Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni—“Ẹ Wà Ní Ìmúratán”
Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni—“Ẹ Wà Ní Ìmúratán”
“Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”—LÚÙKÙ 12:40.
1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìmọ̀ràn Jésù pé ká “wà ní ìmúratán” sọ́kàn?
“NÍGBÀ tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀” tó sì “ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì,” kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ìwọ àti ìdílé rẹ? (Mát. 25:31, 32) Níwọ̀n bí èyí yóò ti wáyé ní wákàtí tí a kò ronú pé ó lè jẹ́, ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká fi ìṣílétí Jésù pé ká “wà ní ìmúratán” sọ́kàn!—Lúùkù 12:40.
2 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a jíròrò bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ṣe lè ran ìdílé lódindi lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí nípa fífi ọwọ́ tó ṣe pàtàkì mú ojúṣe wọn. Ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà mú kí ìdílé wa ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ẹ Jẹ́ Kí Ojú Yín “Mú Ọ̀nà Kan”
3, 4. (a) Kí ló yẹ kí àwọn ìdílé Kristẹni ṣọ́ra fún? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ kí ojú wa “mú ọ̀nà kan”?
3 Kí àwọn ìdílé lè wà ní ìmúratán de bíbọ̀ Kristi, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má ṣe yà bàrà kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Wọ́n gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí àwọn ohun tó ń fa ìpínyà ọkàn má bàa mú kí wọ́n di ẹni tí kò wà ní ìmúratán. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìdílé ló ti kó sínú páńpẹ́ kíkó ohun ìní tara jọ, ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Jésù sọ nípa bá a ṣe lè jẹ́ kí ojú wa “mú ọ̀nà kan.” (Ka Mátíù 6:22, 23.) Gẹ́gẹ́ bí fìtílà ṣe lè tan ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà wa tí èyí á sì jẹ́ ká lè rìn láì ṣubú, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí à ń fi “ojú ọkàn-àyà” ìṣàpẹẹrẹ wa rí lè mú ká ní òye tí a ó fi máa hùwà bó ti yẹ, ká má bàa kọsẹ̀.—Éfé. 1:18.
4 Ojú tó ń ríran kedere ni ojú tó ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, tá a sì lè fi wo ohun kan ní tààràtà. Bó ṣe yẹ kí ojú ọkàn-àyà wa máa ṣiṣẹ́ náà nìyẹn. Láti ní ojú ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ tó mú ọ̀nà kan túmọ̀ sí pé ká ní ète pàtó kan lọ́kàn. Ìyẹn ni pé ká máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí dípò tí a ó fi jẹ́ kí àwọn nǹkan tara máa gbà wá lọ́kàn tí a ó sì máa ṣàníyàn jù nípa bí a ṣe máa bójú tó àwọn ohun tara tí ìdílé wa nílò. (Mát. 6:33) Èyí túmọ̀ sí pé a máa jẹ́ kí àwọn ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn, a ó sì máa fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa.—Héb. 13:5.
5. Báwo ni ọ̀dọ́bìnrin kan ṣe fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ni òun fi “ojú” sùn?
5 Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló máa ń wà níbẹ̀ bí àwọn òbí bá kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ní ojú tó mú ọ̀nà kan. Ṣe àgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ ọ̀dọ́bìnrin kan ní orílẹ̀-èdè Etiópíà. Ó ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ rẹ̀ ní ilé ìwé débi pé nígbà tó parí ilé ẹ̀kọ́ girama wọ́n fún un ní ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, èyí táá jẹ́ kó lè kàwé sí i. Àmọ́ torí pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló fi ṣe àfojúsùn rẹ̀, ó kọ̀ láti gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ náà. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó rí iṣẹ́ kan níbi tí wọ́n á ti máa san ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] owó yúrò, ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé igba [4,200] dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún un lóṣù. Owó ńlá gbáà nìyẹn jẹ́ torí pé iye tí wọ́n sábà máa ń san fún àwọn òṣìṣẹ́ lórílẹ̀-èdè wọn kéré sí ìyẹn. Àmọ́ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà ni ọmọbìnrin náà fi “ojú” sùn. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ kó tó kọ̀ láti gba iṣẹ́ náà. Nígbà tí àwọn òbí ọ̀dọ́bìnrin yìí gbọ́ ohun tí ọmọ wọ́n ṣe báwo ló ṣe rí lára wọn? Ńṣe ni wọ́n bá a yọ̀, wọ́n sì sọ fún un pé inú àwọn dùn sí ohun tó ṣe.
6, 7. Torí ewu wo ló ṣe yẹ ká ‘la ojú wa sílẹ̀’?
6 Nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:22, 23, a lè rí i pé ńṣe ló ń fúnni ní ìkìlọ̀ nípa ìwọra. Jésù kò sọ ohun téèyàn lè rò pé ó yẹ kó jẹ́ òdìkejì jíjẹ́ kí ojú ẹni “mú ọ̀nà kan,” bóyá kó sọ pé, ‘ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá mú ọ̀nà púpọ̀.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lo ọ̀rọ̀ náà “burú.” Ojú tó “burú” ni ojú tí kò “dára; tó jẹ́ onílara,” ìyẹn ni pé ó ní ojúkòkòrò tàbí ìwọra nínú. (Mát. 6:23; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ojúkòkòrò tàbí ìwọra? Bíbélì sọ pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra [tàbí, “ojúkòkòrò”] láàárín yín.”—Éfé. 5:3; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè rọrùn láti mọ̀ bí àwọn ẹlòmíì bá jẹ́ oníwọra, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti mọ̀ pé àwa fúnra wa ti di oníwọra. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu ká ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Jésù pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.” (Lúùkù 12:15) Èyí gba pé ká máa ṣàyẹ̀wò ara wa ká lè mọ ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Àwọn ìdílé Kristẹni gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí iye àkókò àti owó tí wọ́n ń lò láti fi ṣe fàájì, láti fi ṣe eré ìtura àti láti fi kó ohun ìní jọ.
8. Ọ̀nà wo la lè gbà ‘la ojú wa sílẹ̀’ bó bá kan ọjà rírà?
8 Bó o bá fẹ́ ra ohun kan, má kàn rà á torí pé owó rẹ ká a. Kó o tó ra ohunkóhun, ó yẹ kó o ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé màá máa ráyè lò ó déédéé tí màá sì lè máa bójú tó o? Báwo ló ṣe máa gbà mí lákòókò tó kí n tó mọ̀ ọ́n lò dáadáa?’ Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ má ṣe máa gba gbogbo ohun tí àwọn tó ń polówó ọjà ń sọ nípa ọjà wọn gbọ́, kẹ́ ẹ wá lọ ra aṣọ tàbí àwọn nǹkan míì tó gbówó lórí torí pé wọ́n kọ orúkọ ilé iṣẹ́ tó ṣe é sí i lára, yálà ẹ nílò rẹ̀ tàbí ẹ kò nílò rẹ̀. Ẹ gbọ́dọ̀ máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Bákan náà, tún ronú nípa bóyá ohun tó o fẹ́ rà yẹn máa ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de bíbọ̀ Ọmọ ènìyàn. Ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Héb. 13:5.
Ẹ Máa Fi Àwọn Ohun Tẹ̀mí Ṣe Àfojúsùn Yín
9. Báwo ni fífi àwọn ohun tẹ̀mí ṣe àfojúsùn ṣe lè ran ìdílé kan lọ́wọ́?
9 Ọ̀nà míì tí àwọn tó wà nínú ìdílé lè gbà mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára sí i, kí wọ́n sì jẹ́ kí àjọṣe tí ìdílé lápapọ̀ ní pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán ni pé kí wọ́n fi àwọn ohun tẹ̀mí ṣe àfojúsùn wọn kí wọ́n sì sapá kí ọwọ́ wọ́n lè tẹ àfojúsùn náà. Èyí máa jẹ́ kí àwọn ìdílé tó wù pé kí wọ́n máa ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí mọ bí wọ́n ti ń ṣe dáadáa sí, ó sì tún máa jẹ́ kí wọ́n lè pinnu bí ìgbòkègbodò èyíkéyìí tí wọ́n bá fẹ́ lọ́wọ́ sí ti ṣe pàtàkì tó.—Ka Fílípì 1:10.
10, 11. Gẹ́gẹ́ bí ìdílé, àwọn ohun tẹ̀mí wo lẹ fi ṣe àfojúsùn yín, kí lẹ sì máa fẹ́ fi ṣe àfojúsùn yín lọ́jọ́ iwájú?
10 Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló lè tìdí rẹ̀ wá, bí ìdílé bá ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ lè tètè tẹ̀, èyí tí kò kọjá agbára ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà nínú ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá fi ṣe àfojúsùn wọn pé ojoojúmọ́ ni àwọn á máa jíròrò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, àlàyé tí àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń ṣe máa mú kí olórí ìdílé mọ bí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà ṣe lágbára tó. Bí wọ́n bá fi ṣe àfojúsùn wọn láti máa ka Bíbélì pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, èyí máa fún àwọn ọmọ ní àǹfààní títayọ láti mú ìwé kíkà wọn sunwọ̀n sí i, wọ́n á sì máa túbọ̀ lóye àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì. (Sm. 1:1, 2) Ǹjẹ́ kò tún yẹ ká fi ṣe àfojúsùn wa pé a máa mú kí àdúrà wa sunwọ̀n sí i? Ohun mìíràn tó tún dára pé kẹ́ ẹ fi ṣe àfojúsùn yín ni bí ẹ ṣe máa túbọ̀ ní àwọn ànímọ́ tó jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí. (Gál. 5:22, 23) Àbí kẹ̀, ṣé ẹ lè wá ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà máa fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn tẹ́ ẹ̀ ń bá pàdé lóde ẹ̀rí? Bí gbogbo ìdílé bá ń sapá láti ṣe èyí, ó máa mú kí àwọn ọmọ máa fi àánú hàn, ó sì ṣeé ṣe kó wù wọ́n láti gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí kí wọ́n di míṣọ́nnárì.
11 O ò ṣe ronú nípa àwọn ohun mélòó kan tí ìwọ àti ìdílé rẹ̀ lè fi ṣe àfojúsùn yín? Ǹjẹ́ ìdílé rẹ̀ lè fi ṣe àfojúsùn wọn láti máa lo àkókò tó pọ̀ sí i lóde ẹ̀rí? Bó o bá ń bẹ̀rù láti wàásù lórí fóònù, ní òpópónà tàbí láwọn ibi ìtajà ṣé o lè wá nǹkan ṣe sí i? Àbí o lè lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i? Ṣé ẹnì kan nínú ìdílé lè kọ́ èdè míì kó bàa lè wàásù ìhìn rere fún àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀?
12. Kí ni àwọn olórí ìdílé lè ṣe kí wọ́n lè ran ìdílé wọn lọ́wọ́ láti mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i?
12 Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, ó yẹ kó o mọ àwọn ibi tó yẹ kí ìdílé rẹ ti mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i. Lẹ́yìn náà, kó o ní àwọn àfojúsùn pàtó tó máa ran ìdílé rẹ lọ́wọ́. Àwọn ohun tẹ́ ẹ bá fi ṣe àfojúsùn yín nínú ìdílé gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn ohun tí ọwọ́ yín lè tẹ̀, ohun tó bá ipò yín mu àti ohun tí agbára yín gbé. (Òwe 13:12) Àmọ́, ó máa ń gba àkókó kọ́wọ́ tó tẹ àfojúsùn tó lè ṣeni láǹfààní. Torí náà, ó yẹ kó o ra àkókò pa dà fún àwọn àfojúsùn tẹ̀mí látinú àkókò tó o fi ń wo tẹlifíṣọ̀n. (Éfé. 5:15, 16) Ṣiṣẹ́ takuntakun kí ọwọ́ rẹ̀ bàa lè tẹ àwọn àfojúsùn tó o gbé kalẹ̀ fún ìdílé rẹ. (Gál. 6:9) Ìdílé tó bá fi àwọn ohun tẹ̀mí ṣe àfojúsùn rẹ̀ máa jẹ́ kí ìlọsíwájú rẹ̀ “fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tím. 4:15.
Ẹ Máa Ṣe Ìjọsìn Ìdílé Déédéé
13. Ìyípadà wo ló dé bá àkókó tá a máa ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká ronú lé lórí?
13 Ohun pàtàkì kan tó lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ kí wọ́n lè “wà ní ìmúratán” fún bíbọ̀ Ọmọ ènìyàn ni ìyípadà ńlá tó dé bá àkókò tá à ń ṣe ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti January 1, ọdún 2009. Kò tún sídìí fún wa láti máa pàdé pọ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tá a máa ń ṣe nígbà yẹn mọ́ torí pé a ti ń ṣe é pa pọ̀ pẹ̀lú Ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. A ṣe ìyípadà yìí kí àwọn ìdílé Kristẹni lè ní àǹfààní láti mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lágbára sí i nípa ṣíṣètò ìrọ̀lẹ́ kan pàtó lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún Ìjọsìn Ìdílé. Ní báyìí tó ti ṣe díẹ̀ tí ìyípadà yẹn ti wáyé, a lè bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mò ń lo ìrọ̀lẹ́ tó ṣí sílẹ̀ yìí fún Ìjọsìn Ìdílé tàbí fún ìdákẹ́kọ̀ọ́? Ṣé mo ti jàǹfààní látinú ohun tí ìṣètò yìí wà fún?’
