Ṣé Òótọ́ Ni Bíbélì Ní Agbára Àràmàǹdà
“Ọ̀RỌ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Héb. 4:12) Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì máa ń wọni lọ́kàn, ó sì lè yí ìgbésí ayé ẹni pa dà.
Àmọ́, lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn kan nínú ìjọ di apẹ̀yìndà. Ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n ń gbé lárugẹ sì mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí kò tọ́ nípa irú agbára tí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ní. (2 Pét. 2:1-3) Nígbà tó ṣe, àwọn olórí ẹ̀sìn bẹ̀rẹ̀ sí í lo Bíbélì lọ́nà tó mú káwọn ọmọ ìjọ gbà pé ó ní agbára àràmàǹdà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Harry Y. Gamble kọ̀wé pé àwọn kan máa ń lo Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìwé idán. Ó sọ pé ní ọ̀rúndún kẹta, Bàbá Ìjọ tá a mọ̀ sí Origen kọ́ni pé “àǹfààní wà nínú kéèyàn kàn tiẹ̀ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ tó wà nínú Bíbélì. Níbi tí ọ̀rọ̀ lágbára dé, àwọn abọ̀rìṣà pàápàá lè fi ọ̀rọ̀ lásán pidán, torí náà ó dájú pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Ìwé Mímọ́ gbọ́dọ̀ lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ fíìfíì.” Ọ̀gbẹ́ni John Chrysostom tóun náà gbé ní ọ̀rúndún kẹrin kọ̀wé pé: “Bí ìwé Ìhìn Rere bá wà nínú ilé kan, èṣù ò jẹ́ sún mọ́bẹ̀ rárá.” Ó tún sọ pé àwọn kan máa ń gbé ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ jáde látinú ìwé Ìhìn Rere kọ́rùn gẹ́gẹ́ bí oògùn ìṣọ́ra. Ọ̀jọ̀gbọ́n Gamble tún sọ pé Augustine tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì náà kọ́ni pé: “Bí ẹni tórí ń fọ́ bá fi ìwé ìhìn rere Jòhánù sábẹ́ ìrọ̀rí sùn, ṣe ni ẹ̀fọ́rí rẹ̀ máa lọ”! Èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé Bíbélì ní agbára àràmàǹdà. Ṣó yẹ ká gbà pé Bíbélì jẹ́ oògùn tàbí àwúre oríire tó lè dáàbò boni lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi?
Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó wọ́pọ̀ jù lọ táwọn èèyàn ń gbà lo Bíbélì lọ́nà tí kò tọ́. Wọ́n á kàn ṣí Bíbélì sí ibì kan ṣáá, wọ́n á ka gbólóhùn tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí níbẹ̀, wọ́n á sì gbà pé ohun tí wọ́n bá kà yẹn ló máa tọ́ àwọn sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Gamble tún sọ pé nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Augustine gbọ́ ohùn ọmọ kékeré kan ní itòsí ilé rẹ̀ tó ń sọ pé: “Gbà, kó o kà á, gbà, kó o kà á,” ńṣe ni Augustine gbà pé Ọlọ́run ló ń sọ fún òun pé kí òun ṣí Bíbélì kí òun sì ka ibi tí òun bá kọ́kọ́ rí.
Àwọn kan wà tí wọ́n ní èrò tó jọ èyí. Tí wọ́n bá ní ìṣòro, wọ́n á gbàdúrà sí Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, wọ́n á ṣí Bíbélì sí ibì kan ṣáá. Wọ́n sì máa ń gbà gbọ́ pé gbólóhùn táwọn bá kọ́kọ́ rí níbẹ̀ ló máa yanjú ìṣòro àwọn. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń fẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà. Àmọ́, kì í ṣe ọ̀nà tó yẹ káwọn Kristẹni máa gbà wá ìtọ́sọ́nà nínú Ìwé Mímọ́ nìyẹn.
Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé òun máa rán “olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́,” sí wọn. Ó tún sọ pé: “Èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.” (Jòh. 14:26) Èyí fi hàn pé ohun téèyàn bá kọ́ nínú Bíbélì ni ẹ̀mí mímọ́ máa ń ránni létí. Ìgbà yẹn sì lèèyàn tó lè mọ ohun tó yẹ kó ṣe. Ṣùgbọ́n, kéèyàn wulẹ̀ ṣí Bíbélì sí ibì kan ṣáá kò gba pé kó ní ìmọ̀ Bíbélì.
A ti rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí pé oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn ń gbà lo Bíbélì lọ́nà tí kò tọ́. Ṣùgbọ́n, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. (Léf. 19:26; Diu. 18:9-12; Ìṣe 19:19) Òótọ́ ni pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára,” ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ máa lò ó lọ́nà tó tọ́. Ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì ló máa ń yí ìgbésí ayé ẹni pa da, kì í ṣe lílo Bíbélì bíi pé ó ní agbára àràmàǹdà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni irú ìmọ̀ pípéye bẹ́ẹ̀ ti ràn lọ́wọ́. Ó ti jẹ́ kí wọ́n ní ìwà tó dára, ó ti mú kí wọ́n jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tó lè pa wọ́n lára, ó ti mú kí ìdílé wọn wà níṣọ̀kan, ó sì ti mú kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run tó fún wa ní Bíbélì.