Ìṣàkóso Jèhófà Ló Dára Jù Lọ!
Ìṣàkóso Jèhófà Ló Dára Jù Lọ!
“Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé.”—DÁN. 4:17.
1, 2. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tó fi hàn pé ìṣàkóso èèyàn ti forí ṣánpọ́n?
KÒ SÍ iyè méjì pé ìṣàkóso èèyàn ti forí ṣánpọ́n! Ọ̀kan lára ìdí pàtàkì tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn èèyàn ò ní ọgbọ́n tí wọ́n fi lè ṣàkóso ara wọn láṣeyọrí. Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ìjọba èèyàn túbọ̀ ń ṣe kedere báyìí tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso ti fi hàn pé àwọn jẹ́ ‘olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, aláìdúróṣinṣin, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn àti awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.’—2 Tím. 3:2-4.
2 Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn làwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti kọ ìṣàkóso Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè rò pé ńṣe làwọn fẹ́ wà lómìnira. Àmọ́, ńṣe ni wọ́n ń fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Sátánì. Ó ti di ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà báyìí táwọn èèyàn ti ń ṣàkóso ara wọn lábẹ́ ìdarí Sátánì tó jẹ́ “olùṣàkóso ayé yìí.” Èyí gan-an ló sì fà á táyé fi bà jẹ́ débi tó bà jẹ́ dé yìí. (Jòh. 12:31) Nígbà tí ìwé ìtàn kan, ìyẹn The Oxford History of the Twentieth Century, ń sọ̀rọ̀ nípa ipò táráyé wà báyìí, ó sọ pé ẹní bá “ń retí pé kí nǹkan máa lọ déédéé láyé” kàn ń fàkókò ara rẹ̀ ṣòfò ni. Ó ṣàlàyé pé: “Yàtọ̀ sí pé nǹkan ò lè máa lọ déédéé nínú ayé, ńṣe lẹni tó bá fẹ́ kó sàn jù báyìí lọ á wulẹ̀ dá àjálù, ìṣàkóso oníkùmọ̀ àti ogun pàápàá sílẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tí ò ṣeé já ní koro lèyí jẹ́ pé ìṣàkóso èèyàn ti forí ṣánpọ́n!
3. Kí la lè sọ nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run ì bá gbà máa ṣàkóso wa ká ní Ádámù àti Éfà kò dẹ́ṣẹ̀?
3 Ó mà ṣe o, àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kọ ìṣàkóso kan ṣoṣo tó lè ṣàṣeyọrí sílẹ̀, ìyẹn ìṣàkóso Ọlọ́run! Òótọ́ ni pé a kò mọ bí Jèhófà ì bá ṣe ṣètò ìṣàkóso rẹ̀ lórí ayé ká ní Ádámù àti Éfà kò ṣàìgbọràn sí òfin rẹ̀. Àmọ́, ká ní aráyé ti fara mọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run ni, ìfẹ́ ni ì bá gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn èèyàn ò sì ní máa ṣe ojúsàájú. (Ìṣe 10:34; 1 Jòh. 4:8) Àti pé, níwọ̀n bí ọgbọ́n Ọlọ́run tí jẹ́ àwámárìídìí, ó dá wa lójú pé ká ní aráyé ti fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Jèhófà ni, gbogbo àṣìṣe táwọn tó ń ṣagbátẹrù ìjọba èèyàn ti ṣe ì bá tí wáyé. Ìṣàkóso Ọlọ́run ì bá ti kẹ́sẹ járí débi táá fi máa “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sm. 145:16) Lọ́rọ̀ kan ṣá, ìṣàkóso pípé ni ì bá jẹ́. (Diu. 32:4) Àmọ́, bí aráyé ṣe kọ̀ láti fara mọ́ ọn ti mú ìbànújẹ́ púpọ̀ wá!
