Ẹ Ran Àwọn Ọkùnrin Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí
Ẹ Ran Àwọn Ọkùnrin Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí
“Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.” —LÚÙKÙ 5:10.
1, 2. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn, tó fi mọ́ àwọn ọkùnrin, ṣe nígbà tí Jésù wàásù fún wọn? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
NÍGBÀ tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń wàásù jákèjádò ìlú Gálílì, wọ́n wọ ọkọ ojú omi kí wọ́n lè lọ sí ibi tí ó dá. Àmọ́, àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀ lé wọn. Àwọn tó wá lọ́jọ́ yẹn jẹ́ “nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké.” (Mát. 14:21) Ní àkókò míì, ogunlọ́gọ̀ èèyàn tọ Jésù wá, wọ́n fẹ́ kó mú àwọn lára dá, wọ́n sì tún fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lára wọn ni “ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké.” (Mát. 15:38) Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ ọkùnrin wà lára àwọn tó tọ Jésù wá tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Kódà, ó retí pé kí ọ̀pọ̀ àwọn míì tẹ́tí sí òun, torí pé lẹ́yìn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, èyí tó mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí ẹja tó pọ̀ kó, ó sọ fún wọn pé: “Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.” (Lúùkù 5:10) Jésù lo gbólóhùn yìí láti fi iṣẹ́ ìwàásù wọn wé iṣẹ́ ẹja pípa. Bó ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ọ̀pọ̀ ẹja, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ọ̀pọ̀ èèyàn, tó fi mọ́ àwọn ọkùnrin, tó máa tẹ́tí gbọ́ ìwàásù wọn.
2 Lónìí, àwọn ọkùnrin pẹ̀lú máa ń nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìwàásù wa wọ́n sì máa ń tẹ́tí gbọ́ wa. (Mát. 5:3) Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò tẹ̀ síwájú mọ́ nípa tẹ̀mí. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò dá iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan sílẹ̀ lákànṣe tá a fi lè máa wá àwọn ọkùnrin, ó dájú pé ó sọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ àwọn ọkùnrin ìgbà ayé rẹ̀. Bá a ti ń ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ fún wa, ẹ jẹ́ ká jíròrò nǹkan tá a lè ṣe nípa ohun mẹ́ta táwọn ọkùnrin sábà máa ń ṣàníyàn lé lórí lónìí: (1) àtijẹ àtimu, (2) ìbẹ̀rù torí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń rò àti (3) kéèyàn máa ronú pé òun kò tóótun.
Àtijẹ Àtimu
3, 4. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ ọkùnrin máa ń ṣàníyàn lé lórí jù lọ? (b) Kí nìdí tí àwọn ọkùnrin kan fi máa ń fi wíwá àtijẹ àtimu ṣáájú ìjọsìn Ọlọ́run?
3 Akọ̀wé kan sọ fún Jésù pé: “Olùkọ́ . . . èmi yóò tẹ̀ lé ọ lọ sí ibi yòówù tí ìwọ bá fẹ́ lọ.” Àmọ́, nígbà tí Jésù sọ fún un pé “Ọmọ ènìyàn kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé,” ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì, torí pé ó ṣeé ṣe kó ti máa ṣàníyàn nípa ohun tó máa jẹ àti ibi tí yóò máa gbé. Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé akọ̀wé náà di ọmọlẹ́yìn Kristi.—Mát. 8:19, 20.
4 Àwọn ọkùnrin sábà máa ń fi ọ̀ràn àtijẹ àtimu ṣáájú ìjọsìn Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń fi bí wọ́n ṣe máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga àti bí wọ́n ṣe máa rí iṣẹ́ olówó gọbọi sí ipò àkọ́kọ́. Èrò wọn ni pé kòṣeémáàní ni owó jẹ́, torí náà wọ́n gbà pé ó ṣàǹfààní káwọn yára wá a, ó sì bọ́gbọ́n mu ju àǹfààní èyíkéyìí táwọn lè rí nínú káwọn kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ káwọn sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ohun tí Bíbélì ń kọ́ni lè fà wọ́n lọ́kàn mọ́ra, àmọ́ “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè fún ìfẹ́ yòówù tí wọ́n ní sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa. (Máàkù 4:18, 19) Jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti fi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́.
5, 6. Kí ló ran Áńdérù, Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù lọ́wọ́ láti fi èyí tó yẹ sípò àkọ́kọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti wíwá jíjẹ mímu?
5 Iṣẹ́ ẹja pípa ni Áńdérù àti arákùnrin rẹ̀ Símónì Pétérù jọ ń ṣe. Iṣẹ́ yìí kan náà sì ni Jòhánù, arákùnrin rẹ̀ Jákọ́bù àti Sébédè tó jẹ́ bàbá wọn ń ṣe. Òwò wọn ń mówó wọlé gan-an débi pé wọ́n tún háyà àwọn ọkùnrin míì láti máa bá wọn ṣiṣẹ́. (Máàkù 1:16-20) Nígbà tí Jòhánù Olùbatisí kọ́kọ́ sọ fún Áńdérù àti Jòhánù nípa Jésù, ó dá wọn lójú pé wọ́n ti rí Mèsáyà. Áńdérù sọ ohun tó gbọ́ fún arákùnrin rẹ̀ Símónì Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kí Jòhánù náà sọ fún arákùnrin rẹ̀ Jákọ́bù. (Jòh. 1:29, 35-41) Ní oṣù tó tẹ̀ lé e, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà pẹ̀lú Jésù nígbà tó ń wàásù ní ìlú Gálílì, ní Jùdíà àti ní Samáríà. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà pa dà sídìí iṣẹ́ ẹja pípa. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí, àmọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà kọ́ ni ohun tó jẹ wọ́n lọ́kàn jù lọ.
6 Láìpẹ́ sígbà yẹn, Jésù ní kí Pétérù àti Áńdérù máa tọ òun lẹ́yìn òun á sì sọ wọ́n di “apẹja ènìyàn.” Kí làwọn méjèèjì ṣe? “Ní kíá, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé e.” Ohun tí Jákọ́bù àti Jòhánù náà ṣe nìyẹn. “Kíá, ní fífi ọkọ̀ ojú omi náà àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀ lé e.” (Mát. 4:18-22) Kí ló ran àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún? Ṣé wọ́n kàn ṣe ìpinnu náà láì ronú nípa rẹ̀ ni? Rárá o! Ní àwọn oṣù mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ọkùnrin náà ti tẹ́tí sí Jésù, wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe, wọ́n ti rí bó ṣe ní ìtara fún òdodo, wọ́n sì ti rí báwọn èèyàn ṣe nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù rẹ̀ lọ́nà tó kàmàmà. Nítorí ìyẹn, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n ní nínú rẹ̀ lágbára sí i!
7. Báwo la ṣe lè mú káwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà lè pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ bá nílò fún wọn?
7 Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tá a bá ń ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà? (Òwe 3:5, 6) Èyí sinmi púpọ̀ lórí ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ni. Tá a bá ń kọ́ni, a lè tẹnu mọ́ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa rọ̀jò ìbùkún sórí wa tá a bá fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba òun sípò àkọ́kọ́. (Ka Málákì 3:10; Mátíù 6:33.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè lo onírúurú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ láti tẹnu mọ́ bí Jèhófà ṣe ń pèsè fáwọn èèyàn rẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ gbójú fo bí àpẹẹrẹ tiwa ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá ń sọ àwọn ọ̀nà táwa fúnra wa ń gbà láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run fún àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. A tún lè sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tá a kà nínú àwọn ìwé wa fún wọn. *
8. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan láti ‘tọ́ ọ wò, kó sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere’? (b) Báwo la ṣe lè ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere?
8 Béèyàn bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó kọjá pé kéèyàn kà nípa báwọn míì ṣe jàǹfààní ìbùkún Jèhófà tàbí kó gbọ́ nípa rẹ̀. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ṣe òun lóore. Onísáàmù náà kọrin pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í.” (Sm. 34:8) Báwo la ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere? Ẹ jẹ́ ká sọ pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ní ìṣòro owó tún ń gbìyànjú láti borí àṣà búburú kan, irú bíi sìgá mímu, tẹ́tẹ́ títa, tàbí ọtí àmujù. (Òwe 23:20, 21; 2 Kọ́r. 7:1; 1 Tím. 6:10) Tá a bá kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà láti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ láti borí àṣà búburú kan, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní mú kó mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ olóore? Tún ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tá a bá gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́ nípa wíwá àkókò fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti mímúra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé ìjọ kó sì máa lọ sáwọn ìpàdé náà. Bí òun náà bá sì ṣe ń rí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bù kún àwọn ìsapá rẹ̀, ó dájú pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ á túbọ̀ máa lágbára!
