Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn Rẹ Pínyà ní “Ọjọ́ Ìhìn Rere” Yìí
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn Rẹ Pínyà ní “Ọjọ́ Ìhìn Rere” Yìí
ÀWỌN adẹ́tẹ̀ mẹ́rin kan wà lẹ́nu ibodè ìlú tí wọn ò sì rẹ́ni ta wọ́n lọ́rẹ. Àwọn ọmọ ogun Síríà tó sàga ti Samáríà kò jẹ́ kí oúnjẹ wọ̀lú. Ni àwọn adẹ́tẹ̀ bá tún èrò wọn pa, wọ́n rò ó pé kò mọ́gbọ́n dání fáwọn láti wọnú ìlú lọ, torí pé oúnjẹ ti gbówó lórí. Kódà ó tiẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan ti pa èèyàn jẹ.—2 Ọba 6:24-29.
Àwọn adẹ́tẹ̀ náà dà á rò pé, ‘Kí ló dé tá ò kúkú gba ibùdó àwọn ará Síríà lọ? A lọ o, a ò lọ o, kò sí ìyàtọ̀ kankan.’ Torí náà nígbà tí ilẹ̀ ṣú, wọ́n fi òkùnkùn bojú, wọ́n wọnú ibùdó àwọn ọmọ ogun Síríà lọ. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, gbogbo ibẹ̀ dákẹ́ minimini. Kò sí ẹ̀ṣọ́ kankan. Àwọn ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wà lórí ìso, àmọ́ wọn ò rí ọmọ ogun kankan. Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yọjú wonú àgọ́ kan. Wọn ò réèyàn, àmọ́ oúnjẹ àtohun mímu wà nílẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu. Àwọn ọmọ ogun ti fi ibùdó náà sílẹ̀ pátápátá. Ohun tó fà á ni pé Jèhófà ṣiṣẹ́ ìyanu kan, ó jẹ́ káwọn ọmọ ogun Síríà gbọ́ ìró àwọn ẹgbẹ́ ológun míì. Wọ́n sì gbà pé àwọn ọmọ ogun kan ló fẹ́ wá gbéjà ko àwọn, ni wọ́n bá fẹsẹ̀ fẹ. Wọ́n fi gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ wọn sílẹ̀. Wọn ò kọ̀ kí ẹlòmíì wá palẹ̀ wọn mọ́. Ni àwọn adẹ́tẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ tí wọ́n sì mu. Wọ́n tún rí wúrà, fàdákà, ẹ̀wù àtàwọn nǹkan iyebíye míì. Wọ́n lọ kó wọn pa mọ́, wọ́n sì tún pa dà wá kó sí i.
Àwọn adẹ́tẹ̀ náà ń kó àwọn nǹkan iyebíye tí wọ́n rí níbẹ̀ pa mọ́. Àmọ́, bí wọ́n ṣe rántí pé ìyàn ń pa àwọn ará Samáríà lọ, ẹ̀rí ọ̀kan wọn bẹ̀rẹ̀ sí í dà wọ́n láàmú. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara wọn pé: “Ohun tí a ń ṣe kò tọ́. Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìhìn rere!” Bí àwọn adẹ́tẹ̀ náà ṣe yára pa dà sí Samáríà nìyẹn, wọ́n sì lọ sọ ìhìn rere ohun tí wọ́n rí.—2 Ọba 7:1-11.
Àkókò tá a lè pè ní “ọjọ́ ìhìn rere” làwa náà wà yìí. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa “àmì . . . ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mát. 24:3, 14) Ipa wo ló yẹ kí èyí ní lórí wa?
Àníyàn Ṣíṣe Lè Dẹrù Pa Wá
Ohun táwọn adẹ́tẹ̀ yẹn rí mú kí ayọ̀ wọn pọ̀ débi tí wọ́n fi kọ́kọ́ gbàgbé àwọn ará Samáríà. Ohun tó máa jẹ́ tiwọn ni wọ́n gbájú mọ́. Ṣé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sáwa náà? “Àìtó oúnjẹ” wà lára àwọn àmì ìparí ètò àwọn nǹkan. (Lúùkù 21:7, 11) Àmọ́, Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé.” (Lúùkù 21:34) Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa jẹ́ kí àníyàn ìgbésí ayé mú ká gbàgbé pé “ọjọ́ ìhìn rere” la wà yìí.
Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Blessing kò jẹ́ kí àníyàn nípa ohun tó nílò dẹrù pa á. Ó ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ dé ìwọ̀n àyè kan, nígbà tó sì yá, ó fẹ́ arákùnrin kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, òun náà sì di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti orílẹ̀-èdè Benin. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ olùtọ́jú ilé ni mò ń ṣe, mo sì ń gbádùn iṣẹ́ mi.” Nígbà tí Blessing bá wo ọdún méjìlá tó ti fi ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, inú ẹ̀ máa ń dùn pé òun ò gbàgbé pé “ọjọ́ ìhìn rere” la wà yìí.
Ṣọ́ra fún Ìpínyà Ọkàn Tó Ń Gba Àkókò Ẹni
Nígbà tí Jésù fẹ́ rán àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn jáde, ó sọ fún wọn pé: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kéré níye. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Lúùkù 10:2) Béèyàn ò bá jára mọ́ṣẹ́ nígbà ìkórè, ó lè mú kéèyàn pàdánù irè oko, bákan náà, béèyàn ò bá jára mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ọ̀pọ̀ èèyàn lè pàdánù ẹ̀mí wọn. Torí náà Jésù fi kún un pé: “Ẹ má sì gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra nínú ìkíni ní ojú ọ̀nà.” (Lúùkù 10:4) Ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí “ìkíni” nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn kọjá kéèyàn kàn ṣe “ẹ ǹlẹ́ ńbẹ̀ yẹn o” tàbí “ẹ kú déédéé ìwòyí o.” Ó tún kan gbígbáni mọ́ra àti pípẹ́ lórí ìtàkúrọ̀sọ, tó sábàá máa ń wáyé nígbà tí ọ̀rẹ́ méjì bá pàdé. Ohun tí Jésù fìyẹn sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n má gbà káwọn nǹkan tí kò pọn dandan máa pín ọ̀kan wọn níyà, kó má bàa di pé wọ́n ń fàkókò ṣòfò. Èyí fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù wọn gba kánjúkánjú.
Ronú lórí iye àkókò tá a máa fi ṣòfò tá a bá fàyè gba ìpínyà ọkàn. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni wíwo tẹlifíṣọ̀n ti dohun tó ń fàkókò èèyàn ṣòfò jù lọ níbi púpọ̀. Tẹlifóònù alágbèéká àti kọ̀ǹpútà ńkọ́? Wọ́n ṣèwádìí kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láàárín àwọn ẹgbẹ̀rún èèyàn tí kì í ṣe ọ̀dọ́. Ìwádìí náà fi hàn pé “ní àròpọ̀ gbogbo rẹ̀, ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ̀ọ̀kan máa ń fi wákàtí kan àti ìṣẹ́jú méjìdínlọ́gbọ̀n sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù inú ilé lójúmọ́, wọ́n máa ń fi wákàtí kan àti ìṣẹ́jú méjì sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù alágbèéká, ìṣẹ́jú mẹ́tàléláàádọ́ta [53] ni wọ́n fi ń kọ lẹ́tà sáwọn èèyàn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tí wọ́n á sì lo ìṣẹ́jú méjìlélógún [22] lẹ́nu fífi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ nípasẹ̀ tẹlifóònù alágbèéká.” Àròpọ̀ iye àkókò tí wọ́n ń lò lóòjọ́ yìí pọ̀ débi pé ó ju ìlọ́po méjì ohun tá a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóòjọ́ lọ! Báwo ni àkókò tí ìwọ́ náà ń lò lórí àwọn nǹkan yìí ṣe pọ̀ tó?
Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Ernst àti Hildegard Seliger máa ń fiyè sí bí wọ́n ṣe ń lo àkókò wọn. Lápapọ̀, àwọn méjèèjì lo ohun tó ju ogójì ọdún lọ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì àti lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ìjọba Kọ́múníìsì. Lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, àwọn méjèèjì ṣe aṣáájú-ọ̀nà títí tí wọ́n fi parí ìṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé.
Ọ̀pọ̀ ló ń fẹ́ káwọn pẹ̀lú Arákùnrin àti Arábìnrin Seliger jọ máa kọ̀wé síra. Àwọn tọkọtaya yìí, ì bá ti máa lo àkókò wọn lórí kíkọ lẹ́tà àti kíka lẹ́tà. Àmọ́, nǹkan tẹ̀mí ni wọ́n fi sípò kìíní láyé wọn.
Kò sí àní-àní pé gbogbo wa ló wù pé káwa pẹ̀lú ẹbí àtọ̀rẹ́ wa jọ máa gbúròó ara wa, kò sì sóhun tó burú níbẹ̀. Àǹfààní wà nínú kéèyàn máa ṣe oríṣiríṣi nǹkan tó mọ́gbọ́n dání lójoojúmọ́. Síbẹ̀ náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká kíyè sára ká má gbà káwọn ohun tó ń gba àkókò ẹni pín ọkàn wa níyà láwọn ọjọ́ tó yẹ ká máa wàásù ìhìn rere yìí.
Wàásù Ìhìn Rere Náà Kúnnákúnná
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti wà láàyè láwọn “ọjọ́ ìhìn rere” yìí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn wa kúrò lorí ohun tó yẹ ká ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọkàn àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́rin yẹn ṣe kọ́kọ́ kúrò lórí ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Ẹ rántí pé wọ́n wá sọ pé: “Ohun tí a ń ṣe kò tọ́.” Bákàn náà, kò tọ́ káwa náà jẹ́ kí àníyàn lórí ohun tá a nílò àtàwọn ìpínyà ọkàn tó ń gba àkókò ẹni dí wa lọ́wọ́ débi tá ò fi ní máa kópa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù.
Àpẹẹrẹ kan tó ta yọ tá a lè tẹ̀ lé lórí ọ̀ràn yìí ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ogún ọdún àkọ́kọ́ tó lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó ní: “Mo ti wàásù ìhìn rere nípa Kristi kúnnákúnná.” (Róòmù 15:19) Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí ohunkóhun paná ìtara òun. Ẹ jẹ́ káwa náà máa lo ìtara bíi tiẹ̀ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní “ọjọ́ ìhìn rere” yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Blessing ò jẹ́ kí àníyàn nípa nǹkan tó nílò dí i lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Arákùnrin àti Arábìnrin Seliger máa ń kíyè sára nípa bí wọ́n ṣe ń lo àkókò wọn