4. Ibo ni Ọlọ́run fàyè gba Sátánì láti ṣàkóso dé?
4 Síbẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gba àwọn èèyàn láyè láti máa ṣàkóso ara wọn, kò fìgbà kan rí gbé ẹ̀tọ́ tó ní láti máa ṣàkóso lé àwọn ẹ̀dá rẹ̀ lọ́wọ́. Ọba Bábílónì tó jẹ́ alágbára pàápàá gbà tipátipá pé “Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé,” kò tún sí ẹlòmíì. (Dán. 4:17) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí ìfẹ́ Jèhófà di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 6:10) Òótọ́ ni pé Jèhófà ṣì fàyè gba Sátánì ní báyìí ná láti wà nípò “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” kó bàa lè yanjú àríyànjiyàn tí alátakò yìí dá sílẹ̀ pátápátá. (2 Kọ́r. 4:4; 1 Jòh. 5:19) Síbẹ̀, kò tíì ṣeé ṣe fún Sátánì láti ṣe kọjá ohun tí Jèhófà fàyè gbà. (2 Kíró. 20:6; fi wé Jóòbù 1:11, 12; 2:3-6.) Kò sì sígbà tí a kì í rí àwọn èèyàn tí wọ́n pinnu láti fi ara wọn sábẹ́ Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé tí Elénìní Ọlọ́run ń ṣàkóso rẹ̀ ni wọ́n ń gbé.
Bí Ọlọ́run Ṣe Ṣàkóso Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì
5. Àdéhùn wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá Ọlọ́run ṣe?
5 Látìgbà ayé Ébẹ́lì títí dìgbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ èèyàn ló sin Jèhófà tí wọ́n sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (Héb. 11:4-22) Nígbà ayé Mósè, Jèhófà bá àwọn ọmọ Jékọ́bù dá májẹ̀mú, àwọn ló sì di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá Jèhófà ṣe àdéhùn lórúkọ ara wọn àti tàwọn àtọmọdọ́mọ wọn pé àwọn múra tán láti gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Alákòóso. Wọ́n sọ pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.”—Ẹ́kís. 19:8.
6, 7. Báwo ni nǹkan ṣe rí nígbà tí Ọlọ́run ṣàkóso àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
6 Jèhófà ní ohun kan lọ́kàn nígbà tó yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti jẹ́ èèyàn rẹ̀. (Ka Diutarónómì 7:7, 8.) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ àǹfààní táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rí jẹ nìkan ló wà níbẹ̀. Ọ̀ràn náà kan orúkọ Jèhófà àti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ, àwọn ọ̀ràn yìí ló sì ṣe pàtàkì jù. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti jẹ́rìí sí i pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo tó wà. (Aísá. 43:10; 44:6-8) Èyí ló mú kí Jèhófà sọ fún orílẹ̀-èdè yẹn pé: “Ènìyàn mímọ́ ni o jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, Jèhófà sì ti yàn ọ́ láti di ènìyàn rẹ̀, àkànṣe dúkìá, nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.”—Diu. 14:2.
7 Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣàkóso àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn pé kò gbàgbé pé aláìpé ni wọ́n. Síbẹ̀, àwọn òfin rẹ̀ pé, wọ́n sì fi àwọn ànímọ́ Ẹni tó fún wọn láwọn òfin náà hàn. Àwọn òfin tí Jèhófà fi rán Mósè sí wọn fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, pé ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, ó múra tán láti dárí jini àti pé ó ní sùúrù. Nígbà ayé Jóṣúà àtàwọn èèyàn ìran ìgbà yẹn, orílẹ̀-èdè náà pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ní àlàáfíà àti ìbùkún tẹ̀mí. (Jóṣ. 24:21, 22, 31) Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà nìkan ló lè kẹ́sẹ járí.
Ohun Tó Máa Ń Tẹ̀yìn Ìṣàkóso Èèyàn Yọ
8, 9. Ohun tí kò bọ́gbọ́n mu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì béèrè, kí ló sì tẹ̀yìn rẹ̀ yọ?
8 Àmọ́ ṣá, lemọ́lemọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, ààbò Ọlọ́run sì máa ń kúrò lórí wọn láwọn àkókò náà. Nígbà tí wọ́n bá a dójú ẹ̀, wọ́n sọ fún wòlíì Sámúẹ́lì pé àwọn fẹ́ èèyàn táwọn á lè máa fojú rí gẹ́gẹ́ bí ọba àwọn. Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé kó yan ọba tí wọ́n ń fẹ́ fún wọn. Àmọ́ Jèhófà fi kún un pé: “Kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n kọ̀ ní ọba lórí wọn.” (1 Sám. 8:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gbà kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní ọba tí wọ́n á lè máa fojú rí, ó jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa tẹ̀yìn rẹ̀ yọ.—Ka 1 Sámúẹ́lì 8:9-18.
9 Ohun tá a rí nínú ìtàn fi hàn pé òótọ́ ni ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ọ̀pọ̀ wàhálà ló wáyé nígbà táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí jọba nílẹ̀ Ísírẹ́lì, àgàgà tí ọba náà bá jẹ́ aláìṣòótọ́. Pẹ̀lú àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kàn wa, a lè rí ohun tó fà á láti ìgbà pípẹ́ wá tó fi jẹ́ pé àkóso àwọn èèyàn tí kò mọ Jèhófà kì í mú àǹfààní tó wà pẹ́ títí wá. Òótọ́ ni pé àwọn olóṣèlú kan ń tọrọ ìbùkún Ọlọ́run sórí ìsapá wọn láti mú àlàáfíà àti ààbò wá, àmọ́ báwo ni Ọlọ́run ṣe lè bù kún àwọn tí kò fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀?—Sm. 2:10-12.
Orílẹ̀-Èdè Tuntun Tó Wà Lábẹ́ Àkóso Ọlọ́run
10. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fi orílẹ̀-èdè mìíràn rọ́pò orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀?
10 Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi hàn pé àwọn ò fẹ́ sin Jèhófà tọkàntọkàn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n kọ Mèsáyà tí Ọlọ́run yàn, Jèhófà sì kọ àwọn náà, ó wá pinnu láti fi àwùjọ àwọn èèyàn tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè tuntun kan rọ́pò wọn. Látàrí èyí, ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìjọ Kristẹni tó jẹ́ kìkì àwọn ẹni àmì òróró olùjọsìn Jèhófà di èyí tó fìdí múlẹ̀. Ìjọ yẹn ló wá di orílẹ̀-èdè tuntun tó wà lábẹ́ àkóso Jèhófà. Pọ́ọ̀lù pè é ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gál. 6:16.
11, 12. Àwọn apá ibo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ àti “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” fi jọra lórí ọ̀ràn àbójútó?
11 Orílẹ̀-èdè tuntun tó jẹ́ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” fi àwọn nǹkan kan jọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àkọ́kọ́, orílẹ̀-èdè méjèèjì sì tún fàwọn nǹkan míì yàtọ̀ síra. Ara ìyàtọ̀ yẹn ni pé kò séèyàn kankan tó ń jọba lórí ìjọ Kristẹni tó jẹ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tuntun, bákan náà orílẹ̀-èdè tuntun yìí kò nílò àtimáa fi ẹran rúbọ nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ohun kan tí ìjọ Kristẹni àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ fi jọra ni ìṣètò tó wà fún níní àwọn àgbà ọkùnrin, tàbí àwọn alàgbà. (Ẹ́kís. 19:3-8) Àwọn alàgbà yìí kì í ṣàkóso lé agbo Ọlọ́run lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ wọ́n sì ń yọ̀ǹda ara wọn láti máa mú ipò iwájú nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. Wọ́n ń fi tìfẹ́tìfẹ́ bójú tó gbogbo àwọn ará ìjọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n ń fi ọ̀wọ̀ tó yẹ wọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń buyì kún wọn.—2 Kọ́r. 1:24; 1 Pét. 5:2, 3.
12 Bí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” àti “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn bá ń ṣàṣàrò lórí bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ lò, ìmọrírì tí wọ́n ní fún Jèhófà àti ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso á túbọ̀ pọ̀ sí i. (Jòh. 10:16) Bí àpẹẹrẹ, ìtàn fi hàn pé àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lè darí àwọn èèyàn náà sọ́nà tó dára tàbí kí wọ́n kó wọn ṣìnà. Èyí gbìn ín sáwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni lọ́kàn pé ó yẹ kí wọ́n jẹ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ wọn ṣeé fara wé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe alákòóso bí àwọn ọba ìgbàanì.—Héb. 13:7.
Ọ̀nà Tí Jèhófà Ń Gbà Ṣàkóso Lónìí
13. Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo ló wáyé lọ́dún 1914?
13 Lóde òní, àwọn Kristẹni ń polongo pé ayé táwọn èèyàn ń ṣàkóso rẹ̀ yìí ti ń lọ sópin. Lọ́dún 1914, Jèhófà gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run, ó fi í sábẹ́ ìdarí Jésù Kristi Ọba tó ti yàn. Ní àkókò yẹn, ó fún Jésù láṣẹ pé kó “jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣí. 6:2) Ó sọ fún Ọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́ yìí pé: “Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.” (Sm. 110:2) Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé gbogbo ìgbà làwọn orílẹ̀-èdè kì í fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà. Wọn ò yé hùwà bíi pé “Jèhófà kò sí.”—Sm. 14:1.
14, 15. (a) Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń ṣàkóso wa lónìí, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa? (b) Kí ló ń fi hàn lóde òní pé ìṣàkóso Ọlọ́run ló ṣì dára jù lọ?
14 Díẹ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bí arákùnrin Jésù, wọ́n ń ṣiṣẹ́ nìṣó bí “ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi.” (2 Kọ́r. 5:20) Àwọn ni Jésù yàn gẹ́gẹ́ bí ẹrú olóòótọ́ àti olóye kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn ogunlọ́gọ̀ tó jẹ́ Kristẹni, kí wọ́n sì tún máa fún wọn lóúnjẹ tẹ̀mí. Iye àwọn ogunlọ́gọ̀ tí ń pọ̀ sí i yìí ti wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí, wọ́n sì ní ìrètí láti máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:45-47; Ìṣí. 7:9-15) Aásìkí tẹ̀mí táwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn Jèhófà ń gbádùn lóde òní fi hàn pé Jèhófà wà lẹ́yìn ẹrú tí Jésù gbéṣẹ́ lé lọ́wọ́ yìí.
15 Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ mo mọ iṣẹ́ tó já lé mi léjìká nínú ìjọ Ọlọ́run? Ṣé mò ń kọ́wọ́ ti ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣàkóso ìjọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ? Ṣé inú mi dùn pé mo jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó ń ṣàkóso lọ́wọ́ báyìí? Ṣé mo ti pinnu láti máa sọ fáwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run débi tí agbára mi bá gbé e dé?’ Gbogbo wa lápapọ̀ là ń fi tinútinú tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń fún wa tá a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà tá a yàn sípò nínú ìjọ. À ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a fara mọ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣàkóso. (Ka Hébérù 13:17.) Ìtẹríba àtọkànwá yìí ń jẹ́ kí gbogbo wa kárí ayé, wà níṣọ̀kan lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́ nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí. Ó ń mú ká wà ní àlàáfíà, ká máa ṣe ohun tó tọ́, ká sì máa mú ìyìn wá fún Jèhófà, èyí to fi hàn pé ọ̀nà ìṣàkóso rẹ̀ ló dára jù lọ.
Ìṣàkóso Jèhófà Ló Dára Jù Lọ
16. Ìpinnu wo ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe?
16 Kò ní pẹ́ mọ́ táá fi máa rí ojútùú sí àwọn ọ̀ràn tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì. Torí náà, àkókò rèé fáwọn èèyàn láti ṣèpinnu. Ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ pinnu bóyá òun máa fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà tàbí òun máa rọ̀ mọ́ ìṣàkóso èèyàn. Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti ran àwọn ọlọ́kàn tútù lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́. Láìpẹ́, nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jèhófà máa fi ìṣàkóso tirẹ̀ rọ́pò àwọn ìjọba èèyàn tí Sátánì ń darí; ìjọba ti Ọlọ́run yóò sì dúró títí láé. (Dán. 2:44; Ìṣí. 16:16) Ìṣàkóso èèyàn máa dópin, Ìjọba Ọlọ́run yóò sì máa ṣàkóso gbogbo ayé pátá. Nígbà yẹn la ó lè sọ ní ti gidi pé ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣàkóso ló dára jù lọ.—Ka Ìṣípayá 21:3-5.
17. Kí ló yẹ káwọn ọlọ́kàn tútù ronú lé lórí kí wọ́n bàa lè ṣèpinnu tó dára lórí ìṣàkóso tí wọ́n á fara mọ́?
17 Àwọn tí kò tíì pinnu pé ti Jèhófà làwọn máa ṣe ní láti gbàdúrà nípa rẹ̀, kí wọ́n sì ronú nípa àwọn àǹfààní tí ìṣàkóso Ọlọ́run máa mú wá. Ìṣàkóso èèyàn ò tíì rí ojútùú sí ìṣòro ìwà ọ̀daràn tó fi mọ́ ìpániláyà. Àmọ́, ìṣàkóso Ọlọ́run máa mú gbogbo àwọn aṣebi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Sm. 37:1, 2, 9) Ìṣàkóso èèyàn ló ń fa ogun tó ń wáyé nígbà gbogbo, àmọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run máa “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sm. 46:9) Kódà, ìṣàkóso Ọlọ́run máa mú kí àlàáfíà tún pa dà wà láàárín èèyàn àti ẹranko! (Aísá. 11:6-9) Òṣì àti ebi wọ́pọ̀ lábẹ́ ìṣàkóso èèyàn, àmọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run máa mú òṣì àti ebi kúrò. (Aísá. 65:21) Àní àwọn tó tiẹ̀ ní in lọ́kàn láti ṣe rere lára àwọn alákòóso èèyàn kò lè mú àìsàn àti ikú kúrò, àmọ́ lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, àwọn arúgbó àtàwọn aláìsàn yóò pa dà ní okun bíi tìgbà èwe. (Jóòbù 33:25; Aísá. 35:5, 6) Dájúdájú, ayé yóò di Párádísè níbi táwọn òkú á ti jíǹde.—Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15.
18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbà pé ìṣàkóso Ọlọ́run ló dára jù lọ?
18 Láìsí àní-àní, gbogbo aburú tí Sátánì dá sílẹ̀ nígbà tó mú káwọn òbí wa àkọ́kọ́ kúrò lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wọn ni Ọlọ́run yóò mú kúrò. Sì tún wò ó, láti bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà ni Sátánì ti ń kó wàhálà bá aráyé, àmọ́ ẹgbẹ̀rún ọdún kan péré ni Ọlọ́run yóò fi mú gbogbo wàhálà náà kúrò nípasẹ̀ Kristi! Ẹ ò rí i pé ẹ̀rí pàtàkì nìyẹn jẹ́ pé ìṣàkóso Ọlọ́run ló dára jù! Àwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Ọlọrun gbà pé Òun ni Olùṣàkóso wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi hàn lójoojúmọ́, àní ní wákàtí kọ̀ọ̀kan nínú ìgbésí ayé wa, pé olùjọ́sìn Jèhófà ni wá, pé ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ ni wá, kí inú wa sì máa dùn pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti máa sọ fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ gbọ́ pé ìṣàkóso Jèhófà ló dára jù lọ.
Kí Làwọn Ẹsẹ Bíbélì Yìí Kọ́ Wa Nípa Ìṣàkóso Ọlọ́run?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Kò sígbà kankan rí tí Jèhófà gbé ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣàkóso lé ẹnikẹ́ni lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Bá a ṣe ń fi ara wa sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run látọkànwá ń mú ká wà níṣọ̀kan jákèjádò ayé