Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ni Fún Wa Láti Jẹ́ Ti Jèhófà
Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ni Fún Wa Láti Jẹ́ Ti Jèhófà
“A jẹ́ ti Jèhófà.”—RÓÒMÙ 14:8.
1, 2. (a) Àǹfààní wo la ní? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
ÀǸFÀÀNÍ iyebíye ni Jèhófà nawọ́ rẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà tó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù.” (Ẹ́kís. 19:5) Bákan náà, lónìí, àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ fáwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni láti jẹ́ ti Jèhófà. (1 Pét. 2:9; Ìṣí. 7:9, 14, 15) Títí láé la ó máa gbádùn àǹfààní yìí.
2 Yàtọ̀ sí pé àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti jẹ́ ti Jèhófà, ó tún gbé iṣẹ́ kan lé wa lọ́wọ́. Àwọn kan lè máa ronú pé: ‘Ṣé màá lè ṣe ohun tí Jèhófà retí pé kí n máa ṣe? Bí mo bá dẹ́ṣẹ̀, ṣé kò ní ta mí nù? Ṣé jíjẹ́ ti Jèhófà ò ní jẹ́ kí n pàdánù òmìnira mi?’ Ó yẹ kéèyàn ro àwọn nǹkan wọ̀nyí dáadáa lóòótọ́. Àmọ́ ṣá o, ìbéèrè míì wà tó yẹ ká kọ́kọ́ ronú jinlẹ̀ nípa rẹ̀, òun ni pé, Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú jíjẹ́ ti Jèhófà?
Jíjẹ́ Ti Jèhófà Máa Ń Fúnni Láyọ̀
3. Báwo ni bí Ráhábù ṣe pinnu láti sin Jèhófà ṣe ṣe é láǹfààní?
3 Ǹjẹ́ àwọn tó jẹ́ ti Jèhófà ń rí àǹfààní kankan níbẹ̀? Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn ti Ráhábù, aṣẹ́wó kan tó gbé ní ìlú Jẹ́ríkò àtijọ́. Ó dájú pé láti kékeré ni wọ́n ti fojú rẹ̀ mọ bíbọ àwọn òrìṣà ilẹ̀ Kénáánì tó fàyè gba ìwà ìbàjẹ́. Síbẹ̀, nígbà tó gbọ́ bí Jèhófà ṣe ṣẹ́gun fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó rí i pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́. Torí náà, ó fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè dáàbò bo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun fẹ́ kí wọ́n dáàbò bo òun tó bá yá. Bíbélì sọ pé: “A kò ha polongo Ráhábù aṣẹ́wó pẹ̀lú ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́, lẹ́yìn tí ó ti gba àwọn ońṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn?” (Ják. 2:25) Ronú nípa àwọn àǹfààní tó wá jẹ́ tirẹ̀ nígbà tó di ara àwọn èèyàn Ọlọ́run tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́, àwọn tí Ọlọ́run ti fi Òfin rẹ̀ kọ́ ní ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo. Wo bí inú rẹ̀ á ṣe dùn tó nígbà tó fi irú ìgbé ayé tó ń gbé tẹ́lẹ̀ sílẹ̀! Ó fẹ́ ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì tọ́ Bóásì tó bí fún un débi to fi di ẹni tó ta yọ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.—Jóṣ. 6:25; Rúùtù 2:4-12; Mát. 1:5, 6.
4. Báwo ni bí Rúùtù ṣe pinnu láti sin Jèhófà ṣe ṣe é láǹfààní?
4 Rúùtù tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Móábù náà pinnu láti sin Jèhófà. Nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé, ó ṣeé ṣe kó ti máa bọ òrìṣà kan tó ń jẹ́ Kémóṣì àtàwọn òrìṣà míì tí wọ́n ń bọ nílẹ̀ Móábù, àmọ́ ó wá mọ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, ó sì di aya ọmọ Ísírẹ́lì kan tó sá wá sílẹ̀ Móábù torí ìyàn tó mú ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (Ka Rúùtù 1:1-6.) Nígbà tó yá Rúùtù àti orogún rẹ̀, Ópà gbéra pẹ̀lú Náómì ìyá ọkọ wọn, wọ́n forí lé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Náómì rọ àwọn obìnrin méjèèjì yìí pé kí wọ́n pa dà sílé. Kò ní rọrùn fún wọn láti máa gbé ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ìwé Mímọ́ sọ pé Ópà “padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀,” àmọ́ Rúùtù kọ̀ kò pa dà ní tiẹ̀. Ó ṣe ohun tó bá ìgbàgbọ́ rẹ̀ mu, ó sì mọ ẹni tóun fẹ́ jẹ́ tirẹ̀. Ó sọ fún Náómì pé: “Má rọ̀ mí láti pa ọ́ tì, láti padà lẹ́yìn rẹ; nítorí ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sì sùn mọ́jú ni èmi yóò sùn mọ́jú. Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.” (Rúùtù 1:15, 16) Nítorí pé Rúùtù pinnu láti sin Jèhófà, ó jàǹfààní látinú Òfin Ọlọ́run, èyí tó ní àkànṣe ètò fún àwọn opó, àwọn tálákà àtàwọn tí kò ní ilẹ̀. Ó rí ayọ̀, ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ apá Jèhófà.
5. Kí lo ti kíyè sí nípa àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn?
5 Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tó jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n ti ń sìn ín tọkàntọkàn láti ọ̀pọ̀ ọdún wá. Ní kí wọ́n sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí látibẹ̀ fún ẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tí kò níṣòro, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà pé wọ́n rí ayọ̀ nínú sísin Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù kan ṣe sọ, pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—Sm. 144:15.
Jèhófà Kò Retí Ohun Tó Pọ̀ Jù
6. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa bẹ̀rù pé a ò ní lè ṣe ohun tí Jèhófà retí pé ká máa ṣe?
6 O lè máa rò ó pé ṣé wàá lè ṣe ohun tí Jèhófà retí pé kó o ṣe. O lè máa fòyà torí pé o fẹ́ di ìránṣẹ́ Ọlọ́run, tó ní láti máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, tó sì ní láti máa sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Mósè rò pé òun ò tóótun nígbà tí Jèhófà rán an pé kó lọ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ọba Íjíbítì sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ gbé lé Mósè lọ́wọ́ kò kọjá agbára rẹ̀. Jèhófà ‘kọ́ ọ ní ohun tí yóò ṣe.’ (Ka Ẹ́kísódù 3:11; 4:1, 10, 13-15.) Níwọ̀n bí Mósè ò ti kọ ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà fún un, ó láyọ̀ pé òun ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán òun. Ohun tí Jèhófà ń retí látọ̀dọ̀ àwa náà kò pọ̀ jù. Ó mọ̀ pé aláìpé ni wá, ó sì fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 103:14) Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù, sísin Ọlọ́run kò mú ìnira wá, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ń tuni lára torí àwọn míì ń jàǹfààní látinú irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀, ó sì ń mú inú Jèhófà dùn. Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi.”—Mát. 11:28, 29.
7. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó fẹ́ kó o ṣe?
7 Jèhófà yóò máa fún wa ní ìṣírí tá a nílò, tá a bá ṣáà ti ní ìgbọ́kànlé pé á máa fún wa lókun. Bí àpẹẹrẹ, ó dájú pé Jeremáyà kì í ṣe sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́. Torí náà, nígbà tí Jèhófà yàn án láti jẹ́ wòlíì, Jeremáyà sọ pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.” Nígbà tó yá, ó tiẹ̀ sọ pé: “Èmi kì yóò sì sọ̀rọ̀ mọ́ ní orúkọ rẹ̀.” (Jer. 1:6; 20:9) Síbẹ̀, nítorí ìṣírí tí Jèhófà fún Jeremáyà, ogójì ọdún gbáko ló fi wàásù ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí. Jèhófà mú kó dá a lójú lemọ́lemọ́ pé: “Mo wà pẹ̀lú rẹ, láti gbà ọ́ là àti láti dá ọ nídè.”—Jer. 1:8, 19; 15:20.
8. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
8 Bí Jèhófà ṣe fún Mósè àti Jeremáyà lókun, bẹ́ẹ̀ ló ṣe lè ran àwa náà lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó fẹ́ káwa Kristẹni máa ṣe lónìí. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká gbára lé Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Bá a ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni pé ká máa lo gbogbo ohun tó ń pèsè fún wa látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìjọ Kristẹni. Tá a bá jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ ìṣísẹ̀ wa nínú ohun gbogbo, kò sóhun tó lè dí wa lọ́wọ́ tá ò fi ní jẹ́ olóòótọ́ sí i.
Jèhófà Ń Bójú Tó Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan
9, 10. Irú ààbò wo ni Ọlọ́run ṣèlérí nínú Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún?
9 Bí àwọn kan bá ń dà á rò láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n lè máa bẹ̀rù nípa bí wọn ò ṣe ní dẹ́ṣẹ̀, bí wọn ò ṣe ní dẹni ẹ̀tẹ́ lójú Jèhófà àti bí kò ṣe ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Àmọ́, inú wa dùn pé Jèhófà ń dáàbò bò wá ní gbogbo ọ̀nà kí àjọṣe ṣíṣeyebíye tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ má bàa bà jẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo bí Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún ṣe ṣàlàyé rẹ̀.
10 Bí Sáàmù yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ yóò rí ibùwọ̀ fún ara rẹ̀ lábẹ́ òjìji Olódùmarè. Ṣe ni èmi yóò wí fún Jèhófà pé: ‘Ìwọ ni ibi ìsádi mi àti ibi odi agbára mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi yóò gbẹ́kẹ̀ lé dájúdájú.’ Nítorí pé òun tìkára rẹ̀ yóò dá ọ nídè kúrò nínú pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ.” (Sm. 91:1-3) Kíyè sí i pé Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa dáàbò bo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òun tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé òun. (Ka Sáàmù 91:9, 14.) Ààbò wo ló ń ṣèlérí rẹ̀ níbí yìí? Jèhófà gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan láyé ọjọ́un lọ́wọ́ ewu tara, nígbà míì èyí jẹ́ nítorí kó lè dáàbò bo ìlà ìdílé tí Mèsáyà tó ṣèlérí náà máa gbà wá. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ìgbà yẹn náà ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n, tí wọ́n dá lóró tí wọ́n sì pa bí Èṣù ṣe ń gbéjà kò wọ́n kí wọ́n bàa lè ṣíwọ́ jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. (Héb. 11:34-39) Ìdí tí wọ́n fi nígboyà láti fara da gbogbo èyí ni pé Jèhófà dáàbò bò wọ́n nínú ewu tẹ̀mí, tí ì bá ti ba ìwà títọ́ wọn jẹ́. Torí náà, ó ṣe kedere pé ààbò tẹ̀mí ni Ọlọ́run ń ṣèlérí rẹ̀ fún wa nínú Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún.
11. Kí ni “ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,” àwọn wo ni Ọlọ́run sì ń dáàbò bò níbẹ̀?
11 “Ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,” tí onísáàmù náà ń sọ níbí yìí, ṣàpẹẹrẹ ibi ààbò tẹ̀mí. Àwọn tó bá wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlejò Ọlọ́run ti bọ́ lọ́wọ́ ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ba ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run jẹ́. (Sm. 15:1, 2; 121:5) Ìdí tó fi jẹ́ ibi ìkọ̀kọ̀ ni pé àwọn aláìgbàgbọ́ kò lè fòye mọ̀ ọ́n. Ibẹ̀ ni Jèhófà ti ń dáàbò bo àwọn tá a lè ní wọ́n ń sọ pé: ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi yóò gbẹ́kẹ̀ lé.’ Tá a bá dúró sí ibi ààbò yìí, kò sídìí tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù pé a lè ṣubú sínú pańpẹ́ Sátánì tó jẹ́ “pẹyẹpẹyẹ,” ká sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ojú rere Ọlọ́run.
12. Àwọn nǹkan wo ló lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́?
