Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Gbádùn Mọ́ Ẹ Kó sì Ṣe Ẹ́ Láǹfààní
Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Gbádùn Mọ́ Ẹ Kó sì Ṣe Ẹ́ Láǹfààní
Báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè túbọ̀ gbádùn mọ́ wa? Báwo la ṣe lè túbọ̀ jàǹfààní tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́? Ní ṣókí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun pàtàkì mẹ́ta tó lè mú ká jàǹfààní tó pọ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
1 GBÀDÚRÀ: Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o gbàdúrà. (Sm. 42:8) Kí nìdí? Ìdí ni pé apá kan ìjọsìn wa ló yẹ ká máa ka kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí. Torí náà, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ohun tá à ń kà máa wọ̀ wá lọ́kàn, kó sì fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Barbara, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì sọ pé: “Mi ò lè ṣe kí n má gbàdúrà kí n tó ka Bíbélì tàbí kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú mi àti pé ó fara mọ́ ohun tí mò ń ṣe.” Béèyàn bá gbàdúrà kó tó kẹ́kọ̀ọ́, ó máa lóye ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tó fẹ́ jẹ, ohun tó kọ́ á sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn.
2 ṢE ÀṢÀRÒ: Nítorí pé àwọn kan ò ráyè, ńṣe ni wọ́n máa ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóréfèé. Àmọ́, wọ́n máa ń pàdánù àǹfààní tí wọ́n lè rí látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ti lé ní àádọ́ta [50] ọdún tí Carlos ti ń sin Jèhófà, ó ti wá rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kóun máa ya àkókò sọ́tọ̀ láti ṣe àṣàrò kí ẹ̀kọ́ tóun ń kọ́ lè túbọ̀ máa ṣe òun láǹfààní. Ó sọ pé: “Bí mo bá ń ka Bíbélì, mi ò ka ojú ìwé tó pọ̀ tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́, nǹkan bí ojú ìwé méjì ni mò ń kà lójoojúmọ́. Èyí ń mú kí n túbọ̀ ṣe àṣàrò lórí ohun tí mo bá kà, kí n lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì.” (Sm. 77:12) Tá a bá ń wáyè láti ṣe àṣàrò, ìmọ̀ wa máa pọ̀ sí i a ó sì túbọ̀ lóye ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run.—Kól. 1:9-11.
3 FI SÍLÒ: Bí a bá rí ìwúlò ohun kan tá à ń ṣe, ìyẹn á mú ká túbọ̀ máa jàǹfààní látinú rẹ̀. Bí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe rí gan-an nìyẹn. Gabriel, arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́, tó sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, sọ pé: “Ìkẹ́kọ̀ọ́ ń ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tí mò ń bá pàdé lójoojúmọ́, ó sì ń jẹ́ kí n mọ bí màá ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Mo máa ń gbìyànjú láti fi gbogbo ohun tí mò ń kọ́ sílò nínú ìgbésí ayé mi.” (Diu. 11:18; Jóṣ. 1:8) Ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì tún lè fi sílò.—Òwe 2:1-5.
ÀTÚNYẸ̀WÒ: Ẹ wo bí àǹfààní tá a ní láti walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà, tó jẹ́ Orísun ọgbọ́n gbogbo ti pọ̀ tó! (Róòmù 11:33) Torí náà, nígbà tó o bá tún fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́, rí i dájú pé o kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ kà wọ̀ ẹ́ lọ́kàn kó sì fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, máa dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti ṣe àṣàrò lórí ohun tó o kà. Bákan náà, ṣiṣẹ́ lórí ohun tó o kọ́, kó o sì máa fi sílò nínú ìgbésí ayé rẹ. Bó o bá ṣe àwọn ohun pàtàkì wọ̀nyí, wà á rí i pé ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì á gbádùn mọ́ ẹ á sì ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an.