Ìhìn Rere Tó Yẹ Kí Gbogbo Èèyàn Gbọ́
Ìhìn Rere Tó Yẹ Kí Gbogbo Èèyàn Gbọ́
“Ìhìn rere; ní ti tòótọ́, . . . jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà.”—RÓÒMÙ 1:16.
1, 2. Kí nìdí tó o fi ń wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run, kí lo sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ìjọba náà tó o bá ń wàásù?
Ó ṢEÉ ṣe kó ti wá sí ẹ lọ́kàn rí tàbí kó o ti sọ ọ́ rí pé: ‘Kò sí ọjọ́ tí mo jáde òde ẹ̀rí tí inú mi kì í dùn.’ Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run, o mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kó o máa wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí.” Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o lè ka àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa iṣẹ́ ìwàásù láìwòwé.—Mát. 24:14.
2 Bó o ṣe ń wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run, iṣẹ́ tí Jésù bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lò ń ṣe nìṣó. (Ka Lúùkù 4:43.) Ó dájú pé ọ̀kan lára ohun tó o máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ ni pé Ọlọ́run máa tó dá sí ọ̀ràn aráyé. O máa ń jẹ́ kó yé wọn pé nígbà “ìpọ́njú ńlá,” Ọlọ́run máa pa ìsìn èké run ó sì máa mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:21) Ó ṣeé ṣe kó o tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé gbogbo ilẹ̀ ayé máa pa dà di Párádísè nínú Ìjọba Ọlọ́run, àlàáfíà àti ayọ̀ á sì gbilẹ̀. Kódà, “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run tá à ń wàásù rẹ̀ jẹ́ apá kan “ìhìn rere [tá a polongo] ṣáájú fún Ábúráhámù, pé: ‘Nípasẹ̀ rẹ ni a ó bù kún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.’”—Gál. 3:8.
3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ìhìn rere nínú ìwé Róòmù?
3 Ǹjẹ́ ohun kan wà tó yẹ ká túbọ̀ máa tẹnu mọ́ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run tó yẹ kí gbogbo èèyàn gbọ́? Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ó lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọba” àmọ́, ó lo gbólóhùn náà, “ìhìn rere” ní igbà méjìlá. (Ka Róòmù 14:17.) Kí ni Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere nínú lẹ́tà yẹn? Kí nìdí tí ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fi ṣe pàtàkì? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká fi èyí sọ́kàn bá a ṣe ń wàásù “ìhìn rere Ọlọ́run” fún àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?—Máàkù 1:14; Róòmù 15:16; 1 Tẹs. 2:2.
Kí Ló Pọn Dandan Kí Àwọn Ará Róòmù Mọ̀?
4. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù, kí ni ìwàásù rẹ̀ dá lé?
4 A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára ohun tí ìwàásù Pọ́ọ̀lù dá lé nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ fi í sẹ́wọ̀n ní Róòmù. A rí i kà pé nígbà táwọn Júù mélòó kan lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ‘jẹ́rìí kúnnákúnná fún wọn nípa (1) ìjọba Ọlọ́run ó sì lo ìyíniléròpadà pẹ̀lú wọn nípa (2) Jésù.’ Kí ló wá yọrí sí? “Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ohun tí ó sọ gbọ́; àwọn mìíràn kò sì gbà gbọ́.” Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù ‘a sì fi inú rere gba gbogbo àwọn tí wọ́n wọlé wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ní wíwàásù (1) ìjọba Ọlọ́run fún wọn àti kíkọ́ wọn ní àwọn nǹkan nípa (2) Jésù Kristi Olúwa.’ (Ìṣe 28:17, 23-31) Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ kí ni nǹkan mìíràn tó tẹnu mọ́? Ó tẹnu mọ́ ohun kan tó ṣe pàtàkì nínú ọ̀ràn Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ni ipa tí Jésù kó nínú ète Ọlọ́run.
5. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nínú ìwé Róòmù pé ó pọn dandan kí gbogbo èèyàn ṣe?
5 Ó pọn dandan kí gbogbo èèyàn mọ̀ nípa Jésù kí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ìyẹn ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ìwé Róòmù. Ó kọ́kọ́ sọ nípa “Ọlọ́run, ẹni tí mo ń fi ẹ̀mí mi ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìhìn rere nípa Ọmọ rẹ̀.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́.” Lẹ́yìn náà, ó sọ nípa àkókò “tí Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù yóò ṣèdájọ́ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ aráyé, ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere tí mo ń polongo.” Ó tún wá sọ pé: “Láti Jerúsálẹ́mù àti ní àlọyíká títí dé Ílíríkónì ni mo ti wàásù ìhìn rere nípa Kristi.” * (Róòmù 1:9, 16; 2:16; 15:19) Kí lo rò pé ó fà á tí Pọ́ọ̀lù fi tẹnu mọ́ Jésù Kristi nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Róòmù?
6, 7. Ta ló dá ìjọ Róòmù sílẹ̀, àwọn wo ló sì wà nínú ìjọ náà?
6 A kò mọ ìgbà tí wọ́n dá ìjọ Róòmù sílẹ̀. Ṣé àwọn Júù tàbí àwọn aláwọ̀ṣe tó wà níbẹ̀ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ti di Kristẹni kí wọ́n tó pa dà sí Róòmù? (Ìṣe 2:10) Àbí àwọn Kristẹni tó jẹ́ oníṣòwò àti arìnrìn-àjò ló wàásù ìhìn rere dé ìlú Róòmù? Yálà bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn rí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun tá a mọ̀ ni pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti dá ìjọ yẹn sílẹ̀ kí Pọ́ọ̀lù tó kọ lẹ́tà rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni. (Róòmù 1:8) Irú àwọn èèyàn wo ló wà nínú ìjọ yẹn?
7 Júù ni àwọn kan nínú wọn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kí Andironíkọ́sì àti Júníásì, ó pè wọ́n ní “àwọn ìbátan mi,” torí náà ó ṣeé ṣe káwọn pẹ̀lú jẹ́ Júù. Bákan náà, Júù ni Ákúílà tí òun àti ìyàwó rẹ̀ Pírísílà ń ṣe iṣẹ́ àgọ́ pípa ní ìlú Róòmù. (Róòmù 4:1; 9:3, 4; 16:3, 7; Ìṣe 18:2) Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Kèfèrí ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará tí Pọ́ọ̀lù fi ìkíni ránṣẹ́ sí. Àwọn kan nínú wọn lè jẹ́ “ti agbo ilé Késárì,” bóyá kí wọ́n jẹ́ ẹrú Késárì àti àwọn òṣìṣẹ́ kéékèèké.—Fílí. 4:22; Róòmù 1:6; 11:13.
8. Inú ipò tó ń bani nínú jẹ́ wo ni àwọn ará tó wà ní Róòmù bá ara wọn?
8 Bíi ti gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, gbogbo àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù bá ara wọn nínú ipò kan tó ń bani nínú jẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ nípa ipò náà pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Ó ṣe kedere nígbà náà pé ó yẹ kí gbogbo àwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí mọ̀ pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú ètò tí Ọlọ́run ṣe láti gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Ó Yẹ Ká Mọ̀ Pé A Jẹ́ Ẹlẹ́ṣẹ̀
9. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ìhìn rere lè yọrí sí?
9 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà rẹ̀ tó kọ sí àwọn ará Róòmù, ó ṣàlàyé ohun àgbàyanu tí ìhìn rere tí òun mẹ́nu bà léraléra lè yọrí sí. Ó sọ pé: “Èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́, fún Júù lákọ̀ọ́kọ́ àti pẹ̀lú fún Gíríìkì.” Ó dájú pé ó ṣeé ṣe láti rí ìgbàlà. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan òdodo ọ̀rọ̀ kan tó wà nínú Hábákúkù 2:4 (Bibeli Mimọ) tó fi hàn pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì. Ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Ṣugbọn olododo yio wà nipa ìgbagbọ́ rẹ̀.” (Róòmù 1:16, 17; Gál. 3:11; Héb. 10:38) Kí wá ni ìhìn rere tó lè mú kéèyàn rí ìgbàlà yẹn ní í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ náà pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀”?
10, 11. Kí nìdí tí kò fi ṣòro fún àwọn kan láti lóye ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 3:23, síbẹ̀ tó ṣòro fún àwọn míì láti lóye rẹ̀?
10 Kí ẹnì kan tó lè ní ìgbàgbọ́ táá mú kó rí ìgbàlà, ó gbọ́dọ̀ gbà pé òun jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Kì í ṣòro fún àwọn tá a fi Bíbélì tọ́ dàgbà tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run láti gbà pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. (Ka Oníwàásù 7:20.) Síbẹ̀, yálà àwọn wọ̀nyí gbà pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí wọn kò fi taratara gbà bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò ní kí wọ́n má mọ ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀.” (Róòmù 3:23) Àmọ́, tá a bá wà lóde ẹ̀rí, a lè bá àwọn èèyàn tí kò lóye gbólóhùn náà pàdé.
11 Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, bí wọ́n ṣe tọ́ ẹnì kan dàgbà lè máà jẹ́ kó ronú pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí òun sí, tàbí pé òun jogún ẹ̀ṣẹ̀. Síbẹ̀, ó lè gbà pé òun máa ń ṣe àṣìṣe, pé òun ń hu ìwà tí kò dára tàbí kí òun tiẹ̀ ti ṣe ohun tó burú rí. Ó sì tún máa rí i pé bí ọ̀ràn àwọn míì náà ṣe rí nìyẹn. Àmọ́, nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ ọ, ó lè má mọ ìdí tí òun àtàwọn míì fi ń hùwà lọ́nà yẹn. Kódà, ọ̀rọ̀ táwọn kan ń lò fún ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú èdè wọn máa ń mú káwọn míì rò pé ńṣe ni ẹni tí wọ́n pè bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀daràn tàbí pé ó ti kọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà kan. Bó bá wá jẹ́ pé irú ibẹ̀ yẹn ni ẹnì kan gbé dàgbà, ó dájú pé ó lè má tètè gbà pé irú ẹlẹ́ṣẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn lòun jẹ́.
12. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fi gbà gbọ́ pé gbogbo èèyàn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀?
12 Kódà ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ sí kò gbà pé àwa èèyàn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìtàn àròsọ lásán ni wọ́n ka ìtàn Bíbélì nípa Ádámù àti Éfà sí. Ibi tí ọ̀pọ̀ kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ làwọn míì dàgbà sí. Wọn kò gbà pé Ọlọ́run wà, wọn kò sì gbà pé Ẹni Gíga Jù Lọ kan wà tó yẹ kí àwa èèyàn máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ ló jẹ́ tí a kò bá tẹ̀ lé ìlànà tó fi lélẹ̀. Lédè mìíràn, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dà bí àwọn tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ wọn ní ọ̀rúndún kìíní pé wọ́n dà bí ẹni tí ‘kò ní ìrètí kankan’ tí wọ́n sì “wà ní ayé láìní Ọlọ́run.”—Éfé. 2:12.
13, 14. (a) Kí nìdí tí kò fi sí àwíjàre kankan fún àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ tí wọn kò sì tún gbà pé àwa èèyàn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀? (b) Kí ni àìní ìgbàgbọ́ ti yọrí sí fún ọ̀pọ̀ èèyàn?
13 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó sọ ìdí méjì tí kò fi sí àwíjàre kankan fún àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ tí wọn kò sì tún gbà pé àwa èèyàn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, yálà nígbà yẹn lọ́hùn-ún tàbí lóde òní. Ìdí kan ni pé àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá fi ẹ̀rí hàn pé Ẹlẹ́dàá wà. (Ka Róòmù 1:19, 20.) Èyí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nígbà tó kọ̀wé sí àwọn Hébérù láti Róòmù pé: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Héb. 3:4) Ọ̀nà tó gbà sọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó kọ́ ayé àtọ̀run tàbí tó mú kí ó wà.
14 Torí náà, orí ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà nígbà tó kọ̀wé sí àwọn ará Róòmù pé ‘kò sí àwíjàre kankan fún’ ẹnikẹ́ni, tó fi mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì, tó bá ń sin ère aláìlẹ́mìí. Ohun kan náà la lè sọ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún onírúurú ìwà ìṣekúṣe tí wọ́n sì yí ìlò ara wọn lọ́nà ti ẹ̀dá pa dà sí èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá. (Róòmù 1:22-27) Ó bá a mú nígbà náà pé Pọ́ọ̀lù sọ síwájú sí i pé “àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì ni gbogbo wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.”—Róòmù 3:9.
Ohun Tó Ń ‘Jẹ́ Wa Lẹ́rìí’
15. Kí ni gbogbo èèyàn ní, kí ló sì máa ń ṣe?
15 Ìwé Róòmù sọ ìdí mìíràn tí àwọn èèyàn fi gbọ́dọ̀ gbà pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì nílò ohun tó máa gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin ni a óò dá lẹ́jọ́ nípasẹ̀ òfin.” (Róòmù 2:12) Bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ṣàlàyé síwájú sí i pé àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà tí wọ́n kò mọ òfin Ọlọ́run sábà máa ń “ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá.” Kí ló fà á ti wọ́n fi ka ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, ìpànìyàn àti olè jíjà sí ohun tí kò dára? Pọ́ọ̀lù sọ pé ohun tó fà á ni pé: Wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn.—Ka Róòmù 2:14, 15.
16. Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹni tó ní ẹ̀rí ọkàn lè dẹ́ṣẹ̀?
16 Síbẹ̀, o ti lè wá rí i pé kéèyàn ní ẹ̀rí ọkàn tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọlọ́pàá inú tó ń jẹ́ ẹ lẹ́rìí, kò túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ á máa tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá sọ. A lè fi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe àríkọ́gbọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹ̀rí ọkàn, tó sì tún fún wọn ní òfin tó sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jalè, wọn kò sì gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn wọn àti ohun tí kò bá Òfin Jèhófà mu. (Róòmù 2:21-23) Wọ́n jẹ̀bi lọ́nà méjèèjì, ìyẹn sì fi hàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n ní tòótọ́, wọn kò dé ojú ìlà àwọn ìlànà Ọlọ́run wọn kò sì ṣe ohun tó fẹ́. Èyí ba àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn jẹ́.—Léf. 19:11; 20:10; Róòmù 3:20.
17. Kí ni ìwé Róòmù fi hàn pé Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún wa?
17 Àwọn ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú ìwé Róòmù lè dà bí àlàyé tó ń bani nínú jẹ́ nípa ipò tí aráyé àti àwa fúnra wa wà níwájú Olódùmarè. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ọ̀ràn náà síwájú sí i. Ó lo ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 32:1, 2 nígbà tó kọ̀wé sí àwọn ará Róòmù pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti dárí àwọn ìṣe àìlófin wọn jì, tí a sì ti bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀; aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kì yóò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí lọ́rùn lọ́nàkọnà.” (Róòmù 4:7, 8) Èyí fi hàn nígbà náà pé Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lọ́nà tó bá ìlànà òdodo rẹ̀ mu.
Ìhìn Rere Nípa Jésù
18, 19. (a) Ìhìn rere wo ni Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ nínú ìwé Róòmù? (b) Kí la gbọ́dọ̀ mọ̀ ká bàa lè jàǹfààní ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá?
18 Bó o ṣe ń ronú nípa ètò tí Ọlọ́run ṣe láti mú ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà yìí, ó ṣeé ṣe kó o sọ pé, “Ìhìn rere mà lèyí jẹ́ lóòótọ́ o!” Bó ṣe rí gan-an nìyẹn. Ó mú ká rántí ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù tẹ́nu mọ́ nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Róòmù. Bí a ṣe mẹ́nu kàn án tẹ́lẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà.”—Róòmù 1:15, 16.
19 Ìhìn rere yẹn dá lórí ipa tí Jésù máa kó nínú bí ète Ọlọ́run ṣe máa ní ìmúṣẹ. Pọ́ọ̀lù ń fojú sọ́nà fún “ọjọ́ tí Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù yóò ṣèdájọ́ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ aráyé, ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere.” (Róòmù 2:16) Ńṣe ni Pọ́ọ̀lù sọ èyí láti jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára ohun tí “ìjọba Kristi àti ti Ọlọ́run” máa ṣe tàbí ohun tí Ọlọ́run máa ṣe nípasẹ̀ Ìjọba náà. (Éfé. 5:5) Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ká tó lè gbé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ká sì gbádùn àwọn ìbùkún tó máa mú wá, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé (1) àìpé ti sọ wá di ẹlẹ́ṣẹ̀ lójú Ọlọ́run, ká sì mọ (2) ìdí tó fi pọn dandan pé ká ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà. Bí ẹnì kan bá lóye bí èyí ti ṣe pàtàkì tó nínú ìmúṣẹ ète Ọlọ́run, tó fara mọ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe, tó sì mọ ohun tóun máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú, ó lè bú sáyọ̀ pé, “Dájúdájú, ìhìn rere nìyẹn lóòótọ́!”
20, 21. Bá a ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ nínú ìwé Róòmù sọ́kàn, kí ló sì lè jẹ́ àbájáde rẹ̀?
20 Ó yẹ ká fi ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ yìí sọ́kàn bá a ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà nígbà tó sọ nípa Jésù pé: “Kò sí ẹni tí ó gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e tí a óò já kulẹ̀.” (Róòmù 10:11; Aísá. 28:16) Ọ̀rọ̀ nípa Jésù lè má ṣàjèjì sí àwọn tí wọ́n mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́, àwọn míì wà tí ọ̀rọ̀ Jésù máa jẹ́ tuntun létí wọn, á dà bíi pé wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀ rí tàbí kí wọ́n má tilẹ̀ gbà á gbọ́ nínú àṣà ìbílẹ̀ wọn. Bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá wá gba Ọlọ́run gbọ́ tí wọ́n sì ní ìgbọ́kànlé nínú Ìwé Mímọ́, ó máa gba pé ká ṣàlàyé ipa tí Jésù ń kó fún wọn. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bí Róòmù orí 5 ṣe ṣàlàyé ìhìn rere tó dá lórí Jésù yìí. Ó ṣeé ṣe kí ìjíròrò yẹn wúlò fún ẹ bó o bá ń wàásù.
21 Èrè púpọ̀ ló máa tìdí ẹ̀ wá bá a bá ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti lóye ìhìn rere tí ìwé Róòmù sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ nípa rẹ̀, ìyẹn ìhìn rere tó jẹ́ pé “ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́.” (Róòmù 1:16) Yàtọ̀ sí pé a máa rí èrè gbà, á tún máa rí i pé àwọn míì á gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà tí Pọ́ọ̀lù lò nínú Róòmù 10:15 pé: “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere mà dára rèǹtè-rente o!”—Aísá. 52:7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ A tún lè rí gbólóhùn yìí nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì.—Máàkù 1:1; Ìṣe 5:42; 1 Kọ́r. 9:12; Fílí. 1:27.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ìhìn rere wo ni ìwé Róòmù tẹnu mọ́?
• Kí ló yẹ ká jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀?
• Báwo ni “ìhìn rere nípa Kristi” ṣe lè mú kí àwa àti àwọn míì rí ìbùkún gbà?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
Ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ nínú ìwé Róòmù dá lórí ipa pàtàkì tí Jésù kó nínú ète Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Gbogbo wa la bí àléébù tó ń fa ikú mọ́, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀!