Ṣé Ò Ń Tọ Kristi Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo?
Ṣé Ò Ń Tọ Kristi Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo?
“Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń rìn ní ti tòótọ́, . . . ẹ tẹra mọ́ títúbọ̀ ṣe é lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.”—1 TẸS. 4:1.
1, 2. (a) Kí làwọn ohun àgbàyanu tó ṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà ayé Jésù? (b) Kí nìdí tí àkókò tiwa yìí náà fi ṣe pàtàkì?
ǸJẸ́ o ti fìgbà kan rí ronú lórí bó ṣe máa jẹ́ ohun àgbàyanu tó ká sọ pé o wà láyé nígbà tí Jésù gbélé ayé? Ó ṣeé ṣe kó o máa rò pé o lè wà lára àwọn tí Jésù wò sàn, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ wàhálà tí àwọn àìsàn tó ń pọ́nni lójú máa ń mú wá. Ó sì lè jẹ́ pé gbígbọ́rọ̀ látẹnu Jésù, kó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀ tàbí kó o rí bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ni ohun tó máa gbádùn mọ́ ẹ. (Máàkù 4:1, 2; Lúùkù 5:3-9; 9:11) Àǹfààní ńlá ni ì bá jẹ́ láti wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn! (Lúùkù 19:37) Kò sí ìran èèyàn kankan látìgbà yẹn tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tún ṣojú rẹ̀, ohun tí Jésù sì gbé ṣe lórí ilẹ̀ ayé “nípasẹ̀ ẹbọ òun fúnra rẹ̀” kò tún ní pa dà ṣẹlẹ̀ mọ́.—Héb. 9:26; Jòh. 14:19.
2 Àkókò tó ṣe pàtàkì làwa náà ń gbé báyìí o. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àkókò tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé ó jẹ́ “àkókò òpin” àti “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé yìí. (Dán. 12:1-4, 9; 2 Tím. 3:1) Àkókò yìí náà ni wọ́n lé Sátánì kúrò ní ọ̀run. Láìpẹ́, a ó dè é, a ó sì sọ ọ́ “sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” (Ìṣí. 12:7-9, 12; 20:1-3) Àkókò yìí náà la tún ní àǹfààní kíkọyọyọ láti máa polongo “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run kárí ayé, tá a sì ń sọ fún àwọn èèyàn nípa Párádísè tó ń bọ̀, èyí sì jẹ́ iṣẹ́ tí a ò tún ní pa dà ṣe mọ́ láé.—Mát. 24:14.
3. Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, kí ló sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe, kí nìyẹn sì máa gbà pé kí wọ́n ṣe?
3 Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Iṣẹ́ yìí máa gba pé kí wọ́n máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé. Kí nìdí tí wọ́n fi ní láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? Ó jẹ́ láti sọ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i di ọmọlẹ́yìn Kristi, kí òpin tó dé. (Mát. 28:19, 20) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ tí Kristi gbé lé wa lọ́wọ́ yìí?
4. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ tó gbàrònú tí Pétérù sọ nínú 2 Pétérù 3:11, 12 tẹnu mọ́? (b) Kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún?
4 Kíyè sí ọ̀rọ̀ tó gbàrònú tí àpọ́sítélì Pétérù sọ yìí, ó ní: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!” (2 Pét. 3:11, 12) Ọ̀rọ̀ Pétérù yìí tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́nà lójú méjèèjì lákòókò òpin tá a wà yìí, ká lè rí i pé ìgbésí ayé wa dá lórí iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run. Lára irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ayọ̀ ńlá mà ló jẹ́ fún wa o, láti rí bí àwọn ará wa kárí ayé ṣe ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ tí Kristi pa láṣẹ fún wa láti ṣe! Lẹ́sẹ̀ kan náà, a mọ̀ pé a ní láti ṣọ́ra, kí pákáǹleke tá à ń dojú kọ lójoojúmọ́ nínú ayé Sátánì yìí àti ìfẹ́ ti ara tá a ti jogún, má bàa mú kí ìtara tá a fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run dín kù. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè rí i pé à ń tọ Kristi lẹ́yìn.
Fi Tọkàntọkàn Gba Ojúṣe Tí Ọlọ́run Gbé Lé Wa Lọ́wọ́
5, 6. (a) Torí kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe gbóríyìn fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọ́n jọ wà ní Jerúsálẹ́mù, kí ló sì kìlọ̀ fún wọn nípa rẹ̀? (b) Kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́?
5 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó gbóríyìn fún wọn torí pé wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ fara da inúnibíni. Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní rírántí àwọn ọjọ́ àtijọ́ nínú èyí tí, lẹ́yìn tí a ti là yín lóye, ẹ fara da ìdíje ńláǹlà lábẹ́ àwọn ìjìyà.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà kò gbàgbé ìṣòtítọ́ wọn. (Héb. 6:10; 10:32-34) Ó dájú pé bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbóríyìn fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù yìí máa fún wọn ní ìṣírí gan-an. Àmọ́, nínú lẹ́tà yìí kan náà, Pọ́ọ̀lù tún kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tó sábà máa ń mú kí ìtara téèyàn fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run dín kù, béèyàn ò bá tètè wá nǹkan ṣe sí i. Ó sọ pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe “tọrọ gáfárà,” tàbí kí wọ́n máa ṣe àwáwí nípa ìdí tí wọn ò fi ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún wọn.—Héb. 12:25.
6 Ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí nípa fífẹ́ láti “tọrọ gáfárà” kúrò nídìí ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ kan àwa Kristẹni lóde òní pẹ̀lú. A mọ̀ pé a ní láti pinnu pé a kò ní fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́, tàbí ká jẹ́ kí ìtara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run dín kù. (Héb. 10:39) Ó ṣe tán, ọ̀ràn ìyè àti ikú lọ̀rọ̀ ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́.—1 Tím. 4:16.
7, 8. (a) Kí ló máa jẹ́ ká lè máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìṣó? (b) Bí ìtara tá a kọ́kọ́ ní fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run bá ti dín kù, kí ló yẹ ká rántí nípa Jèhófà àti Jésù?
7 Kí ló má ràn wá lọ́wọ́ tí a ò fi ní máa ṣe àwáwí nípa ìdí tí a kò fi ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́? Ohun pàtàkì kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa ṣe àṣàrò déédéé lórí ohun tí ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ fún Ọlọ́run nígbà tí a ya ara wa sí mímọ́ fún un túmọ̀ sí. Lọ́rọ̀ kan, a jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà pé ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ la máa fi ṣe ohun àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa, a sì fẹ́ mú ẹ̀jẹ́ yẹn ṣẹ. (Ka Mátíù 16:24.) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká sinmẹ̀dọ̀ ká sì bi ara wa léèrè pé: ‘Ṣé ó ṣì ń wù mí láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ mi sí Ọlọ́run ṣẹ, bó ṣe ń wù mí nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi? Àbí mo ti pàdánù ìtara tí mo ní bí ọdún ṣe ń gorí ọdún?’
8 Bá a bá ṣe àyẹ̀wò ara wa tọkàntọkàn, tá a sì rí i pé a ti dẹwọ́ lọ́nà kan ṣá, ó máa dára ká rántí ọ̀rọ̀ tó ń tani jí tí wòlíì Sefanáyà sọ, ó ní: “Kí ọwọ́ rẹ má rọ jọwọrọ. Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ. Bí Ẹni tí ó ní agbára ńlá, òun yóò gbà là. Òun yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀.” (Sef. 3:16, 17) Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ lára nígbà tí wọ́n pa dà dé Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ìgbèkùn ní Bábílónì. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí ṣì kan àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iṣẹ́ Jèhófà là ń ṣe, a gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ń tì wá lẹ́yìn, wọ́n sì ń fún wa lókun láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ náà dójú àmì. (Mát. 28:20; Fílí. 4:13) Tá a bá ń sapá láti máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run yìí nìṣó, ó máa bù kún wa, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti máa láásìkí nípa tẹ̀mí.
Ẹ Máa Fìtara ‘Wá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́’
9, 10. Kí ni kókó inú àkàwé Jésù nípa oúnjẹ alẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kan, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú rẹ̀?
9 Nígbà tí Jésù ń jẹ oúnjẹ nílé alákòóso àwọn Farisí kan, ó sọ àpèjúwe kan nípa àsè oúnjẹ alẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kan. Nínú àpèjúwe yẹn, ó ṣàpẹẹrẹ àǹfààní kan tá a nawọ́ rẹ̀ sí onírúurú èèyàn kí wọ́n lè wà ní ìlà láti wọ Ìjọba ọrun. Ó sì tún ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti “tọrọ gáfárà.” (Ka Lúùkù 14:16-21.) Àwọn àlejò tá a pè nínú àpèjúwe Jésù ṣe onírúurú àwáwí nípa ìdí tí wọn kò fi wá síbi àsè náà. Ọ̀kan sọ pé, òun ní láti jáde lọ wo pápá tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ rà. Òmíràn sọ pé, òun ra àjàgà màlúù, òun sì fẹ́ lọ yẹ̀ wọ́n wò. Síbẹ̀, òmíràn sọ pé: ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ aya ni àti pé fún ìdí yìí, n kò lè wá.’ Àwọn àwáwí yìí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀! Ẹni tó bá ra pápá tàbí ohun ọ̀sìn kan ti máa ń wò ó kó tó rà á, torí náà kò sí ìdí tó fi yẹ kó máa kánjú láti tún pa dà lọ wò ó. Kí ló sì lè mú kí ìgbéyàwó téèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe dí èèyàn lọ́wọ́ láti jẹ́ irú ìpè pàtàkì bẹ́ẹ̀? Abájọ tí inú fi bí olùgbàlejò inú àpèjúwe yẹn gan-an!
10 Gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú àkàwé Jésù. Kí ni ẹ̀kọ́ náà? A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ọ̀ràn ara ẹni, irú èyí tí Jésù sọ nínú àpèjúwe yìí, ṣe pàtàkì sí wa débi tí a ó fi pa iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Bí Kristẹni kan ò bá fi àwọn ọ̀ràn ara ẹni sí àyè tó yẹ kí wọ́n wà, díẹ̀díẹ̀ ni ìtara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn a máa dín kù. (Ka Lúùkù 8:14.) Bí a kò bá fẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ sí wa, a gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Jésù yìí sọ́kàn, pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33) Ẹ ò rí i pé ó ń fúnni níṣìírí gan-an láti rí i pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, tàgbàtèwe, ń fi ìmọ̀ràn pàtàkì yẹn sílò! Kódà, ọ̀pọ̀ ló mú kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ àwọn lọ́rùn kí wọ́n lè máa lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Wọ́n ti fojú ara wọn rí i pé fífi ìtara wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ ti jẹ́ káwọn ní ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.
11. Ìtàn inú Bíbélì wo ló ṣàpẹẹrẹ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tọkàntọkàn àti tìtara-tìtara?
11 Láti ṣàpèjúwe bó ti ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kíyè sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé nínú ìgbésí ayé Jèhóáṣì Ọba Ísírẹ́lì. Ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì látọwọ́ àwọn ará Ásíríà, kó ẹ̀dùn ọkàn bá a, ló bá ké lọ bá wòlíì Èlíṣà. Wòlíì náà wá sọ fún un pé kó ta ọfà látojú fèrèsé síhà ilẹ̀ Ásíríà, láti fi hàn pé Jèhófà máa ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè yẹn. Ó yẹ kí èyí ti mú ọkàn ọba náà le. Lẹ́yìn náà, Èlíṣà wá sọ fún Jèhóáṣì pé kó mú ọfà rẹ̀ kó sì ta á sórí ilẹ̀. Ìgbà mẹ́ta péré lo ta á. Inú bí Èlíṣà gidigidi sí èyí, torí bó bá jẹ́ pé ìgbà márùn-ún tàbí mẹ́fà ló ta á ni, ìyẹn ì bá fi hàn pé yóò máa “ṣá Síríà balẹ̀ títí yóò fi pa rẹ.” Fún ìdí yìí, ìgbà mẹ́ta péré ni Jèhóáṣì máa ṣẹ́gun Ásíríà. Torí pé Jèhóáṣì kò lo ìtara, ìgbà mélòó kan péré ló ṣẹ́gun. (2 Ọba 13:14-19) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àkọ́sílẹ̀ yẹn? Jèhófà máa bù kún wa jìngbìnnì tá a bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn àti tìtara-tìtara.
12. (a) Kí ló máa jẹ́ ká lè máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìṣó bá a ti ń kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé? (b) Sọ bó o ṣe ń jàǹfààní nítorí bó o ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.
