Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí Jèhófà Bi Ẹ́ Ní Ìbéèrè?
Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí Jèhófà Bi Ẹ́ Ní Ìbéèrè?
BÍBÉLÌ kún fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìbéèrè tó ń wọni lọ́kàn ṣinṣin. Kódà Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ lo ìbéèrè láti kọ́ni láwọn òtítọ́ pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà lo àwọn ìbéèrè mélòó kan láti kìlọ̀ fún Kéènì pé kó jáwọ́ nínú ọ̀nà ìparun tó ń tọ̀. (Jẹ́n. 4:6, 7) Nígbà míì, ìbéèrè kan ṣoṣo látọ̀dọ̀ Jèhófà ti tó láti mú kí ẹnì kan ṣe ohun tó tọ́. Nígbà tí Jèhófà bi wòlíì Aísáyà pé: “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa? Ìdáhùn rẹ̀ ni pé: “Èmi nìyí! Rán mi.”—Aísá. 6:8.
Jésù Olùkọ́ Ńlá náà lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́. Àwọn ìwé ìhìn rere ṣàkọsílẹ̀ okòó-dín-lọ́ọ̀ọ́dúnrún [280] lára àwọn ìbéèrè Jésù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì ńṣe ló lo ìbéèrè láti pa àwọn alátakò rẹ̀ lẹ́nu mọ́, lọ́pọ̀ ìgbà ìdí tó fi máa ń béèrè ìbéèrè ni láti dénú ọkàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ronú lórí ipò tí wọ́n wà nípa tẹ̀mí. (Mát. 22:41-46; Jòh. 14:9, 10) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó kọ mẹ́rìnlá lára Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì, lo àwọn ìbéèrè láti fi yíni lérò pa dà. (Róòmù 10:13-15) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Róòmù ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìbéèrè. Àwọn ìbéèrè Pọ́ọ̀lù mú kí àwọn tó ń ka ìwé rẹ̀ mọrírì “ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run.”—Róòmù 11:33.
Àwọn ìbéèrè míì máa ń gba pé kéèyàn fèsì, àmọ́ ńṣe làwọn míì máa ń múni ronú jinlẹ̀. Àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣàkọsílẹ̀ bí Jésù ṣe lo àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀. Nígbà kan Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ìwúkàrà Hẹ́rọ́dù,” ìyẹn ìwà àgàbàgebè àtàwọn ẹ̀kọ́ èké wọn. (Máàkù 8:15; Mát. 16:12) Ọ̀rọ̀ yìí kò yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn pé búrẹ́dì tí àwọn kò mú dání ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Kíyè sí bí Jésù ṣe lo ìbéèrè nínú ìjíròrò ṣókí tó wáyé lẹ́yìn náà. “Ó wí fún wọn pé: ‘Èé ṣe tí ẹ fi ń jiyàn lórí níní tí ẹ kò ní ìṣù búrẹ́dì kankan? Ṣé ẹ kò tíì róye síbẹ̀, kí ẹ sì lóye ìtumọ̀ rẹ̀ ni? Ṣé ọkàn-àyà yín kò tètè lóye ni? “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ní ojú, ṣé ẹ kò ríran ni; àti pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ní etí, ṣé ẹ kò gbọ́ran ni?” . . . Ṣé ẹ kò tíì lóye ìtumọ̀ rẹ̀ síbẹ̀?’” Àwọn ìbéèrè Jésù gba pé kéèyàn ronú, èyí sì mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ronú lórí ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ túmọ̀ sí gan-an.—Máàkù 8:16-21.
“Jẹ́ Kí N Bi Ọ́ Léèrè”
Jèhófà Ọlọ́run lo ìbéèrè láti tún èrò Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe. Nípasẹ̀ ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìbéèrè, Jèhófà jẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé kò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. (Jóòbù, orí 38 sí 41) Ǹjẹ́ Jèhófà retí pé kí Jóòbù fèsì ìbéèrè yẹn lọ́kọ̀ọ̀kan? Kò jọ bẹ́ẹ̀. Ńṣe ló lo àwọn ìbéèrè bí “Ibo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀?” láti mú kí Jóòbù ronú ẹ̀ wò. Lẹ́yìn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìbéèrè yẹn, ńṣe ni kẹ́kẹ́ pa mọ́ Jóòbù lẹ́nu. Ohun tó kàn sọ ni pé: “Kí ni èmi yóò fi fún ọ lésì? Mo ti fi ọwọ́ mi lé ẹnu mi.” (Jóòbù 38:4; 40:4) Jóòbù lóye ohun tí Jèhófà ń sọ, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́, kì í ṣe pé Jèhófà kàn fẹ́ kọ́ Jóòbù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ o. Ó tún ṣàtúnṣe ìrònú Jóòbù. Lọ́nà wo?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán” ni Jóòbù, láwọn ìgbà míì àwọn ọ̀rọ̀ tó ń sọ fi hàn pé kò ní èrò tó tọ́, èyí ni Élíhù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó bá Jóòbù wí pé ó ń “polongo ọkàn ara rẹ̀ ní olódodo dípò Ọlọ́run.” (Jóòbù 1:8; 32:2; 33:8-12) Àwọn ìbéèrè tí Jèhófà bi Jóòbù tipa bẹ́ẹ̀ mú kó ní èrò tó tọ́. Nígbà tí Ọlọ́run ń bá Jóòbù sọ̀rọ̀ látinú ẹ̀fúùfù, ó bí i pé: “Ta nìyí tí ń ṣú òkùnkùn bo ìmọ̀ràn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀? Jọ̀wọ́, di abẹ́nú rẹ lámùrè bí abarapá ọkùnrin, sì jẹ́ kí n bi ọ́ léèrè, kí o sì sọ fún mi.” (Jóòbù 38:1-3) Nípasẹ̀ ìbéèrè, Jèhófà wá darí àfiyèsí sí ọgbọ́n àti agbára rẹ̀ tí kò láàlà, bí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti fi hàn. Ìlàlóye yìí jẹ́ kí Jóòbù ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìdájọ́ Jèhófà àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ fún Jóòbù, pé Ọlọ́run Olódùmarè bí i ní ìbéèrè!
Bá A Ṣè Lè Jẹ́ Kí Jèhófà Bi Wá Ní Ìbéèrè
Àwa ńkọ́? Ṣé àwa náà lè jàǹfààní látinú àwọn ìbéèrè tó wà nínú Bíbélì? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè jàǹfààní! Tá a bá jẹ́ kí àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ mú ká sinmẹ̀dọ̀ ká sì ronú, ó lè ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ nípa tẹ̀mí. Àwọn ìbéèrè tó ń wọni lọ́kàn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó túbọ̀ gbéṣẹ́. Kódà, ‘ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sa agbára, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.’ (Héb. 4:12) Àmọ́, kí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn tó lè ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ darí wọn sí ara wa, bíi pé Jèhófà ló dìídì ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wa. (Róòmù 15:4) Jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
“Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” (Jẹ́n. 18:25) Ìbéèrè tí ìdáhùn rẹ̀ jẹ́ mọ̀ọ́nú yìí ni Ábúráhámù bi Jèhófà nígbà tó fẹ́ ṣèdájọ́ Sódómù àti Gòmórà. Ábúráhámù gbà pé kò ṣé e ronú kàn pé kí Jèhófà hùwà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, ìyẹn ni pé kó pa àwọn olódodo run pẹ̀lú àwọn ẹni ibi. Ìbéèrè Ábúráhámù fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ pé olódodo ni Jèhófà.
Lóde òní, àwọn kan lè máa ṣiyè méjì nípa ọ̀ràn ìdájọ́ tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú, wọ́n lè máa rò ó pé àwọn wo gan-an ló máa la Amágẹ́dọ́nì já tàbí pé àwọn wo ló máa jíǹde. Dípò tí a ó fi jẹ́ kí irú èrò bẹ́ẹ̀ máa kó ìdààmú bá wa, a lè ronú nípa ìbéèrè Ábúráhámù. Tí a bá mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi Baba wa ọrún tí kì í ṣègbè, tí a sì ní ìgbọ́kànlé nínú ìdájọ́ òdodo àti àánú rẹ̀, bíi ti Ábúráhámù, kò ní jẹ́ ká máa lo àkókò àti agbára wa dà nù lórí ohun tí kò pọn dandan, iyè méjì tó ń tánni lókun àti àríyànjiyàn tí kò wúlò.
“Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?” (Mát. 6:27) Nígbà tí Jésù ń bá àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀, tó fi mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó lo ìbéèrè yìí láti jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì fún wọn láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọjọ́ ìkẹyìn àwọn nǹkan ìsinsìnyí ń mú kí àníyàn wa túbọ̀ pọ̀, àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tá à ń rò nìyẹn ṣá, ìwàláàyè wa kò ní torí ẹ̀ gùn sí i, nǹkan ò sì ní torí ìyẹn sàn sí i fún wa.
Nígbàkigbà tí ọ̀ràn ara wa tàbí ti ẹnì kan tá a nífẹ̀ẹ́ bá ń mú ká ṣàníyàn, rírántí ìbéèrè Jésù lè mú ká dẹ́kun láti máa ṣàníyàn. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fòpin sí ìdààmú àti èrò tí kò tọ́, èyí tó lè mú ká máa ro àròkàn, kí ọkàn wa dà rú, tàbí kó rẹ̀ wá tẹnutẹnu. Jésù mú kó dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run tó ń bọ́ àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, tó sì ń wọ àwọn ewéko inú pápá láṣọ, mọ gbogbo ohun tí a ṣe aláìní.—Mát. 6:26-34.
“Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí oókan àyà rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kí ẹ̀wù rẹ̀ gan-an má sì jóná?” (Òwe 6:27) A lè rí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí bàbá kan ń bá ọmọ rẹ̀ sọ nínú orí mẹ́sàn-án àkọ́kọ́ nínú ìwé Òwe. Ìbéèrè tá a béèrè lókè yìí ní í ṣe pẹ̀lú ohun búburú tó máa ń tìdí panṣágà yọ. (Òwe 6:29) Tá a bá kíyè sí i pé à ń bá ẹni tí kò yẹ tage tàbí tí à ń fi ọkàn yàwòrán ìṣekúṣe, ó yẹ kí ìbéèrè yìí máa ró gbọnmọgbọnmọ lọ́kàn wa. Torí náà, ó bá ìlànà mu pé kí ẹnì kan bi ara rẹ̀ ní ìbéèrè yìí bó bá ń ṣe é bíi kó gbé ìgbésẹ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání. Ẹ ò rí i pé kedere ló tẹ ìlànà Bíbélì yìí mọ́ wa lọ́kàn pé: ‘Ohun tí èèyàn bá fúnrúgbìn ló máa ká.’—Gál. 6:7.
“Ta ni ìwọ láti ṣèdájọ́ ìránṣẹ́ ilé ẹlòmíràn?” (Róòmù 14:4) Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù, ó jíròrò ìṣòro tó jẹyọ láàárín àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Torí pé inú àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra làwọn kan lára àwọn Kristẹni wọ̀nyí ti wá, wọ́n máa ń fẹ́ ṣèdájọ́ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn lórí ìpinnu tí wọ́n bá ṣe àti ìwà wọn. Ìbéèrè tí Pọ́ọ̀lù bi wọ́n yìí rán wọn létí pé ó yẹ kí wọ́n máa fi ìfẹ́ bá ara wọn lò kí wọ́n sì fi ìdájọ́ sílẹ̀ fún Jèhófà.
Bákan náà lónìí, ipò ìgbésí ayé àwọn èèyàn Jèhófà yàtọ̀ síra. Síbẹ̀ Jèhófà ti mú kí wọ́n ṣera wọn lọ́kàn bí òṣùṣù ọwọ̀. Ṣé àwa náà ń pa kún ìṣọ̀kan yẹn? Tá a bá tètè ń bẹnu àtẹ́ lu ohun kan tí arákùnrin tàbí arábìnrin wa kan ṣe tọkàntọkàn, ó máa mọ́gbọ́n dání ká bi ara wa ní ìbéèrè Pọ́ọ̀lù yẹn.
Ìbéèrè Máa Ń Mú Ká Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí ti jẹ́ ká rí bí àwọn ìbéèrè tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára tó. Tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tó wà láyìíká àwọn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan, a ó lè mọ bí àwa fúnra wa ṣe lè mú wọn bá ipò wa mu. Bá a sì ṣe ń ka Bíbélì, a máa rí àwọn ìbéèrè míì tó ṣàǹfààní fún wa.—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 14.
Tá a bá jẹ́ kí àwọn ìbéèrè tó ń wọni lọ́kàn ṣinṣin tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa tó jinlẹ̀ lórí wa, á jẹ́ ká lè mú ìrònú wa àti ọkàn-àyà wa bá ọ̀nà òdodo Jèhófà mu. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti bi Jóòbù ní ìbéèrè, Jóòbù sọ pé: “Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ojú mi ti rí ọ.” (Jóòbù 42:5) Jóòbù ti wá túbọ̀ mọ Jèhófà, àfi bíi pé ó ń wò ó kòrókòró. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn tiẹ̀ sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Ják. 4:8) Ǹjẹ́ ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run látòkè délẹ̀, tó fi mọ́ àwọn ìbéèrè tó wà nínú rẹ̀, ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí, ká sì túbọ̀ “rí” Jèhófà kedere ju ti tẹ́lẹ̀ lọ!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
Báwo ni bíbi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí ṣe lè mú kó o máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó?
▪ “Jèhófà ha ní inú dídùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ bí pé kí a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà?”—1 Sám. 15:22.
▪ “Ẹni tí ó ṣẹ̀dá ojú, ṣé kò lè rí ni?”—Sm. 94:9.
▪ “Kí àwọn ènìyàn sì máa wá ògo ara wọn, ṣé ògo ni?”—Òwe 25:27.
▪ “Ǹjẹ́ ríru tí inú rẹ ru fún ìbínú ha jẹ́ lọ́nà ẹ̀tọ́ bí?”—Jónà 4:4.
▪ “Àǹfààní wo ni yóò jẹ́ fún ènìyàn kan bí ó bá jèrè gbogbo ayé ṣùgbọ́n tí ó pàdánù ọkàn rẹ̀?”—Mát. 16:26.
▪ “Ta ni yóò yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi?”—Róòmù 8:35.
▪ “Kí ni ìwọ ní tí kì í ṣe pé ìwọ gbà?”—1 Kọ́r. 4:7.
▪ “Àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn?”—2 Kọ́r. 6:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Kí ni Jóòbù kọ́ látinú àwọn ìbéèrè tí Jèhófà bi í?