Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Darí Yín
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Darí Yín
“Ní ọgbọ́n, ní òye.”—ÒWE 4:5.
1, 2. (a) Kí ló ran àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro tó bá a fínra? (b) Báwo lo ṣe lè ní ọgbọ́n àti òye?
“NÍGBÀ tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.” Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó sọ̀rọ̀ yìí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn ìgbà kan wà tó ṣòro fún un láti ṣe ohun tó tọ́. Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo ìṣòro tó bá a fínra yìí? Ó sọ pé: “Èmi abòṣì ènìyàn!” (Róòmù 7:21-24) Ǹjẹ́ o mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù? Ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún ìwọ náà nígbà míì láti ṣe ohun tó tọ́? Ṣé ìyẹn máa ń tán ẹ ní sùúrù, bó ṣe ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Pọ́ọ̀lù borí ìṣòro tó bá a fínra, ìwọ náà lè borí ìṣòro rẹ.
2 Ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù ṣàṣeyọrí ni pé ó jẹ́ kí “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” máa darí òun. (2 Tím. 1:13, 14) Nípa bẹ́ẹ̀, ó ní ọgbọ́n àti òye tó jẹ́ kó lè kojú àwọn ìṣòro tó ní, kó sì ṣe àwọn ìpinnu tó dáa. Jèhófà Ọlọ́run lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti ní ọgbọ́n àti òye. (Òwe 4:5) Ó ti fún wa ní ìmọ̀ràn tó dára jù lọ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Ka 2 Tímótì 3:16, 17.) Ṣàgbéyẹ̀wò bó o ṣe lè jàǹfààní nínú àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nínú àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, lórí ọ̀ràn ìnáwó àti nígbà tó o bá dá wà.
Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Darí Rẹ Nínú Ilé
3, 4. Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún ẹ láti máa tẹ̀ lé ìlànà àwọn òbí rẹ, kí ló sì fà á tí àwọn òbí fi máa ń fi ìlànà lélẹ̀?
3 Ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún ẹ láti máa tẹ̀ lé ìlànà tí àwọn òbí rẹ fi lélẹ̀? Kí ló lè mú kó rí bẹ́ẹ̀? Ó lè jẹ́ pé o fẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fún ẹ lómìnira. Kò sóhun tó burú nínú ìyẹn. Ara pé o ti ń dàgbà di géńdé nìyẹn. Àmọ́ nígbà tó o ṣì wà lábẹ́ àwọn òbí rẹ, ojúṣe rẹ ni láti tẹ̀ lé ohun táwọn òbí rẹ bá sọ.—Éfé. 6:1-3.
4 Tó o bá ní èrò tó tọ́ nípa àwọn ìlànà tí àwọn òbí rẹ fi lélẹ̀ àti ohun tí wọ́n ní kó o ṣe, ó máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti ṣègbọràn. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ rẹ lè jọ ti ọ̀dọ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún kan tó ń jẹ́ Brielle, a tó sọ nípa àwọn òbí rẹ̀ pé: “Wọn kò mọ̀ pé èmi náà kì í ṣe ọmọdé mọ́. Wọn kì í fẹ́ kí n sọ tẹnu mi, kí n ṣe ìpinnu tàbí kí n tiẹ̀ mọ̀ pé mo ti dàgbà.” Bíi ti Brielle, ó lè máa ṣe ìwọ náà bíi pé àwọn òbí rẹ kò fún ẹ lómìnira tó bó o ṣe fẹ́. Àmọ́, torí pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ àwọn òbí rẹ lógún ni wọ́n ṣe fún ẹ ní àwọn ìlànà tí wàá máa tẹ̀ lé. Láfikún sí i, àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni mọ̀ pé àwọn máa jíhìn fún Jèhófà nípa bí wọ́n ṣe bójú tó ẹ.—1 Tím. 5:8.
