Kọrin Sí Jèhófà!
Kọrin Sí Jèhófà!
“Èmi yóò máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà.”—SM. 146:2.
1. Nígbà tí Dáfídì ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, kí ló mú kó kọ díẹ̀ lára àwọn sáàmù rẹ̀?
NÍGBÀ tí Dáfídì ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ó lo ọ̀pọ̀ wákàtí nínú àwọn pápá tó wà nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti bójú tó agbo ẹran bàbá rẹ̀. Bí Dáfídì ṣe ń ṣọ́ àwọn àgùntàn, ó tún ń ṣàkíyèsí àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà dá, irú bí ojú ọ̀run tó kún fún àwọn ìràwọ̀, “àwọn ẹranko pápá gbalasa” àti “àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.” Àwọn ohun tó rí náà wú u lórí gan-an, ìyẹn ló sì mú kó kọ àwọn orin ìyìn tó wọni lọ́kàn sí Olùṣẹ̀dá gbogbo àwọn ohun àgbàyanu yìí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn orin tí Dáfídì kọ wà nínú ìwé Sáàmù. a—Ka Sáàmù 8:3, 4, 7-9.
2. (a) Ipa wo ni orin lè ní lórí èèyàn? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan. (b) Kí la lè rí kọ́ nípa àjọse tó wà láàárín Dáfídì àti Jèhófà látinú Sáàmù 34:7, 8 àti Sáàmù 139:2-8?
2 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láàárín àkókò yìí ni Dáfídì mú kí òye rẹ̀ nípa orin kíkọ sunwọ̀n sí i. Ó wá di ọ̀jáfáfá débi pé Sọ́ọ̀lù Ọba ké sí i pé kó wá ta háàpù fún òun. (Òwe 22:29) Àwọn orin tí Dáfídì kọ fún ọba tí ìdààmú ọkàn ti bá náà tù ú lára bí orin tó dára ṣe sábà máa ń tu àwọn èèyàn lára lónìí. Nígbàkigbà tí Dáfídì bá ta háàpù rẹ̀, “ìtura a sì wà fún Sọ́ọ̀lù, nǹkan a sì máa lọ dáadáa fún un.” (1 Sám. 16:23) Àwọn orin tí akọrin tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run yìí kọ ṣì wúlò títí dòní. Ronú nípa èyí ná! Lónìí, lẹ́yìn ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti bí Dáfídì, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí ipò wọn yàtọ̀ síra, láti apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé, máa ń ka àwọn sáàmù tí Dáfídì kọ déédéé kó lè fún wọn ní ìtùnú àti ìrètí.—2 Kíró. 7:6; ka Sáàmù 34:7, 8; 139:2-8; Ámósì 6:5.
Ipa Rere Tí Orin Ń Kó Nínú Ìjọsìn Tòótọ́
3, 4. Báwo ni wọ́n ṣe ṣètò kíkọ orin mímọ́ nígbà ayé Dáfídì?
3 Dáfídì ní ẹ̀bùn orin kíkọ, ó sì lo ẹ̀bùn náà lọ́nà tó dára jù lọ, ìyẹn ni láti fi yin Jèhófà. Lẹ́yìn tí Dáfídì di ọba Ísírẹ́lì, ó ṣètò pé kí wọ́n máa kọ àwọn orin aládùn gẹ́gẹ́ bí apá kan ìjọsìn nínú àgọ́ ìjọsìn. Ó ju ìdá kan nínú mẹ́wàá lọ lára àwọn ọmọ Léfì tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn nǹkan bí ẹgbàajì [4,000] èèyàn, tí Dáfídì yàn gẹ́gẹ́ bí “olùfi ìyìn fún” Jèhófà, àwọn ọ̀ọ́dúnrún dín méjìlá [288] ni wọ́n sì “kọ́ ní iṣẹ́ orin kíkọ sí Jèhófà, gbogbo àwọn ògbógi.”—1 Kíró. 23:3, 5; 25:7.
4 Dáfídì fúnra rẹ̀ ló ṣàkójọ ọ̀pọ̀ lára orin tí àwọn ọmọ Léfì náà kọ. Ọmọ Ísírẹ́lì èyíkéyìí tó bá ní àǹfààní láti wà níbi tí wọ́n ti ń kọ àwọn sáàmù Dáfídì lórin ti ní láti gbádùn àwọn orin náà gan-an. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà tí wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú wá sí Jerúsálẹ́mù, “Dáfídì sọ fún àwọn olórí ọmọ Léfì pé kí wọ́n yan àwọn arákùnrin wọn sípò àwọn akọrin pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin, àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù àti aro, kí wọ́n máa kọrin sókè láti mú kí ìró ayọ̀ yíyọ̀ ròkè.”—1 Kíró. 15:16.
