“Èso Ti Ẹ̀mí” Ń Fi Ògo Fún Ọlọ́run
“Èso Ti Ẹ̀mí” Ń Fi Ògo Fún Ọlọ́run
“A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀.”—JÒH. 15:8.
1, 2. (a) Àwọn àǹfààní wo la ní láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí? (b) Ẹ̀bùn tó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá wo ló mú kó rọrùn fún wa láti sìn ín?
RONÚ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjì yìí: Arábìnrin àgbàlagbà kan kíyè sí i pé ó dà bíi pé ohun kan ń da arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ lọ́kàn rú. Ó ṣètò láti bá a ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Bí wọ́n ṣe ń bára wọn sọ̀rọ̀ láàárín ilé kan sí òmíràn, arábìnrin ọ̀dọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó ń dà á lọ́kàn rú fún un. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn lọ́jọ́ yẹn, nígbà tí arábìnrin ọ̀dọ́ yẹn ń gbàdúrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bí ìfẹ́ tí arábìnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí náà ní ṣe mú kó dá sí ọ̀ràn òun; ohun tí arábìnrin ọ̀dọ́ náà sì nílò gan-an nìyẹn. Ní ibòmíràn, tọkọtaya kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ òkèèrè níbi tí wọ́n ti lọ wàásù dé. Níbi àpèjẹ kan, bí wọ́n ṣe ń fi ìdùnnú sọ àwọn ìrírí wọn, arákùnrin ọ̀dọ́ kan rọra ń tẹ́tí gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, bí ọ̀dọ́kùnrin náà pẹ̀lú ṣe ń gbára dì láti lọ ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ àjèjì, ó ronú kan tọkọtaya yẹn àti ìjíròrò wọn, èyí tó mú kí òun náà fẹ́ láti di míṣọ́nnárì.
2 Ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ lókè yìí mú kó o rántí ẹnì kan tó ṣe ohun kan tó nípa rere lórí ìgbésí ayé rẹ tàbí ẹnì kan tí ìwọ náà ṣe ohun tó nípa rere lórí ìgbésí ayé rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjíròrò kan ṣoṣo lè ṣàì tó láti yí ìgbésí ayé èèyàn pa dà sí rere, síbẹ̀ a máa ń ní àǹfààní lójoojúmọ́ láti fún àwọn míì níṣìírí ká sì fún wọn lókun. Jẹ́ ká sọ pé ohun kan wà tó máa mú kí agbára àti ànímọ́ tó o ní sunwọ̀n sí i kó lè túbọ̀ ṣàǹfààní fáwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ kó sì mú kí ìwọ alára túbọ̀ wúlò fún Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o ò ní ka irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí ohun àgbàyanu? Irú ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa gan-an nìyẹn, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé wa, ó ń mú ká ní àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra èyí tó lè mú kí gbogbo apá iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run sunwọ̀n sí i. Ẹ̀bùn àgbàyanu mà nìyẹn o!—Ka Gálátíà 5:22, 23.
3. (a) Bá a bá ń fi “èso ti ẹ̀mí” ṣèwà hù, báwo nìyẹn ṣe máa fi ògo fún Ọlọ́run? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
3 Àwọn ànímọ́ tó jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí ló ń jẹ́ ka mọ àkópọ̀ ìwà Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Orísun ẹ̀mí náà. (Kól. 3:9, 10) Jésù sọ ìdí tó gbawájú jù lọ tí àwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ sapá láti fara wé Ọlọ́run nígbà tó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀.” * (Jòh. 15:8) Bá a bá ṣe ń fi “èso ti ẹ̀mí” ṣèwà hù, bẹ́ẹ̀ ni àbájáde rẹ̀ á túbọ̀ máa fara hàn kedere nínú ọ̀nà tá a gbà ń sọ̀rọ̀ àti nínú ìwà wa; ìyẹn á sì tún máa fi ògo fún Ọlọ́run wa. (Mát. 5:16) Àwọn ọ̀nà wo ni èso ti ẹ̀mí gbà yàtọ̀ sí àwọn ìwà tá à ń rí nínú ayé Sátánì? Báwo la ṣe lè máa fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù? Kí nìdí tó fi lè dà bí ohun tó ṣòro fún wa láti fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù? A máa gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò bá a bá ṣe ń jíròrò apá mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú èso ti ẹ̀mí, ìyẹn ni ìfẹ́, ìdùnnú àti àlàáfíà.
Ìfẹ́ Tá A Gbé Karí Ìlànà Ọlọ́run
4. Irú ìfẹ́ wo ni Jésù ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa fi ṣèwà hù?
4 Ìfẹ́ tí èso ti ẹ̀mí ń jẹ́ ká ní yàtọ̀ gedegbe sí irú ìfẹ́ tó wọ́pọ̀ nínú ayé. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ó jẹ́ ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà Ọlọ́run. Jésù fi bí ìfẹ́ yìí ṣe yàtọ̀ tó hàn nínú Ìwàásù Orí Òkè. (Ka Mátíù 5:43-48.) Ó sọ pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń fẹ́ láti fi ohun tí ẹnì kan bá ṣe sí wọn san án pa dà fún un. Irú “ìfẹ́” bẹ́ẹ̀ ò gba nǹkan kan lọ́wọ́ ẹni, ìfẹ́ ṣe fún mi kí n ṣe fún ẹ lásán ni. Bá a bá fẹ́ ‘fi ara wa hàn ní ọmọ Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,’ a gbọ́dọ̀ yàtọ̀. Dípò tí a ó fi máa fi ohun táwọn èèyàn bá ṣe sí wa san án pa dà fún wọn, a gbọ́dọ̀ máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn míì wò wọ́n, ká sì máa bá wọn lò bó ṣe ń bá wọn lò. Àmọ́, báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe fún wa láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa, bí Jésù ṣe pàṣẹ pé ká ṣe?
5. Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ hàn sí àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wa?
5 Ronú nípa àpẹẹrẹ kan tó wà nínú Bíbélì. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń wàásù ní Fílípì, wọ́n mú wọn, wọ́n lù wọ́n ní àlùbami, wọ́n jù wọ́n sí yàrá inú lọ́hùn-ún nínú túbú, wọ́n sì de ẹsẹ̀ wọn pinpin mọ́ àbà. Lákòókò tí wọ́n fi wà níbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí onítúbú náà pàápàá ti hùwà tí kò dára sí wọn. Nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé sì mú kí gbogbo ìdè wọn tú, ṣé wọ́n wá bí wọ́n ṣe máa gbẹ̀san lára ọkùnrin náà? Rárá o. Àníyàn àtọkànwá tí wọ́n ní fún ire ọkùnrin náà, ìyẹn ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ wọn, mú kí wọ́n tètè sọ̀rọ̀ kó má bàa pa ara rẹ̀, èyí sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún onítúbú náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ pátá láti di onígbàgbọ́. (Ìṣe 16:19-34) Bákan náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa lóde òní ti tọ ipa ọ̀nà kan náà “ní sísúre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni.”—Róòmù 12:14.
6. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ fún àwọn ará wa? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 21.)
6 Ìfẹ́ tá a ní fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tún jinlẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. “A . . . wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti fi ọkàn wa lélẹ̀ fún àwọn arákùnrin wa.” (Ka 1 Jòhánù 3:16-18.) Àmọ́ ṣá o, a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ní àwọn ọ̀nà kéékèèké. Bí àpẹẹrẹ, bá a bá ṣẹ ẹnì kan tá a jọ jẹ́ ará nítorí ohun tá a sọ tàbí nítorí ohun tá a ṣe, a lè fi ìfẹ́ hàn nípa lílo ìdánúṣe láti wá àlàáfíà pẹ̀lú onítọ̀hún. (Mát. 5:23, 24) Bó bá jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣẹ̀ wá ńkọ́? Ǹjẹ́ a ‘ṣe tán láti dárí jì í,’ àbí nígbà míì ó máa ń ṣe wá bíi pé ká di ẹni bẹ́ẹ̀ sínú? (Sm. 86:5) Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ èyí tí èso ti ẹ̀mí ń jẹ́ ká ní lè mú ká bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí kò tó nǹkan mọ́lẹ̀ ká sì dárí ji ara wa fàlàlà ‘àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ń dárí jì wá fàlàlà.’—Kól. 3:13, 14; 1 Pét. 4:8.
7, 8. (a) Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ṣe tan mọ́ ìfẹ́ tá a ní fún àwọn èèyàn? (b) Báwo la ṣe lè mú kí ìfẹ́ wa fún Jèhófà jinlẹ̀ sí i? (Wo àwòrán tó wà nísàlẹ̀.)
7 Báwo la ṣe lè ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ fún àwọn ará wa? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i. (Éfé. 5:1, 2; 1 Jòh. 4:9-11, 20, 21) Ní àwọn àkókò tá a fi ń sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́ nígbà tá a bá ń ka Bíbélì, tá à ń ṣe àṣàrò, tá a sì ń gbàdúrà ńṣe là ń bọ́ ọkàn wa yó tí ìfẹ́ tá a ní fún Baba wa ọ̀run sì ń jinlẹ̀ sí i. Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ máa ra àkókò pa dà ká bàa lè sún mọ́ Ọlọ́run.
8 A lè ṣàkàwé rẹ̀ báyìí: Jẹ́ ká sọ pé ó ní wákàtí kan pàtó lóòjọ́ tó o lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o ṣe àṣàrò lé e lórí, kó o sì gbàdúrà sí Jèhófà. Ṣé o kò ní ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti rí i pé kò sí ohun tó gba àkókò tó o fẹ́ lò pẹ̀lú Jèhófà yẹn mọ́ ẹ lọ́wọ́? Àmọ́, kò sí ohun tó lè ní ká má gbàdúrà sí Ọlọ́run, èyí tó pọ̀ jù lára wa ló sì lè ka Bíbélì nígbàkigbà tá a bá fẹ́. Síbẹ̀, ó lè gba pé ká ṣe àwọn ohun tí kò ní jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ gba àkókò tó yẹ ká fi wà pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ wa lọ́wọ́. Ǹjẹ́ o máa ń ra àkókò pa dà bó bá ti lè ṣeé ṣe tó lójoojúmọ́ kó o lè sún mọ́ Jèhófà?
“Ìdùnnú Ẹ̀mí Mímọ́”
9. Kí ni ohun pàtàkì kan nípa ìdùnnú tí ẹ̀mí mímọ́ ń mú kéèyàn ní?
9 Ohun pàtàkì kan nípa ànímọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ ń mú kéèyàn ní ni pé ó máa ń tọ́jọ́. Ìdùnnú, tó jẹ́ ànímọ́ tá a máa gbé yẹ̀ wò ṣìkejì, á jẹ́ ká rí bí èyí ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀. A lè fi ìdùnnú wé irúgbìn kan tó rọ́kú, tó sì lè dàgbà ní àyíká tí kò dára fún ọ̀gbìn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jákèjádò ilẹ̀ ayé ti “tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà lábẹ́ ìpọ́njú púpọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ẹ̀mí mímọ́.” (1 Tẹs. 1:6) Àwọn mìíràn ń dojú kọ ìnira àti àdánù. Síbẹ̀, Jèhófà ń fún wọn lágbára nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ ‘láti fara dà á ní kíkún, kí wọ́n sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.’ (Kól. 1:11) Kí ni orísun ìdùnnú yìí?
10. Kí ni orísun ìdùnnú wa?
10 Láìdàbí “ọrọ̀ àìdánilójú” inú ayé Sátánì yìí, àǹfààní tá à ń rí gbà nínú àwọn ìṣúra tẹ̀mí tí Jèhófà fi jíǹkí wa máa ń wà pẹ́ títí. (1 Tím. 6:17; Mát. 6:19, 20) Ó mú ká ní ìrètí tí ń fúnni láyọ̀ pé ọjọ́ ọ̀la ayérayé kan ń bọ̀ wá. A ní ìdùnnú jíjẹ́ apá kan ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni tó wà kárí ayé. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run ni orísun ìdùnnú wa. Ìmọ̀lára tiwa náà dà bíi ti Dáfídì, tó jẹ́ pé nígbà tó ní láti máa gbé gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, ó fi orin yin Jèhófà pé: “Nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sàn ju ìyè, ètè mi yóò gbóríyìn fún ọ. Bí èmi yóò ṣe máa fi ìbùkún fún ọ nìyẹn ní ìgbà ayé mi.” (Sm. 63:3, 4) Kódà bá a bá ní ìṣòro, ó ṣì máa ń ti ọkàn wa wá láti kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run.
11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìdùnnú sin Jèhófà?
11 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!” (Fílí. 4:4) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì fún àwọn Kristẹni láti máa fi ìdùnnú ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà? Ó jẹ́ nítorí ọ̀ràn àríyànjiyàn tó kan ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Sátánì sọ pé kò sí ẹni tó ti ọkàn rẹ̀ wá láti máa sin Ọlọ́run. (Jóòbù 1:9-11) Bá a bá ní láti sin Jèhófà kìkì nítorí pé ó yẹ ká sìn ín àmọ́ tí a kò láyọ̀ bá a ṣe ń sìn ín, a jẹ́ pé ẹbọ ìyìn wa kò tíì pé nìyẹn. Torí náà, à ń sapá láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú onísáàmù náà pé: “Ẹ fi ayọ̀ yíyọ̀ sin Jèhófà. Ẹ fi igbe ìdùnnú wọlé wá síwájú rẹ̀.” (Sm. 100:2) Iṣẹ́ ìsìn tá a bá fínnú fíndọ̀ ṣe láti ọkàn wá máa ń fògo fún Ọlọ́run.
12, 13. Kí la lè ṣe ká lè borí èrò tí kò tọ́?
12 Àmọ́ òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé, ìgbà míì máa ń wà tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olùfọkànsìn pàápàá á rẹ̀wẹ̀sì tí wọ́n á sì máa sapá láti ní èrò tó dáa. (Fílí. 2:25-30) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ nírú àkókò bẹ́ẹ̀? Ìwé Éfésù 5:18, 19 sọ pé: “Ẹ máa kún fún ẹ̀mí, ẹ máa fi àwọn sáàmù àti ìyìn sí Ọlọ́run àti àwọn orin ẹ̀mí bá ara yín sọ̀rọ̀, kí ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa fi ohùn orin gbè é nínú ọkàn-àyà yín sí Jèhófà.” Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò?
13 Bí èrò tí kò tọ́ bá gbà wá lọ́kàn, a lè gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká sì gbìyànjú láti ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tó yẹ fún ìyìn. (Ka Fílípì 4:6-9.) Àwọn kan ti rí i pé táwọn bá ń gbọ́ orin Ìjọba Ọlọ́run táwọn sì rọra ń kọ ọ́ tẹ̀ lé e, ó máa ń mú ọkàn àwọn yọ̀ ó sì máa ń mú káwọn gbé ọkàn kúrò lórí èrò tí kò tọ́. Arákùnrin kan tó bá ara rẹ̀ nínú ipò kan tí kò bára dé, èyí tó máa ń mú kí inú bí i kó sì rẹ̀wẹ̀sì sọ pé: “Yàtọ̀ sí pé mo máa ń gbàdúrà àtọkànwá déédéé, mo tún kọ́ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run mélòó kan sórí. Ọkàn mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ bí mo bá ń kọ àwọn orin ìyìn tó gbádùn mọ́ni yìí sí Jèhófà, yálà mo gbóhùn sókè ni o tàbí mò ń kọ ọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́. Àkókò yẹn náà ni ìwé Sún Mọ́ Jèhófà jáde sí. Ẹ̀ẹ̀mejì ni mo kà á lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Ńṣe ló dà bí òróró amáratuni fún ọkàn mi. Mo rọ́wọ́ ìbùkún Jèhófà nínú ìsapá tí mo ṣe.”
“Ìdè Asonipọ̀ṣọ̀kan Ti Àlàáfíà”
14. Kí ni ohun pàtàkì kan nípa àlàáfíà tí ẹ̀mí mímọ́ ń mú kéèyàn ní?
14 Ní àwọn àpéjọ àgbáyé wa, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí àwọ̀ àti àṣà wọn yàtọ̀ síra tí wọ́n máa ń pàdé níbẹ̀ máa ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ ọlọ́yàyà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. Irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká rí ohun tí àlàáfíà táwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn lónìí mú kó ṣeé ṣe, ó ń mú kí wọ́n gbádùn ìṣọ̀kan kárí ayé. Ó sábà máa ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu tí wọ́n bá rí àwọn tí wọ́n rò pé ó yẹ kí wọ́n máa bára wọn ṣọ̀tá bí wọ́n ṣe ń “fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:3) Bá a bá ronú ohun tó ti ní láti ná àwọn kan kí wọ́n tó lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn míì, a óò rí i pé ohun àgbàyanu ni ìṣọ̀kan yìí jẹ́.
15, 16. (a) Èrò wo ni Pétérù ní bó ṣe ń dàgbà, báwo nìyẹn sì ṣe jẹ́ ìṣòro fún un? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ran Pétérù lọ́wọ́ láti ní èrò tó yàtọ̀?
15 Bí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ àwọn èèyàn kan dàgbà bá yàtọ̀ síra, ó máa ń ṣòro láti mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan. Ká lè lóye ohun tó máa ń gbà kí irú ìṣọ̀kan yìí tó lè ṣeé ṣe, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pétérù, èyí tó wáyé ní ọ̀rúndún kìíní. Nínú ọ̀rọ̀ tó sọ, a lè lóye ojú tó fi ń wo àwọn Kèfèrí tí kò dádọ̀dọ́. Ó ní: “Ẹ̀yin mọ̀ dáadáa bí ó ti jẹ́ aláìbófinmu tó fún Júù kan láti dara pọ̀ mọ́ tàbí sún mọ́ ènìyàn ẹ̀yà mìíràn; síbẹ̀, Ọlọ́run ti fi hàn mí pé èmi kò gbọ́dọ̀ pe ènìyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́.” (Ìṣe 10:24-29; 11:1-3) Torí èrò tó wọ́pọ̀ nígbà ayé Pétérù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò tóun náà ní bó ṣe ń dàgbà ni pé àwọn Júù bíi tòun nìkan ni Òfin kàn án nípa pé kóun fẹ́ràn. Ó ṣeé ṣe kó ti rò pé kò sóhun tó burú níbẹ̀ bí òun bá ń wo àwọn Kèfèrí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀tá tó yẹ kóun kórìíra. *
16 Ronú nípa bó ṣe máa nira tó fún Pétérù bó ṣe ń wọ ilé Kọ̀nílíù lọ. Ṣó tiẹ̀ lè ṣeé ṣe fún ọkùnrin kan tó ti ní èrò òdì nípa àwọn Kèfèrí tẹ́lẹ̀ rí láti ‘so pọ̀ ní ìṣọ̀kan’ pẹ̀lú wọn “nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà”? (Éfé. 4:3, 16) Síbẹ̀, ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, ẹ̀mí Ọlọ́run ti ṣí ọkàn Pétérù payá, nípa bẹ́ẹ̀ ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tó yàtọ̀, ó sì ti ń borí ẹ̀tanú tó ní. Nínú ìran kan tó rí, Jèhófà mú kó ṣe kedere sí i pé ẹ̀yà ẹnì kan tàbí orílẹ̀-èdè tó ti wá kò ní ipa kankan lórí ojú tí Ọlọ́run fi ń wo irú ẹni bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 10:10-15) Torí náà, ó rọrùn fún Pétérù láti sọ fún Kọ̀nílíù pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Pétérù yí pa dà, ó sì wá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará” ní ti tòótọ́.—1 Pét. 2:17.
17. Ọ̀nà wo ni ìṣọ̀kan tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn gbà jẹ́ àgbàyanu?
17 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù jẹ́ ká mọrírì ìyípadà àgbàyanu tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí. (Ka Aísáyà 2:3, 4.) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” ti yí èrò wọn pa dà kó lè wà ní ìbámu pẹ̀lú “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Ìṣí. 7:9; Róòmù 12:2) Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti pa èrò wọn dà yìí ló ti fìgbà kan jingiri sínú ìkórìíra, ìṣọ̀tá àti ẹ̀mí ìyapa tó kún inú ayé Sátánì yìí. Àmọ́, nípasẹ̀ ohun tí wọ́n kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, wọ́n ti mọ béèyàn ṣe ń “lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà.” (Róòmù 14:19) Ìṣọ̀kan tí èyí mú wá sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run.
18, 19. (a) Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kàn wa ṣe lè pa kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè pa kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run? Àwọn tó ti ilẹ̀ òkèèrè wá wà nínú ọ̀pọ̀ ìjọ. Àṣà àwọn kan lè yàtọ̀ sí tiwa tàbí kí wọ́n má mọ èdè wa sọ dáadáa. Ṣé a máa ń dá sí wọn? Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dábàá pé ká ṣe nìyẹn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sí àwọn ara Róòmù, níbi táwọn Júù àtàwọn Kèfèrí wà, ó sọ pé: “Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wá, pẹ̀lú ògo fún Ọlọ́run ní iwájú.” (Róòmù 15:7) Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ rẹ tó yẹ kó o mọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?
19 Kí la tún lè ṣe kí ẹ̀mí mímọ́ lè máa darí ìgbésí ayé wa? A máa gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn tí a ó ti jíròrò àwọn apá tó kù lára èso ti ẹ̀mí.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Lára èso tí Jésù mẹ́nu kàn ni “èso ti ẹ̀mí” àti “èso ètè” tí àwa Kristẹni fi ń rúbọ sí Ọlọ́run nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.—Héb. 13:15.
^ Léfítíkù 19:18 sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di kùnrùngbùn sí ọmọ àwọn ènìyàn rẹ; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbà pé àwọn Júù nìkan làwọn gbólóhùn náà, “ọmọ àwọn ènìyàn rẹ” àti “ọmọnìkejì rẹ” ń tọ́ka sí. Òfin béèrè pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó kù. Àmọ́, kò fara mọ́ èrò táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ọ̀rúndún kìíní ń gbé lárugẹ, pé ọ̀tá àwọn ni gbogbo àwọn tí kì í ṣe Júù àti pé ó yẹ kí àwọn kórìíra wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo la ṣe lè fi ìfara-ẹni-rúbọ hàn fún àwọn ará wa?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìdùnnú sin Ọlọ́run?
• Báwo la ṣe lè máa pa kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
“Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Gangan Nìyí”
Ìwé kan tó sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ìjọba Násì, ìyẹn Between Resistance and Martyrdom—Jehovah’s Witnesses in the Third Reich ṣàlàyé ohun tí Júù ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n sọ nípa ìgbà tó kọ́kọ́ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé lẹ́yìn tó dé sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Neuengamme. Ó ní:
“Lójú ẹsẹ̀ tí àwa Júù tó wá láti Dachau wọ inú àgọ́ náà, ńṣe làwọn Júù yòókù bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo nǹkan tí wọ́n ní pa mọ́ ká má bàa bá wọn lò ó. . . . Ká tó dé inú [àgọ́ náà], gbogbo wa là ń ran ara wa lọ́wọ́. Àmọ́ nínú àgọ́ tó jẹ́ pé ìgbàkigbà ni ikú lè dé, ohun tó jẹ gbogbo èèyàn lógún jù lọ ni bí wọ́n ṣe máa dáàbò bo ara wọn, kò sí ohun tó kàn wọ́n nípa àwọn ẹlòmíì. Ṣùgbọ́n ohun tó yani lẹ́nu ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ṣe ní tiwọn. Ní àkókò yẹn, wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ kára láti tún àwọn páìpù omi mélòó kan ṣe. Ojú ọjọ́ tutù, gbogbo wọn sì dúró láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ nínú omi tó tutù bíi yìnyín. Kò sí ẹni tó mọ bí wọ́n ṣe lè fara da irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Wọ́n sọ pé Jèhófà ló ń fún àwọn lókun. Bíi ti àwa yòókù, wọ́n nílò búrẹ́dì wọn lójú méjèèjì torí pé ebi ń pa wọ́n. Àmọ́ kí ni wọ́n ń ṣe? Wọ́n máa ń kó gbogbo búrẹ́dì tí wọ́n ní jọ, wọ́n á jẹ ìdajì lára rẹ̀, wọ́n á sì fún àwọn ará wọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti Dachau ní ìdajì yòókù. Wọ́n á kí wọn káàbọ̀, wọ́n á sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu. Wọ́n á kọ́kọ́ gbàdúrà kí wọ́n tó jẹun. Ìwọ̀n tí wọ́n bá rí jẹ máa ń tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì ń láyọ̀. Wọ́n á sọ pé ebi kò pa àwọn mọ́. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyí tí mo fi sọ pé: Àwọn Kristẹni tòótọ́ gangan nìyí.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ǹjẹ́ ò ń wá àkókò lójoojúmọ́ látinú àwọn ìgbòkègbodò mìíràn kó o bàa lè sún mọ́ Jèhófà?