Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ wíwò tí Kristẹni kan ń wo ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe lè burú gan-an débi tí wọ́n fi lè yọ ọ́ lẹ́gbẹ́?
▪ Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè burú débẹ̀. Ìyẹn sì jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sá jìnnà sí gbogbo ohun tó lè mú kí ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, yálà wọ́n kọ ọ́ sílẹ̀ tàbí wọ́n gbé e jáde nínú ìwé ìròyìn, fíìmù, fídíò àti lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
Àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe wà káàkiri ibi gbogbo lágbàáyé. Àwọn tó ń lọ́wọ́ sí àṣà tó ń ṣèpalára yìí sì ti pọ̀ sí i torí pé Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kí àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe wà lárọ̀ọ́wọ́tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àwọn kan tiẹ̀ ti ṣàdédé bá ara wọn lórí irú àwọn ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì bẹ́ẹ̀, yálà wọ́n jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà. Àwọn kan sì máa ń mọ̀ọ́mọ̀ lọ sórí àwọn ìkànnì náà láìmikàn, torí pé yálà wọ́n wà nínú ilé tàbí ọ́fíìsì, wọ́n lè ka àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe tàbí kí wọ́n wò ó láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni rí wọn. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn Kristẹni ka èyí sí ọ̀ràn pàtàkì?
A rí ìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì nínú ìkìlọ̀ Jésù. Ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mát. 5:28) Òótọ́ ni pé kò sí ohun tó burú nínú kí tọkọtaya bá ara wọn lò pọ̀, ó sì máa ń mú kí wọ́n gbádùn ara wọn. (Òwe 5:15-19; 1 Kọ́r. 7:2-5) Àmọ́, ohun tí àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe wà fún kọ́ nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń ṣe àgbéyọ ìbálópọ̀ tí kò tọ́ èyí tó ń gbé irú èròkérò tí Jésù kìlọ̀ nípa rẹ̀ wá síni lọ́kàn. Ó dájú nígbà náà pé kíka àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe àti wíwò wọ́n, kò bá ìtọ́ni Ọlọ́run mu. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.”—Kól. 3:5.
Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì péré ni Kristẹni kan wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe ńkọ́? A lè fi ọ̀rọ̀ irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ wé ipò eléwu tí onísáàmù náà Ásáfù bá ara rẹ̀ nígbà kan. Ó ní: “Ní tèmi, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lọ́nà, díẹ̀ ló kù kí a mú ìṣísẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́.” Báwo ni irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ ṣe lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ kó sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run bó bá ń wo àwòrán àwọn ọkùnrin tàbí àwọn obìnrin tí wọ́n wà ní ìhòòhò tàbí ọkùnrin àti obìnrin tó ń bára wọn lò pọ̀? Bíi ti Ásáfù, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ní: “Ìyọnu sì ń bá mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, mo sì ń gba ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ní òròòwúrọ̀.”—Sm. 73:2, 14.
Kristẹni kan tó ń hu ìwà burúkú gbọ́dọ̀ pe orí ara rẹ̀ wálé, kó sì wá ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ó lè rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gbà nínú ìjọ. Bíbélì sọ pé: “Bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù, bí olúkúlùkù yín ti ń ṣọ́ ara rẹ̀ lójú méjèèjì.” (Gál. 6:1) Alàgbà kan tàbí méjì lè ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n ‘gbàdúrà ìgbàgbọ́ tó lè mú aláàárẹ̀ náà lára dá, a óò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í.’ (Ják. 5:13-15) Àwọn tó ti wá ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n lè jáwọ́ nínú ìwà èérí yìí ti rí i pé sísún mọ́ Ọlọ́run ti dára fún wọn, bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Ásáfù.—Sm. 73:28.
Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn kan tó ti dẹ́ṣẹ̀ kò ronú pìwà dà “ìwà àìmọ́ àti àgbèrè àti ìwà àìníjàánu wọn.” * (2 Kọ́r. 12:21) Nínú àlàyé tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Marvin R. Vincent ṣe nípa ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn pè ní “ìwà àìmọ́,” ó sọ pé ó “ní í ṣe pẹ̀lú ìwà èérí tó burú bògìrì.” Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọ̀ràn kan tó jẹ mọ́ wíwo àwòrán tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe burú jáì ju kéèyàn máa wo ẹni tó wà ní ìhòòhò tàbí ọkùnrin àti obìnrin tó ń bára wọn lò pọ̀. Àwọn kan wà tó burú bògìrì, tó ń kóni nírìíra, èyí tó jẹ mọ́ kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lò pọ̀, kí àwùjọ àwọn èèyàn jùmọ̀ máa bára wọn lò pọ̀, kí èèyàn máa bá ẹranko lò pọ̀, kí wọ́n máa fi ìhòòhò àwọn ọmọdé hàn, kí àwọn ọmọọ̀ta máa fipá bá ẹnì kan ṣoṣo lò pọ̀, kí wọ́n máa han àwọn obìnrin léèmọ̀, kí wọ́n de èèyàn mọ́lẹ̀ láti bá a lò pọ̀ tàbí kí wọ́n fi ọ̀dájú dáni lóró. Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn kan tí wọ́n “wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí” ti wá “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere, wọ́n [sì] fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.”—Éfé. 4:18, 19.
Pọ́ọ̀lù tún mẹ́nu kan “ìwà àìmọ́” nínú Gálátíà 5:19. Ọ̀mọ̀wé kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé Gálátíà “ní pàtàkì jù lọ lè mú kó [dúró] fún onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí kò bá ìwà ẹ̀dá mu.” Kristẹni wo ló jẹ́ sọ pé irú àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, tó ń kóni nírìíra, tó sì ń fi ìbálòpọ̀ hàn lọ́nà òdì, èyí tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí kì í ṣe “onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí kò bá ìwà ẹ̀dá mu” àti èyí tó burú bògìrì? Ibi tí Pọ́ọ̀lù parí ọ̀rọ̀ náà sí nínú Gálátíà 5:19-21 ni pé “àwọn tí ń fi irúfẹ́ [ìwà àìmọ́ bẹ́ẹ̀] ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” Torí náà, bó bá ti di bárakú fún ẹnì kan láti máa wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, èyí tó ń kóni nírìíra, tó sì ń fi ìbálòpọ̀ hàn lọ́nà òdì, tó sì ṣeé ṣe kó ti máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún àkókò gígùn, tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ronú pìwà dà, tí kó sì yí pa dà, kò ní lè máa bá a nìṣó láti wà nínú ìjọ Ọlọ́run. A ní láti yọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́gbẹ́ ká lè dáàbò bo ìjọ, kí ìjọ lè máa wà ní mímọ́.—1 Kọ́r. 5:5, 11.
Inú wá dùn láti mọ̀ pé àwọn kan tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, èyí tí ń kóni nírìíra, ti tọ àwọn alàgbà lọ wọ́n sì ti rí ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí wọ́n nílò kí wọ́n lè ṣe ìyípadà pátápátá. Jésù gba àwọn kan ní ìjọ Sádísì ìgbàanì níyànjú, ó ní: “Kí o sì fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́ kù tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú lókun, . . . máa bá a lọ ní fífi bí o ṣe gbà àti bí o ṣe gbọ́ sọ́kàn, sì máa bá a lọ ní pípa á mọ́, kí o sì ronú pìwà dà. Dájúdájú, láìjẹ́ pé o jí, . . . ìwọ kì yóò sì mọ̀ rárá ní ti wákàtí tí èmi yóò dé bá ọ.” (Ìṣí. 3:2, 3) Ó ṣeé ṣe láti ronú pìwà dà, kéèyàn sì di ẹni tá a já gbà, bí ẹni pé kúrò nínú iná.—Júúdà 22, 23.
Àmọ́, ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí olúkúlùkù wa ṣe ìpinnu tó fìdí múlẹ̀ pé a kò ní sún mọ́ bèbè ewu yẹn. Bẹ́ẹ̀ ni, a gbọ́dọ̀ pinnu pé a máa sá fún gbogbo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Ní ti ìyàtọ̀ tó wà láàárín “ìwà àìmọ́ àti àgbèrè àti ìwà àìníjàánu,” wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 2006, ojú ìwé 29 sí 31.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]
Kristẹni kan tó ń hu ìwà burúkú gbọ́dọ̀ pe orí ara rẹ̀ wálé, kó sì wá ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí