Kórè Ìbùkún Yanturu Nípasẹ̀ Ọba Tí Ọlọ́run Ń fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Darí!
Kórè Ìbùkún Yanturu Nípasẹ̀ Ọba Tí Ọlọ́run Ń fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Darí!
“Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e.”—AÍSÁ. 11:2.
1. Kí ni àwọn kan ti sọ nípa àwọn ìṣòro tó wà nínú ayé?
NÍ ỌDÚN 2006, Stephen Hawking tó jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà lójú òfuurufú béèrè pé: “Nínú ayé tí ìdàrúdàpọ̀ ti bá ọ̀ràn ìṣèlú rẹ̀ yìí, táwọn èèyàn ti jingíri sínú ìwàkiwà, tí àyíká sì ti bà jẹ́ kọjá sísọ, báwo ni aráyé ṣe lè máa wà nìṣó fún ọgọ́rùn-ún ọdún sí i?” Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn New Statesman sọ pé: “A kò tíì fòpin sí òṣì, ọwọ́ wa kò sì tíì tẹ àlàáfíà tó kárí ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dà bíi pé òdì kejì ohun tá à ń retí ló ń ṣẹlẹ̀. Kì í kúkú ṣe pé a kò gbìyànjú tó. A ti dán ìjọba Kọ́múníìsì wò nínú èyí tí ètò ọrọ̀ ajé ti wà lábẹ́ àṣẹ ìjọba, a sì ti gbìyànjú ètò ìṣàkóso tí ètò ọrọ̀ ajé ti wà lọ́wọ́ àwọn ọlọ́rọ̀; a ti dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ bóyá ayé á jẹ́ ṣọ̀kan; orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan sì ti gbìyànjú láti kó ohun ìjà runlérùnnà jọ kí wọ́n má bàa dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ra wọn mọ́. A ti ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ‘ogun láti fòpin sí ogun kan ṣoṣo’ ká lè fi hàn pé a mọ bí a ṣe lè fòpin sí ogun.”
2. Báwo ni Jèhófà ṣe máa tó lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lórí ilẹ̀ ayé?
2 Irú ọ̀rọ̀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí kò lè ya àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́nu. Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run kò dá àwa èèyàn láti máa ṣàkóso ara wa. (Jer. 10:23) Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọba Aláṣẹ wa láyé àtọ̀run. Nítorí bẹ́ẹ̀, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa láwọn ìlànà tí a ó máa tẹ̀ lé, kó pinnu ohun tó yẹ ká fi ìgbésí ayé wa ṣe, kó sì fi ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ hàn wá. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa tó lo ọlá àṣẹ rẹ̀ láti fòpin sí ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn tó ti forí ṣánpọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ìjọba ni wọ́n ti dán wò. Ọlọ́run tún máa mú ìparun wá sórí gbogbo àwọn tó bá kọ̀ láti fara mọ́ ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí aráyé jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé àti ẹrú Sátánì Èṣù, tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.”—2 Kọ́r. 4:4.
3. Kí ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà?
3 Nígbà tí ayé bá di Párádísè, Jèhófà máa fi ìfẹ́ lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run láti ṣàkóso aráyé nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà. (Dán. 7:13, 14) Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Ọba Ìjọba yìí pé: “Ẹ̀ka igi kan yóò sì yọ láti ara kùkùté Jésè; àti láti ara gbòǹgbò rẹ̀, èéhù kan yóò máa so èso. Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ńlá, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Aísá. 11:1, 2) Ọ̀nà wo gan-an ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà mú kí Jésù Kristi tó jẹ́ ‘ẹ̀ka igi láti ara kùkùté Jésè’ yìí kúnjú ìwọ̀n láti ṣàkóso aráyé? Àwọn ìbùkún wo la máa gbádùn lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀? Kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe ká lè gbádùn àwọn ìbùkún náà?
Ọlọ́run Mú Kó Kúnjú Ìwọ̀n Láti Ṣàkóso
4-6. Ìmọ̀ ṣíṣe pàtàkì tí Jésù ní wo ló máa jẹ́ kó lè sìn gẹ́gẹ́ bí Ọba, Àlùfáà Àgbà àti Onídàájọ́ tó ní ọgbọ́n tó sì tún jẹ́ oníyọ̀ọ́nú?
4 Jèhófà fẹ́ kí Ọba, Àlùfáà Àgbà àti Onídàájọ́ tó ní ojúlówó ọgbọ́n tó sì tún jẹ́ oníyọ̀ọ́nú ran àwọn èèyàn tó jẹ́ ọmọ abẹ́ ìjọba yìí lọ́wọ́ títí wọ́n á fi di pípé. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi yan Jésù Kristi tó sì fi ẹ̀mí mímọ́ ràn án lọ́wọ́, kó lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣe àwọn ojúṣe tó ṣe pàtàkì jù lọ yẹn. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìdí tí Jésù fi máa ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ láṣeyọrí lọ́nà pípé pérépéré.
5 Jésù ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ nípa Ọlọ́run. Ọmọ bíbí kan ṣoṣo náà mọ Baba ju bí ẹnikẹ́ni ṣe mọ̀ ọ́n lọ, ó sì ṣeé ṣe kó ti wà pẹ̀lú rẹ̀ fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún. Ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi wà pẹ̀lú Bàbá rẹ̀, ó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ nípa Jèhófà débi tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí.” (Kól. 1:15) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”—Jòh. 14:9.
6 Yàtọ̀ sí Jèhófà, Jésù lẹni tó tún ní ìmọ̀ tó kún rẹ́rẹ́ jù lọ nípa gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá, títí kan aráyé. Kólósè 1:16, 17 kà pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ [Ọmọ Ọlọ́run] ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí . . . Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wà ṣáájú gbogbo ohun mìíràn, nípasẹ̀ rẹ̀ sì ni a gbà mú kí gbogbo ohun mìíràn wà.” Ìwọ ronú nípa ìyẹn ná! Gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run, Jésù lọ́wọ́ nínú ṣíṣẹ̀dá gbogbo nǹkan yòókù tí Ọlọ́run dá. Torí náà, ó mọ tinú-tòde gbogbo àgbáyé, látorí àwọn ẹ̀dá tó kéré bí egunrín iyanrìn tó fi dórí ọpọlọ ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ ohun àgbàyanu. Dájúdájú, Kristi ni ẹni tí Bíbélì ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n.—Òwe 8:12, 22, 30, 31.
7, 8. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ran Jésù lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
7 Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yan Jésù. Jésù sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, ó rán mi jáde láti wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, láti rán àwọn tí a ni lára lọ pẹ̀lú ìtúsílẹ̀, láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.” (Lúùkù 4:18, 19) Nígbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi, kò sí àní-àní pé ẹ̀mí mímọ́ mú kó rántí àwọn nǹkan tó ti kọ́ lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ṣáájú ká tó bí i gẹ́gẹ́ bí èèyàn, tó fi mọ́ àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà.—Ka Aísáyà 42:1; Lúùkù 3:21, 22; Jòhánù 12:50.
8 Nítorí pé ẹ̀mí mímọ́ fún Jésù lágbára tó sì tún ní ara àti èrò pípé, ó tipa bẹ́ẹ̀ dí ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí, ó sì tún jẹ́ Olùkọ́ títóbi lọ́lá jù lọ. Kódà, “háà ń ṣe” gbogbo àwọn tó ń tẹ́tí sí i nítorí “ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mát. 7:28) Ohun kan ni pé, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó fa ìṣòro aráyé, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀, àìpé àti àìní ìmọ̀ Ọlọ́run. Bákan náà, ó ṣeé ṣe fún un láti mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, ìyẹn sì nípa lórí ọ̀nà tó gbà bá wọn lò.—Mát. 9:4; Jòh. 1:47.
9. Kí ló mú kó o túbọ̀ ní ìgbọ́kànlé pé Jésù máa jẹ́ Alákòóso rere nígbà tó o ronú lórí àwọn nǹkan tí ojú rẹ̀ rí nígbà tó wà láyé?
