Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Tó O Ní Fáwọn Ará Máa Pọ̀ Sí I
Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Tó O Ní Fáwọn Ará Máa Pọ̀ Sí I
“Ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ yín.”—ÉFÉ. 5:2.
1. Kí ni àmì pàtàkì tí Jésù sọ pé wọ́n á fi máa dá àwa ọmọlẹ́yìn òun mọ̀?
WÍWÀÁSÙ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láti ilé dé ilé jẹ́ ohun kan táwọn èèyàn fi ń dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀. Àmọ́, Kristi Jésù sọ ohun míì táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe, táwọn èèyàn á fi máa dá wa mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tòótọ́. Ó sọ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòh. 13:34, 35.
2, 3. Ipa wo ni ìfẹ́ ará tó wà láàárín wa máa ń ní lórí àwọn tó ń wá sí ìpàdé wa?
2 Ìfẹ́ tó wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni kò lẹ́gbẹ́. Bí ìgbà tí irin tútù, ìyẹn mágínẹ́ẹ̀tì bá fa irin mọ́ra wọn ni ìfẹ́ ṣe máa ń so àwọn èèyàn Jèhófà pọ̀ ní ìṣọ̀kan, ó sì máa ń fa àwọn olóòótọ́ èèyàn wá sínú ìjọsìn tòótọ́. Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Marcelino, ní orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Ìjàǹbá kan ṣẹlẹ̀ níbi iṣẹ́ ọkùnrin náà tó mú kí ojú rẹ̀ ọ̀tún fọ́. Lẹ́yìn ìjàǹbá yẹn, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ́ kiri pé torí pé ó jẹ́ oṣó lojú ẹ̀ ṣe fọ́. Kàkà kí pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lọ àtàwọn ọmọ ìjọ yòókù tù ú nínú, ṣe ni wọ́n lé e kúrò nínú ìjọ wọn. Nígbà tí ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún un pé kó wá sí ìpàdé wọn, ó kọ̀. Kò tún fẹ́ lọ sí ibòmíì tí wọ́n tún ti máa lé e kúrò nínú ìjọ.
3 Nígbà tí Marcelino pàpà tẹ̀lé e lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ yà á lẹ́nu. Ńṣe ni wọ́n gbà á tọwọ́tẹsẹ̀, ó sì rí ìtùnú gba látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì tó gbọ́ níbẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé, ó ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìṣó, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2006. Ní báyìí, ó ti ń sọ̀rọ̀ Bíbélì fáwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àtàwọn aládùúgbò rẹ̀, ó sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mélòó kan. Marcelino fẹ́ káwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbádùn irú ìfẹ́ tóun náà ti gbádùn láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé ká “máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́” sọ́kàn?
4 Lóòótọ́, ìfẹ́ ará tó wà láàárín wa máa ń dùn mọ́ni, àmọ́ gbogbo wa la gbọ́dọ̀ sapá láti rí i pé iná ìfẹ́ yẹn kò jó rẹ̀yìn. Ronú nípa àwọn èèyàn tó ń yáná lọ́wọ́ alẹ́ nínú òtútù. Tí wọn ò bá ko iná yẹn, ó dájú pé ó máa kú. Bákan náà, iná ìfẹ́ tó wà láàárín àwa Kristẹni tòótọ́ yóò máa jó rẹ̀yìn tá ò bá máa koná mọ́ ọn. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ fún wa, ó ní: “Ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ yín, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún yín gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àti ẹbọ sí Ọlọ́run fún òórùn tí ń run dídùn.” (Éfé. 5:2) Ìbéèrè tá a fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí ni, Báwo ni mo ṣe lè máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́?
“Ẹ̀yin, Pẹ̀lú, Ẹ Gbòòrò Síwájú”
5, 6. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé kí wọ́n “gbòòrò síwájú”?
5 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “A ti la ẹnu wa sí yín, ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, ọkàn-àyà wa ti gbòòrò síwájú. Àyè kò há fún yín ní inú wa, ṣùgbọ́n àyè há fún yín ní inú ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ẹ̀yin fúnra yín. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí èrè iṣẹ́ ní ìdápadà—mo ń sọ̀rọ̀ bí ẹní ń bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀—ẹ̀yin, pẹ̀lú, ẹ gbòòrò síwájú.” (2 Kọ́r. 6:11-13) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n mú ìfẹ́ wọn gbòòrò sí i?
6 Ṣàgbéyẹ̀wò bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì yẹn ná. Ìgbà tí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni ń parí lọ ni Pọ́ọ̀lù wá sí ìlú Kọ́ríńtì. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ṣòro gan-an nígbà tí Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀, síbẹ̀ kò pa iṣẹ́ náà tì. Láìpẹ́ láìjìnnà, ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìlú yẹn gba ìhìn rere. “Ọdún kan àti oṣù mẹ́fà,” ni Pọ́ọ̀lù fi ń lo ara rẹ̀ láti máa kọ́ wọn nínú ìjọ tuntun náà tó sì ń fún wọn lókun. Ó ṣe kedere pé ó ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì. (Ìṣe 18:5, 6, 9-11) Kò sí ìdí kankan tí kò fi yẹ káwọn náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Àmọ́, àwọn kan nínú ìjọ yẹn fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó lè jẹ́ ohun tó fà á ni pé àwọn kan nínú wọn kò fẹ́ràn àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ tó sojú abẹ níkòó. (1 Kọ́r. 5:1-5; 6:1-10) Tàbí kó jẹ́ pé àwọn míì nínú wọn ń fetí sí ìbàjẹ́ Pọ́ọ̀lù tí ‘àwọn àpọ́sítélì adárarégèé’ ń ṣe. (2 Kọ́r. 11:5, 6) Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin òun ní ojúlówó ìfẹ́ sí òun. Torí náà, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n mú ìfẹ́ wọn “gbòòrò síwájú,” pé kí wọ́n sún mọ́ òun àtàwọn míì tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́.
7. Báwo la ṣe lè mú ìfẹ́ ará wa ‘gbòòrò sí i’?
7 Àwa ńkọ́? Báwo la ṣe lè mú ìfẹ́ ará wa ‘gbòòrò sí i’? Ó máa ń rọrùn fáwọn tí ọjọ́ orí wọn sún mọ́ra tàbí tí wọ́n jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà tàbí ọmọ ìlú kan náà láti máa bá ara wọn rìn. Bákan náà, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí irú eré ìnàjú kan náà sábà máa ń jọ rìn. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tó da àwa àtàwọn Kristẹni kan pọ̀ ti ń mú ká máa yẹra fáwọn míì, ó yẹ ká “gbòòrò síwájú.” Ó bọ́gbọ́n mu ká bi ara wa léèrè pé: ‘Ṣé ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń bá àwọn tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ dà wá pọ̀ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí kí n bá wọn ṣeré jáde? Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣé mo máa ń dọ́gbọ́n yẹra fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ wa, torí mo gbà pé ó yẹ kó pẹ́ díẹ̀ kí n tó sọ wọ́n di ọ̀rẹ́? Ǹjẹ́ tọmọdétàgbà nínú ìjọ ni mo máa ń kí?’
8, 9. Báwo ni ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà ní Róòmù 15:7 yóò ṣe mú ká máa kí ara wa lọ́nà tó máa mú ìfẹ́ ará tó wà láàárín wa gbilẹ̀?
8 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa kíkí ara wa, ohun tó máa jẹ́ ká lè máa fi ojú tó tọ́ wo àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà ni ọ̀rọ̀ kan tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Róòmù. (Ka Róòmù 15:7.) Ohun tí ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tá a pè ní “fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà” nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yẹn túmọ̀ sí ni pé “ká fi inú rere tàbí ẹ̀mí aájò àlejò gba ẹnì kan, ká gbà á sínú ẹgbẹ́ kan tàbí ká sọ ọ́ dọ̀rẹ́.” Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, tọwọ́tẹsẹ̀ ni ẹni tó bá lẹ́mìí àlejò ṣíṣe máa ń gba ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan lálejò, ó sì máa ń jẹ́ kó mọ̀ pé inú òun dùn láti rí i. Kristi ti tẹ́wọ́ gba àwa náà lọ́nà yẹn, Bíbélì sì rọ̀ wá pé káwa náà tẹ́wọ́ gba àwọn olùjọ́sìn bíi tiwa bí Kristi ṣe gbà wá.
9 Bá a ṣe ń kí àwọn ará wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti láwọn ibòmíì, a lè kíyè sí àwọn kan tó jẹ́ pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tá a ti rí wọn tàbí tá a ti jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn. A lè fi bí ìṣẹ́jú mélòó kan bá wọn sọ̀rọ̀. Tó bá di ìgbà ìpàdé míì, a tún lè ṣe ohun kan náà sí àwọn míì. Tá a bá fi máa ṣe bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀ẹ̀melòó kan, yóò ti ṣeé ṣe fún wa láti jíròrò pẹ̀lú gbogbo ará ìjọ wa, tí a ó sì gbádùn rẹ̀. Kò sídìí láti máa ṣèyọnu tá ò bá rí gbogbo wọn bá sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ kan náà. Kò yẹ ká rí ẹni tó máa bínú tí a ò bá rí i kí ní gbogbo ìpàdé.
