“Ojoojúmọ́ Ni Iṣẹ́ Apínwèé-Ìsìn-Kiri Túbọ̀ Ń Gbádùn Mọ́ Mi”
Látinú Àpamọ́ Wa
“Ojoojúmọ́ Ni Iṣẹ́ Apínwèé-Ìsìn-Kiri Túbọ̀ Ń Gbádùn Mọ́ Mi”
NÍ ỌDÚN 1886, ọgọ́rùn-ún kan ẹ̀dà ìwé Millennial Dawn, Apá Kìíní, ni wọ́n kó láti Ilé Bíbélì tó wà ní ìlú Allegheny, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ sí ìlú Chicago, ní ìpínlẹ̀ Illinois. Arákùnrin Charles Taze Russell ní in lọ́kàn láti kó àwọn ìwé tuntun náà sí àwọn ilé ìtàwé kó lè tipa bẹ́ẹ̀ dé ọwọ́ àwọn èèyàn. Ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ tó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tó máa ń ṣe alágbàtà àwọn ìwé ìsìn, sì ti gbà pé kí wọ́n kó àwọn ẹ̀dá ìwé Millennial Dawn ṣọwọ́ sí òun. Àmọ́, ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, wọ́n dá gbogbo ìwé náà pa dà sí Ilé Bíbélì.
Ohun tí wọ́n gbọ́ pé ó ṣẹlẹ̀ ni pé inú bí ajíhìnrere kan táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó nígbà tó rí ìwé Millennial Dawn níbi tí wọ́n pàtẹ ìwé tirẹ̀ sí. Ó wá fi ìbínú sọ pé bí wọn kò bá kó ìwé Millennial Dawn kúrò lórí àtẹ, òun àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ òun tí wọ́n jẹ́ gbajúgbajà ajíhìnrere máa wá kó ìwé àwọn kúrò lọ́dọ̀ wọn, àwọn á sì kó o lọ sí ilé ìtàwé míì. Pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ ni alágbàtà náà fi dá àwọn ìwé Millennial Dawn pa dà. Yàtọ̀ sí títa àwọn ìwé náà ní ilé ìtàwé, a tún ti polówó rẹ̀ nínú àwọn ìwé ìròyìn. Ṣùgbọ́n àwọn tó ń ṣe àtakò sí wa rí sí i pé àwọn oníwèé ìròyìn wọ́gi lé àdéhùn tí wọ́n bá wa ṣe láti polówó ìwé náà. Báwo wá ni ìtẹ̀jáde tuntun yìí ṣe máa tẹ àwọn tó ń wá òtítọ́ lọ́wọ́?
Ọwọ́ àwọn tí à ń pè ní apínwèé-ìsìn-kiri ní ìgbà yẹn ni ojútùú sí ìṣòro yìí wà. * Ní ọdún 1881, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower jẹ́ kó di mímọ̀ pé a nílò ẹgbẹ̀rún kan [1,000] àwọn oníwàásù tí wọ́n lè máa fi èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kiri. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apínwèé-ìsìn-kiri náà kò ju ọgọ́rùn-ún mélòó kan lọ, wọ́n fọ́n àwọn irúgbìn òtítọ́ káàkiri nípa pípín àwọn ìtẹ̀jáde náà délé dóko. Nígbà tó fi máa di ọdún 1897, iye ìwé Millennial Dawn tí wọ́n ti pín ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan. Àwọn apínwèé-ìsìn-kiri ló sì ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ náà. Owó ìtìlẹyìn táṣẹ́rẹ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn máa ń rí bí wọ́n bá gba àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí tí wọ́n bá fi ìwé kan sódè ni wọ́n máa ń fi gbọ́ bùkátà ara wọn.
Àwọn wo ni àwọn apínwèé-ìsìn-kiri tó jẹ́ onígboyà yìí? Àwọn kan lára wọn wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, àwọn míì sì ti dàgbà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn kò tíì ṣègbéyàwó tàbí kí wọ́n ti ṣègbéyàwó àmọ́ kí wọ́n má tíì bímọ, àmọ́ àwọn ìdílé tó dara pọ̀ mọ́ wọn pọ̀ díẹ̀. Àwọn apínwèé-ìsìn-kiri déédéé máa ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí tó pọ̀ lójoojúmọ́, àwọn olùrànlọ́wọ́ apínwèé-ìsìn-kiri sì máa ń lo wákàtí kan tàbí méjì lóòjọ́. Gbogbo èèyan kọ́ ni ìléra rẹ̀ gbé e láti jẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ sí ní ipò tí wọ́n á fi lè ṣe iṣẹ́ náà. Àmọ́, nígbà àpéjọ tá a ṣe ní ọdún 1906, wọ́n sọ fún àwọn tó lè ṣe iṣẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri pé kò pọn dandan kí wọ́n “mọ̀wé gan-an, tàbí kí wọ́n ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀, tàbí kí wọ́n jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́.”
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ní gbogbo ilẹ̀, àwọn èèyàn tí kò kàwé rẹpẹtẹ ṣe iṣẹ́ tó pabanbarì. Arákùnrin kan fi ojú bù ú pé láàárín ọdún méje òun fi ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000] ìwé sóde. Síbẹ̀, ó sọ pé, “Torí kí n lè di ẹni tó ń ta ìwé kọ́ ni mo ṣe wọṣẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri, bí kò ṣe tori kí n lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà àti fún òtítọ́ rẹ̀.” Ibi yòówù kí àwọn àpínwèé-ìsìn-kiri náà lọ, irúgbìn òtítọ́ ń fìdí múlẹ̀, àwùjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrú.
Àwọn àlùfáà kórìíra àwọn àpínwèé-ìsìn-kiri, wọ́n sì máa ń pè wọ́n ní àkiritàwèé. Ilé Ìṣọ́ ọdún 1892 ṣàlàyé pé: “Díẹ̀ làwọn tó mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ojúlówó aṣojú Olúwa tàbí tí wọ́n mọ bí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọn ṣe ń bọlá fún Olúwa.” Àmọ́, bí ọ̀kan nínú wọ́n ṣe sọ, ìgbésí ayé àpínwèé-ìsìn-kiri kì í ṣe “ìgbésí ayé jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí kò ní wàhálà nínú.” Àwọn bàtà àti kẹ̀kẹ́ tí ara wọn gbàyà ni ohun pàtàkì tí wọ́n ń lò láti fi rìn láti ibì kan sí ìbòmíràn. Bí àwọn èèyàn kò bá lówó lọ́wọ́, ńṣe ni àwọn àpínwèé-ìsìn-kiri máa ń gba oúnjẹ dípò owó ìwé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ àwọn oníwàásù yìí lẹ́yìn ọjọ́ kan nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, síbẹ̀ tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi máa ń pa dà sínú àwọn àgọ́ tàbí yàrá tí wọ́n háyà. Nígbà tó ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo Kẹ̀kẹ́ Apínwèé-ìsìn-kiri, ìyẹn ọkọ̀ àgbéléṣe kan tó dà bí ilé tó dín ọ̀pọ̀ àkókò àti ìnáwó kù. *
Látìgbà àpéjọ àgbègbè tó wáyé ní ìlú Chicago ní ọdún 1893 la ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi apá pàtàkì kan tó dá lórí àwọn àpínwèé-ìsìn-kiri kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ. Apá yìí máa ń ṣe àgbéjáde àwọn ìrírí tó fani mọ́ra, àwọn àbá nípa onírúurú ọgbọ́n téèyàn lè fi wàásù àti àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Arákùnrin Russell rọ àwọn oníwàásù tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ kára yìí pé kí wọ́n máa jẹun yó dáadáa ní òwúrọ̀, kí wọ́n máa mu ife wàrà kan tó bá ti ń di ọwọ́ ọ̀sán, bí ojú ọjọ́ bá sì gbóná, kí wọ́n máa mu ohun aládùn tó tutù.
Àwọn àpínwèé-ìsìn-kiri tó ń wá alábàáṣiṣẹ́, tàbí ẹni tí wọ́n á jọ́ máa wàásù, fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ yẹ́lò sára asọ wọn. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di àpínwèé-ìsìn-kiri máa ń bá àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà ṣiṣẹ́. Ó jọ pé wọ́n nílò irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, torí pé nígbà kan tí ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di àpínwèé-ìsìn-kiri ń fi àwọn ìwé náà lọni, ìbẹ̀rù mú kó sọ pé, “Ṣé ẹ fẹ́ àwọn ìwé yìí, àbí ẹ kò fẹ́?” Ó múni láyọ̀ pé onílé náà gba àwọn ìwé yẹn, ó sì di arábìnrin lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Arákùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ‘Ṣé kí n máa bá iṣẹ́ olówó gọbọi tí mò ń ṣe yìí lọ kí n sì máa fi ẹgbẹ̀rún kan [1,000] owó dọ́là ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù lọ́dọọdún àbí kí n kúkú di àpínwèé-ìsìn-kiri?’ Wọ́n sọ fún un pé kò sí èyí tí inú Olúwa kò dùn sí nínú méjèèjì, àmọ́ èyí tó máa mú kó rí ìbùkún tó pọ̀ jù lọ gbà ni pé kó ya àkókò rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Olúwa ní tààràtà. Arábìnrin Mary Hinds rí iṣẹ́ àpínwèé-ìsìn-kiri gẹ́gẹ́ bí “ọ̀nà tó dára jù lọ tó lè gbà ṣe àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ lóore.” Onítìjú èèyàn ni Alberta Crosby, ó sì máa ń bẹ̀rù, àmọ́ ó sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni iṣẹ́ Apínwèé-ìsìn-kiri túbọ̀ ń gbádùn mọ́ mi.”
Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ nípa tara àti nípa tẹ̀mí fún àwọn apínwèé-ìsìn-kiri tí wọ́n jẹ́ onítara yẹn ṣì ń rọ̀ mọ́ ogún tẹ̀mí wọn. Bí kò bá tíì sí apínwèé-ìsìn-kiri tàbí aṣáájú-ọ̀nà kankan nínú ìdílé yín, ṣé ẹ̀yin náà á kúkú sọ ọ́ di ohun tí ẹ ó máa ṣe? Ẹ máa rí i pé ojoojúmọ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú á túbọ̀ máa fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Lẹ́yìn ọdún 1931, a yí orúkọ náà “apínwèé-ìsìn-kiri” pa dà sí “aṣáájú-ọ̀nà.”
^ A máa ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn ọkọ̀ tó dà bí ilé yìí nínú àpilẹkọ kan lọ́jọ́ iwájú.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 32]
Kò pọn dandan kí wọ́n “mọ̀wé gan-an, tàbí kí wọ́n ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀, tàbí kí wọ́n jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Arákùnrin A. W. Osei, tó jẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri ní orílẹ̀-èdè Gánà, ní nǹkan bí ọdún 1930
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Òkè: Àwọn apínwèé-ìsìn-kiri: Edith Keen àti Gertrude Morris ní orílẹ̀-èdè England, nǹkan bí ọdún 1918; ìsàlẹ̀: Stanley Cossaboom àti Henry Nonkes lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, pẹ̀lú òfìfo páálí àwọn ìwé tí wọ́n fi sóde