Àárín Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Lo ti Lè Rí Ààbò
Àárín Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Lo ti Lè Rí Ààbò
“Èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ nínú ìjọ ńlá.”—SM. 35:18.
1-3. (a) Kí ló lè mú àwọn Kristẹni lọ sí ibi tó lè wu àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà léwu? (b) Ibo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ti lè rí ààbò?
NÍGBÀ tí Joe àti ìyàwó rẹ̀ wà ní àkókò ìsinmi, wọ́n ṣeré lọ sí ìsàlẹ̀ òkun níbi tí òkìtì iyùn àti onírúurú ẹja ńlá àti kékeré tó láwọ̀ mèremère wà. Wọ́n tún lúwẹ̀ẹ́ síwájú sí i láti wo àwọn òkìtì iyùn tó wà nínú òkun lọ́hùn-ún. Nígbà tí wọ́n wá dé ibì kan, wọ́n ṣàdédé rí i pé àwọn ti já sínú ọ̀gbun ńlá kan nísàlẹ̀ omi. Ìyàwó Joe sọ pé: “Mo ronú pé a ti ń lọ jìnnà ju bó ṣe yẹ lọ.” Àmọ́ Joe dá a lóhùn pé: “Fara ẹ balẹ̀, mo mọ ohun tí mò ń ṣe.” Joe sọ pé kò pẹ́ tí òun fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì pé: ‘Ibo ni gbogbo àwọn ẹja tó wà níbí gbà lọ?’ Ẹ̀rù bà á nígbà tó rí ohun tó fà á. Ó ṣàdédé rí ẹja ekurá kan tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ látinú alagbalúgbú omi náà. Ó dájú pé kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ. Àmọ́, bó ṣe kù díẹ̀ kí ẹja náà dé ọ̀dọ́ rẹ̀ ló bá yà bàrá, ó sì pòórá mọ́ wọn lójú.
2 Kristẹni kan lè bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tó ń fani lọ́kàn mọ́ra nínú ayé Sátánì yìí, irú bí eré ìnàjú, iṣẹ́ àti nǹkan ìní débi tí kò fi ní mọ̀ pé òun ti fẹ́ já sínú ọ̀gbun ńlá bíi ti ẹni tó wà nísàlẹ̀ omi. Alàgbà ìjọ ni Joe tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè yìí. Ó sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí mú kí n ronú nípa irú ẹgbẹ́ tí à ń kó. Ó dáa ká máa lúwẹ̀ẹ́ ní ibi tí ààbò wà tó sì gbádùn mọ́ni, ìyẹn nínú ìjọ!” Ká má ṣe lúwẹ̀ẹ́ lọ sínú ibú omi tó léwu, níbi tí a kò ti ní rí àwọn èèyàn Ọlọ́run bá kẹ́gbẹ́ tí a sì ti lè bá ewu pàdé. Tí a bá sì ṣèèṣì bá ara wa níbi tó léwu, ńṣe ni ká tètè ṣẹ́rí pa dà sí ‘ibi ti ewu kò sí.’ Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè fi àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà sínú ewu.
3 Ibi tó léwu gan-an ni ayé yìí jẹ́ fún àwọn Kristẹni lóde òní. (2 Tím. 3:1-5) Sátánì mọ̀ pé omi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ lẹ́yìn ẹja òun, ó sì ń wá bó ṣe máa pa àwọn tí kò bá kíyè sára jẹ. (1 Pét. 5:8; Ìṣí. 12:12, 17) Àmọ́, ibi ààbò la wà. Jèhófà ti pèsè ibi tá a ti lè rí ààbò tí ohunkóhun kò sì ní ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́, ìyẹn ìjọ Kristẹni.
4, 5. Èrò wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa ọjọ́ ọ̀la wọn, kí sì nìdí?
4 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń wu àwọn èèyàn léwu tó sì ń kó ìdààmú ọkàn bá wọn, síbẹ̀ díẹ̀ ni ohun tí àwọn aláṣẹ ayé lè ṣe nípa rẹ̀. Ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn kò balẹ̀ torí pé ìwà ipá, rògbòdìyàn, owó ìgbọ́bùkátà tó ń lọ sókè sí i àti ìṣòro ọ̀ràn àyíká ń kó ìpayà bá wọn. Ìṣòro ọjọ́ ogbó àti àìlera kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Àwọn èèyàn míì tó ní iṣẹ́, ilé, owó ìgbọ́bùkátà àti ìlera dé ìwọ̀n àyè kan máa ń ṣe kàyéfì bóyá àwọn nǹkan wọ̀nyí máa tọ́jọ́.
5 Ìbàlẹ̀ ọkàn pẹ̀lú ti di àléèbá fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Ibi tó wá burú sí ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti fọkàn sí i pé tí àwọn bá ṣe ìgbéyàwó tí àwọn sì ní ìdílé tàwọn, ọ̀ràn bùṣe nìyẹn àti pé ọkàn àwọn á balẹ̀, síbẹ̀ pàbó ni ìfojúsọ́nà wọn já sí. Tó bá sì kan níní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kò mọ ọ̀nà àbáyọ, wọn ò sì rí ìwúlò ìtọ́sọ́nà tí wọ́n ń rí gbà. Ohun tó sì fà á ni ìwàkíwà tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn ń hù àti àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tí wọ́n fi ń kọ́ wọn. Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé kò sóhun tí àwọn lè ṣe ju pé kí àwọn gbé ìrètí àwọn karí sáyẹ́ǹsì tàbí ìwà rere àti làákàyè àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Kò yà wá lẹ́nu nígbà náà pé, ọkàn àwọn èèyàn tó yí wa ká kò balẹ̀, wọn ò sì fẹ́ máa ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la.
6, 7. (a) Kí ló mú kí ojú tí àwọn tó ń sin Ọlọ́run fi ń wo nǹkan yàtọ̀ sí ti àwọn tí kò sìn ín? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò?
6 Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló wà láàárín àwọn tó jẹ́ ara ìjọ Kristẹni àtàwọn èèyàn míì! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn Jèhófà náà máa ń dojú kọ ọ̀pọ̀ lára irú ìṣòro tó ń bá àwọn tó yí wa ká fínra, síbẹ̀ ojú tá a fi ń wo àwọn ìṣòro náà yàtọ̀ sí tiwọn. (Ka Aísáyà 65:13, 14; Málákì 3:18.) Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì ṣe àwọn àlàyé tó tẹ́ni lọ́rùn nípa ipò tí aráyé bá ara rẹ̀, a sì ti gbára dì láti kojú àwọn ìpèníjà àti ìṣòro tó ń bá wa fínra. Torí náà, a kì í ṣe àníyàn kọjá bó ṣe yẹ nípa ọjọ́ ọ̀la. Jíjẹ́ tá a jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà ti gbà wá lọ́wọ́ èrò òdì tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ìṣekúṣe àti àwọn ohun tó máa ń tìdí rẹ̀ yọ. Àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ń tipa bẹ́ẹ̀ jàǹfààní ìfọ̀kànbalẹ̀ tí aráyé kò mọ̀ nípa rẹ̀.—Aísá. 48:17, 18; Fílí. 4:6, 7.
7 Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ lè jẹ́ ká ronú nípa ààbò tí àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà ń gbádùn, èyí tó yàtọ̀ gédégbé sí ti àwọn tí kò sin Jèhófà. Àwọn àpẹẹrẹ yìí lè mú ká tún inú rò, ká yí ìwà wa pa dà, ká sì rí i bóyá a lè túbọ̀ máa fi àwọn ìlànà tí Ọlọ́run pèsè láti máa dáàbò bò wá sílò.—Aísá. 30:21.
“Ẹsẹ̀ Mi Fẹ́rẹ̀ẹ́ Yà Kúrò Lọ́nà”
8. Kí ló máa ń pọn dandan pé kí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe nígbà gbogbo?
8 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn ni àwọn tó yàn láti sin Jèhófà, tí wọ́n sì fẹ́ láti máa ṣègbọràn sí i, kì í ti í fẹ́ bá àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn Ọlọ́run kẹ́gbẹ́. Kódà, Jèhófà ti sọ pé ìṣọ̀tá máa wà láàárín àwọn olùjọ́sìn òun àtàwọn tó ń tọ Sátánì lẹ́yìn. (Jẹ́n. 3:15) Torí pé àwọn olùjọ́sìn Jèhófà fọwọ́ pàtàkì mú ìlànà Ọlọ́run, wọn kì í hùwà bíi ti àwọn èèyàn tó yí wọn ká. (Jòh. 17:15, 16; 1 Jòh. 2:15-17) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Ọlọ́run. Ìgbà míì tiẹ̀ wà tí àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ṣe kàyéfì bóyá ó bọ́gbọ́n mu láti máa gbé ìgbésí ayé ìfara-ẹni-rúbọ.
9. Sọ ohun tí ojú ẹni tó kọ Sáàmù 73 rí.
9 Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó bẹ̀rẹ̀ sí ronú bóyá ìpinnu tóun ṣe mọ́gbọ́n dání ni ẹni tó kọ Sáàmù 73, èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ásáfù. Ẹni tó kọ Sáàmù yìí fẹ́ mọ ohun tó fà á tó fi dà bíi pé àwọn ẹni burúkú máa ń rọ́wọ́ mú, tí wọ́n ń láyọ̀, tí wọ́n sì ń rí towó ṣe, nígbà tí àwọn tó ń gbìyànjú láti sin Ọlọ́run máa ń dojú kọ àdánwò àti ìnira.—Ka Sáàmù 73:1-13.
10. Kí nìdí tí ìbéèrè onísáàmù yìí fi ṣe pàtàkì sí ẹ?
10 Ǹjẹ́ ìwọ náà ti béèrè irú ìbéèrè tó jọ èyí tí ẹni tó kọ Sáàmù yìí béèrè? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kò sí ìdí tó fi yẹ kó o máa dá ara rẹ lẹ́bi tàbí kó o máa ronú pé ìgbàgbọ́ rẹ kò kún tó. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, tó fi mọ́ àwọn tí Jèhófà lò láti kọ Bíbélì ló ní irú èrò bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 21:7-13; Sm. 37:1; Jer. 12:1; Háb. 1:1-4, 13) Kódà, ìbéèrè tí gbogbo àwọn tó fẹ́ láti sin Jèhófà gbọ́dọ̀ ronú lé lórí, kí wọ́n sì wá ìdáhùn sí ni pé: Ǹjẹ́ sísin Jèhófà àti ṣíṣègbọràn sí i ni ohun tó dára jù lọ? Èyí fara jọ ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Pàtàkì ló sì jẹ́ nínú àríyànjiyàn Sátánì nípa ẹ̀tọ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. (Jẹ́n. 3:4, 5) Torí náà, ó dára gan-an kí gbogbo wa ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí onísáàmù yìí ń ṣàníyàn lé lórí. Ṣé ó yẹ ká máa jowú àwọn ẹni ibi tó ń fọ́nnu, tó sì jọ pé nǹkan ń lọ dáadáa fún? Ṣé ó yẹ ká yà “kúrò” nínú sísin Jèhófà ká sì máa fara wé wọn? Ohun tí Sátánì máa fẹ́ ká ṣe gan-an nìyẹn.
11, 12. (a) Báwo ni onísáàmù náà ṣe borí iyè méjì rẹ̀, ẹ̀kọ́ wo ni èyí sì kọ́ wa? (b) Kí ló ti mú kó o parí èrò sí ibi tí onísáàmù náà parí èrò rẹ̀ sí?
11 Kí ló ran onísáàmù náà lọ́wọ́ láti borí iyè méjì rẹ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́wọ́ pé ẹsẹ̀ òun fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lọ́nà òdodo, ojú tó fi ń wo ọ̀ràn náà yí pa dà nígbà tó “wá sínú ibùjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run,” ìyẹn nígbà tó dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run nínú àgọ́ ìjọsìn tàbí nínú tẹ́ńpìlì tó sì ṣàṣàrò nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe. Ìgbà yẹn ló wá ṣe kedere sí onísáàmù yìí pé òun kò fẹ́ kí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn aṣebi ṣẹlẹ̀ sí òun. Ó tún hàn sí i pé nítorí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn àti ohun tí wọ́n yàn láti ṣe, “orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́” ni wọ́n wà. Onísáàmù náà kíyè sí i pé gbogbo àwọn tó ń ṣe ìṣekúṣe tí wọ́n sì ń kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà ló dájú pé wọ́n máa wá sí òpin “nípasẹ̀ ìpayà òjijì,” àmọ́ Jèhófà yóò wà pẹ̀lú àwọn tó ń sìn ín. (Ka Sáàmù 73:16-19, 27, 28.) Láìsí àní-àní, wàá ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn lè fẹ́ láti máa gbé ìgbé ayé wọn bó ṣe wù wọ́n láìka àwọn ìlànà Ọlọ́run sí, àmọ́ kò sí bí wọ́n ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ àbájáde búburú tó máa ń tìdí rẹ̀ yọ.—Gál. 6:7-9.
12 Kí làwọn ohun míì tá a tún rí kọ́ látara onísáàmù náà? Ó rí ààbò láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì tún kọ́gbọ́n lára wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ronú lọ́nà tó já gaara tó sì mọ́gbọ́n dání nígbà tó lọ sí ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn Jèhófà. Bákan náà lóde òní, a lè rí àwọn agbaninímọ̀ràn tó gbọ́n ní àwọn ìpàdé Kristẹni, a ó sì tún gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ níbẹ̀. Abájọ tí Jèhófà fi sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Wọ́n máa rí ìṣírí gbà níbẹ̀, wọ́n á sì kọ́ bí wọ́n á ṣe máa fọgbọ́n hùwà.—Aísá. 32:1, 2; Héb. 10:24, 25.
Fọgbọ́n Yan Àwọn Tí Ò Ń Bá Ṣọ̀rẹ́
13-15. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Dínà, kí ni ìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀? (b) Kí nìdí tí bíbá àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni ṣọ̀rẹ́ fi jẹ́ ààbò?
13 Dínà ọmọ Jékọ́bù jẹ́ àpẹẹrẹ kan lára àwọn tó kó sínú ìjàngbọ̀n torí pé ó ń bá àwọn èèyàn tí kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà ṣọ̀rẹ́. Ohun tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa Dínà fi hàn pé ó ti di àṣà rẹ̀ láti máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì tó wà lágbègbè tí ìdílé rẹ̀ ń gbé. Àwọn ọmọ Kénáánì kì í tẹ̀ lé ìlànà kan náà bíi ti àwọn olùjọ́sìn Jèhófà bó bá dọ̀ràn ìwà rere. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí fi hàn pé ọ̀nà tí àwọn ará Kénáánì gbà gbé ìgbé ayé wọn ló mú kí ilẹ̀ wọn kún fún ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe, ìjọsìn tó ń gbé ìbálòpọ̀ tó gbòdì lárugẹ àti ìwà ipá. (Ẹ́kís. 23:23; Léf. 18:2-25; Diu. 18:9-12) Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà torí pé ó bá àwọn èèyàn wọ̀nyí ṣọ̀rẹ́.
14 Ọkùnrin kan ní ìlú yẹn tó ń jẹ́ Ṣékémù tí wọ́n sọ pé ó “ní ọlá jù lọ nínú gbogbo ilé baba rẹ̀” rí Dínà “ó mú un, ó sùn tì í, ó sì tẹ́ ẹ lógo.” (Jẹ́n. 34:1, 2, 19) Èyí mà bani nínú jẹ́ o! Ǹjẹ́ o rò pé Dínà jẹ́ ronú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí òun? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló kàn fẹ́ yan àwọn ọ̀dọ́ bíi tiẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, kó má sì ronú pé wọ́n lè ṣe àìdáa sí òun. Àmọ́, wọ́n tan Dínà jẹ pátápátá.
15 Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé a kò lè máa bá àwọn aláìgbàgbọ́ ṣọ̀rẹ́ kí láburú kankan má sì ṣẹlẹ̀ sí wa. Ìwé Mímọ́ sọ pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́r. 15:33) Àmọ́, kò séwu fún ẹ tó o bá yan àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́, tí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ìlànà Jèhófà, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, lọ́rẹ̀ẹ́. Irú àwọn ọ̀rẹ́ rere bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kó o lè máa hùwà ọgbọ́n.—Òwe 13:20.
“A Ti Wẹ̀ Yín Mọ́”
16. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì?
16 Ìjọ Kristẹni ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú àwọn àṣà tó ń sọni di ẹlẹ́gbin. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì, ó sọ̀rọ̀ nípa ìyípadà tí àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ ti ṣe kí wọ́n lè máa gbé ìgbésí ayé tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. Àwọn kan ti jẹ́ alágbèrè, abọ̀rìṣà, onípanṣágà, abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, olè, ọ̀mùtípara àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “A ti wẹ̀ yín mọ́.”—Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
17. Báwo ni títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì ṣe yí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn pa dà?