12 Àwọn ìṣòro tá à ń bá yí nígbèésí ayé lè dán ìtara wa àti ìfọkànsìn wa fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run wò. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ń kojú ìṣòro ọrọ̀ ajé tí kò fara rọ. Ohun tó jẹ́ ìṣòro àwọn míì ni àìsàn líle koko tí kò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe tó bí wọ́n ṣe ń fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Síbẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè wá nǹkan ṣe ká lè rí i dájú pé a kò jẹ́ kí ìtara wa dín kù, àti pé à ń bá a lọ láti máa tọ Kristi lẹ́yìn nígbà gbogbo. Jọ̀wọ́ wo díẹ̀ lára àwọn àbá àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́, tá a tò sínú àpótí náà, “Kí Ló Máa Jẹ́ Kó O Lè Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn?” Ronú lórí ọ̀nà tó o lè gbà máa fi wọ́n sílò lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ wàá rí èrè tó pọ̀ gan-an. Tá a bá ń jẹ́ kọ́wọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó máa jẹ́ ká fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ìgbésí ayé wa á nítumọ̀, á sì jẹ́ ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ayọ̀. (1 Kọ́r. 15:58) Síwájú sí i, tá a bá ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wa tọkàntọkàn, á jẹ́ ká lè máa fi ‘wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’—2 Pét. 3:12.
Gbé Ipò Rẹ Yẹ̀ Wò
13. Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá tọkàntọkàn la fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?
13 Ó ṣe pàtàkì ká rántí pé, kì í ṣe iye àkókò tá a lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló ń fi hàn pé a ṣe é tọkàntọkàn. Ipò tó yí ẹnì kọ̀ọ̀kan ká yàtọ̀. Inú Jèhófà lè máa dùn sí ẹnì kan tó ń lo wákàtí kan tàbí méjì lóde ẹ̀rí lóṣooṣù, tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí ìlera rẹ̀ gbà á láyè láti ṣe nìyẹn. (Fi wé Máàkù 12:41-44.) Torí náà, ká lè mọ̀ bóyá tọkàntọkàn la fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, a ní láti ṣàyẹ̀wò ara wa, ká sì mọ̀ bóyá ohun tí agbára wa àti ipò wa gbé là ń ṣe. Bá a sì ṣe jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, a fẹ́ máa fi ojú tó fi ń wo nǹkan wò ó. (Ka Róòmù 15:5; 1 Kọ́r. 2:16) Kí ni Jésù fi sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀? Ó sọ fún ogunlọ́gọ̀ èèyàn ní Kápánáúmù pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43; Jòh. 18:37) Bó o ti ń ronú nípa ìtara tí Jésù ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, gbé ipò rẹ yẹ̀ wò kó o lè mọ̀ bóyá o ṣì lè fi kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.—1 Kọ́r. 11:1.
14. Àwọn ọ̀nà míì wo la lè gbà mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i?
14 Bá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ipò wa, ó lè mú ká parí èrò sí pé ó yẹ ká fi kún àkókò tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Mát. 9:37, 38) Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ wa tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ilé ìwé ti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i, wọ́n sì ń rí ayọ̀ tó ń wá látinú fífi ìtara ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ṣé ìwọ náà á fẹ́ láti ní irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀? Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ti gbé ipò wọn yẹ̀ wò, wọ́n sì pinnu pé àwọn lè ṣí lọ sí àgbègbè kan lórílẹ̀-èdè wọn tàbí lórílẹ̀-èdè míì, níbi tá a ti nílò oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Àwọn míì sì ti kọ́ èdè míì kí wọ́n lè ran àwọn tó ń sọ èdè náà lọ́wọ́. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòro láti fi kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìbùkún ló wà níbẹ̀, a sì lè ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ “kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tím. 2:3, 4; 2 Kọ́r. 9:6.
Àwọn Àpẹẹrẹ Inú Bíbélì Tá A Lè Tẹ̀ Lé
15, 16. Àpẹẹrẹ àwọn wo la lè tẹ̀ lé bí a bá fẹ́ jẹ́ onítara ọmọlẹ́yìn Kristi?
15 Kí ni àwọn kan lára àwọn tó di àpọ́sítélì ṣe, nígbà tí Kristi pè wọ́n pé kí wọ́n wá di ọmọlẹ́yìn òun? Bíbélì sọ nípa Mátíù pé: “Ó fi ohun gbogbo sílẹ̀ sẹ́yìn, ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé e.” (Lúùkù 5:27, 28) A kà nípa Pétérù àti Áńdérù, tí wọ́n ń pẹja pé: “Kíá, ní pípa àwọn àwọ̀n náà tì, wọ́n tẹ̀ lé e.” Lẹ́yìn náà Jésù rí Jákọ́bù àti Jòhánù, tí àwọn àti bàbá wọn jọ ń tún àwọ̀n tí wọ́n fi ń pẹja ṣe. Kí ni wọ́n ṣe nígbà tí Jésù pè wọ́n? “Kíá, ní fífi ọkọ̀ ojú omi náà àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀ lé e.”—Mát. 4:18-22.
16 Àpẹẹrẹ àtàtà mìíràn ni ti Sọ́ọ̀lù tó wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣe inúnibíni rírorò sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, ó yíwà pa dà, ó sì di “ohun èlò tí a ti yàn” láti polongo orúkọ Kristi. “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni [Pọ́ọ̀lù] bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Jésù nínú àwọn sínágọ́gù, pé Ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.” (Ìṣe 9:3-22) Bó sì ti jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ní láti fara da ọ̀pọ̀ ìnira àti inúnibíni, kò pàdánù ìtara rẹ̀.—2 Kọ́r. 11:23-29; 12:15.
17. (a) Kí ni ìpinnu rẹ lórí títọ Kristi lẹ́yìn? (b) Àwọn ìbùkún wo là ń gbádùn bá a ti ń fi tọkàntọkàn àti gbogbo okun wa ṣe ìfẹ́ Jèhófà?
17 Ó dájú pé a fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ká má ṣe lọ́ra, ká má sì ṣe fà sẹ́yìn láti jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. (Héb. 6:11, 12) Ìbùkún wo là ń rí bá a ti ń sapá láti máa fi ìtara tọ Kristi lẹ́yìn nígbà gbogbo? À ń rí ojúlówó ìtura nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, a sì ń rí ìtẹ́lọ́rùn tó ń wá látinú títẹ́wọ́ gba àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn àtàwọn ojúṣe nínú ìjọ. (Sm. 40:8; ka 1 Tẹsalóníkà 4:1.) Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ kárakára nínú títọ Kristi lẹ́yìn, à ń gbádùn ìbùkún jìngbìnnì tí kì í ṣá, irú bí àlàáfíà ọkàn, ìfọ̀kànbalẹ̀, ìtẹ́lọ́rùn, ojúure Ọlọ́run, a sì nírètí ìyè àìnípẹ̀kun.—1 Tím. 4:10.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Iṣẹ́ pàtàkì wo la gbé lé wa lọ́wọ́, irú ojú wo ló sì yẹ ká máa fi wò ó?
• Kí ni ohun tó sábà máa ń mú kí ìtara téèyàn fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run dín kù, èyí tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún, kí sì nìdí?
• Báwo la ṣe lè gbé ipò wa yẹ̀ wò?
• Kí ló máa jẹ́ ká lè máa tọ Kristi lẹ́yìn?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Kí Ló Máa Jẹ́ Kó O Lè Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn?
▪ Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tó o bá kà.—Sm. 1:1-3; 1 Tím. 4:15.
▪ Máa gbàdúrà ní gbogbo ìgbà fún ìtìlẹ́yìn àti ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí Ọlọ́run.—Sek. 4:6; Lúùkù 11:9, 13.
▪ Máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń fi ìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.—Òwe 13:20; Héb. 10:24, 25.
▪ Mọ̀ pé àkókò kánjúkánjú là ń gbé yìí.—Éfé. 5:15, 16.
▪ Máa rántí àbájáde búburú tó wà nínú kéèyàn “tọrọ gáfárà.”—Lúùkù 9:59-62.
▪ Máa ronú nígbà gbogbo nípa ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ àti ìbùkún jìngbìnnì tó ń wá látinú sísin Jèhófà àti títọ Kristi lẹ́yìn tọkàntọkàn.—Sm. 116:12-14; 133:3; Òwe 10:22.