“Jọ̀wọ́, Ṣé O Lè Yà Wá Ní Fọ́tò?”
“Jọ̀wọ́, Ṣé O Lè Yà Wá Ní Fọ́tò?”
Ní ìparí ọjọ́ kejì àpéjọ àgbègbè kan, Josué, tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, lọ sí àárín ìgboro ìlú Querétaro, kó lè mọ ìlú lọ. Tọkọtaya arìnrìn-àjò afẹ́ kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kòlóńbíà, Javier àti Maru, ní kí Josué ya àwọn ní fọ́tò. Torí pé Josué àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí múra dáadáa tí báàjì àpéjọ àgbègbè sì wà láyà wọn, tọkọtaya yìí béèrè bóyá ibi ayẹyẹ ìgboyèjáde tàbí ibi àkànṣe mìíràn kan ni wọ́n ti ń bọ̀. Josué ṣàlàyé fún wọn pé àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn wá, wọ́n sì ní kí tọkọtaya náà wá síbẹ̀ lọ́jọ́ Sunday.
Tọkọtaya yìí rò pé ó máa rí bákan táwọn bá wá torí pé aṣọ táwọn wọ̀ kò bójú mu fún irú àpéjọ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, Josué fún wọn ní orúkọ rẹ̀ àti nọ́ńbà tẹlifóònù ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ti ń sìn.
Ní oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún Josué láti gbúròó Javier. Tọkọtaya yìí wá sí àpéjọ àgbègbè náà, wọ́n sì fẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ àwọn níbi tí wọ́n ń gbé nígbà yẹn ní ìlú Mexico City. Kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Javier àti Maru lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kíá ni wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé. Lẹ́yìn oṣù mẹ́wàá, wọ́n di akéde. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkọtaya náà ní láti kó lọ sí ìlú Tòróńtò, lórílẹ̀-èdè Kánádà, wọ́n ń bá a nìṣó láti máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, wọ́n sì ṣèrìbọmi.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Josué rí lẹ́tà kan gbà látọ̀dọ̀ Javier, ó sì ṣàlàyé ohun tó mú kó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ sínú lẹ́tà náà. Ó wá fi kún un pé: “Kí èmi àti ìyàwó mi tó wá sí àpéjọ àgbègbè yẹn, a ti sọ̀rọ̀ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ kí Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà. Nígbà tá a rí bí ẹ ṣe múra dáadáa, a rò pé ó ní láti jẹ́ pé ìpàdé pàtàkì kan lẹ ti ń bọ̀. Ohun tó wú wa lórí ní àpéjọ náà ni bí wọ́n ṣe fi ibi tá a máa jókòó sí hàn wá tìfẹ́tìfẹ́, tí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti máa fojú bá ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n ń kà lọ àti ìwà àwọn tó wà ní àpéjọ náà. Wọn kò wo ti pé a múra gẹ́gẹ́ bí arìnrìn-àjò afẹ́.”
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Josué yìí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì! Ó sọ pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere, yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.” (Oníw. 11:6) Nígbàkigbà tí àkókò bá ṣí sílẹ̀, ǹjẹ́ ìwọ náà lè fún irúgbìn nípa sísọ fún àwọn èèyàn nípa àpéjọ tó ń bọ̀ lọ́nà tàbí àsọyé fún gbogbo ènìyàn? Jèhófà lè lò ẹ́ láti mú àwọn tí ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ torí pé wọ́n nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run wá sínú òtítọ́, bó ti ṣe fún Javier àti Maru.—Aísá. 55:1.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Alejandro Voeguelin, Maru Pineda, Alejandro Pineda, Javier Pineda àti Josué Ramírez ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò