Jèhófà Ń Gbọ́ Igbe Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀
Jèhófà Ń Gbọ́ Igbe Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀
SÓLÓMỌ́NÌ ọlọ́gbọ́n Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kíyè sí i pé: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo [wa].” (Oníw. 9:11) Ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tàbí àdánwò lílekoko lè da ìgbésí ayé wa rú lọ́nà tó burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tá a jọ sún mọ́ra gan-an nínú ìdílé lè kú lójijì, èyí sì lè fa ìbànújẹ́ ńlá báni. Ní àwọn ọ̀sẹ̀ àti oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, ìbànújẹ́ náà lè pọ̀ lápọ̀jù, ó sì lè mú kéèyàn sọ̀rètí nù. Nǹkan lè tojú súni débi táá fi máa ṣèèyàn bíi pé òun jẹ̀bi àti pé òun kò kúnjú ìwọ̀n láti gbàdúrà sí Jèhófà nítorí ìmọ̀lára òun.
Nírú ipò bẹ́ẹ̀, èèyàn nílò ìṣírí, ìgbatẹnirò àti ìfẹ́. Onísáàmù náà Dáfídì kọ orin tó fini lọ́kàn balẹ̀ yìí pé: “Jèhófà ń fún gbogbo àwọn tí ó ṣubú ní ìtìlẹyìn, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde.” (Sm. 145:14) Bíbélì sọ fún wa pé “ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíró. 16:9) Ó wà “pẹ̀lú ẹni tí a tẹ̀ rẹ́, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí, láti mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọ jí àti láti mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.” (Aísá. 57:15) Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú fún àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí?
‘Ọ̀rọ̀ Tí Ó Bọ́ sí Àkókò’
Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà pèsè ìrànlọ́wọ́ lásìkò tí ó tọ́ jẹ́ nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn ará nínú ìjọ Kristẹni. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹs. 5:14) Bí àwọn ará tí wọ́n jẹ́ aláàánú bá ṣaájò ẹni tí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn, ó lè mára tuni lásìkò ìdààmú àti ìbànújẹ́. Ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú tá a sọ, kódà láàárín àkókò kúkúrú, lè nípa tó pọ̀ nínú gbígbé ẹni tó sorí kọ́ ró. Ó lè jẹ́ ẹnì kan tó ti ní ìṣòro ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn nígbà kan rí ló máa sọ ọ̀rọ̀ kan tó fúnni ní ìṣírí. Ó sì lè jẹ́ ọ̀rẹ́ wa kan tó ti ní ìrírí nípa ìgbésí ayé ló máa pe àfiyèsí wa sí ohun kan. Láwọn ọ̀nà wọ̀nyí, Jèhófà lè mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọjí.
Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin alàgbà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alex, kò pẹ́ tó ṣègbéyàwó ni ìyàwó rẹ̀ kú nítorí àìsàn kògbóògùn kan tó ṣe é. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan tó lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò sapá láti sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fún Alex. Ìyàwó tirẹ̀ náà ti ṣaláìsí àmọ́ ó ti fẹ́ ẹlòmíì. Alábòójútó arìnrìn-àjò náà sọ bí ìbànújẹ́ ṣe dorí òun kodò. Ara máa ń tù ú nígbà tó bá wà pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú Òwe 15:23.
iṣẹ́ ìsìn pápá àti láwọn ìpàdé. Tó bá wá wọ inú yàrá rẹ̀, tó sì tilẹ̀kùn, ó máa ń nímọ̀lára ìdánìkanwà. Alex sọ pé: “Ara tù mí gan-an nígbà tí mo mọ̀ pé bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mí kì í ṣe ohun tuntun àti pé bó ṣe ń ṣe àwọn míì náà nìyẹn.” Dájúdájú, ‘ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò tó dára’ lè tuni nínú lásìkò tí wàhálà bá wà.—Kristẹni míì tó jẹ́ alàgbà, tó mọ àwọn èèyàn mélòó kan tí ọkọ tàbí aya wọn ti kú sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí fún Alex. Ó bá Alex kẹ́dùn, ó sì sọ fún un tìfẹ́tìfẹ́ pé Jèhófà mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wa àti ohun tá a nílò. Arákùnrin náà sọ pé: “Bọ́dún ti ń gorí ọdún, tó o bá rí i pé o nílò ẹnì kejì, ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ṣe ni pé kó o gbé ẹlòmíì níyàwó.” Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn kú, tí wọ́n sì fẹ́ láti fẹ́ ẹlòmíì ni ipò wọn á gbà wọ́n láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, nígbà tí Alex ń ronú nípa ọ̀rọ̀ arákùnrin yẹn, ó sọ pé, “Tí wọ́n bá rán ẹ létí pé fífẹ́ ẹlòmíì jẹ́ ìṣètò tí Jèhófà ṣe, kò ní jẹ́ kó o máa ro èròkerò pé o máa di aláìṣòótọ́ sí ẹnì kejì rẹ tàbí sí ètò ìgbéyàwó tí Jèhófà dá sílẹ̀ bó o bá yàn láti fẹ́ ẹlòmíì lọ́jọ́ iwájú.”—1 Kọ́r. 7:8, 9, 39.
Onísáàmù náà Dáfídì, tí òun fúnra rẹ̀ dojú kọ ọ̀pọ̀ àdánwò àti ìnira, gbà pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” (Sm. 34:15) Ó dájú pé Jèhófà lè dáhùn àdúrà àwọn ẹni rírẹlẹ̀ tó ń ké pè é lásìkò tó tọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtùnú látẹnu àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ní ìfòyemọ̀ tí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú wọn. Ohun tí Ọlọ́run pèsè fún wa yìí níye lórí gan-an, ó sì gbéṣẹ́.
Àwọn Ìpàdé Ìjọ Ń Ranni Lọ́wọ́
Èròkerò sábà máa ń wá sọ́kàn ẹni tó sorí kọ́, èyí sì lè mú kó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Àmọ́ Owe 18:1 kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” Alex gbà pé: “Bí ọkọ tàbí aya ẹni bá kú, èròkerò á kàn máa ṣàdédé wá síni lọ́kàn.” Ó rántí pé òun máa ń bi ara òun pé: “‘Àbí ohun kan wà tó yẹ kí n ṣe tí mi ò ṣe ni? Ṣé mi ò bá ti túbọ̀ lo ẹ̀mí ìgbatẹnirò àti òye?’ Mi ò fẹ́ máa dá wà. Mi ò fẹ́ pa dà sípò àpọ́n. Ó ṣòro láti gbé àwọn èrò wọ̀nyí kúrò lọ́kàn torí pé ojoojúmọ́ ni wàá máa rántí pé o kò lẹ́nì kejì.”
Ẹni tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí máa ń nílò àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run táá máa bá ṣọ̀rẹ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Èèyàn á bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pàdé láwọn ìpàdé ìjọ. Tá a bá wà ní ìpàdé, a máa ń ṣí ọkàn wa payá láti gbọ́ àwọn èrò Ọlọ́run tó máa ń gbéni ró.
Àwọn ìpàdé ìjọ máa ń jẹ́ ká máa fi ojú tó tọ́ wo ipò tá a bá ara wa. Bá a ṣe ń gbọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a sì ń ṣàṣàrò lé wọn lórí, ńṣe là ń pọkàn pọ̀ sórí ọ̀ràn pàtàkì tó wà nílẹ̀, ìyẹn ni bí Jèhófà ṣe máa dá ara rẹ̀ láre gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run àti bó ṣe máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, kì í wulẹ̀ ṣe ìyà tó ń jẹ wá nìkan. Síwájú sí i, láwọn àkókò tá a fi ń gbọ́ àwọn ìtọ́ni tẹ̀mí yẹn, ó ń fún wa lókun láti mọ̀ pé bí àwọn míì kò bá tiẹ̀ mọ ohun tá à ń bá yí tàbí tí wọn kò lóye bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wa, ó dájú pé Jèhófà mọ̀ ọ́n. Ó mọ̀ pé “nítorí ìrora ọkàn-àyà, ìdààmú máa ń bá ẹ̀mí.” (Òwe 15:13) Ọlọ́run tòótọ́ fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́, èyí sì ń fún wa ní ìṣírí àti okun láti máa bá a lọ.—Sm. 27:14.
Nígbà táwọn ọ̀tá ń gbógun ti Dáfídì Ọba lójú méjèèjì, ó ké pe Ọlọ́run pé: “Àárẹ̀ sì mú ẹ̀mí mi nínú mi; ọkàn-àyà mi ti kú tipiri nínú mi.” (Sm. 143:4) Ìpọ́njú lè tán èèyàn lókun nípa tara àti ní ti ìmọ̀lára, kódà ó lè mú kí ọkàn ẹni kú tipiri. Àìsàn tàbí àìlera ọlọ́jọ́ pípẹ́ lè mú ìpọ́njú wá. A lè ní ìdánilójú pé Jèhófà á ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á. (Sm. 41:1-3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kì í woni sàn lọ́nà ìyanu lóde òní, ó máa fún àwọn tó ń ṣàìsàn ní ọgbọ́n àti okun tí wọ́n nílò láti fara da ipò náà. Má gbàgbé pé Jèhófà ni Dáfídì yíjú sí nígbà tí ìṣòro dorí rẹ̀ kodò. Ó kọrin pé: “Mo ti rántí àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn; mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ; tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.”—Sm. 143:5.
Bí wọ́n ṣe kọ ọ̀rọ̀ onímìísí yìí sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé Jèhófà mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wa. Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé ó ń gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. Tá a bá tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ‘òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé wa ró.’—Sm. 55:22.
“Gbàdúrà Láìdábọ̀”
Ìwé Jákọ́bù 4:8 sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” Ọ̀nà kan tá a lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run jẹ́ nípasẹ̀ àdúrà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé ká “máa gbàdúrà láìdábọ̀.” (1 Tẹs. 5:17) Kódà tó bá ṣòro fún wa láti sọ bí ìṣòro wa ṣe rí, “ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú àwọn ìkérora tí a kò sọ jáde.” (Róòmù 8:26, 27) Kò sí àní-àní pé Jèhófà mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa.
Monika tó gbádùn irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà sọ pé: “Nípasẹ̀ àdúrà, Bíbélì kíkà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́, mo ti wá mọ̀ ọ́n lára pé Jèhófà ti di Ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́. Ó ti wá di ẹni gidi sí mi débi pé, mò ń rí ọwọ́ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi nígbà gbogbo. Ó máa ń tù mí nínú láti mọ̀ pé bí mi ò bá tiẹ̀ lè ṣàlàyé bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi, ó mọ ìṣòro mi. Mo mọ̀ pé inú rere rẹ̀ àti ìbùkún rẹ̀ kò lópin.”
Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká mọrírì ìfẹ́ àti ọ̀rọ̀ ìtùnú látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ká máa fi ìmọ̀ràn àti àwọn ìránnilétí tá à ń rí gbà láwọn ìpàdé ìjọ sílò, ká sì máa tú ohun tó wà lọ́kàn wa jáde fún Jèhófà nínú àdúrà. Àwọn ìpèsè tó bọ́ sákòókò yìí jẹ́ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fi hàn pé òun bìkítà fún wa. Alex ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun fúnra rẹ̀. Ó sọ pé: “Tá a bá ṣe ipa tiwa láti máa lo àwọn ohun tí Jèhófà Ọlọ́run pèsè fún wa láti mú ká lókun nípa tẹ̀mí, a óò ní ‘agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá’ láti fara da ìṣòro èyíkéyìí tá a bá dojú kọ.”—2 Kọ́r. 4:7.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀
Ìwé Sáàmù kún fún àwọn ọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú bí nǹkan ṣe rí lára ẹni, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó mú un dáni lójú pé Jèhófà ń gbọ́ igbe ẹni rírẹlẹ̀ tí ẹ̀dùn ọkàn ti mú kó sorí kọ́. Gbé àwọn àyọkà inú Sáàmù yìí yẹ̀ wò:
“Mo ń ké pe Jèhófà ṣáá nínú wàhálà mi, mo sì ń kígbe sí Ọlọ́run mi fún ìrànlọ́wọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohùn mi láti inú tẹ́ńpìlì rẹ̀, igbe mi níwájú rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ sì dé etí rẹ̀ wàyí.”—Sm. 18:6.
“Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” —Sm. 34:18.
“[Jèhófà] ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.”—Sm. 147:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
‘Ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò’ máa ń tuni nínú lásìkò wàhálà!