17 Àwọn èèyàn tí kò ní ìgbàgbọ́ kì í rí ìlànà tó péye táá máa tọ́ wọn sọ́nà. Àwọn fúnra wọn ló máa ń yan ipa ọ̀nà tí wọ́n á máa tọ̀ tàbí kí wọ́n máa gbé irú ìgbé ayé tí àwọn èèyàn tó yí wọn ká ń gbé, bí àwọn ará Kọ́ríńtì ìgbàanì ṣe gbé ìgbé ayé wọn kí wọ́n tó di onígbàgbọ́. (Éfé. 4:14) Àmọ́, ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ohun tó fẹ́ ṣe ní agbára láti yí ìgbésí ayé àwọn tó ń fi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ sílò pa dà sí rere. (Kól. 3:5-10; Héb. 4:12) Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà nínú ìjọ Kristẹni lónìí ló máa sọ fún ẹ pé, kí àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́, kó sì tó di pé àwọn ń tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà, ohun tó wu àwọn làwọn ń ṣe. Síbẹ̀, wọn kò ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀. Ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nìkan ni wọ́n tó ní àlàáfíà.
18. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́ kan, kí ni ìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀?
18 Àmọ́, àwọn kan tó ti yàn láti kúrò ‘nínú omi tí kò léwu,’ ìyẹn ìjọ Kristẹni ti wá ń jẹ̀ka àbámọ̀ báyìí. Arábìnrin kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Kíkẹ́, ṣàlàyé pé “inú òtítọ́ ni wọ́n bí òun sí, tí wọ́n sì ti tọ́ òun dàgbà,” àmọ́ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó fi ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀ láti lọ máa lépa “àwọn ohun tó ń fani mọ́ra nínú ayé.” Lára ohun tó tìdí ẹ̀ yọ ni pé ó gboyún, ó sì ṣẹ́ oyún náà. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ọdún mẹ́ta tí mo lò lẹ́yìn òde ìjọ dá ọgbẹ́ tí kò lè jinná sí mi lọ́kàn. Èyí tó ń da ọkàn mi láàmú jù níbẹ̀ ni pé mo pa ọmọ mi tí mi ò tíì bí. . . . Mo fẹ́ sọ fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rò pé àwọn lè lọ ‘jẹ̀gbádùn’ ayé fún ìgbà díẹ̀ pé: ‘Ẹ má dan wò o!’ Ó lè dà bí ìgbádùn ní ìbẹ̀rẹ̀, àmọ́ ìgbẹ̀yìn rẹ̀ máa ń korò bí ewúro. Kò sí ohun tí ayé lè fúnni ju ìbànújẹ́ lọ. Mo mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé mo ti tọ́ ọ wò. Má ṣe fi ètò Jèhófà sílẹ̀! Ibẹ̀ nìkan lo ti lè gbé ìgbé ayé tó máa fún ẹ láyọ̀.”
19, 20. Ààbò wo ni ìjọ Kristẹni ń pèsè, báwo ló sì ṣe ń pèsè rẹ̀?
19 Ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó o bá kúrò nínú ìjọ Kristẹni tó jẹ́ ibi ààbò. Ọ̀pọ̀ àwọn tó rántí ìgbésí ayé asán tí wọ́n ń gbé kí wọ́n tó tẹ́wọ́ gba òtítọ́ kò ní fẹ́ ronú nípa rẹ̀ rárá. (Jòh. 6:68, 69) O lè rí ààbò kúrò lọ́wọ́ ewu àti àìláyọ̀ tó kún inú ayé Sátánì yìí tó o bá sún mọ́ àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin rẹ pẹ́kípẹ́kí. Tó o bá mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́, tó o sì ń wá sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé, ìyẹn á máa rán ẹ létí ọgbọ́n tó wà nínú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, á sì máa fún ẹ ní ìṣírí láti máa fi àwọn ìlànà yẹn sílò nígbèésí ayé rẹ. Ní gbogbo ọ̀nà, ó yẹ kó o ‘máa gbé Jèhófà lárugẹ nínú ìjọ ńlá,’ bí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù ti ṣe.—Sm. 35:18.
20 Àmọ́, fún àwọn ìdí tó yàtọ̀ síra, ìgbà míì wà tó máa ń ṣòro fún gbogbo Kristẹni láti dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Àfi kí ẹnì kan sọ ohun tó tọ́ láti ṣe fún wọn. Kí ni ìwọ tàbí ìjọ lápapọ̀ lè ṣe láti ran àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lọ́wọ́ nírú àkókò yẹn? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jíròrò bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè máa ‘tu àwọn ará wa nínú, ká sì máa gbé wọn ró.’—1 Tẹs. 5:11.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó kọ Sáàmù 73?
• Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà kọ́ wa?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé inú ìjọ Kristẹni lo ti lè rí ààbò?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ibi tí kò léwu ni kó o ti máa lúwẹ̀ẹ́; dúró nínú ìjọ!