Nátánì—Adúróṣinṣin Tó Gbé Ìjọsìn Mímọ́ Lárugẹ
Nátánì—Adúróṣinṣin Tó Gbé Ìjọsìn Mímọ́ Lárugẹ
Kò rọrùn láti mú kí ọkùnrin alágbára kan gbà pé òun ti hùwà ìbàjẹ́ àti pé ó yẹ kí òun ṣàtúnṣe. Ṣé wàá kojú irú ẹni bẹ́ẹ̀ tó o bá mọ̀ pé ó ti pa ọkùnrin kan torí kí àṣírí rẹ̀ má bàa tú?
Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ó sì lóyún. Kí Dáfídì bàa lè bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó mú kí wọ́n pa ọkọ Bátí-ṣébà, lẹ́yìn náà ló wá sọ ọ́ di aya. Ọ̀pọ̀ oṣù ti kọjá lẹ́yìn tí Dáfídì ti ṣe àṣemáṣe yìí, kò sì sí àní-àní pé ó ń bá a nìṣó láti máa ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Àmọ́, Jèhófà kò ṣaláì jẹ́ kí ọba dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá náà. Ó rán Nátánì wòlíì rẹ̀ sí Dáfídì láti lọ sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un.
Iṣẹ́ tó nira lèyí. Bó o bá fi ara rẹ sí ipò Nátánì, wàá rí i pé ohun tó mú kó rán Dáfídì létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni pé ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó sì rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà rẹ̀. Báwo ni wòlíì náà ṣe máa ṣe é, táá sì mú kí Dáfídì Ọba gbà pé ó yẹ kí òun ronú pìwà dà?
OLÙKỌ́ TÓ GBỌ́N
O ò ṣe wá ìṣẹ́jú díẹ̀ láti ka ohun tó wà nínú 2 Sámúẹ́lì 12:1-25? Jẹ́ ká sọ pé ìwọ lo dúró síwájú Dáfídì dípò Nátánì, tó o sì ń sọ ìtàn yìí fún un pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú ńlá kan, ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ aláìnílọ́wọ́. Ó ṣẹlẹ̀ pé ọlọ́rọ̀ náà ní àgùntàn àti màlúù púpọ̀ gan-an; ṣùgbọ́n ọkùnrin aláìnílọ́wọ́ náà kò ní nǹkan kan bí kò ṣe abo ọ̀dọ́ àgùntàn kan, èyí kékeré kan, tí ó rà. Ó sì ń pa á mọ́ láàyè, ó sì ń dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, gbogbo wọn lápapọ̀. Ara òkèlè rẹ̀ ni ó ti ń jẹ, inú ife rẹ̀ sì ni ó ti ń mu, oókan àyà rẹ̀ sì ni ó máa ń dùbúlẹ̀ sí, ó sì wá dà bí ọmọbìnrin fún un. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, àlejò kan tọ ọlọ́rọ̀ náà wá, ṣùgbọ́n ó fà sẹ́yìn kúrò ní mímú lára àgùntàn tirẹ̀ àti màlúù tirẹ̀ láti pèsè rẹ̀ fún arìnrìn-àjò tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá. Nítorí náà, ó mú abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọkùnrin aláìnílọ́wọ́ náà, ó sì pèsè rẹ̀ fún ọkùnrin tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá.”—2 Sám. 12:1-4.
Olùṣọ́ àgùntàn ni Dáfídì fúnra rẹ̀ torí náà ó ti ní láti gbà pé bí ọ̀ràn náà ṣe rí gan-an ni Nátánì ṣe ròyìn rẹ̀. Ẹnì kan tó máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé: “Nátánì ti máa ń lọ sọ́dọ̀ Dáfídì láti gbẹnu sọ fún àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́ tí wọ́n fi ọwọ́ ọlá gbá lójú. Torí náà, Dáfídì rò pé irú ohun tó tún wá ṣe nìyẹn.” Ká tiẹ̀ sọ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ó gba kí Nátánì jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run kó sì ní ìgboyà kó tó lè sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọba. Ìtàn tí Nátánì sọ yìí mú kí ìbínú Dáfídì ru. Ó kígbe pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, ikú tọ́ sí ọkùnrin tí ó ṣe èyí!” Lẹ́yìn náà ni Nátánì sọ ohun tó mú kí ara rẹ̀ rọ̀ wọ̀ọ̀, ó ní: “Ìwọ fúnra rẹ ni ọkùnrin náà!”—2 Sám. 12:5-7.