10. Àǹfààní iyebíye wo ló wà fún gbogbo wa nínú ètò Jèhófà, báwo la sì ṣe lè lo àǹfààní yẹn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?
10 Ibi ìkíni ni títẹ́wọ́ gba àwọn èèyàn bí ọ̀rẹ́ ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Tá a bá tibẹ̀ yẹn bẹ̀rẹ̀, ó lè yọrí sí ìjíròrò alárinrin tó sì lè sọ wá dọ̀rẹ́ tá a jọ máa bá ara wa kalẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọ àgbègbè àtàwọn àpéjọ wa yòókù bá ń kí ara wọn, tí wọ́n ń sọ orúkọ ara wọn àti ibi tí wọ́n ti wá, tí wọ́n sì jọ ń sọ̀rọ̀, ó máa ń wù wọ́n kí ojú wọn tún ara rí. Bákan náà, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sábà máa ń di ọ̀rẹ́ torí pé wọ́n á ti rí àwọn ànímọ́ rere tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn ní nígbà tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Bó ṣe máa ń rí fáwọn tó lọ́wọ́ nínú ètò ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá náà nìyẹn. Ọ̀pọ̀ àǹfààní láti ní ọ̀rẹ́ tó máa bá wa kalẹ̀ ló wà nínú ètò Jèhófà. Tá a bá mú ìfẹ́ wa ‘gbòòrò sí i,’ èyí á jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ wa máa pọ̀ sí i, á sì tún mú kí ìfẹ́ tó so wa pọ̀ nínú ìjọsìn tòótọ́ máa lágbára sí i.
Máa Wáyè Fáwọn Èèyàn
11. Gẹ́gẹ́ bí Máàkù 10:13-16, ṣe fi hàn, àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀?
11 Gbogbo Kristẹni ló yẹ kó sapá láti jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́ bíi ti Jésù. Wo ohun tí Jésù ṣe nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò fẹ́ jẹ́ káwọn òbí mú àwọn ọmọ wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Jésù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun, nítorí ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.” (Máàkù 10:13-16) Ẹ ò rí bí inú àwọn èwe yẹn yóò ti dùn tó, pé Olùkọ́ Ńlá ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sáwọn, èyí tó jẹ́ kó ráyè gbọ́ tàwọn!
12. Àwọn ohun wo ló lè mú kó ṣòro fún wa láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?
12 Ó yẹ kí olúkúlùkù àwa Kristẹni bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mo máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ráyè rí mi, àbí ńṣe ni mo máa ṣe bíi pé ọwọ́ mi ti dí jù?’ Àwọn ohun kan wà tí kò burú láyè ara wọn, àmọ́ tó jẹ́ pé tá a bá ń ṣe wọ́n nígbà míì, wọ́n lè ṣèdíwọ́ fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a bá wà láàárín àwọn èèyàn, tó bá jẹ́ pé tẹlifóònù alágbèéká là ń gbájú mọ́ tàbí tó bá jẹ́ pé gbohùngbohùn kékeré tá à ń kì bọ etí máa ń wà létí wa ṣáá, wọ́n lè máa rò pé a ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni dá sí wa. Táwọn èèyàn bá sábà ń rí wa pé kọ̀ǹpútà àtẹ́lẹwọ́ la máa ń tẹjú mọ́, wọ́n lè gbà pé kò wù wá láti bá àwọn sọ̀rọ̀. Lóòótọ́, “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” wà o, àmọ́ ìgbà tá a bá wà láàárín àwọn èèyàn sábà máa ń jẹ́ “ìgbà sísọ̀rọ̀.” (Oníw. 3:7) Àwọn kan lè sọ pé, “ó tẹ́ mi lọ́rùn kí n dá wà,” tàbí pé, “kì í wù mí kí n máa sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àárọ̀.” Síbẹ̀, tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́, kódà láwọn ìgbà tó dà bíi pé kò wù wá láti sọ̀rọ̀, ó jẹ́ ẹ̀rí pé a ní ìfẹ́ tí “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́r. 13:5.
13. Irú ọwọ́ wo ni Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì fi máa mú àwọn ará?
13 Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́ pé kó máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo ará ìjọ. (Ka 1 Tímótì 5:1, 2.) Ó yẹ káwa náà máa ṣe àwọn ará wa tó jẹ́ àgbàlagbà bíi bàbá àti ìyá wa, ká sì máa ṣe àwọn tó kéré lọ́jọ́ orí bí ọmọ ìyá wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní sí èyíkéyìí nínú àwọn ará wa ọ̀wọ́n tó máa rò pé a ta òun nù bí àjèjì.
14. Àǹfààní wo ló wà nínú bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń gbéni ró?
14 Bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró, ńṣe là ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ máa sún mọ́ Ọlọ́run, kí ara wọn sì túbọ̀ máa yá gágá. Arákùnrin kan tó ń sìn ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sọ pé inú òun dùn bóun ṣe ń rántí báwọn kan tó ti pẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ṣe máa ń wáyè láti bá òun sọ̀rọ̀ déédéé nígbà tóun ṣẹ̀ṣẹ̀ dé Bẹ́tẹ́lì. Ó fi kún un pé, ọ̀rọ̀ tó ń fúnni níṣìírí tí wọ́n ń bá òun sọ jẹ́ kóun rí ara òun bí ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Nísinsìnyí, òun náà ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àgbààgbà yẹn nípa bó ṣe máa ń bá àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì sọ̀rọ̀.
Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Jẹ́ Ká Wá Àlàáfíà
15. Kí ló fi hàn pé èdèkòyédè lè wáyé láàárín wa?
15 Ó jọ bíi pé aáwọ̀ kan wáyé láàárín arábìnrin méjì kan tí wọ́n ń jẹ́ Yúódíà àti Síńtíkè nínú ìjọ Fílípì ìgbàanì, tó sì ṣòro láti yanjú. (Fílí. 4:2, 3) Bákan náà, ìgbà kan wà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà gbé ọ̀rọ̀ kan gbóná fún ara wọn débi táwọn èèyàn fi mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. (Ìṣe 15:37-39) Àwọn ìtàn yẹn fi hàn pé èdèkòyédè lè wáyé láàárín àwọn olùjọ́sìn Jèhófà. Síbẹ̀, Jèhófà pèsè ohun táá máa jẹ́ ká lè yanjú èdèkòyédè, tí àárín wa yóò fi lè pa dà gún régé. Àmọ́, ó ń retí ohun kan látọ̀dọ̀ wa.
16, 17. (a) Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó nínú yíyanjú aáwọ̀? (b) Báwo ni ọ̀nà tí Jékọ́bù gbà lọ bá Ísọ̀ ṣe fi hàn pé ìrẹ̀lẹ̀ ṣe pàtàkì?
16 Ká sọ pé ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ kan fẹ́ gbé ọkọ lọ sí ìrìn àjò kan. Ó dájú pé kẹ́ ẹ tó lè gbéra, o ní láti ki kọ́kọ́rọ́ bọ ẹnu ọkọ̀ yẹn kó o lè fi ṣí iná rẹ̀. Bí ọ̀ràn yíyanjú aáwọ̀ ṣe rí náà nìyẹn, kọ́kọ́rọ́ kan wà tẹ́ ẹ máa lò láti yanjú rẹ̀. Ìrẹ̀lẹ̀ ni kọ́kọ́rọ́ ọ̀hún. (Ka Jákọ́bù 4:10.) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ yẹn ló máa jẹ́ kí àwọn tí aáwọ̀ wà láàárín wọn tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì láti yanjú ọ̀ràn náà. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ kan tó fi hàn bẹ́ẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́.
17 Ìgbà kan wà tí Ísọ̀ di Jékọ́bù tó jẹ́ ìbejì rẹ̀ sínú, tó fẹ́ pa á torí pé Jékọ́bù gba ẹ̀tọ́ Ísọ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí. Lẹ́yìn ogún ọdún gbáko, àwọn méjèèjì tún wá fẹ́ pàdé ara wọn, “àyà sì fo Jékọ́bù gidigidi, ó sì ṣàníyàn.” Ó gbà pé kò sí ni kí Ísọ̀ má gbéjà ko òun. Ṣùgbọ́n, Jékọ́bù ṣe ohun kan tí Ísọ̀ kò retí pé ó lè ṣe. Bó ṣe ń sún mọ́ ọ̀dọ̀ Ísọ̀, ó “bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba mọ́lẹ̀.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Ísọ̀ sì sáré lọ pàdé rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbá a mọ́ra, ó sì gbórí lé e lọ́rùn, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n sì bú sẹ́kún.” Bó ṣe di pé kò sí ìjà kankan mọ́ nìyẹn. Ìkórìíra yòówù tí ì báà wà lọ́kàn Ísọ̀, ìrẹ̀lẹ̀ Jékọ́bù ti pẹ̀tù sọ́kàn rẹ̀.—Jẹ́n. 27:41; 32:3-8; 33:3, 4.
18, 19. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa fúnra wa kọ́kọ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ nígbà tí aáwọ̀ bá wáyé? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ tí ẹni tá a jọ ní aáwọ̀ kò bá kọ́kọ́ gbà kí ọ̀ràn náà yanjú?
18 Àwọn ìmọ̀ràn tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn wà nínú Bíbélì lórí ọ̀ràn yíyanjú aáwọ̀. (Mát. 5:23, 24; 18:15-17; Éfé. 4:26, 27) a Àmọ́ tá ò bá fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn yẹn, ó máa ṣòro láti wá àlàáfíà. Ọ̀ràn náà kò lè yanjú tá a bá ń retí pé ẹni tá a jọ ní aáwọ̀ ló yẹ kó lo ìrẹ̀lẹ̀, torí pé àwa náà ní láti lo ìrẹ̀lẹ̀.
19 Tó bá dà bíi pé ìgbésẹ̀ tá a kọ́kọ́ gbé láti jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwa àti ẹni tá a jọ ní aáwọ̀ kò yanjú ọ̀ràn náà, kó yẹ ká fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ẹni náà lè nílò àkókò díẹ̀ láti da ọ̀ràn náà rò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣàìdáa tó burú jáì sí i. Ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn ìgbà náà kí wọ́n tó rí i, ó sì ti di olórí ìjọba orílẹ̀-èdè Íjíbítì nígbà yẹn. Àmọ́ ọkàn wọn ti yí pa dà, wọ́n sì tọrọ àforíjì. Jósẹ́fù forí jì wọ́n, àwọn ọmọ Jékọ́bù sì di orílẹ̀-èdè tó láǹfààní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà. (Jẹ́n. 50:15-21) Táwa náà bá ń gbìyànjú láti wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, a ó máa ṣàlékún ìṣọ̀kan àti ayọ̀ ìjọ.—Ka Kólósè 3:12-14.
Ẹ Jẹ́ Ká Nífẹ̀ẹ́ “ní Ìṣe àti Òtítọ́”
20, 21. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí Jésù ṣe wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
20 Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.” (Jòh. 13:15) Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ àwọn méjèèjìlá tán ni nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí. Ohun tí Jésù ṣe yẹn kì í kàn-án ṣe ààtò ẹ̀sìn, kì í sì í ṣe pé ó kàn ń fi inúure hàn lásán. Kí Jòhánù tó sọ nípa bí Jésù ṣe wẹ ẹsẹ̀ wọn, ó sọ pé: “Bí Jésù ti nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tí wọ́n wà ní ayé, ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòh. 13:1) Ìfẹ́ tó ní sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yìí ló mú kó ṣe iṣẹ́ kan tó jẹ́ pé ẹrú ló sábà máa ń ṣe é. Ó wá yẹ kí ìrẹ̀lẹ̀ mú káwọn náà máa ṣe ohun tó fi ìfẹ́ hàn fún ara wọn. Ká sòótọ́, ó yẹ kí ìfẹ́ tòótọ́ tá a ní fún gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin mú ká fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún àti pé a bìkítà fún wọn.
21 Àpọ́sítélì Pétérù tí Jésù Ọmọ Ọlọ́run wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ mọ ìtumọ̀ ohun tí Jésù ṣe yẹn. Pétérù sọ pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ gaara nípa ìgbọràn yín sí òtítọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.” (1 Pét. 1:22) Àpọ́sítélì Jòhánù tí Olúwa wẹ ẹsẹ̀ tirẹ̀ náà sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòh. 3:18) Ǹjẹ́ kí ìṣe wa máa fi hàn pé a ní ìfẹ́ àwọn ará wa látọkàn wá.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 144 sí 150.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà mú kí ìfẹ́ tá a ní láàárín ara wa ‘gbòòrò sí i’?
• Kí ló máa jẹ́ ká lè máa wáyè gbọ́ tàwọn èèyàn?
• Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó nínú wíwá àlàáfíà?
• Kí ló yẹ kó mú ká bìkítà fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ẹ máa fi ọ̀yàyà tẹ́wọ́ gba àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Máa lo àǹfààní tó o ní láti ráyè gbọ́ tàwọn èèyàn