésí ayé tó nítumọ̀ tí kò sì ní lópin hàn wá. Kò sí ìmọ̀ tó ṣeyebíye tàbí tó ṣe pàtàkì ju ìhìn rere lọ. Ẹ̀bùn tí kò ṣe é díye lé tó ń fúnni láyọ̀ tó ga tí Ọlọ́run fún wa ló jẹ́. Ayọ̀ wa tún máa ń pọ̀ sí i tá a bá sọ nípa ẹ̀bùn yìí fáwọn èèyàn.—Ìṣe 20:35.
14. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún ohun tá à ń kọ́ni lágbára sí i?
14 Kí lo lè ṣe láti mú kí ìfẹ́ tó o ní fún ìhìn rere pọ̀ sí i? Bó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, máa dánu dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kó o bàa lè ronú lórí ohun tó o kà. Bí àpẹẹrẹ, fojú inú wò ó pé o wà pẹ̀lú Jésù nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé tàbí pé ò ń bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò. Fojú inú wò ó pé o wà nínú ayé tuntun, kó o sì fojú inú wo bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà náà. Fojú inú wo àwọn ìbùkún tó o ti ní torí bó o ṣe ń ṣègbọràn sí ìhìn rere. Tó o bá jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún ìhìn rere lágbára, àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ á rí i. Torí náà, ó yẹ ká máa fara balẹ̀ ronú lórí ohun tá a ti kọ́, ká sì máa fiyè sí ohun tá à ń kọ́ni.—Ka 1 Tímótì 4:15, 16.
A Gbọ́dọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn
15. Kí nìdí tó fi yẹ kí olùkọ́ nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?
15 Olùkọ́ tó mọ bá a ṣe ń kọ́ni máa ń jẹ́ kára tu àwọn tó ń kọ́, kí wọ́n bàa lè fọkàn sí ẹ̀kọ́ náà, kí wọ́n sì lè lóhùn sí i. Olùkọ́ tó nífẹ̀ẹ́ ẹni máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ torí pé ó bìkítà. Ó máa ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ẹ̀ dá lórí ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ níbàámu pẹ̀lú òye wọn. Ó mọ ibi tí agbára àwọn tó ń kọ́ mọ àti ipò tó yí wọn ká. Tí olùkọ́ bá nírú ìfẹ́ yìí, àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ á mọ̀, èyí á sì jẹ́ kí ẹ̀kọ́ náà gbádùn mọ́ olùkọ́ àtàwọn tó ń kọ́.
16. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn?
16 Jésù fi irú ìfẹ́ yìí hàn. Ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jésù gbà fìfẹ́ hàn ni bó ṣe yọ̀ǹda ìwàláàyè pípé rẹ̀ káwọn èèyàn bàa lè rí ìgbàlà. (Jòh. 15:13) Lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, gbogbo ìgbà ló máa ń múra tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kó sì kọ́ wọn nípa Baba rẹ̀. Dípò kó jókòó pé káwọn èèyàn wá bá òun, ńṣe ló máa ń fẹsẹ̀ rìnrìn àjò ọ̀nà tó jìn kó bàa lè lọ wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. (Mát. 4:23-25; Lúùkù 8:1) Ó ní sùúrù, ó sì lóye àwọn èèyàn. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nílò pé kó tún ojú ìwòye wọn ṣe, ó ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. (Máàkù 9:33-37) Ó fún wọn níṣìírí bó ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé wọ́n máa di oníwàásù ìhìn rere tó dáńgájíá. Kò tíì sí olùkọ́ tó nífẹ̀ẹ́ ẹni bíi Jésù láyé. Ìfẹ́ tó ní sáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ jẹ́ káwọn náà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ó sì jẹ́ kí wọ́n pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.—Ka Jòhánù 14:15.
17. Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn?
17 Bíi ti Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sáwọn èèyàn tí wọ́n wàásù fún. Wọ́n fara da àtakò, wọ́n sì fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n bàa lè wàásù ìhìn rere, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn sì kẹ́sẹ járí. Ìfẹ́ tí wọ́n ní sáwọn tí wọ́n wàásù fún yìí mà ga o! Àwọn ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ wọni lọ́kàn gan-an, ó ní: “Àwa di ẹni pẹ̀lẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀. Nítorí náà, ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.”—1 Tẹs. 2:7, 8.
18, 19. (a) Kí nìdí tá a fi ń yọ̀ǹda ara wa tinútinú ká lè máa ṣiṣẹ́ ìwàásù? (b) Sọ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé àwọn èèyàn ń kíyè sí ìfẹ́ tá à ń fi hàn.
18 Bákan náà, lákòókò tiwa yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù kárí ayé láti wá àwọn tó fẹ́ mọ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń fẹ́ sìn ín. Ohun tó ju bílíọ̀nù kan wákàtí lọ là ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lọ́dọọdún láti ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sẹ́yìn, iṣẹ́ náà sì ń bá a nìṣó. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù gba pé ká yááfì àkókò, okun àti ohun ìní wa, tinútinú la fi ń ṣe é. Bíi ti Jésù, àwa náà mọ̀ pé ìfẹ́ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ni pé káwọn èèyàn ní ìmọ̀ tó máa jẹ́ kí wọ́n ní ìyè ayérayé. (Jòh. 17:3; 1 Tím. 2:3, 4) Ìfẹ́ ló ń jẹ́ ká ran àwọn tó mọyì òtítọ́ lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bíi tiwa.
19 Àwọn èèyàn ń kíyè sí ìfẹ́ tá à ń fi hàn. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà máa ń kọ lẹ́tà ìtùnú sáwọn téèyàn wọn bá ṣaláìsí. Ọkùnrin kan kọ̀wé sí arábìnrin yìí pé: “Ẹnú kọ́kọ́ yà mí pé ẹnì kan lè ṣe ohun tó tóyẹn láti kọ lẹ́tà sẹ́nì tí kò mọ̀ rí kó bàa lè ràn án lọ́wọ́ láti fara da ipò tó nira bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo kàn lè sọ ni pé, o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn àti Ọlọ́run tó ń tọ́ èèyàn sọ́nà nígbèésí ayé.”
20. Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tìfẹ́tìfẹ́?
20 Ọkùnrin kan sọ pé, béèyàn bá nífẹ̀ẹ́ ohun tó fẹ́ ṣe tó sì lóye bó ṣe máa ṣe é, á ṣàṣeyọrí. Nígbà tá a bá ń kọ́ni, a máa ń sapá láti ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn. Tá a bá fẹ́ di olùkọ́ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń wọni lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ká sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Bá a ṣe ń mú irú ìfẹ́ yìí dàgbà, tá a sì ń fi hàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kì í ṣe ayọ̀ tó wà nínú fífúnni nìkan la máa ní, ọkàn wa á tún balẹ̀ pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àti pé à ń múnú Jèhófà dùn.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn ní ìhìn rere, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká . . .
nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
nífẹ̀ẹ́ ohun tá à ń kọ́ni?
nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Kí ló mú kí ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni yàtọ̀ sí tàwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kíkọ́ni lọ́nà tó yanjú gba pé kéèyàn ní ìmọ̀, kó mọ bó ṣe fẹ́ kọ́ni, èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé kó nífẹ̀ẹ́