Olùgbé Fún Ìgbà Díẹ̀” Ni Wá
“Mo gbà yín níyànjú gẹ́gẹ́ bí àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ láti máa ta kété sí àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ara.” —1 PÉT. 2:11.
1, 2. Àwọn wo ní Pétérù pè ní “àwọn ẹni tí a yàn”? Kí nìdí tó fi pè wọ́n ní “olùgbé fún ìgbà díẹ̀”?
NÍ NǸKAN bí ọgbọ́n ọdún lẹ́yìn tí Jésù pa dà sí ọ̀run, àpọ́sítélì Pétérù kọ lẹ́tà kan sí àwùjọ àwọn èèyàn kan tó pè ní “olùgbé fún ìgbà díẹ̀ tí wọ́n tú ká káàkiri ní Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà, Éṣíà, àti Bítíníà.” Ó tún pè wọ́n ní “àwọn ẹni tí a yàn.” (1 Pét. 1:1) Àwọn tí Pétérù pè ní “àwọn ẹni tí a yàn” yìí ni àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn tí ó sì fún ní “ìbí tuntun sí ìrètí tí ó wà láàyè,” kí wọ́n lè ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Ka 1 Pétérù 1:3, 4.) Àmọ́, kí nìdí tí Pétérù tún fi pè wọ́n ní “àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀”? (1 Pét. 2:11) Kí nìdí tó fi yẹ ká sọ̀rọ̀ nípa lẹ́tà tí Pétérù kọ yìí nígbà tó jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ni ẹni àmì òróró?
2 Ó bá a mu pé àpọ́sítélì Pétérù pe àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró ní ọ̀rúndún kìíní ní “olùgbé fún ìgbà díẹ̀.” Ìdí sì ni pé àwọn ẹni àmì òróró bíi tiwọn lóde òní pẹ̀lú jẹ́ olùgbé fún ìgbà díẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà jẹ́ ọ̀kan lára “agbo kékeré” tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. Ó sọ pé: “Ní tiwa, ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́ bí aráàlú ń bẹ ní ọ̀run, láti ibi tí a ti ń fi ìháragàgà dúró de olùgbàlà pẹ̀lú, Jésù Kristi Olúwa.” (Lúùkù 12:32; Fílí. 3:20) Èyí túmọ̀ sí pé nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró bá kú, wọ́n á fi ayé tí Sátánì ń ṣàkóso rẹ̀ yìí sílẹ̀. Wọ́n á wá lọ sí ọ̀run níbi tí wọn ò ti ní kú mọ́ láé. (Ka Fílípì 1:21-23.) Látàrí èyí, “olùgbé fún ìgbà díẹ̀” ni wọ́n ní tòótọ́.
3. Ìbéèrè wo ló yẹ ká béèrè nípa “àwọn àgùntàn mìíràn”?
3 “Àwọn àgùntàn mìíràn” wá ń kọ́? (Jòh. 10:16) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé wọn yóò máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, a lè pe àwọn náà ní olùgbé fún ìgbà díẹ̀. Lọ́nà wo?
“GBOGBO ÌṢẸ̀DÁ Ń BÁ A NÌṢÓ NÍ KÍKÉRORA PA PỌ̀”
4. Kí ni àwọn kan fẹ́ láti fi ọgbọ́n ìṣèlú, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tàbí owó ṣe, àmọ́ tí kò ṣeé ṣe?
4 Títí tí ètò àwọn nǹkan búburú yìí á fi dópin, gbogbo aráyé, tó fi mọ́ àwa èèyàn Jèhófà, á máa bá a nìṣó láti jìyà àbájáde ìwà ọ̀tẹ̀ Sátánì. Ìwé Róòmù 8:22 sọ pé: “Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” Àwọn kan tó lọ́kàn rere fẹ́ láti fi ọgbọ́n ìṣèlú, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tàbí owó tún ayé yìí ṣe kí ìyà má bàa jẹ àwọn èèyàn mọ́. Àmọ́, pàbó ni gbogbo ìsapá wọn ń já sí.
5. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ṣe láti ọdún 1914, kí sì nìdí?
5 Láti ọdún 1914 tí Ọlọ́run ti gbé Jésù Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń wá sábẹ́ àkóso Kristi. Wọn kò fẹ́ máa ṣe bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì, wọn kò sì fẹ́ láti lọ́wọ́ sí ìṣàkóso rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi ìgbésí ayé wọn àtàwọn ohun ìní wọn ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run.—Róòmù 14:7, 8.
6. Kí nìdí tá a fi lè pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àtìpó tàbí olùgbé fún ìgbà díẹ̀?
6 A lè rí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè tó ju igba [200] lọ. A sì máa ń pa òfin ìlú mọ́. Àmọ́, ibi yòówù ká máa gbé, ńṣe la dà bí àtìpó tàbí olùgbé fún ìgbà díẹ̀. A kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú, a kì í sì í dá sí rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ. Kódà láti ìsinsìnyí lọ, a ti ń wo ara wa gẹ́gẹ́ bí ọmọ ayé tuntun. Inú wa dùn pé kò ní pẹ́ mọ́ tí ètò àwọn nǹkan búburú yìí á fi wá sópin. A kò sì ní máa gbé ayé gẹ́gẹ́ bí olùgbé fún ìgbà díẹ̀ mọ́.
7. Ìgbà wo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò ní jẹ́ olùgbé fún ìgbà díẹ̀ mọ́, ibo ni wọ́n á sì máa gbé?
7 Láìpẹ́, Jésù máa pa ètò àwọn nǹkan búburú yìí run. Tí Jésù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso aráyé, ó máa mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, àwa èèyàn ò sì ní máa jìyà mọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tó jẹ́ Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, Jésù máa pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ run. Àmọ́, àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run á máa gbé títí láé nínú Párádísè. (Ka Ìṣípayá 21:1-5.) Kò ní sí gbogbo ohun tó ń fa ìjìyà fún aráyé mọ́ nígbà yẹn, olúkúlùkù á sì ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.
ÌWÀ WO LÓ YẸ KÁWỌN KRISTẸNI TÒÓTỌ́ MÁA HÙ?
8, 9. Kí ni Pétérù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé káwọn Kristẹni “ta kété sí àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ara”?
8 Pétérù sọ irú ìwà tó yẹ kí àwọn Kristẹni máa hù. Ó ní: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo gbà yín níyànjú gẹ́gẹ́ bí àtìpó àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ láti máa ta kété sí àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ara, tí í ṣe àwọn ohun náà gan-an tí ń bá ìforígbárí nìṣó lòdì sí ọkàn.” (1 Pét. 2:11) Àwọn ẹni àmì òróró ni Pétérù kọ lẹ́tà yẹn sí, ṣùgbọ́n ó tún wúlò fún àwọn tí Jésù pè ní àgùntàn mìíràn.
9 Àwọn ìfẹ́ ọkàn kan wà tí kò burú, bí wọn ò bá ṣáà ti ta ko ìlànà Ẹlẹ́dàá. Kódà, ńṣe ni irú àwọn ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀ máa ń mú kí ayé túbọ̀ gbádùn mọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, lára irú àwọn ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀ ni pé ká jẹ, ká mu, kí àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa sì jọ gbádùn ara wa. Ìfẹ́ ọkàn ti ara míì ni pé kéèyàn ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya ẹni. (1 Kọ́r. 7:3-5) Ṣùgbọ́n, irú “ìfẹ́-ọkàn ti ara” tí Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni èyí “tí ń bá ìforígbárí nìṣó lòdì sí ọkàn.” Ìtumọ̀ Bíbélì míì tiẹ̀ pè é ní “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.” (Ìròhìn Ayọ̀) Níwọ̀n bí a ti mọ ohun tó tọ́, ó yẹ ká ṣọ́ra fún ìfẹ́ ọkàn ti ara yòówù tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu àti èyí tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Ìdí sì ni pé irú ìfẹ́ ọkàn ti ara bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí ikú.
10. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọgbọ́n tí Sátánì ń lò láti mú kí àwa Kristẹni wá sábẹ́ àkóso rẹ̀?
10 Ńṣe ni Sátánì fẹ́ ká gbàgbé pé “olùgbé fún ìgbà díẹ̀” la jẹ́ nínú ètò àwọn nǹkan búburú yìí. Mélòó la fẹ́ kà nínú àwọn ìdẹkùn tó ń lò. Ó fẹ́ ká máa kó ohun ìní tara jọ, ká máa ṣèṣekúṣe, ká máa wá ipò ọlá, ká má ro tẹlòmíì mọ́ tiwa, ká sì tún ní ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni. Dájúdájú, ó yẹ ká kíyè sára. Tá a bá pinnu pé a ò ní lọ́wọ́ sí irú àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tara yìí, ńṣe là ń fi hàn pé a kò fẹ́ wà lábẹ́ àkóso Sátánì. A ó sì tún tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé olùgbé fún ìgbà díẹ̀ la jẹ́ nínú ètò àwọn nǹkan búburú yìí. Ohun tó wù wá ni pé ká máa gbé títí láé nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. A sì ń sapá gidigidi ká lè wọnú ayé tuntun náà.
ÌWÀ RERE
11, 12. Ojú wo làwọn kan fi ń wo àwọn àjèjì? Ojú wo làwọn kan fi ń wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
11 Pétérù tún sọ ohun míì tó yẹ káwọn “olùgbé fún ìgbà díẹ̀” máa ṣe. Ó sọ pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.” Wọ́n sábà máa ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó bá jẹ́ àjèjì ní ìlú kan. Wọ́n sì lè máa fojú èèyàn burúkú wò wọ́n torí pé wọn kì í ṣe bíi ti àwọn aládùúgbò wọn. Kódà, ọ̀rọ̀ ẹnu wọn, ìṣesí wọn, ìmúra wọn àti ìrísí wọn pàápàá lè yàtọ̀. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá ń hùwà rere tí wọ́n sì jẹ́ ọmọlúwàbí, àwọn èèyàn lè rí i pé wọn kì í ṣe èèyàn burúkú bí àwọn ṣe rò.—1 Pét. 2:12.
12 Bí ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni tòótọ́ ṣe rí náà nìyẹn. A yàtọ̀ sí àwọn aládùúgbò wa láwọn ọ̀nà kan. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa ń yàtọ̀ sí tiwọn. Eré ìnàjú wa máa ń yàtọ̀ sí tiwọn. Ìmúra wa sì máa ń fi wá hàn yàtọ̀ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn. Èyí wá mú kí àwọn tó ti gbọ́ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa wa bẹ̀rẹ̀ sí í fojú èèyàn burúkú wò wá. Ṣùgbọ́n, àwọn míì máa ń gbóríyìn fún wa nítorí ìwà rere wa.
13, 14. Kí ni gbólóhùn náà, a fi ọgbọ́n “hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀,” túmọ̀ sí? Àwọn àpẹẹrẹ wo la rí?
13 Ìwà rere wa lè pa àwọn tó ń sọ̀rọ̀ wa ní búburú lẹ́nu mọ́. Jésù ni ẹnì kan ṣoṣo tó ṣègbọràn sí Ọlọ́run láìkù síbì kan. Síbẹ̀, àwọn èèyàn fẹ̀sùn èké kàn án. Àwọn kan sọ pé alájẹkì àti ọ̀mùtí ni. Wọ́n tiẹ̀ tún sọ pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ló ń bá kẹ́gbẹ́. Ṣùgbọ́n, ìwà rere rẹ̀ fi hàn pé kì í ṣe èèyàn burúkú gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe rò. Abájọ tí Jésù fi sọ pé “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mát. 11:19) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tó ń gbé nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Jámánì máa ń sọ pé ìgbé ayé àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì kò bá ti ayé mu. Ṣùgbọ́n olórí ìlú náà gbèjà ìdílé Bẹ́tẹ́lì, ó ní: “Ìgbé ayé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sìn níbẹ̀ yàtọ̀ lóòótọ́, àmọ́ wọn ò ni àwọn ará àdúgbò lára rárá.”
14 Irú èyí tún ṣẹlẹ̀ ní ìlú Moscow lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Àwọn èèyàn fi oríṣiríṣi ẹ̀sùn èké kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀. Wọ́n sọ pé ńṣe ni wọ́n máa ń tú ìdílé ká, wọ́n máa ń jẹ́ káwọn èèyàn gbẹ̀mí ara wọn, wọn kì í sì í tọ́jú ara wọn nígbà tí wọ́n bá ṣàìsàn. Ṣùgbọ́n nígbà tó di oṣù June, ọdún 2010, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù tó wà ní ìlú Strasbourg, lórílẹ̀-èdè Faransé kéde pé, àwọn ara ìlú Moscow kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa dá sí ọ̀ràn ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọn kò sì gbọ́dọ̀ dí wọn lọ́wọ́ láwọn ìpàdé wọn. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù tún sọ pé àwọn ilé ẹjọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kò ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n yìí. Àti pé ńṣe ni wọ́n kàn lo òfin ìlú Moscow lọ́nà tí kò tọ́ láti gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
A MÁA Ń ṢÈGBỌRÀN SÍ ÌJỌBA
15. Ìlànà Bíbélì wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ní gbogbo ayé ń tẹ̀ lé?
15 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Moscow àti gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé tún ń ṣe ohun míì tí Pétérù sọ pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe. Ó sọ pé: “Nítorí Olúwa, ẹ fi ara yín sábẹ́ gbogbo ohun tí ẹ̀dá ènìyàn ṣẹ̀dá: yálà sábẹ́ ọba gẹ́gẹ́ bí onípò gíga tàbí sábẹ́ àwọn gómìnà.” (1 Pét. 2:13, 14) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé nínú ayé búburú yìí. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, tọkàntọkàn la fi ń ṣègbọràn sí àwọn aláṣẹ ìjọba ní “àwọn ipò wọn aláàlà,” ìyẹn nígbàkigbà tí òfin wọn kò bá ta ko ti Ọlọ́run.—Ka Róòmù 13:1, 5-7.
16, 17. (a) Kí ló fi hàn pé a kì í dìtẹ̀ sí ìjọba? (b) Kí ni àwọn aláṣẹ ìjọba kan sọ?
16 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ìgbé ayé wa nínú ètò àwọn nǹkan búburú yìí gẹ́gẹ́ bí “olùgbé fún ìgbà díẹ̀.” Àmọ́, a kì í ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, bẹ́ẹ̀ ni a kì í ṣàríwísí àwọn èèyàn. A kì í sì í bá ẹnikẹ́ni fa wàhálà torí pé ó fara mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kan tàbí ká máa ṣe awuyewuye lórí ọ̀nà tó dára jù lọ láti bójú tó ohun tó ń lọ láwùjọ. Àwọn ẹlẹ́sìn kan máa ń lọ́wọ́ sí ìṣèlú, àmọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí ìṣèlú. A kì í ṣe àríwísí ọ̀nà tí ìjọba ń gbà ṣàkóso. Torí náà, a ò tiẹ̀ lè bá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nídìí ká máa da ìlú rú tàbí ká máa ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba.
17 Pétérù sọ pé kí a máa “fi ọlá fún ọba.” Torí náà àwa Kristẹni máa ń ṣègbọràn sí àwọn aláṣẹ ìjọba, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ bu ọ̀wọ̀ àti ọlá fún wọn. (1 Pét. 2:17) Láwọn ìgbà míì, àwọn aláṣẹ ìjọba fúnra wọn máa ń sọ pé àwọn ò ní ẹ̀rí kan tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ èèyàn eléwu. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọ̀gbẹ́ni olóṣèlú kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì, tó ń jẹ́ Steffen Reiche. Ọkùnrin yìí jẹ́ mínísítà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ kan lórílẹ̀-èdè Jámánì, ó sì tún wá di ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè Jámánì nígbà tó yá. Ó sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà hùwà ọmọlúwàbí gan-an nígbà tí ìjọba Násì ń ṣe inúnibíni sí wọn. Pẹ̀lú bí ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n ṣe pọ̀ tó, wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n sì ń hùwà rere sí àwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n.” Ó tún sọ pé: “Irú ìwà yìí gan-an ló yẹ kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Jámánì máa hù, pàápàá jù lọ bó ṣe jẹ́ pé ńṣe làwọn kan túbọ̀ ń hùwà àìdáa sí àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì, tí wọ́n ń gbéjà ko àwọn tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ tàbí tí wọn kò sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà pẹ̀lú wọn.”
A NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ARÁ WA
18. (a) Kí nìdí tí gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé fi nífẹ̀ẹ́ ara wa? (b) Kí làwọn kan sọ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
18 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará, ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run.” (1 Pét. 2:17) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rù Ọlọ́run, ìyẹn ni pé a kì í fẹ́ ṣe ohun tí kò fẹ́. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tá a ní yìí ló mú ká máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Inú wa ń dùn bí àwa àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kárí ayé ṣe jùmọ̀ ń sin Jèhófà. Abájọ tá a fi “ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” Irú ìfẹ́ tá a ní síra wa yìí ṣọ̀wọ́n nínú ayé, ìdí nìyẹn tí ẹnu fi máa ń ya àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n bá rí bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wa tó. Bí àpẹẹrẹ, nígbà àpéjọ àgbáyé tó wáyé lórílẹ̀-èdè Jámánì lọ́dún 2009, ẹnu ya obìnrin kan tó máa ń mú àwọn èèyàn rìnrìn àjò nígbà tó kíyè sí bí àwọn ará ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ara wọn tí wọ́n sì ń ran ara wọn lọ́wọ́. Ó sọ pé látìgbà tí òun ti ń ṣe iṣẹ́ yìí, òun ò tíì rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí. Ọ̀kan lára àwọn ara wa tó wà níbẹ̀ wá sọ lẹ́yìn náà pé: “Ẹnu yà á gan-an bó ṣe ń sọ gbogbo nǹkan tó ṣàkíyèsí nípa wa, pẹ̀lú ìtara ló sì fi sọ̀rọ̀.” Ǹjẹ́ o ti gbọ́ káwọn kan tó kíyè sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípa wa ní àpéjọ kan tó o lọ?
19. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe? Kí nìdí tó fi yẹ ká pinnu bẹ́ẹ̀?
19 Ohun tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí ti fi hàn ní onírúurú ọ̀nà pé òótọ́ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ìgbé ayé wa nínú ètò àwọn nǹkan búburú yìí gẹ́gẹ́ bí “olùgbé fún ìgbà díẹ̀.” A láyọ̀ láti máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà yìí. A ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó. A gbà gbọ́ dájú pé ayé tuntun òdodo Ọlọ́run kò ní pẹ́ dé mọ́. Tó bá dìgbà náà, a kò ní jẹ́ “olùgbé fún ìgbà díẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n a ó máa gbé ayé títí láé. Ṣé ìwọ náà ń retí ayé tuntun yẹn?