9 Jésù gbé láyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn. Ohun tí ojú Jésù fúnra rẹ̀ rí gẹ́gẹ́ bí èèyàn àti àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ní pẹ̀lú àwọn èèyàn aláìpé mú kó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ Ọba. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó di dandan fún [Jésù] láti dà bí ‘àwọn arákùnrin’ rẹ̀ lọ́nà gbogbo, kí ó lè di àlùfáà àgbà tí ó jẹ́ aláàánú àti olùṣòtítọ́ nínú àwọn ohun tí ó jẹmọ́ ti Ọlọ́run, kí ó bàa lè rú ẹbọ ìpẹ̀tù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. Nítorí níwọ̀n bí òun fúnra rẹ̀ ti jìyà nígbà tí a ń dán an wò, ó lè wá ṣe àrànṣe fún àwọn tí a ń dán wò.” (Héb. 2:17, 18) Torí pé ‘a dán Jésù wò,’ ó lè bá àwọn tí à ń dán wò kẹ́dùn. Ìyọ́nú tó ní hàn gbangba lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó rọrùn fún àwọn aláìsàn, àwọn aláàbọ̀-ara, àwọn tí a tẹ̀ lórí ba àtàwọn ọmọdé pàápàá láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Máàkù 5:22-24, 38-42; 10:14-16) Àwọn ọlọ́kàn tútù àtàwọn tí wọ́n fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Lọ́wọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, àwọn agbéraga, àwọn tó ń ṣe fọ́ńté àtàwọn tí “kò ní ìfẹ́ fún Ọlọ́run” pa á tì, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ṣàtakò sí i.—Jòh. 5:40-42; 11:47-53.
10. Ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ni Jésù gbà fi ìfẹ́ tó ní sí wa hàn?
10 Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. Bí Jésù ṣe múra tán láti kú nítorí wa la lè pè ní ẹ̀rí tó tóbi jù lọ tó fi hàn pé ó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ Alákòóso. (Ka Sáàmù 40:6-10.) Kristi sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 15:13) Dájúdájú, Jésù kò dà bí àwọn alákòóso tí wọ́n jẹ́ aláìpé, tí wọ́n máa ń fi owó àwọn aráàlú ṣara rindin, ńṣe ló fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn èèyàn.—Mát. 20:28.
Ọlọ́run Fún Un Lágbára Kí Aráyé Lè Jàǹfààní Látinú Ẹbọ Ìràpadà
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìgbọ́kànlé tó kún rẹ́rẹ́ pé Jésù ni Olùràpadà wa?
11 Ó bá a mu gan-an pé Jésù tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ló kọ́kọ́ mú ká jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀! Kódà, nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ ká rí àpẹẹrẹ àwọn ohun tó máa gbé ṣe gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà wa nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀, èyí tá a máa gbádùn bá a bá jẹ́ olóòótọ́. Ó wo àwọn aláìsàn àtàwọn aláàbọ̀ ara sàn, ó jí òkú dìde, ó bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn, kódà ó pàṣẹ fún àwọn nǹkan bí òkun àti ẹ̀fúùfù pé kí wọ́n pa rọ́rọ́. (Mát. 8:26; 14:14-21; Lúùkù 7:14, 15) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe torí àtifi ọlá àṣẹ àti agbára tó ní ṣe fọ́rífọ́rí ló mú kó ṣe gbogbo ohun tó ṣe yìí, bí kò ṣe láti fi hàn pé òun jẹ́ aláàánú àti onífẹ̀ẹ́. Ó tiẹ̀ sọ fún adẹ́tẹ̀ kan tó bẹ̀ ẹ́ pé kó wo òun sàn pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.” (Máàkù 1:40, 41) Jésù ṣì máa fi irú ìyọ́nú yìí hàn nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀, àmọ́ èyí yóò jẹ́ jákèjádò ayé.
12. Báwo ni Aísáyà 11:9 ṣe máa ní ìmúṣẹ?
12 Kristi àti àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ yóò máa bá ètò kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, èyí tí Jésù bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, nìṣó. Lọ́nà yìí ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà 11:9 máa gbà ní ìmúṣẹ, èyí tó sọ pé: “Ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” Ó dájú pé ẹ̀kọ́ táwọn èèyàn máa kọ́ nípa Ọlọ́run yóò jẹ́ kí wọ́n gba ìtọ́ni nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bójú tó ilẹ̀ ayé àti àìlóǹkà àwọn ẹ̀dá alààyè tó máa wà níbẹ̀, bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Ádámù pé kó ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Nígbà tí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún náà bá fi máa parí, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:28 yóò ti ní ìmúṣẹ, a ó sì ti jàǹfààní látinú ìràpadà náà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.
Ọlọ́run Fún Un Lágbára Láti Ṣèdájọ́
13. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ òdodo?
13 Kristi ni “Ẹni tí Ọlọ́run ti fàṣẹ gbé kalẹ̀ . . . pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.” (Ìṣe 10:42) Nígbà náà, ohun ìtùnú ló jẹ́ fún wa láti mọ̀ pé kò sẹ́ni tó lè mú kí Jésù hùwà ìbàjẹ́, àti pé ńṣe ni òdodo àti ìṣòtítọ́ dà bí ìgbànú tó dè le tantan mọ́ abẹ́nú rẹ̀! (Aísá. 11:5) Ó fi hàn pé òun kórìíra ìwọra, àgàbàgebè àtàwọn ìwà ibi míì, ó sì dẹ́bi fún àwọn tí kò bìkítà nípa àwọn tó ń jìyà. (Mát. 23:1-8, 25-28; Máàkù 3:5) Síwájú sí i, Jésù fi hàn pé ìrísí èèyàn kò lè tan òun jẹ, “nítorí pé òun tìkára rẹ̀ mọ ohun tí ó wà nínú ènìyàn.”—Jòh. 2:25.
14. Ọ̀nà wo ni Jésù ń gbà fi ìfẹ́ tó ní fún òdodo àti ìdájọ́ òdodo hàn ní báyìí, ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?
14 Jésù ń bá a nìṣó láti máa fi ìfẹ́ tó ní fún òdodo àti ìdájọ́ òdodo hàn nípa bó ṣe ń ṣe àbójútó iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó tíì gbòòrò jù lọ. Kò sí ẹ̀dá èèyàn, ìjọba àti ẹ̀mí burúkú èyíkéyìí tó lè dá iṣẹ́ yìí dúró tí a kò fi ní lè ṣe é débi tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe é dé. Torí náà, ó dá wa lójú gbangba pé nígbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì bá fi máa parí, ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run á ti gbilẹ̀ kárí ayé. (Ka Aísáyà 11:4; Mátíù 16:27.) O lè wá bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ọ̀nà tí mò ń gbà hùwà sáwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù fi hàn pé mo fìwà jọ Jésù? Ǹjẹ́ mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bí mo bá tilẹ̀ ní àìlera tàbí tí àwọn nǹkan míì bá mú kó ṣòro fún mi láti ṣe tó bí mo ṣe fẹ́?’
15. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn ká lè máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?
15 Ó máa ṣeé ṣe fún wa láti sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, tá a bá fi sọ́kàn pé òun ló ni iṣẹ́ ìwàásù náà. Òun ló pàṣẹ pé ká máa ṣe iṣẹ́ náà; ó ń tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ darí rẹ̀; ó sì ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà lágbára. Ǹjẹ́ o mọyì àǹfààní tó o ní láti jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ tó ń fi ẹ̀mí rẹ̀ darí? Yàtọ̀ sí Jèhófà, ta ló tún lè fi ẹ̀mí rẹ̀ darí àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méje, tí aráyé ka ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn sí “àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù,” kí wọ́n lè máa lọ́wọ́ nínú wíwàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn ní òjìlérúgba-ó-dín-mẹ́rin [236] ilẹ̀?—Ìṣe 4:13.
Kórè Ìbùkún Yanturu Nípasẹ̀ Kristi!
16. Kí ni Jẹ́nẹ́sísì 22:18 jẹ́ ká mọ̀ nípa ìbùkún Ọlọ́run?
16 Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.” (Jẹ́n. 22:18) Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa sin Ọlọ́run lè máa fi ìgbọ́kànlé retí àwọn ìbùkún tí Irú-ọmọ tó jẹ́ Mèsáyà náà máa mú wá. Wọ́n sì fi àwọn ìbùkún náà sọ́kàn bí wọ́n ti ń jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ní báyìí.
17, 18. Ìlérí tí Jèhófà ṣe wo la kà nípa rẹ̀ nínú Diutarónómì 28:2, kí ló sì túmọ̀ sí fún wa?
17 Ọlọ́run sọ nígbà kan fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù nípa tara pé: “Gbogbo ìbùkún wọ̀nyí [tí Ọlọ́run la lẹ́sẹẹsẹ nínú májẹ̀mú Òfin] yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì dé bá ọ, nítorí pé ìwọ ń bá a nìṣó láti máa fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diu. 28:2) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní náà lè gbádùn irú ìbùkún yìí. Bó o bá fẹ́ rí ìbùkún Jèhófà, “máa fetí sí” ohùn rẹ̀. Nípa báyìí, àwọn ìbùkún rẹ̀ “yóò . . . wá sórí rẹ, yóò sì dé bá ọ.” Àmọ́, kí ló túmọ̀ sí láti “fetí sí” Ọlọ́run?
18 Fífetí sí Ọlọ́run túmọ̀ sí kéèyàn máa ṣe àṣàrò tọkàntọkàn lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti oúnjẹ tẹ̀mí tí Ọlọ́run ń pèsè. (Mát. 24:45) Ó tún túmọ̀ sí ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. Jésù sọ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.” (Mát. 7:21) Torí náà, fífetí sí Ọlọ́run túmọ̀ sí kéèyàn máa ṣètìlẹ́yìn látọkànwá fún ètò tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, ìyẹn ìjọ Ọlọ́run tó ní àwọn alàgbà tá a yàn sípò gẹ́gẹ́ bí “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn.”—Éfé. 4:8.
19. Báwo la ṣe lè rí ìbùkún gbà?
19 Àwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, tí wọ́n ń ṣojú fún ìjọ Kristẹni lápapọ̀, wà lára “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” yìí. (Ìṣe 15:2, 6) Ìwà tá a bá sì ń hù sí àwọn arákùnrin Kristi nípa tẹ̀mí jẹ́ ohun pàtàkì tó máa pinnu bí Ọlọ́run ṣe máa ṣèdájọ́ wa nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀. (Mát. 25:34-40) Torí náà, ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà rí ìbùkún gbà ni pé ká máa fi ìdúróṣinṣin ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run.
20. (a) Kí ni ojúṣe pàtàkì tí Ọlọ́run gbé lé “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” lọ́wọ́? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì àwọn arákùnrin wọ̀nyí?
20 Àwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn alàgbà ìjọ pẹ̀lú wà lára “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn,” ẹ̀mí mímọ́ la sì fi yan gbogbo wọn sípò. (Ìṣe 20:28) Ojúṣe pàtàkì tí Ọlọ́run gbé lé àwọn arákùnrin wọ̀nyí lọ́wọ́ jẹ́ láti máa gbé àwọn èèyàn Ọlọ́run ró “títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé ọkùnrin, tí a ó fi dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.” (Éfé. 4:13) Àmọ́ ṣá o, aláìpé bíi tiwa ni àwọn náà o. Síbẹ̀, a ó ṣe ara wa láǹfààní tá a bá ń fi ìmọrírì hàn fún wọn tá a sì ń ṣègbọràn, bí wọ́n ṣè ń fìfẹ́ ṣe olùṣọ́ àgùntàn wa.—Héb. 13:7, 17.
21. Kí nìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú fún wa láti ṣègbọràn sí Ọmọ Ọlọ́run?
21 Láìpẹ́, Kristi máa gbéjà ko ètò búburú ti Sátánì. Nígbà tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìdájọ́ tí Jésù bá ṣe ló máa pinnu bóyá a máa yè bọ́ tàbí a kò ní yè bọ́, torí pé Ọlọ́run ti fún un láṣẹ láti ṣamọ̀nà “ogunlọ́gọ̀ ńlá” lọ sí “àwọn ìsun omi ìyè.” (Ìṣí. 7:9, 16, 17) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe nísinsìnyí láti máa tẹrí ba látọkànwá fún Ọba tí Jèhófà ń fi ẹ̀mí rẹ̀ darí, ká sì mọrírì rẹ̀.
Kí Lo Rí Kọ́ Látinú . . .
• Ìṣe 10:42?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jésù fi hàn pé òun jẹ́ oníyọ̀ọ́nú nígbà tó jí ọmọbìnrin Jáírù dìde
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jésù Kristi ń ṣe àbójútó iṣẹ́ ìwàásù tó tíì gbòòrò jù lọ