Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Àgbàlagbà?
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Àgbàlagbà?
IGI kan wà ní ojú ọ̀nà etíkun ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí wọ́n sọ pé òun ni igi tí wọ́n tíì ya fọ́tò rẹ̀ jù lọ láyé. Orúkọ rẹ̀ ni Lone Cypress. Ìròyìn fi hàn pé igi náà ti lò ju àádọ́talérúgba [250] ọdún. Àwọn èèyàn mọ̀ pé igi mèremère yìí rọ́kú, ìyẹn ló mú kí wọ́n máa pàfiyèsí sí i lóríṣiríṣi ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lo okùn láti gbé igi náà ró, wọ́n sì to òkúta yí ìdí rẹ̀ ká.
Igi Lone Cypress yìí lè mú wa rántí àwọn Kristẹni àgbàlagbà tó wà láàárín wa, àwọn náà ti fara da ọ̀pọ̀ nǹkan. Ọ̀nà pàtàkì kan tí wọ́n gbà ṣe èyí jẹ́ nípa pípolongo ìhìn rere. Wòlíì Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé “àwọn àgbà ọkùnrin” máa polongo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Jóẹ́lì 2:28-32; Ìṣe 2:16-21) Kàn tiẹ̀ ronú nípa ọ̀pọ̀ wákàtí tí wọ́n ń lò nínú ríran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run! (Mát. 24:14) Àwọn kan lára àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ àgbàlagbà yìí ti kojú inúnibíni àti àwọn ìṣòro míì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Táwọn èèyàn bá lè kíyè sí igi cypress lásán-làsàn torí pé ó rọ́kú, tí wọ́n sì torí ẹ̀ fi okùn gbé e ró, tí wọ́n sì tún to òkúta yí ìdí rẹ̀ ká, ẹ ò rí i pé ó yẹ kí àwa náà mọyì àwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wa, ká máa buyì kún wọn, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn!
Jèhófà Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì pé: “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó.” (Léf. 19:32) Láàárín àwọn èèyàn Jèhófà lóde òní, a rí àwọn olùṣòtítọ́ tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tí wọ́n sì ti ń ‘bá Ọlọ́run rìn’ fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Míkà ) Bí wọ́n sì ṣe ń bá a nìṣó láti máa fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò, “adé ẹwà” ni ewú orí wọn jẹ́ lóòótọ́.— 6:8Òwe 16:31.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́ nímọ̀ràn pé: “Má ṣe fi àṣìṣe àgbà ọkùnrin hàn lọ́nà mímúná janjan.” Kàkà bẹ́ẹ̀, Tímótì ní láti máa “pàrọwà fún un gẹ́gẹ́ bí baba” àti “àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá.” (1 Tím. 5:1, 2) Èyí tó túmọ̀ sí pé Tímótì ní láti “dìde dúró” níwájú orí ewú. Fún ìdí yìí, ó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ kí ọ̀nà tí a ń gbà sọ̀rọ̀ sí àwọn àgbàlagbà fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún wọn.
Ìwé Róòmù 12:10 sọ pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” Ó hàn gbangba pé àwọn alábòójútó nínú ìjọ máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn Kristẹni tó ti dàgbà. Àmọ́ gbogbo wa ló yẹ ká mú ipò iwájú nínú bíbu ọlá fáwọn ẹlòmíì.
Àmọ́ ṣá o, ojúṣe àwọn ọmọ ni láti máa bójú tó àwọn òbí wọn àtàwọn òbí wọn àgbà. Ní ti igi Lone Cypress, àwọn èèyàn ti wá oríṣiríṣi ọ̀nà láti dáàbò bò ó kó má bàa kú, wọn ò sì tíì jáwọ́. Bákan náà, ó yẹ kí àwa náà wá ọ̀nà tí a ò fi máa buyì kún àwọn òbí wa àtàwọn òbí wa àgbà. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń fara balẹ̀ gbọ́ tiwọn, ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa ṣe nǹkan lọ́nà tó wù wá láìgba tiwọn rò.—Òwe 23:22; 1 Tím. 5:4.
Àwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wa ṣeyebíye lójú Jèhófà. Kì í fi wọ́n sílẹ̀. (Sm. 71:18) Ọlọ́run tòótọ́ máa ń fún wọn lágbára kí wọ́n lè máa fi ìṣòtítọ́ sìn ín nìṣó. Ǹjẹ́ kí àwa náà máa ti àwọn àgbàlagbà yìí lẹ́yìn ká sì máa bọlá fún wọn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bí igi Lone Cypress ṣe nílò ohun kan láti gbé e ró, náà ni àwọn àgbàlagbà ṣe nílò pé ká máa buyì kún wọn, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn
[Credit Line]
American Spirit Images/age fotostock