14. (a) Kí ni ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé tàbí ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ka ya ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́?
14 Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé tàbí ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé ni pé ká lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. (Ják. 4:8) Bá a bá ń wá àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, tí ìmọ̀ tá a ní nípa Ẹlẹ́dàá sì ń pọ̀ sí i, ó máa fún àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ lókun. Bá a bá ṣe sún mọ́ Jèhófà tó bẹ́ẹ̀ náà la ṣe máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó ‘pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú wa àti pẹ̀lú gbogbo okun wa.’ (Máàkù 12:30) Kò sí àní-àní pé a fẹ́ láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run, a sì fẹ́ máa ṣe àfarawé rẹ̀. (Éfé. 5:1) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí Ìjọsìn Ìdílé ní ìrọ̀lẹ́ máa wáyé déédéé, kí ìdílé wa lè “wà ní ìmúratán” nípa tẹ̀mí bá a ti ń retí “ìpọ́njú ńlá” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀. (Mát. 24:21) Ìgbàlà wa rọ̀ mọ́ ọn.
15. Ipa wo ni Ìjọsìn Ìdílé nírọ̀lẹ́ lè ní lórí ọwọ́ tí àwọn tó wà nínú ìdílé fi mú ara wọn?
15 Ohun mìíràn tí ìṣètò Ìjọsìn Ìdílé wà fún ni láti mú kí àwọn tó wà nínú ìdílé túbọ̀ sún mọ́ ara wọn. Bí ìdílé bá ń wá àkókò láti jọ jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí pa pọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí máa nípa lórí ọwọ́ tí wọ́n fi mú ara wọn. Nígbà tí tọkọtaya bá ń sọ bí ìṣúra tẹ̀mí tí wọ́n jọ ṣàwárí ṣe múnú wọn dùn tó, ó máa mú kí wọ́n túbọ̀ ṣe ara wọn lọ́kan. (Ka Oníwàásù 4:12.) Bí àwọn òbí àtàwọn ọmọ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé pa pọ̀ ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ tí í ṣe “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” ṣe gbogbo wọn lọ́kan.—Kól. 3:14.
16. Sọ ọ̀nà tí àwọn arábìnrin mẹ́ta kan ń gbà jàǹfààní látinú bí wọ́n ṣe ya ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
16 Ṣe àgbéyẹ̀wò bí àwọn arábìnrin mẹ́ta kan ṣe jàǹfààní látinú bí wọ́n ṣe ya ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arábìnrin àgbàlagbà mẹ́ta tó jẹ́ opó yìí kò bá ara wọn tan, ìlú kan náà ni wọ́n ń gbé, ó sì ti tó ọdún mélòó kan tí wọ́n ti ń bára wọn ṣọ̀rẹ́. Torí pé ó wù wọ́n kí wọ́n túbọ̀ máa ṣe nǹkan pa pọ̀, tí wọ́n sì fẹ́ kí àkókò tí wọ́n á máa lò pa pọ̀ máa fún àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lókun, dípò kó kàn jẹ́ láti máa fi gbádùn ara wọn, wọ́n pinnu láti ya ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan sọ́tọ̀ tí wọ́n á fi máa pàdé láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwé “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n kọ́kọ́ ń lò nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “A máa ń gbádùn àkókò tá à ń lò débi pé ó sábà máa ń lé ní wákàtí kan tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. A máa ń gbìyànjú láti fojú inú yàwòrán ipò táwọn ará wa ní ọ̀rúndún kìíní wà, a sì máa ń jíròrò ohun tá a máa ṣe tá a bá bára wa nírú ipò bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà a máa ń gbìyànjú láti lo àwọn kókó tá a bá kọ́ nígbà ìjíròrò náà lóde ẹ̀rí. Èyí ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn túbọ̀ gbádùn mọ́ wa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, a sì ń kẹ́sẹ járí.” Yàtọ̀ sí pé ìṣètò yìí ti fún àjọṣe tí àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́ta yìí ní pẹ̀lú Ọlọ́run lókun, ó tún ti mú kí wọ́n túbọ̀ mọwọ́ ara wọn sí i. Wọ́n sọ pé: “A mọrírì ìṣètò yìí gan-an ni.”
17. Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ kí Ìjọsìn Ìdílé nírọ̀lẹ́ kẹ́sẹ járí?
17 Ìwọ náà ńkọ́? Àwọn àǹfààní wo lò ń rí látinú àkókò tó o yà sọ́tọ̀ fún ṣíṣe Ìjọsìn Ìdílé tàbí fún ìdákẹ́kọ̀ọ́? Bó bá jẹ́ pé ìgbà tó o bá ráyè nìkan lò ń ṣe é, o kò ní lè jàǹfààní nínú ohun tí ìṣètò náà wà fún. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ló yẹ kó wà níbẹ̀ ní àkókò tí ẹ fi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sí. Kò yẹ kẹ́ ẹ pa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ nítorí ohun tí kò tó nǹkan. Síwájú sí i, kẹ́ ẹ rí i pé ìtẹ̀jáde tẹ́ ẹ̀ ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní àwọn ìsọfúnni tó máa ran ìdílé yín lọ́wọ́. Báwo lo ṣe lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gbádùn mọ́ni? Lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́, jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fi ọ̀wọ̀ hàn kó sì tuni lára.—Ják. 3:18. *
Ẹ “Wà Lójúfò” Kí Ẹ sì “Wà ní Ìmúratán”
18, 19. Ipa wo ló yẹ kí mímọ̀ pé bíbọ̀ Ọmọ ènìyàn ti sún mọ́lé ní lórí ìwọ àti ìdílé rẹ?
18 Bí ipò ayé ṣe ń bà jẹ́ sí i lọ́jọ́ wa yìí ti mú kó dá wa lójú pé láti ọdún 1914 wá ni a ti wọ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé búburú Sátánì. Ó dájú pé ogun Amágẹ́dọ́nì máa tó jà. Kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọmọ ènìyàn á fi wá láti mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ sórí àwọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run. (Sm. 37:10; Òwe 2:21, 22) Ṣé kò yẹ kí mímọ̀ tó o mọ̀ pé àwọn nǹkan yìí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ nípa lórí ìwọ àti ìdílé rẹ?
19 Ǹjẹ́ ò ń ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Jésù pé ká jẹ́ kí ojú wa “mú ọ̀nà kan”? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ayé yìí lè máa lépa ọrọ̀, òkìkí tàbí agbára, ṣé àwọn ohun tẹ̀mí ni ìdílé rẹ fi ń ṣe àfojúsùn wọn? Ṣé ò ń jàǹfààní látinú ìṣètò Ìjọsìn Ìdílé tàbí ti ìdákẹ́kọ̀ọ́? Ṣé ó ń ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe ara yín lọ́kan kẹ́ ẹ sì sún mọ́ Jèhófà? Bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, bó o bá jẹ́ ọkọ, aya tàbí ọmọ, ǹjẹ́ ò ń ṣe ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe lànà rẹ̀ sílẹ̀, tó o sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ran gbogbo àwọn tó wà nínu ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti máa “wà lójúfò”? (1 Tẹs. 5:6) Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa “wà ní ìmúratán” de bíbọ̀ Ọmọ ènìyàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Bó o bá fẹ́ mọ ìtẹ̀jáde tó o lè lò àti bí o ṣe lè mú kí gbogbo ìdílé jàǹfààní nínú Ìjọsìn Ìdílé kó sì gbádùn mọ́ni, wo Ilé Ìṣọ́ October 15, 2009, ojú ìwé 29 sí 31.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Ṣàlàyé bí àwọn ìdílé tó jẹ́ Kristẹni ṣe lè máa “wà ní ìmúratán” nípa . . .
níní ojú tó “mú ọ̀nà kan.”
níní àfojúsùn tẹ̀mí àti wíwá bí ọwọ́ ṣe máa tẹ àfojúsùn náà.
ṣíṣe Ìjọsìn Ìdílé ní ìrọ̀lẹ́ déédéé.
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ojú tó “mú ọ̀nà kan” máa jẹ́ ká kọ àwọn ohun tó ń fa ìpínyà ọkàn nínú ayé sílẹ̀