5. Báwo ní gbígbọ́ràn sí àwọn òbí rẹ lẹ́nu ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní?
5 Ní ti gidi, ńṣe ni títẹ̀lé ìlànà táwọn òbí rẹ fi lélẹ̀ dà bí ìgbà tó o san gbèsè tó o jẹ báńkì, bó o bá ṣe ń san gbèsè náà pa dà lásìkò, bẹ́ẹ̀ náà ni báńkì náà á túbọ̀ máa fọkàn tán ẹ láti yá ẹ lówó. Bákan náà, o jẹ àwọn òbí rẹ ní gbèsè ọ̀wọ̀ àti ìgbọràn. (Ka Òwe 1:8.) Bó o bá ṣe ń ṣègbọràn sí, bẹ́ẹ̀ lọkàn àwọn òbí rẹ á ṣe túbọ̀ máa balẹ̀ láti fún ẹ lómìnira sí i. (Lúùkù ) Àmọ́ tó bá jẹ́ gbogbo ìgbà lo máa ń rú òfin tí wọ́n fún ẹ, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bí àwọn òbí rẹ bá dín àǹfààní tí wọ́n fún ẹ kù tàbí kí wọ́n tiẹ̀ gba gbogbo rẹ̀ pátá lọ́wọ́ rẹ. 16:10
6. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti jẹ́ onígbọràn?
6 Ọ̀nà kan tí àwọn òbí lè gbà ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìlànà wọn ni pé kí àwọn náà fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Bí àwọn fúnra wọn ṣe ń fínnúfíndọ̀ pa àwọn òfin Jèhófà mọ́ fi hàn pé àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́gbọ́n dání. Èyí á jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún àwọn ọmọ láti máa fi irú ojú kan náà wo àwọn ìlànà táwọn òbí wọn fi lélẹ̀. (1 Jòh. 5:3) Láfikún sí i, Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ìgbà kan tí Jèhófà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láǹfààní láti sọ tẹnu wọn nípa àwọn ọ̀ràn kan. (Jẹ́n. 18:22-32; 1 Ọba 22:19-22) Ǹjẹ́ àwọn àkókò kan wà tí àwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn láǹfààní láti sọ tẹnu wọn lórí àwọn ọ̀ràn kan?
7, 8. (a) Ìṣòro wo ni àwọn ọ̀dọ́ kan ń dojú kọ? (b) Kí lo gbọ́dọ̀ mọ̀ kó o lè jàǹfààní látinú ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ?
7 Àwọn ọ̀dọ́ tún lè dojú kọ ìṣòro ohun tí wọ́n máa ṣe nígbà tí wọ́n bá ń rò pé àwọn òbí àwọn ń rí sí àwọn ju bó ṣe yẹ lọ. Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti ọ̀dọ́kùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Craig, tó sọ pé, “Ńṣe ni màmá mi dà bí ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, àṣìṣe mi ni wọ́n máa ń wá ṣáá.”
8 Ńṣe ni ìtọ́sọ́nà àti ìbáwí máa ń dà bíi pé wọ́n ń ṣe àríwísí èèyàn. Bíbélì náà sọ pé, kódà nígbà tí wọ́n bá báni wí lọ́nà tó tọ́, ó máa ń ṣòro láti gbà á mọ́ra. (Héb. 12:11) Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ? Ohun pàtàkì tó yẹ kó o rántí ni pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìfẹ́ tí àwọn òbí rẹ ní sí ẹ ló mú kí wọ́n bá ẹ wí. (Òwe 3:12) Wọ́n ò fẹ́ kó o máa hùwàkiwà, ńṣe ni wọ́n fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ànímọ́ tó dáa. Ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí rẹ mọ̀ pé tí àwọn bá kọ̀ táwọn kò tọ́ ẹ sọ́nà, ohun tó túmọ̀ sí ni pé àwọn kórìíra rẹ! (Ka Òwe 13:24.) Kó o sì tún mọ̀ pé, ṣíṣe àṣìṣe jẹ́ ara ọ̀nà téèyàn ń gbà kẹ́kọ̀ọ́. Torí náà tí wọ́n bá tọ́ ẹ sọ́nà, kí ló dé tí o kò wo ọgbọ́n tó wà nínú ohun tí wọ́n sọ? “Níní [ọgbọ́n] gẹ́gẹ́ bí èrè sàn ju níní fàdákà gẹ́gẹ́ bí èrè, níní in gẹ́gẹ́ bí èso sì sàn ju níní wúrà pàápàá.”—Òwe 3:13, 14.
9. Dípò tí àwọn ọ̀dọ́ á fi máa ronú pé ìwà tí kò dáa ni wọ́n ń hù sáwọn, kí ni wọ́n lè ṣe?
9 Àmọ́ àwọn òbí náà máa ń ṣe àṣìṣe o. (Ják. 3:2) Ìgbà míì wà tí wọ́n lè sọ̀rọ̀ láìronú jinlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń bá ẹ wí. (Òwe 12:18) Kí ló lè mú kí àwọn òbí rẹ hùwà lọ́nà yẹn? Ó lè jẹ́ pé wọ́n ní ìdààmú ọkàn tàbí kí wọ́n wò ó pé ẹ̀bi àwọn ni àṣìṣe tó o ṣe. Dípò tí wàá fi máa ronú pé wọ́n ń hùwà tí kò tọ́ sí ẹ, kí ló dé tí o kò fi ìmọrírì hàn fún bí wọ́n ṣe sapá látọkàn wá láti ràn ẹ́ lọ́wọ́? Bí o bá ń gba ìbáwí, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an nígbà tó o bá dàgbà.
10. Báwo lo ṣe lè túbọ̀ máa pa ìlànà àwọn òbí rẹ mọ́, kó o sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà wọn?
10 Ṣé wàá fẹ́ láti túbọ̀ máa pa ìlànà àwọn òbí rẹ mọ́, kó o sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà wọn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o túbọ̀ máa wá àyè láti bá wọn sọ̀rọ̀. Báwo lo ṣe lè ṣe ìyẹn? Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o máa fetí sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Ják. 1:19) Dípò tí wàá fi tètè máa sọ pé kò sí ohun tó burú nínú nǹkan tó o ṣe, sapá láti pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ra, kó o sì gbọ́ ohun tí àwọn òbí rẹ fẹ́ sọ. Ohun tí wọ́n sọ ni kó o pọkàn pọ̀ lé lórí, kì í ṣe ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ ọ́. Lẹ́yìn náà, kó o wá ronú ọ̀nà tó o lè gbà tún ọ̀rọ̀ àwọn òbí rẹ sọ lọ́kàn rẹ, kó o sì wá fún wọn lésì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kó dá wọn lójú pé o gbọ́ ohun tí wọ́n sọ. Tó o bá wá fẹ́ ṣàlàyé nípa ohun tó o sọ tàbí ohun tó o ṣe ńkọ́? Lọ́pọ̀ ìgbà, ó mọ́gbọ́n dání pé kó o ‘ṣàkóso ètè rẹ’ títí dìgbà tó o fi máa ṣe ohun tí àwọn òbí rẹ fẹ́. (Òwe 10:19) Bí àwọn òbí rẹ bá rí i pé o ti gbọ́ tiwọn, àwọn náà á fẹ́ gbọ́ tẹnu rẹ. Irú ìwà àgbà bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń darí rẹ.
Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Darí Rẹ Láti Máa Ṣọ́wó Ná
11, 12. (a) Tó bá dọ̀rọ̀ owó, kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa níṣìírí pé ká ṣe, kí sì nìdí? (b) Báwo làwọn òbí rẹ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣọ́wó ná?
11 Bíbélì sọ pé: ‘Owó jẹ́ fún ìdáàbòbò.’ Àmọ́ ẹsẹ Bíbélì kan náà yẹn fi hàn pé ọgbọ́n tún wá ṣe pàtàkì ju owó lọ. (Oníw. 7:12) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìṣírí pé ká máa fojú pàtàkì wo owó, kò sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ owó. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ owó? Gbé àpèjúwe yìí yẹ̀ wò: Ọ̀bẹ jẹ́ ohun èlò tó wúlò gan-an fún agbọ́únjẹ tó já fáfá. Àmọ́ ọ̀bẹ yìí kan náà lè ṣe ẹni tí kò fiyè sí ohun tó ń ṣe tàbí tí kò bìkítà léṣe. Bí owó ṣe rí náà nìyẹn, ó wúlò gan-an tá a bá lò ó lọ́nà tó tọ́. Àmọ́, àwọn tó “pinnu láti di ọlọ́rọ̀” sábà máa ń jẹ́ kí owó bá àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé wọn jẹ́, kódà ó máa ń ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Abájọ tí wọ́n fi máa ń fi “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—Ka 1 Tímótì 6:9, 10.
12 Báwo lo ṣe lè máa fọgbọ́n ṣọ́wó ná? O lè ní kí àwọn òbí rẹ kọ́ ẹ bó o ṣe lè wéwèé bí wàá ṣe máa náwó. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i, ẹni òye sì ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá.” (Òwe 1:5) Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Anna ní kí àwọn òbí òun fún òun ní irú ìtọ́sọ́nà tó já fáfá bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Dádì mi kọ́ mi bí màá ṣe wéwèé ìnáwó mi, ó sì kọ́ mi bó ti ṣe pàtàkì tó láti mọ bí èèyàn á ṣe máa ṣọ́wó ìdílé ná.” Mọ́mì Anna náà kọ́ ọ láwọn ohun tó lè ṣe láti máa ṣọ́wó ná. Anna sọ pé: “Mọ́mì mi kọ́ mi láti máa yọwó ọjà láwọn ibi mélòó kan kí n tó rà á.” Àǹfààní wo nìyẹn ti wá ṣe fún Anna? Ó sọ pé: “Ó ti wá ṣeé ṣe fún mi láti máa bojú tó àwọn ìnáwó ara mi. Mi ò kì í ná ìnákúnàá, torí náà ọkàn mi balẹ̀ torí pé mi ò kì í tọrùn bọ gbèsè.”
13. Báwo lo ṣe lè máa kó ara rẹ níjàánu lórí ọ̀rọ̀ owó níná?
13 Wàá kàn rí i pé ńṣe lo máa ń tọrùn bọ gbèsè tó bá jẹ́ pé ńṣe lo kàn ń kù gìrì rajà tàbí tó ò ń náwó láti fi ṣe fọ́rífọ́rí fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí o kò fi ní kó sínú ìṣòro yìí? Ní ti ọ̀rọ̀ owó níná, o gbọ́dọ̀ kọ́ láti mọ bí wàá ṣe máa kó ara rẹ níjàánu. Ohun tí Ellena, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Bí mo bá máa jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi, mo ti máa ń pinnu iye tí màá ná. . . . Mo tún rí i pé ó mọ́gbọ́n dání láti lọ sọ́jà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tó mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná, tí wọ́n sì máa fún mi ní ìṣírí láti yọwọ́ ọjà káàkiri, kó má ṣe jẹ́ pé ohun tí mo bá kọ́kọ́ rí ni màá rà.”
14. Kí nìdí tó o fi gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra fún “agbára ìtannijẹ ọrọ̀”?
14 Wíwá owó àti ṣíṣọ́ owó ná jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé èèyàn. Àmọ́, Jésù sọ pé “àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn,” ló máa ń ní ojúlówó ayọ̀. (Mát. 5:3) Ó kìlọ̀ pé àwọn nǹkan bí “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè fún ìfẹ́ tẹ́nì kan ní fún àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run pa. (Máàkù 4:19) Ṣé o wá rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kó o máa jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run darí rẹ, kó o sì máa fi ojú tó tọ́ wo owó?
Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Darí Rẹ Nígbà Tó O Bá Dá Wà
15. Ìgbà wo ló ṣeé ṣe kí Sátánì dán ìdúróṣinṣin rẹ sí Ọlọ́run wò jù lọ?
15 Ìgbà wo lo rò pé Sátánì lè dán ìdúróṣinṣin rẹ sí Ọlọ́run wò jù lọ, ṣé ìgbà tó o bá wà pẹ̀lú àwọn èèyàn ni àbí ìgbà tó o bá dá wà? Nígbà tó o bá wà nílé ìwé tàbí níbi iṣẹ́, ó ṣeé ṣe kó o túbọ̀ wà lójúfò láti kọ ohun tó bá fẹ́ dán ẹ wò. O máa ń wà lójúfò láti rí ohun tó lè wu àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run léwu. Ìgbà tó o bá ń gbafẹ́ tó o sì gbàgbéra ló ṣeé ṣe jù lọ pé kó o ṣìwà hù.
16. Kí nìdí tó o fi ní láti ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà tó o bá tiẹ̀ dá wà?
16 Kí nìdí tó o fi ní láti ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà tó o bá tiẹ̀ dá wà? Rántí èyí: Bákan méjì ni, yálà kó o ṣe ohun tó dun Jèhófà tàbí kó o mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Jẹ́n. 6:5, 6; Òwe 27:11) Ohun tó o bá ṣe kan Jèhófà torí pé ‘ó bìkítà fún ẹ.’ (1 Pét. 5:7) Ó fẹ́ kó o gbọ́ràn sí òun lẹ́nu, kó o lè ṣe ara rẹ láǹfààní. (Aísá. 48:17, 18) Nígbà tí àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀, wọ́n mú kí inú rẹ̀ bà jẹ́. (Sm. 78:40, 41) Lọ́wọ́ kejì, Jèhófà ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún wòlíì Dáníẹ́lì, kódà áńgẹ́lì kan tiẹ̀ pè é ní “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.” (Dán. 10:11) Kí nìdí? Ìdí ni pé Dáníẹ́lì jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, kì í ṣe ní gbangba nìkan àmọ́ nígbà tó dá wà pẹ̀lú.—Ka Dáníẹ́lì 6:10.
17. Ìbéèrè wo lo lè bi ara rẹ nígbà tó o bá fẹ́ yan eré ìnàjú?
17 Láti lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run nígbà tó o bá wà níwọ nìkan, o gbọ́dọ̀ mú kí “agbára ìwòye [rẹ máa] fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́” kó o sì “tipasẹ̀ lílò” kọ́ àwọn agbára náà nípa ṣíṣe ohun tó o mọ̀ pé ó tọ́. (Héb. 5:14) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́, kó o sì yàgò fún ohun tí kò tọ́ nígbà tó o bá fẹ́ yan orin tó o máa gbọ́, eré tó o máa wò tàbí ìkànnì tó o máa lọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Béèrè àwọn ìbéèrè yìí lọ́wọ́ ara rẹ: ‘Ṣé nǹkan yìí á mú kí n máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, àbí ńṣe ló máa mú kí n máa yọ̀ “nítorí àjálù ẹlòmíràn”?’ (Òwe 17:5) ‘Ǹjẹ́ ó máa ràn mí lọ́wọ́ láti “nífẹ̀ẹ́ ohun rere” àbí ńṣe ló máa mú kó ṣòro fún mi láti “kórìíra ohun búburú”?’ (Ámósì 5:15) Ohun tó ò ń ṣe nígbà tó o bá dá wà ló máa fi nǹkan tó o kà sí pàtàkì jù hàn.—Lúùkù 6:45.
18. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá ti ń lọ́wọ́ nínú ìwà tí kò dáa ní kọ̀rọ̀, kí sì nìdí?
18 Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá ti ń lọ́wọ́ nínú ìwà tó o mọ̀ pé kò dáa ní kọ̀rọ̀? Rántí pé “ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” (Òwe 28:13) Kì í ṣe ìwà ọgbọ́n láti máa bá a nìṣó ní híhùwà tí kò dáa, kó o sì “máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run!” (Éfé. 4:30) O ní ojúṣe kan lọ́dọ̀ Ọlọ́run, lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ àti lọ́dọ̀ ìwọ fúnra rẹ láti jẹ́wọ́ ìwà àìtọ́ èyíkéyìí tó o bá hù. Lórí ọ̀ràn yìí, “àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ” lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn sọ pé: “Kí wọ́n sì gbàdúrà lé [oníwà àìtọ́ náà] lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.” (Ják. 5:14, 15) Lóòótọ́ o, èyí lè mú ìtìjú díẹ̀ dání, ó sì ṣeé ṣe kó ní àbájáde tí kò bára dé. Àmọ́ tó o bá ní ìgboyà láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́, wàá bọ́ lọ́wọ́ ìpalára ọjọ́ iwájú, wàá sì ní ìtura tó ń wá látinú níní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.—Sm. 32:1-5.
Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀
19, 20. Kí ni Jèhófà fẹ́ kó o ní, àmọ́ kí lo gbọ́dọ̀ ṣe?
19 Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó sì fẹ́ kí ìwọ náà láyọ̀. (1 Tím. 1:11) Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ ẹ́ lógún gan-an. Kódà bí kò bá sí ẹnì tó kíyè sí ìsapá rẹ láti ṣe ohun tó tọ́, Ọlọ́run ń kíyè sí i. Kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Jèhófà. Ó ń wò ẹ́, kì í ṣe kó lè wá ẹ̀sùn sí ẹ lẹ́sẹ̀, àmọ́ kó lè tì ẹ́ lẹ́yìn nínú ìsapá rẹ láti ṣe ohun tó tọ́. “Ojú [Ọlọ́run] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kíró. 16:9.
20 Torí náà, jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí rẹ, kó o sì máa fi àwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò. Wàá tipa bẹ́ẹ̀ ní ọgbọ́n àti òye láti borí àwọn ìṣòro tó le gan-an, wàá sì lè ṣe àwọn ìpinnu tó lágbára nígbèésí ayé rẹ. Kì í ṣe pé inú àwọn òbí rẹ àti Jèhófà máa dùn sí ẹ nìkan ni, àmọ́ ìwọ fúnra rẹ á ní ojúlówó ayọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí làwọn ọ̀dọ́ lè ṣe láti máa tẹ̀ lé ìlànà àti ìtọ́sọ́nà àwọn òbí wọn, kó sì ṣe wọ́n láǹfààní?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa fi ojú tó tọ́ wo owó?
• Báwo lo ṣe lè máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà kódà nígbà tó o bá dá wà?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ṣé wàá jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run nígbà tó o bá dá wà?