‘Àwọn Ohun Tó Ṣe Ti Bá A Lọ ní Tààràtà’
‘Àwọn Ohun Tó Ṣe Ti Bá A Lọ ní Tààràtà’
ARÁKÙNRIN Theodore Jaracz, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé láàárọ̀ ọjọ́ Wednesday, June 9, 2010. Ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] ni. Àwọn tó sì gbẹ̀yìn rẹ̀ ni Melita tó ti jẹ́ ìyàwó rẹ̀ láti ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta [53] sẹ́yìn, àtàwọn míì bíi ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin kan àti àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́ta, ọkùnrin kan obìnrin méjì.
Wọ́n bí Arákùnrin Jaracz ní September 28, ọdún 1925, ní àgbègbè Pike County, ní ìpínlẹ̀ Kentucky, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà hàn ní August 10, 1941, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, èyí tó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó ṣe fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67].
Lọ́dún 1946, nígbà tí Arákùnrin Jaracz wà lọ́mọ ogún ọdún, ó lọ sí kíláàsì keje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n ní kí Arákùnrin Jaracz lọ ṣe iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ní ìlú Cleveland, tó wà lágbègbè ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́dún 1951, wọ́n yàn án pé kó lọ sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ẹ̀ka ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ìwé ọdọọdún ti 1983 Yearbook of Jehovah’s Witnesses ròyìn pé Arákùnrin Jaracz “jẹ́ ìṣírí ńlá fún àwọn ará jákèjádò orílẹ̀-èdè náà nítorí bó ṣe ní ìtara fún ìwàlétòlétò ètò Ọlọ́run àti bó ṣe ń múpò iwájú lóde ẹ̀rí.”
Lẹ́yìn tí Arákùnrin Jaracz pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó gbé Melita Lasko níyàwó ní December 10, 1956. Iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ni wọ́n ń ṣe lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn, wọ́n ń fi taratara ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti àgbègbè láwọn apá ibi tó gbòòrò lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́wọ́ ìparí ọdún 1974, wọ́n pe Arákùnrin Jaracz pé kó wá di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
A óò máa rántí Arákùnrin Jaracz gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jẹ́ olùfọkànsìn àti adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà, tó sì fi tọkàntọkàn gbájú mọ́ ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ó jẹ́ ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ tó sì láájò, ó sì tún jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó ń fi ire àwọn ẹlòmíì ṣáájú tirẹ̀. (1 Kọ́r. 13:4, 5) Bó ṣe ń fi ire àwọn ẹlòmíì ṣáájú tirẹ̀ yìí hàn nínú bó ṣe ń fẹ́ kí wọ́n máa hùwà tó tọ́ sí ẹni gbogbo kí wọ́n sì máa fi àánú hàn sí wọn. Síwájú sí i, ìfẹ́ tó ní fún àwọn èèyàn àti bí ọ̀rọ̀ wọn ṣe jẹ ẹ́ lógún mú kó máa fìtara kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dùn wá gan-an bá a ṣe pàdánù arákùnrin tó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára ní Bẹ́tẹ́lì àti láàárín ẹgbẹ́ ará kárí ayé yìí, a láyọ̀ pé Arákùnrin Jaracz fi ìdúróṣinṣin ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ó dá wa lójú pé ó ti jẹ́ ‘olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, ó sì ti gba adé ìyè.’ (Ìṣí. 2:10) Kò sì sí ìyè méjì pé ‘àwọn ohun tí ó ṣe ti bá a lọ ní tààràtà.’—Ìṣí. 14:13.