5, 6. (a) Kí nìdí tí Dáfídì fi fún orin ní àfiyèsí tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nígbà ìṣàkóso rẹ̀? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé ọwọ́ pàtàkì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì fi mú orin nínú ìjọsìn wọn?
5 Kí nìdí tí wọ́n fi fún orin ní àfiyèsí tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nígbà ayé Dáfídì? Ṣé torí pé Dáfídì Ọba jẹ́ akọrin ni? Rárá o, ìdí mìíràn wà tó mú kó rí bẹ́ẹ̀, èyí tí Hesekáyà Ọba tó jẹ́ olódodo mú kó ṣe kedere ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà nígbà tó mú iṣẹ́ ìsìn nínú tẹ́ńpìlì pa dà bọ̀ sípò. Nínú ìwé 2 Kíróníkà 29:25, a kà pé: “Ó [ìyẹn Hesekáyà] mú kí a yan àwọn ọmọ Léfì sí ilé Jèhófà, pẹ̀lú aro, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti pẹ̀lú háàpù, nípa àṣẹ Dáfídì àti ti Gádì olùríran fún ọba àti ti Nátánì wòlíì, nítorí pé àṣẹ náà jẹ́ láti ọwọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀.”
6 Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà tipasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ darí àwọn olùjọsìn rẹ̀ láti máa fi orin yin òun. A tilẹ̀ yọ̀ǹda pé kí àwọn akọrin tó wá látinú ìdílé àwọn àlùfáà kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tá a yàn fún àwọn ọmọ Léfì yòókù, kí wọ́n lè lo àkókò tó pọ̀ tó láti ṣe àkójọ àwọn orin, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n tún fi dánra wò.—1 Kíró. 9:33.
7, 8. Ní ti kíkọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run, kí ló ṣe pàtàkì ju kéèyàn mọ orin kọ?
7 O lè sọ pé, “Ní ti orin kíkọ, ó dájú pé wọn ò lè kà mí mọ́ àwọn ògbógi akọrin nínú àgọ́ ìjọsìn láé!” Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ akọrin náà ló jẹ́ ògbógi nídìí iṣẹ́ orin kíkọ. Bí 1 Kíróníkà 25:8 ṣe sọ, àwọn tó jẹ́ “akẹ́kọ̀ọ́” wà lára wọn. Ó tún yẹ ká kíyè sí i pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan wà nínú àwọn ẹ̀yà míì lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ògbóǹkangí olórin àti akọrin, àmọ́ kìkì àwọn ọmọ Léfì ni Jèhófà yàn pé kó máa bójú tó orin kíkọ. Ó lè dá wa lójú pé yálà àwọn ọmọ Léfì olóòótọ́ yìí jẹ́ “ògbógi” tàbí “akẹ́kọ̀ọ́” gbogbo wọn ló ń ṣe iṣẹ́ orin kíkọ náà tọkàntọkàn.
8 Dáfídì fẹ́ràn orin, ó sì tún jẹ́ ọ̀jáfáfá akọrin. Àmọ́, ṣé ẹ̀bùn téèyàn ní nìkan ló ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run? Nínú Sáàmù 33:3, Dáfídì sọ pé: “Ẹ sa gbogbo ipá yín ní títa àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ti ẹ̀yin ti igbe ìdùnnú.” Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká ‘sa gbogbo ipá wa’ láti yin Jèhófà.
Ipa Tí Orin Kó Lẹ́yìn Ìgbà Ayé Dáfídì
9. Ṣàpèjúwe ohun tó ṣeé ṣe kó o rí tàbí kó o gbọ́ ká ní o lọ síbi ṣíṣí tẹ́ńpìlì nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì.
9 Nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì, wọ́n máa ń lo orin gan-an nínú ìjọsìn mímọ́. Nígbà ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì, àwọn ẹgbẹ́ akọrin wà níbẹ̀, wọ́n ya ibì kan sọ́tọ̀ fún àwọn tó ń lo ohun èlò ìkọrin tá a fi idẹ ṣe, ọgọ́fà [120] kàkàkí ló sì wà níbẹ̀. (Ka 2 Kíróníkà 5:12.) Bíbélì sọ fún wa pé “àwọn afunkàkàkí [tí gbogbo wọ́n jẹ́ àlùfáà] àti àwọn akọrin ṣe ọ̀kan ní mímú kí a gbọ́ ìró kan ní yíyin Jèhófà àti dídúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, . . . ‘nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere, nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.’” Bí ìró ayọ̀ orin yẹn ṣe ròkè, “ilé náà kún fún àwọsánmà,” èyí tó fi hàn pé wọ́n rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Èyí mà múni lọ́kàn yọ̀ o, ẹ sì wo bó ti jẹ́ ohun tó ń múni kún fún ọ̀wọ̀ tó láti gbọ́ bí ohùn àwọn kàkàkí náà àti ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn akọrin ti ṣe ọ̀kan!—2 Kíró. 5:13.
10, 11. Kí ló fi hàn pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lo orin nínú ìjọsìn wọn?
10 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní náà lo orin nínú ìjọsìn wọn. Àmọ́, inú àwọn ilé àdáni ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ti ń pàdé, wọ́n kì í pàdé nínú àgọ́ ìjọsìn tàbí tẹ́ńpìlì. Nítorí inúnibíni àtàwọn ìdí mìíràn, ibi tí wọ́n ti ń pàdé kì í fi bẹ́ẹ̀ tù wọ́n lára. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn fi orin yin Ọlọ́run lógo.
11 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará tó wà ní Kólósè níyànjú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní ṣíṣí ara yín létí lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú àwọn sáàmù, àwọn ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn orin tẹ̀mí pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.” (Kól. 3:16) Lẹ́yìn tí wọ́n ju Pọ́ọ̀lù àti Sílà sẹ́wọ̀n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í “gbàdúrà, wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọ́run,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìwé orin lọ́wọ́ wọn. (Ìṣe 16:25) Bí wọ́n bá fi ẹ́ sẹ́wọ̀n, mélòó lára àwọn orin tó wà nínú ìwé orin wa lo lè kọ láìwòwé?
12. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run?
12 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé orin máa ń buyì kún ìjọsìn wa, ó máa dára ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń fi hàn pé mo mọrírì àwọn orin náà? Ǹjẹ́ mo máa ń sa gbogbo ipá mi láti tètè dé sí àwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ kí n lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ará láti kọ orin ìbẹ̀rẹ̀, ṣé mo sì máa ń kọ orin látọkànwá? Ǹjẹ́ mo máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ mi mọ̀ pé àkókò tá a fi máa ń kọrin nígbà tí ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run bá parí láti bẹ̀rẹ̀ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tàbí tí àsọyé bá parí láti bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ kì í ṣe àkókò ìsinmi, tí wọ́n lè fi máa jáde lọ síta, bóyá nítorí kí wọ́n lè lọ nasẹ̀?’ Apá kan ìjọsìn wa ni orin kíkọ jẹ́. Torí náà, yálà a jẹ́ “ògbógi” tàbí “akẹ́kọ̀ọ́,” gbogbo wa lè pa ohùn wa pọ̀ láti kọrin ìyìn sí Jèhófà, a sì gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 8:12.
Bí Ìgbà Ṣe Ń Yí Pa Dà Làwọn Ohun Tá A Nílò Ń Yí Pa Dà
13, 14. Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn máa kọrin látọkànwá láwọn ìpàdé ìjọ? Ṣàkàwé.
13 Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower tá à ń pè ní Ilé Ìṣọ́ báyìí, ṣàlàyé ọ̀kan lára àwọn ìdí tí àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì gan-an. Ó sọ pé: “Kíkọ òtítọ́ lórin jẹ́ ọ̀nà kan tó dára fáwọn èèyàn Ọlọ́run láti gba òtítọ́ sínú kó sì kọjá lọ sínú ọkàn wọn.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ orin wa la gbé ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, torí náà bó bá tiẹ̀ jẹ́ díẹ̀ la mọ̀ lára àwọn orin náà, ìyẹn lè jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wa. Bí àwọn ará ṣe máa ń kọrin látọkànwá ní ìpàdé sábà máa ń fa àwọn tó wá fún ìgbà àkọ́kọ́ mọ́ra gidigidi.
14 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lọ́dún 1869, nígbà tí Arákùnrin C. T. Russell ń bọ̀ láti ibi iṣẹ́, ó gbọ́ táwọn kan ń kọrin nínú gbọ̀ngàn kan tó wà lábẹ́ ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sí. Lákòókò yẹn nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ó ti gbà pé kò síbi tóun ti lè rí òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Torí náà, ó pinnu láti gbájú mọ́ òwò ṣíṣe, èrò rẹ̀ sì ni pé bí òwò náà bá ti ń mówó wọlé, òun á lè máa fi owó náà gbọ́ tàwọn aláìní bí òun kò bá tiẹ̀ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Arákùnrin Russell wọ inú gbọ̀ngàn tó kún fún eruku tó sì ṣókùnkùn náà, ó sì rí i pé ìsìn ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀. Ó jókòó, ó sì tẹ́tí sílẹ̀. Lẹ́yìn náà ló kọ̀wé pé ohun tóun gbọ́ lálẹ́ ọjọ́ yẹn “ti tó, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, láti sọ ìgbàgbọ́ [òun] tí kò lágbára mọ́ pé Bíbélì ní ìmísí Ọlọ́run dọ̀tun.” Kíyè sí i pé orin tí Arákùnrin Russell gbọ́ ló mú kó lọ bá àwọn tó ń ṣe ìpàdé náà.
15. Àwọn àtúnṣe wo nípa òye tá a ní ló mú kó pọn dandan láti tún ìwé orin wa ṣe?
15 Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá òye tá a ní nípa Ìwé Mímọ́. Ìwé Òwe 4:18 sọ pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” Ìmọ́lẹ̀ tó túbọ̀ ń tàn sórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó di dandan láti ṣe àtúnṣe ọ̀nà tá a gbà ń ‘kọ òtítọ́ lórin.’ Ó tó ogún ọdún tá a fi lo ìwé orin náà, Kọrin Ìyìn sí Jehofah. b Látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó, ìmọ́lẹ̀ ti túbọ̀ tàn sórí àwọn ẹ̀kọ́ bíi mélòó kan. Èyí ló fà á tí àwọn ọ̀rọ̀ kan tá a lò nínú ìwé orin náà kò fi bágbà mu mọ́. Bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe “àṣeyẹ, ayẹyẹ tàbí ìṣe-ìrántí ikú Kristi” là ń ṣe, bí kò ṣe “Ìrántí Ikú Kristi.” Ohun tá a sì ń sọ báyìí ni pé orúkọ Jèhófà yóò di “sísọ di mímọ́,” kì í ṣe pé a óò “dá a láre.” Àti pé, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kì í ṣe “èso ti ẹ̀mí” ńṣe ni wọ́n jẹ́ “apá kọ̀ọ̀kan lára èso ti ẹ̀mí.” Torí náà, bá a bá fojú ẹ̀kọ́ òtítọ́ wò ó, ó jẹ́ ohun tó pọn dandan láti mú kí ìwé orin wa bá òye tá a ní nípa Ìwé Mímọ́ mu.
16. Báwo ni ìwé orin wa tuntun ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Éfésù 5:19?
16 Nítorí èyí àtàwọn ìdí mìíràn, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká tẹ ìwé orin tuntun náà, Kọrin sí Jèhófà, jáde. A ti dín iye orin tó wà nínú ìwé orin wa tuntun náà kù sí márùndínlógóje [135]. Torí pé àwọn orin náà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ mọ́, kò ní ṣòro láti kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ orin tuntun náà sórí, bó tiẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára wọn. Èyí bá ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Éfésù 5:19 mu.—Kà á.
O Lè Fi Ìmọrírì Hàn
17. Èrò wo ló lè mú ká borí ìtìjú nígbà tá a bá ń kọrin láwọn ìpàdé ìjọ?
17 Ǹjẹ́ ó yẹ ká jẹ́ kí ìtìjú mú ká máa bẹ̀rù láti kọrin láwọn ìpàdé ìjọ? Wò ó báyìí ná: Bó bá di pé ká sọ̀rọ̀, ṣé kì í ṣe òótọ́ ni pé “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà”? (Ják. 3:2) Síbẹ̀, a kì í torí pé a lè ṣi ọ̀rọ̀ sọ ká wá dẹ́kun láti máa yin Jèhófà nípa wíwàásù láti ilé dé ilé. Nígbà náà, ṣó wá yẹ ká dẹ́kun fífi orin yin Ọlọ́run lógo torí pé a kò lóhùn orin? Inú Jèhófà tó “yan ẹnu fún ènìyàn” máa ń dùn bá a ṣe ń fi ohùn wa kọrin ìyìn sí i.—Ẹ́kís. 4:11.
18. Fúnni ní àwọn àbá lórí bá a ṣe lè mọ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé orin wa.
18 Àwọn àwo CD tá a pè ní Sing to Jehovah—Vocal Renditions, èyí tó ní àwọn orin tá a fẹnu kọ wà ní àwọn èdè mélòó kan. A lo àwọn akọrin àtàwọn ohun èlò orin láti fi kọ àwọn orin aládùn tó wà nínú ìwé orin wa tuntun sínú àwọn àwo CD náà. Ọ̀nà tá a gbà kọ àwọn orin náà sì mú kí wọ́n dùn-ún gbọ́ sétí. Máa gbọ́ wọn déédéé; bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ o kò ní pẹ́ mọ díẹ̀ lára àwọn orin wa tuntun náà. A ṣe àkójọ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀rọ̀ orin náà lọ́nà tó fi jẹ́ pé bó o bá ti kọ ìlà kan, kò ní fi bẹ́ẹ̀ ṣòro fún ẹ láti mọ ohun tó yẹ kó wà ní ìlà tó tẹ̀ lé e. Torí náà, bó o bá ń gbọ́ àwọn àwo CD náà, o ò ṣe kúkú máa kọ ọ́ tẹ̀ lé e? Bó o bá ti mọ orin náà àtàwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ dáadáa látilé, ó dájú pé wàá lè máa fi ìdánilójú kọrin ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
19. Kí làwọn ohun tó wé mọ́ ṣíṣètò àwọn akọrin láti fi ohun èlò ìkọrin kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run?
19 A lè má tètè mọyì àwọn orin tí wọ́n fi ohun èlò ìkọrin kọ, èyí tá a máa ń gbádùn láwọn àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè wa. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ la máa ń ṣe láti ṣètò àwọn orin wọ̀nyí. Lẹ́yìn tá a bá ti yan àwọn orin tá a máa lò, a ó wá fara balẹ̀ ṣètò bí àwọn akọrin mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] tó ń bá Watchtower kọrin ṣe máa fi ohun èlò ìkọrin kọ àwọn orin náà. Lẹ́yìn náà ni àwọn akọrin náà máa lo àìmọye wákàtí láti ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ orin tí wọ́n máa fi dánra wò, wọ́n á wá lọ gba ohùn àwọn orin náà sílẹ̀ níbi ìgbohùnsílẹ̀ wa tó wà ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York. Mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọ̀nyí ni kì í gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Gbogbo wọn ló sì kà á sí àǹfààní ńlá láti kópa nínú pípèsè àwọn orin aládùn fún àwọn àpéjọ Kristẹni. Àwa pẹ̀lú lè fi hàn pé a mọrírì ìsapá tí wọ́n fìfẹ́ ṣe yìí. Bí ẹni tó jẹ́ alága láwọn àpéjọ wa bá ké sí wa láti tẹ́tí sí ohùn orin, ẹ jẹ́ ká lọ sórí ìjókòó wa ní kánmọ́ ká sì fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn orin tí wọ́n fìfẹ́ pèsè yìí.
20. Kí lo pinnu láti ṣe?
20 Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àwọn orin tá à ń kọ láti fi yìn ín. Àwọn orin náà ṣe pàtàkì lójú rẹ̀. A lè mú ọkàn rẹ̀ yọ̀ nípa kíkọrin látọkànwá nígbàkigbà tá a bá pé jọ fún ìjọsìn. Torí náà, yálà a jẹ́ ògbógi tàbí akẹ́kọ̀ọ́, ẹ jẹ́ ká máa “kọrin sí Jèhófà”!—Sm. 104:33.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó gbàfiyèsí pé ní ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn tí Dáfídì ti kú, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn áńgẹ́lì wá kéde ìbí Mèsáyà fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn, tí wọ́n ń ṣọ́ agbo ẹran wọn nínú àwọn pápá tó wà nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.—Lúùkù 2:4, 8, 13, 14.
b Èdè tó lé lọ́gọ́rùn-ún la túmọ̀ orin okòólérúgba ó lé márùn-ún [225] tó wà nínú ìwé orin yìí sí.
Kí Lèrò Rẹ?
• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé orin ń kó ipa pàtàkì nínú ìjọsìn lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
• Kí ni pípa àṣẹ Jésù tó wà nínú Mátíù 22:37 mọ́ ní í ṣe pẹ̀lú kíkọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run tọkàntọkàn?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi ìmọrírì tó yẹ hàn fún àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ṣé o kì í jẹ́ káwọn ọmọ rẹ fi ìjókòó wọn sílẹ̀ láìnídìí nígbà tí orin bá ń lọ lọ́wọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ǹjẹ́ o máa ń kọ́ àwọn orin wa tuntun nílé?