Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ O Rántí?
Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
• Kí nìdí tá a fi lè gbà pé ọgbà Édẹ́nì wà lóòótọ́?
Bíbélì sọ pé ó wà lóòótọ́, ó sì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan pàtàkì mélòó kan nípa ibi tó wà. Méjì lára àwọn odò tí Bíbélì sọ pé ó ṣàn jáde láti inú ọgbà náà ṣì wà títí dòní. Ìtàn àròsọ tàbí ìtàn àgbọ́sọ kì í sábàá sọ irú kúlẹ̀kúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nípa ibi tó ṣì wà títí dòní. Jésù, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbíyè lé jù lọ, sọ pé ẹni gidi ni Ádámù àti Éfà.—1/1, ojú ìwé 5 sí 6 àti 9.
• Ṣé Ọlọ́run mọ̀ pé Ádámù àti Éfà máa dẹ́ṣẹ̀?
Rárá o. Jèhófà fún wọn ní òye àti òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n, èyí tó lè mú kí wọ́n yàn láti ṣègbọràn tàbí kí wọ́n ṣàìgbọràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní agbára láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú, ńṣe ló máa ń lo agbára náà lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu.—1/1, ojú ìwé 13 sí 15.
• Ṣé àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń lo orúkọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oògùn tí ń dáàbò boni?
Àwọn èèyàn kan máa ń wo ohun kan tàbí àmì kan gẹ́gẹ́ bí oògùn tàbí ohun tó ní agbára láti dáàbò bò wọ́n lọ́nà ìyanu, àmọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run kì í wo orúkọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oògùn tí ń dáàbò boni. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, wọ́n ń wá bí wọ́n á ṣe máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sá di orúkọ rẹ̀. (Sef. 3:12, 13)—1/15, ojú ìwé 5 sí 6.
• Ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, àwọn wo ló jàǹfààní látinú àṣà pípèéṣẹ́?
Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni. Ó fún àwọn òtòṣì tó ń pèéṣẹ́ láǹfààní láti jẹ́ òṣìṣẹ́ kára. Ó fún àwọn míì láǹfààní láti jẹ́ ọ̀làwọ́ àti láti máa wojú Ọlọ́run fún ìbùkún.—2/1, ojú ìwé 15.
• Kí nìdí tí Jèhófà fi kọ Sọ́ọ̀lù Ọba sílẹ̀?
Ó yẹ kí Sọ́ọ̀lù dúró kí wòlíì Ọlọ́run dé láti wá rú ẹbọ, àmọ́ ó ṣàìgbọràn ó sì lọ rú ẹbọ náà fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, kò ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé kó pa àwọn ọ̀tá wọn run.—2/15, ojú ìwé 22 sí 23.
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a kórìíra ìwà àìlófin?
Ká má ṣe sọ ara wa di ẹrú ọtí líle, ká sá fún iṣẹ́ awo, ká sì fetí sí ìkìlọ̀ Jésù nípa ìṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ sá fún wíwo àwòrán oníhòòhò àti onírúurú èròkérò tó lè máa gbé wá sọ́kàn wa. (Mát. 5:27, 28) Bákan náà, a kò gbọ́dọ̀ máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a ti yọ lẹ́gbẹ́.—2/15, ojú ìwé 29 sí 32.
• Kí ló gba àfiyèsí nípa ilé oyin tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì òde òní?
Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ilé oyin tó ju ọgbọ̀n lọ, èyí tí àwọn ọ̀mọ̀wé fojú bù pé á tó ìdajì tọ́ọ̀nù oyin tí wọ́n ń mú jáde níbẹ̀ lọ́dọọdún. Èyí fi hàn pé wọ́n sin oyin ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run sọ pé á máa “ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kís. 3:8)—3/1, ojú ìwé 15.
• Báwo ni Jeremáyà ṣe dà bí igi “tí a gbìn sẹ́bàá omi, tí ó na gbòǹgbò rẹ̀”? (Jer. 17:7, 8)
Kò dẹ́kun láti máa mú èso jáde; bẹ́ẹ̀ ni kò sì jẹ́ kí àwọn afiniṣẹ̀sín nípa lórí òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó tẹra mọ́ jíjọ́sìn Ọlọ́run tó jẹ́ Orísun omi tó ń gbé ìwàláàyè ró, ó sì ń ṣe ohun tó bá sọ fún un.—3/15, ojú ìwé 14.
• Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún Màtá pé nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò? (Lúùkù 10:41, 42)
Jésù kò sọ pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan ti ara torí bó ṣe pèsè onírúurú oúnjẹ; kò sì sọ pé iṣẹ́ àṣekára tó ṣe kò wúlò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń pe àfiyèsí sí ohun tó fi sí ipò àkọ́kọ́. Màtá kò lo àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tó ní láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára sí i.—4/1, ojú ìwé 12 sí 13.
• Àwọn ohun wo ló kù díẹ̀ káàtó nínú bí wọ́n ṣe gbọ́ ẹjọ́ Jésù?
Ilé ẹjọ́ náà kò gbọ́ tẹnu rẹ̀. Wọ́n fàyè gba àwọn ẹlẹ́rìí èké. Alẹ́ ni wọ́n gbọ́ ẹjọ́ náà. Ọjọ́ kan náà tí ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀ ló parí.—4/1, ojú ìwé 20.