Ronú nípa ìdí tí Nátánì fi bojú tó ọ̀ràn náà lọ́nà yẹn. Kò rọrùn fún ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan láti fi ojú tó tọ́ wo ọ̀ràn ẹni náà láì gbè sẹ́yìn rẹ̀. Gbogbo wa la máa ń ṣe àwáwí ká lè dá ara wa láre tá a bá ṣe ohun kan tó kù-díẹ̀-káà-tó. Àmọ́, àpèjúwe tí Nátánì ṣe mú kí Dáfídì dá ara rẹ̀ lẹ́bi láìmọ̀. Ọba rí i kedere pé ìwà tí Nátánì sọ pé onítọ̀hún hù burú jáì. Àmọ́, lẹ́yìn tí Dáfídì ti fi ẹnu ara rẹ̀ dá ìwà náà lẹ́bi ni Nátánì tó sọ pé ọba ni ẹni náà. Ìgbà yẹn ni Dáfídì tó rí bí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá ṣe burú tó. Èyí sì wá mú kó ṣeé ṣe fún un láti gba ìbáwí. Ó gbà pé òótọ́ ni panṣágà tóun ṣe pẹ̀lú Bátí-ṣébà ti mú kóun “tẹ́ńbẹ́lú” Jèhófà, ó sì fara mọ́ ìbáwí tí Nátánì fún un nítorí ohun tó ṣe.—2 Sám. 12:9-14; Sm. 51, àkọlé.
Kí la lè rí kọ́ nínú èyí? Àfojúsùn ẹni tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé kó ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́. Nátánì bọ̀wọ̀ fún Dáfídì, torí náà ó fọgbọ́n bá a sọ̀rọ̀. Nátánì mọ̀ pé Dáfídì nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Torí náà, ó lo àpèjúwe tó máa mú kí Dáfídì fẹ́ láti lo àwọn ànímọ́ náà. Àwa pẹ̀lú lè ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan. Lọ́nà wo? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá jẹ́ kí àwọn fúnra wọn ṣe ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó tọ́ tá ò sì mú kí wọ́n rò pé a sàn jù wọ́n lọ tàbí pé ẹ̀tọ́ wa ni láti sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe fún wọn. Ó ṣe tán, kì í ṣe ohun tó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́ lójú tiwa ló ṣe pàtàkì bí kò ṣe ohun tí Bíbélì bá sọ fún wa.
Nátánì jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, ìyẹn sì ni olórí ohun tó mú kó lè bá ọba alágbára náà wí. (2 Sám. 12:1) Bí àwa náà bá jẹ́ adúróṣinṣin bíi tirẹ̀, a máa ní ìgboyà láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà tímọ́tímọ́.
Ó GBÉ ÌJỌSÌN MÍMỌ́ LÁRUGẸ
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rẹ́ àtàtà ni Dáfídì àti Nátánì torí pé Dáfídì sọ ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ ní Nátánì. (1 Kíró. 3:1, 5) Nígbà tí orúkọ Nátánì kọ́kọ́ fara hàn nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì, òun àti Dáfídì jọ wà pa pọ̀ ni. Àwọn méjèèjì ló nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kò sì sí iyè méjì pé ọba máa ń ka ọ̀rọ̀ Nátánì kún, torí pé ó sọ fún wòlíì náà pé ó wu òun láti kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún Jèhófà. Dáfídì sọ pé: “‘Kíyè sí i, nísinsìnyí, èmi ń gbé inú ilé kédárì nígbà tí àpótí Ọlọ́run tòótọ́ ń gbé ní àárín àwọn aṣọ àgọ́.’ Látàrí èyí, Nátánì sọ fún ọba pé: ‘Ohun gbogbo tí ó bá wà ní ọkàn-àyà rẹ—lọ ṣe é, nítorí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.’”—2 Sám. 7:2, 3.
Nígbà tí Dáfídì sọ fún Nátánì pé òun fẹ́ láti kọ́ ibùdó ìjọsìn mímọ́ tó máa jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé fún Jèhófà, tọkàntọkàn ni Nátánì tó ń fi òótọ́ sin Jèhófà fi fọwọ́ sí ìwéwèé rẹ̀ yìí. Àmọ́, èrò tó wà lọ́kàn Nátánì ló sọ fún Dáfídì kì í ṣe ti Jèhófà. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, Ọlọ́run fi ohun tó yàtọ̀ síyẹn rán wòlíì yìí sí ọba: Kì í ṣe Dáfídì ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Dáfídì ló máa kọ́ ọ. Àmọ́, Nátánì kéde pé Ọlọ́run máa bá Dáfídì dá májẹ̀mú kí ìtẹ́ rẹ̀ bàa lè “fìdí . . . múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—2 Sám. 7:4-16.
Ohun tí Nátánì ní lọ́kàn nípa ẹni tó máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà kò bá ìfẹ́ inú Ọlọ́run mu. Àmọ́, torí pé wòlíì yìí jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kò ráhùn rárá, ńṣe ló fara mọ́ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà ó sì kọ́wọ́ tì í. Àpẹẹrẹ rere láti tẹ̀ lé ni èyí bó bá ṣẹlẹ̀ pé Ọlọ́run bá wa wí ní ọ̀nà èyíkéyìí! Àwọn nǹkan tí Nátánì gbé 1 Kíró. 23:1-5; 2 Kíró. 29:25.
ṣe lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì fi hàn pé kò pàdánù ojú rere Ọlọ́run. Kódà, ó jọ pé Jèhófà mí sí Nátánì àti Gádì tó jẹ́ olùríran láti darí Dáfídì pé kó ṣètò ẹgbàajì [4,000] akọrin fún iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì.—KÒ JẸ́ KÍ IPÒ ỌBA BỌ́ SỌ́WỌ́ ẸLÒMÍÌ
Nátánì mọ̀ pé Sólómọ́nì ló máa jọba lẹ́yìn Dáfídì tó ti darúgbó. Torí náà, Nátánì gbé ìgbésẹ̀ ní kíá nígbà tí Ádóníjà fẹ́ láti fipá gbàjọba lọ́wọ́ Dáfídì tó ti darúgbó. Lọ́tẹ̀ yìí, Nátánì tún jẹ́ adúróṣinṣin ó sì fi ọgbọ́n hàn. Lákọ̀ọ́kọ́, ó rọ Bátí-ṣébà láti rán Dáfídì létí ìbúra rẹ̀ pé òun máa sọ Sólómọ́nì ọmọ wọn di ọba. Lẹ́yìn náà, Nátánì fúnra rẹ̀ gba ọ̀dọ̀ ọba lọ láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá òun ló fún Ádóníjà láṣẹ láti gorí ìtẹ́. Lẹ́yìn tí Dáfídì tó ti darúgbó rí bí ọ̀ràn náà ṣe wúwo tó, ó pàṣẹ fún Nátánì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ míì tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin pé kí wọ́n fòróró yan Sólómọ́nì kí wọ́n sì kéde pé òun ni ọba. Bí ìpètepèrò Ádóníjà láti fipá gbàjọba ṣe forí ṣánpọ́n nìyẹn.—1 Ọba 1:5-53.
ÒPÌTÀN TÍ KÌ Í ṢE JU ARA RẸ̀ LỌ
Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé Nátánì àti Gádì ló kọ ìwé 1 Sámúẹ́lì orí 25 sí 31 àti 2 Sámúẹ́lì lódindi. A kà nípa àwọn ìtàn tí Ọlọ́run mí sí wọn láti kọ sínú àwọn ìwé yìí pé: “Ní ti àwọn àlámọ̀rí Dáfídì Ọba, àwọn ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn, ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú àwọn ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì aríran àti nínú àwọn ọ̀rọ̀ Nátánì wòlíì àti nínú àwọn ọ̀rọ̀ Gádì olùríran.” (1 Kíró. 29:29) Àkọsílẹ̀ kan tún wà nípa àwọn “àlámọ̀rí Sólómọ́nì,” èyí tí Bíbélì sọ pé Nátánì wà lára àwọn tó kọ ọ́. (2 Kíró. 9:29) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Nátánì ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba, kódà lẹ́yìn ikú Dáfídì.
Ó lè jẹ́ pé Nátánì fúnra rẹ̀ ló kọ ọ̀pọ̀ ohun tá a mọ̀ nípa rẹ̀. Bí kò sì ṣe pariwo ara rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ kan tó sọ tún jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa irú ẹni tó jẹ́. Ó dájú pé òpìtàn tí kì í ṣe ju ara rẹ̀ lọ ni Nátánì. Kò wá bó ṣe máa ṣe orúkọ ńlá fún ara rẹ̀. Ìwé kan tó ń sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tiẹ̀ sọ pé, àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí kò sọ “ohunkóhun fún wa nípa rẹ̀ àti ìdílé tó ti wá.” A kò mọ ohunkóhun nípa orírun Nátánì tàbí ìgbésí ayé rẹ̀.
Ó JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN SÍ JÈHÓFÀ
Látinú àwọn ohun díẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ ti jẹ́ ká mọ̀ nípa Nátánì, ó ṣe kedere pé ó níwà ìrẹ̀lẹ̀ àmọ́ ó fi ìtara gbé àwọn ìṣètò Ọlọ́run lárugẹ. Iṣẹ́ ńlá ni Jèhófà Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. Nátánì jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, ó sì ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń fẹ́. Ṣe àṣàrò lórí àwọn ànímọ́ rẹ̀, kó o sì sapá láti máa fi wọ́n ṣèwà hù.
Ọlọ́run lè má sọ pé kó o lọ bá àwọn ọba tó ṣe panṣágà wí tàbí kó o lọ sọ èrò àwọn tó fẹ́ fipá gbàjọba di asán. Àmọ́, ìrànlọ́wọ́ tí Ọlọ́run ń pèsè lè mú kó o jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run kó o sì máa gbé àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ lárugẹ. O tún lè máa fi ìgboyà àti ọgbọ́n kọ́ni ní òtítọ́, kó o sì tún máa gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Torí pé Nátánì kò fẹ́ kí ipò ọba bọ́ sọ́wọ́ ẹlòmíì, ó fọgbọ́n bá Bátí-ṣébà sọ̀rọ̀