“Àwọn “Olùgbé Fún Ìgbà Díẹ̀” Ń Sin Jèhófà Ní Ìṣọ̀kan
“Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè sì ni yóò jẹ́ àgbẹ̀ yín àti olùrẹ́wọ́ àjàrà yín. Àti pé ní ti ẹ̀yin, àlùfáà Jèhófà ni a óò máa pè yín.”—AÍSÁ. 61:5, 6.
1. Èrò wo làwọn kan ní nípa àwọn àjèjì? Kí nìdí tí irú èrò bẹ́ẹ̀ kò fi dára?
ATI rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí pé àwọn kan wà tí wọn kò fẹ́ràn àwọn àjèjì tàbí àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Ńṣe ni wọ́n tiẹ̀ máa ń wo irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tìkà-tẹ̀gbin. Wọ́n sì máa ń ronú pé àwọn sàn jù wọ́n lọ. Àmọ́, irú èrò bẹ́ẹ̀ kò dára. Ohun tí àwọn tó bá ní irú èrò bẹ́ẹ̀ kò mọ̀ ni pé kò sí ẹni tó sàn ju ẹlòmíì lọ. Ìwé kan tó ń jẹ́ The Races of Mankind sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ọmọ ìyá kan náà ni gbogbo ìran èèyàn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó bá jẹ́ ọmọ ìyà kan náà lè yàtọ̀ síra, ọmọ ìyà ṣì ni wọ́n.
2, 3. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn àjèjì?
2 Nígbà àtijọ́, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú, ó sì yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí èèyàn rẹ̀. Látàrí èyí, wọ́n ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Àwọn àjèjì kò ní irú àjọṣe yìí pẹ̀lú Ọlọ́run. Torí náà, òfin tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ hùwà àìdáa sáwọn àjèjì, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe lóde òní nìyẹn. Kò sí orílẹ̀-èdè tá ò ti lè rí àwọn àjèjì. Àwa Kristẹni kò gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúsàájú tàbí ẹ̀tanú. Kí nìdí? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ bá àwọn àjèjì tó wà láàárín wọn gbé pọ̀ bíi pé ọmọ ìyá kan náà ni wọ́n. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ràn àwọn àjèjì. Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jèhófà pé: “Àbí Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ni òun í ṣe? Òun kì í ha ṣe Ọlọ́run àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú.”—Róòmù 3:29; Jóẹ́lì 2:32.
4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé kò sí àjèjì kankan láàárín “Ísírẹ́lì Ọlọ́run”?
4 Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ṣàìgbọràn, wọn kò sì ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́. Torí náà, Jèhófà dá májẹ̀mú tuntun pẹ̀lú ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó sì fi wọ́n rọ́pò wọn. Ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí ni Bíbélì pè ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16) Pọ́ọ̀lù sọ pé nínú orílẹ̀-èdè tuntun yìí, kò sí “Gíríìkì tàbí Júù, ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, Síkítíánì, ẹrú, òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo, ó sì wà nínú ohun gbogbo.” (Kól. 3:11) Torí náà, a lè sọ pé kò sí àjèjì nínú ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nígbà yẹn.
5, 6. (a) Kí la lè béèrè nípa ohun tó wà nínú Aísáyà 61:5, 6? (b) Àwọn wo ni Aísáyà pè ní “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” àti “àlùfáà Jèhófà”? (d) Báwo ni àwọn méjèèjì yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀?
5 Ẹnì kan lè máa ṣe kàyéfì nípa ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà orí 61, tó ṣì ń ní ìmúṣẹ nínú ìjọ Kristẹni. Ẹsẹ 6 sọ nípa àwọn tí yóò máa sìn gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà Jèhófà.” Ṣùgbọ́n ẹsẹ 5 sọ pé “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” á máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn “àlùfáà.” Kí nìdí tá a fi pe àwọn kan ní ọmọ ilẹ̀ òkèèrè?
6 Lónìí, àwọn “àlùfáà Jèhófà” ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ní ipa nínú “àjíǹde èkíní” tí “wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, tí wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún.” (Ìṣí. 20:6) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni adúróṣinṣin míì tún wà tí wọ́n ní ìrètí láti gbé nínú ayé tuntun. Àwọn Kristẹni yìí ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí yóò máa gbé ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn kò sí lára “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ńṣe ni wọ́n dà bí “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” tàbí àjèjì. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ń kọ́wọ́ ti “àwọn àlùfáà Jèhófà,” tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí “àgbẹ̀” àti “olùrẹ́wọ́ àjàrà,” nínú iṣẹ́ ìkórè náà. Wọ́n ń wàásù fún àwọn èèyàn, wọ́n sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́nà yìí, wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró láti bọlá fún Ọlọ́run. Àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” jùmọ̀ ń wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ń ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa sin Ọlọ́run títí láé.—Jòh. 10:16.
A JẸ́ “OLÙGBÉ FÚN ÌGBÀ DÍẸ̀” BÍI TI ÁBÚRÁHÁMÙ
7. Báwo ni àwa Kristẹni lóde òní ṣe dà bí Ábúráhámù àtàwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì mìíràn?
7 A ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí pé àwa Kristẹni tòótọ́ dà bí àjèjì, tàbí olùgbé fún ìgbà díẹ̀ nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí. Èyí mú kí ọ̀rọ̀ wa dà bíi ti àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì, irú bí Ábúráhámù. Bíbélì sọ pé wọ́n “jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.” (Héb. 11:13) Yálà a ní ìrètí láti lọ sí ọ̀run tàbí láti máa gbé nínú ayé tuntun, àwa náà lè ní irú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tí Ábúráhámù ní pẹ̀lú Jèhófà. Jákọ́bù sọ pé: “‘Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì kà á sí òdodo fún un,’ ó sì di ẹni tí a ń pè ní ‘ọ̀rẹ́ Jèhófà.’”—Ják. 2:23.
8. Ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù? Ǹjẹ́ Ábúráhámù ṣàníyàn nípa ìgbà tí ìlérí yẹn máa ṣẹ?
8 Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa bù kún gbogbo ìdílé tó wà láyé nípasẹ̀ Ábúráhámù àtàwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo ní ìlérí yìí máa ṣe láǹfààní o, gbogbo orílẹ̀-èdè pátá ni! (Ka Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì máa pẹ́ gan-an kí ìlérí yìí tó ṣẹ, ìgbàgbọ́ Ábúráhámù kò yingin. Ó ju ọgọ́rin [80] ọdún lọ tí òun àti ìdílé rẹ̀ fi ń ṣí láti ibì kan lọ sí ibòmíì. Àmọ́, ní gbogbo àkókò yẹn, Ábúráhámù kò fi Jèhófà sílẹ̀.
9, 10. (a) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ábúráhámù? (b) Kí là ń pé àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá ṣe?
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù kò mọ ìgbà tí Ọlọ́run máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó ṣì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì sìn ín tọkàntọkàn. Torí pé Ábúráhámù máa ń rántí pé olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ni òun, kò gbé ìgbé ayé rẹ̀ bíi tàwọn ọmọ ìbílẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó bá lọ. (Héb. 11:14, 15) Ó bọ́gbọ́n mu pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ábúráhámù, ká má ṣe máa kó ohun ìní tara jọ, ká má ṣe máa wá ipò ọlá láwùjọ, ká má sì ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ wa gbà wá lọ́kàn! Àwọn nǹkan yìí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń lé nínú ayé lónìí. Kí nìdí tí a ó fi máa lé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nínú ètò àwọn nǹkan búburú tó máa tó wá sópin yìí? Kí nìdí tá a fi máa nífẹ̀ẹ́ ayé tó máa tó pa run yìí? Bíi ti Ábúráhámù, àwa náà ń retí ohun kan tó fi gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ dára ju àwọn nǹkan tá à ń rí nísinsìnyí lọ. A sì fẹ́ fi sùúrù dúró títí tí Jèhófà á fi mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.—Ka Róòmù 8:25.
10 Jèhófà ṣì ń pe àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo láti wá gba ìbùkún tó ṣèlérí nípasẹ̀ irú ọmọ Ábúráhámù. Ó ju ẹgbẹ̀ta [600] èdè lọ tí àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ “àwọn àlùfáà Jèhófà,” àtàwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n jẹ́ “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,” fi ń pe gbogbo èèyàn kárí ayé láti wá gba ìbùkún yìí.
NÍFẸ̀Ẹ́ GBOGBO ÈÈYÀN
11. Kí ló ṣe kedere nínú àdúrà tí Sólómọ́nì gbà?
11 Nígbà tí Sólómọ́nì ń ya tẹ́ńpìlì sí mímọ́ lọ́dún 1026 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù. Ó sọ nínú àdúrà àtọkànwá tó gbà pé àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè lè jàǹfààní látinú májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá bí wọ́n bá gbàdúrà síhà tẹ́ńpìlì. Ó sọ pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, tí kì í ṣe ara àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí ó sì ti ilẹ̀ jíjìnnà wá ní tòótọ́ nítorí orúkọ rẹ (nítorí wọn yóò gbọ́ nípa orúkọ ńlá rẹ àti nípa ọwọ́ líle rẹ àti nípa apá rẹ nínà jáde), tí ó sì wá ní ti gidi, tí ó sì gbàdúrà síhà ilé yìí, kí ìwọ alára fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè náà ké pè ọ́ sí; kí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé lè wá mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe.”—1 Ọba. 8:41-43.
12. Kí nìdí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi dà bí àjèjì lójú àwọn èèyàn?
12 Àjèjì ni ẹni tí kì í ṣe ọmọ ìbílẹ̀ orílẹ̀-èdè tó ń gbé tàbí ẹni tó kàn ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè kan. Bí ọ̀rọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe rí nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà kárí ayé, Ìjọba Ọlọ́run nìkan la fara mọ́. Jésù Kristi sì ni Ọba Ìjọba náà. Ìdí nìyẹn tí a kì í fi í dá sí ìṣèlú, bí àwọn kan bá tiẹ̀ ń sọ pé ọ̀rọ̀ wa kò bá ti gbogbo ayé mu.
13. (a) Kí la lè ṣe tí a kò fi ní máa wo àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àjèjì? (b) Ojú wo ni Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa fi wo ara wọn?
13 Lára àwọn nǹkan tó lè mú kéèyàn tètè dá àwọn àjèjì mọ̀ ni, bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, àṣà wọn, bí wọ́n ṣe rí àti bí wọ́n ṣe ń múra pàápàá. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn àjèjì fi jọra pẹ̀lú àwọn èèyàn tó kù láyé. Àwọn ọ̀nà tí wọ́n gbà jọra yìí sì ṣe pàtàkì gan-an ju ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn lọ. Torí náà, tá a bá dẹ́kun láti máa ronú nípa bí ẹnì kan ṣe yàtọ̀ sí wa, a kò ní máa wò ó bí àjèjì. Ká sọ pé orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo ni gbogbo ayé yìí ni, tó sì jẹ́ pé ìjọba kan ṣoṣo ló ń ṣàkóso ayé, kò ní sí ẹni tí à bá máa pè ní àjèjì. Ohun tó sì wu Jèhófà nígbà tó dá èèyàn ni pé, kí gbogbo èèyàn wà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. Ní báyìí ńkọ́? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè máa gbé pa pọ̀ bí ọmọ ìyá kan náà, kí wọ́n má sì máa wo ara wọn gẹ́gẹ́ bí àjèjì?
14, 15. Kí làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀ ń gbé ṣe báyìí?
14 Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, wọ́n sì máa ń ronú pé orílẹ̀-èdè tàwọn ló dára jù lọ. Àmọ́, ó tuni lára láti rí àwọn kan tí wọ́n fẹ́ràn àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo. Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn fún wa láti yí èrò tá a ní nípa àwọn ẹlòmíì pa dà. Ọ̀gbẹ́ni Ted Turner tó dá ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n CNN sílẹ̀ ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé, ó sì sọ ohun tó wú u lórí nípa wọn. Ó ní: “Ohun tí mo rí nígbà tí mo bá oríṣiríṣi èèyàn ṣiṣẹ́ yà mí lẹ́nu gan-an ni. Èmi kì í wo àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì bí àjèjì, alájọgbáyé ni mo kà wọ́n sí. Èyí mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í wo ọ̀rọ̀ náà ‘àjèjì’ bí ohun tí kò yẹ kéèyàn máa sọ jáde lẹ́nu. Mo wá ṣe òfin kan ní ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n CNN pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ lo ọ̀rọ̀ yìí lórí afẹ́fẹ́, wọn kò sì gbọ́dọ̀ máa lò ó nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ níbi iṣẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí wọ́n kàn sọ orílẹ̀-èdè tí onítọ̀hún ti wá.”
15 Ní gbogbo ayé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀ nìkan la kì í wo àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo gẹ́gẹ́ bí àjèjì, Ọlọ́run la sì fi èyí jọ. Ojú tó fi ń wo àwọn èèyàn la fi ń wò wọ́n, torí náà èrò tó dára la ní nípa wọn. A kì í ronú pé àwọn tí kì í ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè wa kò ṣeé fọkàn tán tàbí ká máa fura sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni a kì í kórìíra wọn. A mọyì àwọn ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo ní. Ǹjẹ́ o gbà pé ohun àrà ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ṣe yìí? Ǹjẹ́ ìwọ fúnra rẹ ti jàǹfààní látàrí bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀ kì í ṣeé wo ẹnikẹ́ni bí àjèjì?
KÒ NÍ SÍ ÀJÈJÌ NÍNÚ AYÉ TUNTUN
16, 17. Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nígbà tí Ìṣípayá 16:16 àti Dáníẹ́lì 2:44 bá ní ìmúṣẹ?
16 Láìpẹ́, gbogbo orílẹ̀-èdè máa dojú ìjà kọ Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣí. 16:14, 16; 19:11-16) Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ [2,500] ọdún báyìí tí Ọlọ́run ti mí sí wòlíì Dáníẹ́lì láti sàsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìjọba èèyàn. Ó sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dán. 2:44.
17 Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá ṣẹ? Lóde òní, àwọn ibodè tó pààlà sáwọn orílẹ̀-èdè ti sọ àwa èèyàn di àjèjì sí ara wa. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, àwọn ibodè yìí kò ní sí mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ò lè rí bákan náà nínú ayé tuntun, ńṣe ni ìyàtọ̀ èyíkéyìí tó bá wà lára àwa èèyàn á máa gbé ògo Jèhófà yọ, á sì fi hàn pé Ọba oníṣẹ́ àrà ni Ọlọ́run. Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu là ń retí yìí! Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa fi gbogbo ọkàn wa bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá gbogbo wa, ká sì máa yìn ín.
Ṣé ò ń retí ìgbà tí àwọn ibodè tó pààlà sáwọn orílẹ̀-èdè kò ní sí mọ́, tí ẹnikẹ́ni ò sì ní jẹ́ àjèjì?
18. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó fi hàn pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í wo ẹnikẹ́ni bí àjèjì?
18 Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe lóòótọ́ pé kí gbogbo èèyàn kárí ayé má ṣe máa wo ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí àjèjì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe. Kódà ní báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í wo ẹnikẹ́ni bí àjèjì. Àpẹẹrẹ kan ni ti ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, a pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan tí kò tóbi pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì, kó bàa lè rọrùn láti máa bójú tó wọn, kí àwọn ará sì lè túbọ̀ gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14) Nígbàkigbà tá a bá pa ẹ̀ka ọ́fíìsì wa méjì tó wà ní orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pọ̀ báyìí, lójú tiwa a ò rí wọn bí orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mọ́. Àfi bí òfin orílẹ̀-èdè kò bá fàyè gbà wá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rí tó lágbára lèyí jẹ́ pé Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run ti ń ya àwọn ibodè tó pààlà sí àwọn orílẹ̀-èdè lulẹ̀ báyìí. Láìpẹ́, ó máa mú kí gbogbo ayé wà níṣọ̀kan nígbà tó bá “parí ìṣẹ́gun rẹ̀.”—Ìṣí. 6:2.
19. Kí ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ táwa èèyàn Jèhófà ń kọ́ ti mú kó ṣeé ṣe?
19 Látinú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá, oríṣiríṣi èdè la sì ń sọ. Ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Bíbélì pè ní “èdè mímọ́” ló so wá pọ̀, a ò sì ní ya ara wa títí láé. (Ka Sefanáyà 3:9.) Ńṣe ni gbogbo wa dà bí ọmọ ìyá kan náà kárí ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé burúkú yìí náà là ń gbé, a kì í ṣe bíi tàwọn tó wà lábẹ́ àkóso Sátánì. Ti pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà níṣọ̀kan báyìí jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé, nínú ayé tuntun, kò ní sí ẹnì kankan tí a ó máa pè ní àjèjì. Tó bá dìgbà yẹn, inú gbogbo àwọn tó bá wà láyé máa dùn gan-an tí wọ́n bá rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Ìwé tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀ sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ọmọ ìyá kan náà ni gbogbo ìran èèyàn.”