Ìbẹ̀rù Torí Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ń Rò
9, 10. (a) Kí nìdí tí Nikodémù àti Jósẹ́fù ará Arimatíà kò fi fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù làwọn? (b) Lónìí, kí nìdí táwọn ọkùnrin kan kò fi fẹ́ láti máa tọ Kristi lẹ́yìn?
9 Àwọn ọkùnrin kan lè máà fẹ́ láti tọ Kristi lẹ́yìn ní kíkún torí pé wọ́n fẹ́ láti ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe. Nikodémù àti Jósẹ́fù ará Arimatíà kò fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù làwọn torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n torí ohun táwọn Júù míì máa sọ tàbí torí ohun tí wọ́n máa ṣe bí wọ́n bá mọ̀. (Jòh. 3:1, 2; 19:38) Kì í ṣe pé wọ́n kàn ń bẹ̀rù ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀ o. Ohun tó fà á ni pé ìkórìíra tí àwọn olórí ẹ̀sìn ní fún Jésù ti wá pọ̀ sí i débi pé bí ẹnikẹ́ni bá gba Jésù gbọ́ ńṣe ni wọ́n á lé onítọ̀hún kúrò nínú sínágọ́gù.—Jòh. 9:22.
10 Ní àwọn ibì kan lónìí, bí ọkùnrin kan bá ní ìfẹ́ tó pọ̀ fún Ọlọ́run, Bíbélì, tàbí ìsìn, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tàbí àwọn ìbátan rẹ̀ lè máa yọ ọ́ lẹ́nu. Ní àwọn ibòmíì, ó tiẹ̀ lè jẹ́ ohun tó léwu pàápàá láti sọ pé èèyàn fẹ́ yí ẹ̀sìn òun pa dà. Ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ láti ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe túbọ̀ lágbára gan-an lórí ẹni béèyàn bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ológun, nídìí òṣèlú, tàbí tó bá jẹ́ ẹni tó gbajúmọ̀ ní àdúgbò tó ń gbé. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin ará Jámánì kan sọ pé: “Òótọ́ ni ohun tí ẹ̀yìn Ẹlẹ́rìí ń wàásù pé Bíbélì fi kọ́ni. Àmọ́ bí mo bá di Ẹlẹ́rìí lónìí, gbogbo èèyàn á ti mọ̀ kílẹ̀ ọ̀la tó mọ́. Kí làwọn èèyàn á máa rò nípa mi níbi iṣẹ́, ládùúgbò àti nínú ẹgbẹ́ tí èmi àti ìdílé mi wà? Ẹ̀mí mi ò gbé e.”
11. Báwo ni Jésù ṣe ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ìbẹ̀rù èèyàn?
11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn àpọ́sítélì Jésù tó jẹ́ ojo, síbẹ̀ gbogbo wọn sapá kí wọ́n lè borí ìbẹ̀rù èèyàn. (Máàkù 14:50, 66-72) Kí ni Jésù ṣe láti mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dojú kọ àtakò tó pọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà wọn? Jésù mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀ de àwọn àtakò tí wọ́n máa dojú kọ. Ó sọ fún wọn pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín, àti nígbàkigbà tí wọ́n bá ta yín nù láwùjọ, tí wọ́n sì gàn yín, tí wọ́n sì ta orúkọ yín nù gẹ́gẹ́ bí ẹni burúkú nítorí Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 6:22) Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé àwọn èèyàn máa kẹ́gàn wọn. “Nítorí Ọmọ ènìyàn,” ni wọ́n á sì ṣe kẹ́gàn wọn. Jésù tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run máa tì wọ́n lẹ́yìn bí wọ́n bá ṣáà ti ń gbẹ́kẹ̀ lé E pé kó ran àwọn lọ́wọ́ kó sì fún àwọn lókun. (Lúùkù 12:4-12) Bákan náà, Jésù fẹ́ kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọlẹ́yìn dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kí wọ́n sì bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́.—Máàkù 10:29, 30.
12. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ìbẹ̀rù èèyàn?
12 Àwa náà gbọ́dọ̀ ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ìbẹ̀rù èèyàn. Ó sábà máa ń rọrùn jù láti kojú ìṣòro téèyàn bá wà ní ìmúrasílẹ̀ fún. (Jòh. 15:19) Bí àpẹẹrẹ, o kò ṣe ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti múra àwọn ẹsẹ Bíbélì tó rọrùn, tó sì bá onírúurú ipò mu sílẹ̀, èyí tó lè fi dáhùn ìbéèrè tí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn míì bá bi í tàbí èyí tó lè lò bí wọ́n bá ta ko ohun tó gbà gbọ́? Yàtọ̀ sí pé ká sọ ọ́ di ọ̀rẹ́ wa, a tún lè fojú rẹ̀ mọ àwọn míì tá a jọ wà nínú ìjọ, pàápàá jù lọ àwọn tí ipò wọn jọra pẹ̀lú tirẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a gbọ́dọ̀ kọ́ ọ pé kó máa gbàdúrà déédéé látọkànwá. Èyí lè ràn án lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run kó sì fi Jèhófà ṣe Ibi ìsádi àti Àpáta rẹ̀.—Ka Sáàmù 94:21-23; Jákọ́bù 4:8.
Kéèyàn Máa Ronú Pé Òun Kò Tóótun
13. Béèyàn bá ń ronú pé òun kò tóótun, báwo nìyẹn ṣe lè mú kó máà fà sẹ́yìn láti lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run?
13 Àwọn ọkùnrin kan máa ń fà sẹ́yìn láti lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run torí pé wọn kò mọ̀wé kà dáadáa tàbí nítorí pé wọn kò lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó já gaara tàbí nítorí pé wọ́n máa ń tijú. Àwọn ọkùnrin kan kì í fẹ́ láti sọ èrò wọn tàbí bí nǹkan ṣe rí lára wọn ní gbangba. Ó ti lè pọ̀ jù fún irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ láti máa ronú nípa kíkẹ́kọ̀ọ́, dídáhùn láwọn ìpàdé ìjọ, tàbí wíwàásù ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì. Arákùnrin kan sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, mo máa ń yara lọ sẹ́nu ilẹ̀kùn, màá ṣe bí ẹní ń tẹ aago tó wà níbẹ̀, màá sì rọra fi ibẹ̀ sílẹ̀, nírètí pé kò sẹ́ni tó máa gbọ́ mi tàbí tó máa rí mi. . . . Àìsàn ni lílọ láti ilé dé ilé máa ń dá sí mi lára.”
14. Kí ló fà á táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò fi lè mú ọmọkùnrin kan tó ní ẹ̀mí èṣù lára dá?
14 Ronú nípa bó ṣe máa rí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà tí wọn kò lè mú ọmọkùnrin kan tó ní ẹ̀mí èṣù lára dá. Bàbá ọmọ náà wá sọ́dọ̀ Jésù ó sì sọ pé: “[Ọmọ mi] jẹ́ alárùn wárápá, ó sì ń ṣàmódi, nítorí ó máa ń ṣubú sínú iná ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti sínú omi ní ọ̀pọ̀ ìgbà; mo sì mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.” Jésù lé ẹ̀mí èṣù tó wà lára ọmọkùnrin náà kúrò ó sì mú un lára dá. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jésù wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwa kò lè lé e jáde?” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Nítorí ìgbàgbọ́ yín tí ó kéré ni. Nítorí lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró músítádì, ẹ ó sọ fún òkè ńlá yìí pé, ‘Ṣípò kúrò ní ìhín lọ sí ọ̀hún,’ yóò sì ṣípò, kò sì sí ohunkóhun tí kì yóò ṣeé ṣe fún yín.” (Mát. 17:14-20) Ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà ṣe pàtàkì kéèyàn tó lè borí àwọn ìṣòro tó ga bí òkè. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ téèyàn bá gbàgbé bí ìgbàgbọ́ ti ṣe pàtàkì tó, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbára lé agbára tirẹ̀? Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí, ìyẹn á sì mú kó máa ronú pé òun kò tóótun láti sin Jèhófà.
15, 16. Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ń ronú pé òun kò tóótun, báwo la ṣe lè mú kó borí irú èrò bẹ́ẹ̀?
15 Ọ̀nà kan tó dára tá a lè gbà ran ẹnì kan tó ronú pé òun kò tóótun lọ́wọ́ láti borí èrò náà ni pé ká gbà á níyànjú pé kó máa ronú nípa Jèhófà dípò tí yóò fi máa ronú nípa ara rẹ̀. Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e.” (1 Pét. 5:6, 7) Èyí béèrè pé ká ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ pé kí wọ́n ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹni tó bá fẹ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run máa ń fọwọ́ tó ṣe pàtàkì gan-an mú àwọn nǹkan tó bá jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Ó máa ń nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì máa fi “èso ti ẹ̀mí” ṣèwà hù nínú ìgbésí ayé rẹ̀. (Gál. 5:22, 23) Ó máa ń fọwọ́ pàtàkì mú àdúrà. (Fílí. 4:6, 7) Ó sì tún máa ń gbára lé Ọlọ́run pé ó máa fún òun ní ìgboyà àti agbára tí òun bá nílò láti kojú ipò èyíkéyìí tàbí láti ṣe ojúṣe èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé lé òun lọ́wọ́ láṣeyọrí.—Ka 2 Tímótì 1:7, 8.
16 A tún lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́wọ́ kí bí wọ́n ṣe ń kàwé, bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀, tàbí bí wọ́n ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ lè sunwọ̀n sí i. Àwọn míì lè rò pé àwọn kò tóótun láti sin Ọlọ́run nítorí àwọn ìwà burúkú tí wọ́n ti hù kí wọ́n tó mọ Jèhófà. A lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́wọ́ nípa fífi ìfẹ́ hàn sí wọn ká sì fi sùúrù bá wọn lò. Jésù sọ pé: “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.”—Mát. 9:12.
Ẹ Ran Àwọn Ọkùnrin Púpọ̀ sí I Lọ́wọ́ Láti Sin Jèhófà
17, 18. (a) Báwo la ṣe lè bá àwọn ọkùnrin púpọ̀ sí i sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Inú Bíbélì nìkan la ti lè rí ìhìn rere tó ń fọkàn ẹni balẹ̀ gan-an, ó sì wù wá pé kí àwọn ọkùnrin púpọ̀ sí i gbọ́ ìhìn rere náà. (2 Tím. 3:16, 17) Torí náà, báwo la ṣe lè bá àwọn ọkùnrin púpọ̀ sí i sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? A lè ṣe èyí nípa lílo àkókò púpọ̀ sí i láti wàásù fáwọn èèyàn ní ìrọ̀lẹ́, ní ọ̀sán láwọn òpin ọ̀sẹ̀, tàbí nígbà ìsinmi tá a lè bá ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin nílé. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe a lè ní kí wọ́n jẹ́ ká bá ẹni tó jẹ́ baálé ilé sọ̀rọ̀. Bá ò tiẹ̀ sí lóde ẹ̀rí, ẹ jẹ́ ká wàásù fáwọn alábàáṣiṣẹ́ wa tó jẹ́ ọkùnrin nígbà tó bá bójú mu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àwọn arábìnrin tí ọkọ wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ bá sì wà nínú ìjọ, a lè wàásù fáwọn ọkọ wọn.
18 Bá a ti ń wàásù fún olúkúlùkù ẹni tá à ń bá pàdé, ó lè dá wa lójú pé àwọn tó mọrírì iṣẹ́ ìwàásù wa máa tẹ́tí gbọ́ wa. Ẹ jẹ́ ká fi sùúrù ran gbogbo àwọn tó bá ní ìfẹ́ àtọkànwá sí òtítọ́ lọ́wọ́. Àmọ́, báwo la ṣe lè ran àwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi lọ́wọ́ kí wọ́n lè sapá láti tóótun fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ Ọlọ́run? A máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Wo àwọn ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook of Jehovah’s Witnesses àti àwọn ìtàn ìgbésí ayé tá à ń gbé jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo la ṣe lè ran àwọn ọkùnrin lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ìjọsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́?
• Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa fẹ́ láti máa ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe?
• Bí ẹnì kan bá ń ronú pé òun kò tóótun, báwo la ṣe lè mú kó borí irú èrò bẹ́ẹ̀?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ṣé o máa ń wá bó o ṣe lè wàásù ìhìn rere fáwọn ọkùnrin?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Báwo lo ṣe lè múra àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀ láti kojú àwọn àdánwò?