12 Àwọn ewu wo ló lè ba àjọṣe ṣíṣeyebíye tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́? Onísáàmù náà mẹ́nu kan àwọn ewu mélòó kan, lára wọn ni “àjàkálẹ̀ àrùn tí ń rìn nínú ìṣúdùdù, . . . [àti] ìparun tí ń fini ṣe ìjẹ ní ọjọ́kanrí.” (Sm. 91:5, 6) “Pẹyẹpẹyẹ” náà ti fi ìfẹ́ láti wà lómìnira dẹ pańpẹ́ mú ọ̀pọ̀ èèyàn. (2 Kọ́r. 11:3) Ìwọra, ìgbéraga àti ìfẹ́ àtikó ọrọ̀ jọ ló fi ń dẹ pańpẹ́ mú àwọn míì. Ohun tó sì fi ń ṣi àwọn míì lọ́nà ni àwọn ẹ̀kọ́ tó dá lórí èrò èèyàn lásán, irú bí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, ẹfolúṣọ̀n àti ẹ̀sìn èké. (Kól. 2:8) Ó sì ti fi onírúurú ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ dẹ pańpẹ́ mú ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn nǹkan tó dà bí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń lò yìí lè ba àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, wọ́n sì ti mú kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn pàdánù ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 91:7-10; Mát. 24:12.
Bó O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ìfẹ́ Tó O Ní fún Ọlọ́run
13. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ewu tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́?
13 Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ yìí? Ìwé Sáàmù sọ pé: “Òun yóò pa àṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, láti máa ṣọ́ ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ.” (Sm. 91:11) Àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń ṣamọ̀nà wa, wọ́n sì ń dáàbò bò wá, ká bàa lè máa wàásù ìhìn rere. (Ìṣí. 14:6) Bákan náà, àwọn alàgbà ń rí i dájú pé Ìwé Mímọ́ làwọn fi ń kọ́ wa, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ fi ẹ̀kọ́ èké tàn wá jẹ. Àwọn alàgbà tún lè ṣèrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣòro fún láti dẹ́kun híhùwà bí àwọn èèyàn ayé. (Títù 1:9; 1 Pét. 5:2) Bákan náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí kò jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kó sí wa lórí, tí ìfẹ́ ìṣekúṣe kò fi wọ̀ wá lọ́kàn, tí ìlépa ọrọ̀ àti ipò ọlá àtàwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ míì tó fi mọ́ èròkerò kò fi kó sí wa lọ́kàn. (Mát. 24:45) Kí ni kò jẹ́ kó o kó sínú àwọn ewu wọ̀nyí?
14. Kí la lè ṣe láti jàǹfààní ààbò tí Ọlọ́run ń pèsè?
14 Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ máa wà ní “ibi ìkọ̀kọ̀” Ọlọ́run tó jẹ́ ibi ààbò yẹn? Bá a ṣe ní láti máa dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ ewu, irú bí ìjàǹbá, àwọn ọ̀daràn tàbí àrùn, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àwọn ewu tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jèhófà ń fún wa nínú àwọn ìtẹ̀jáde, àwọn ìpàdé àti ní àwọn àpéjọ. A tún máa ń tọ àwọn alàgbà lọ pé kí wọ́n fún wa nímọ̀ràn. Ó sì dájú pé à ń jàǹfààní látinú onírúuru ànímọ́ táwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ká sòótọ́, ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ máa ń sọ wá di ọlọgbọ́n.—Òwe 13:20; ka 1 Pétérù 4:10.
15. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà lè dáàbò bò ẹ́ lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè mú kó o pàdánù ojú rere rẹ̀?
15 Kò sídìí kankan tó fi yẹ ká máa ṣiyè méjì pé bóyá ni Jèhófà lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè mú ká pàdánù ojú rere rẹ̀. (Róòmù. 8:38, 39) Ó ti dáàbò bo ìjọ rẹ̀ lódindi lọ́wọ́ àwọn sàràkí sàràkí aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn olóṣèlú tó ń bá wa ṣọ̀tá. Kì í kúkú ṣe ikú wa làwọn wọ̀nyí ń wá bí kò ṣe bí wọ́n ṣe máa yà wá ya Ọlọ́run wa mímọ́. Àmọ́ ìlérí Jèhófà ń ṣẹ sí wa lára, pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.”—Aísá. 54:17.
Ta Ló Lè Sọ Wá Di Òmìnira?
16. Kí nìdí tí ayé ò fi lè fún wa lómìnira?
16 Ṣé jíjẹ́ tá a jẹ́ ti Jèhófà yóò fi òmìnira wa dù wá ni? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, jíjẹ́ ti ayé ló máa fi òmìnira wa dù wá. Ayé ti sọ ara wọn dàjèjì sí Jèhófà, ìkà sì ni ọlọ́run tó ń ṣàkóso wọn, ńṣe ló máa ń mú àwọn èèyàn sìn. (Jòh. 14:30) Bí àpẹẹrẹ, ètò nǹkan ti Sátánì yìí ń lo ọrọ̀ ajé tí kò fara rọ láti mú àwọn èèyàn sìn. (Fi wé Ìṣípayá 13:16, 17.) Ẹ̀ṣẹ̀ náà tún ní ọ̀nà tó ń gbà sọ àwọn èèyàn di ẹrú. (Jòh. 8:34; Héb. 3:13) Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláìgbàgbọ́ lè máa sọ pé gbígbé ìgbé ayé tí kò bá ìlànà Ọlọ́run mu ló máa ń sọni di òmìnira, kò ní pẹ́ tí àwọn tó bá tẹ́tí sí wọn á fi rí i pé àwọn ti di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbésí ayé oníwà ìbàjẹ́.—Róòmù 1:24-32.
17. Irú òmìnira wo ni Jèhófà ń fún wa?
17 Àmọ́, Jèhófà máa dá wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ohun tó lè pa wá lára tá a bá jọ̀wọ́ ara wa fún un. Ọ̀ràn wa fẹ́ dà bíi ti ẹnì kan tó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún oníṣẹ́ abẹ́ tó mọṣẹ́ dunjú kó bàa lè gbà á lọ́wọ́ àìsàn tó lè pa á. Ohun kan wà tó dà bí àìsàn tó lè pa àwa náà, ìyẹn ni ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. Àyàfi tá a bá jọ̀wọ́ ara wa fún Jèhófà, lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, la fi lè ní ìrètí pé a máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a ó sì wà láàyè títí láé. (Jòh. 3:36) Bí a ṣe máa túbọ̀ fọkàn tán oníṣẹ́ abẹ kan táwọn èèyàn ń ròyìn rẹ̀ ní rere, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà á túbọ̀ máa pọ̀ sí i bá ò bá ṣíwọ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Ìdí rèé tó fi yẹ ká máa bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, torí pé ìyẹn ló máa jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run débi tí ẹ̀rù kankan ò fi ní bà wá mọ́ pé a jẹ́ tirẹ̀.—1 Jòh. 4:18.
18. Kí ló máa jẹ́ èrè àwọn tó bá jẹ́ ti Jèhófà?
18 Jèhófà fún gbogbo èèyàn lómìnira láti yan ohun tí wọ́n bá fẹ́. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diu. 30:19, 20) Ó fẹ́ kí àwa fúnra wa yàn láti sin òun, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òun. Ó dájú pé jíjẹ́ ti Ọlọ́run tá a nífẹ̀ẹ́ yìí kò ní fi òmìnira wa dù wá, kàkà bẹ́ẹ̀, á mú ká máa láyọ̀ nígbà gbogbo.
19. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ló mú ká jẹ́ tirẹ̀?
19 Àwa ẹlẹ́ṣẹ̀ ò yẹ lẹ́ni tó ń jẹ́ ti Ọlọ́run pípé. Ńṣe la wulẹ̀ ń jọlá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. (2 Tím. 1:9) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Bí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Jèhófà, bí a bá sì kú, a kú fún Jèhófà. Nítorí náà, bí a bá wà láàyè àti bí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:8) Ó dájú pé a ò ní kábàámọ̀ láé pé a jẹ́ ti Jèhófà.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú jíjẹ́ ti Jèhófà?
• Kí ló ń mú ká lè ṣe ohun tí Ọlọ́run ń retí pé ká máa ṣe?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ní káwọn míì sọ àǹfààní tí wọ́n ti rí látinú jíjẹ́ ti Jèhófà fún ẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń dáàbò bò wá?