Ǹjẹ́ O Mọyì Ogún Tẹ̀mí Wa?
“Ọlọ́run . . . yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè . . . láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.”—ÌṢE 15:14.
1, 2. (a) Kí ni “àtíbàbà Dáfídì”? Báwo ni wọ́n ṣe tún un kọ́? (b) Àwọn wo ni wọ́n jùmọ̀ ń wàásù ìhìn rere lónìí?
LỌ́DÚN 49 Sànmánì Kristẹni, ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọ̀rúndún kìíní ṣe ìpàdé kan ní Jerúsálẹ́mù. Níbi ìpàdé náà, Jákọ́bù sọ pé: “Símíónì [Pétérù] ti ṣèròyìn ní kínníkínní bí Ọlọ́run ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn. Ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì sì bá èyí mu, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, èmi yóò padà, èmi yóò sì tún àtíbàbà Dáfídì tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́; èmi yóò sì tún àwókù rẹ̀ kọ́, èmi yóò sì gbé e nà ró lẹ́ẹ̀kan sí i, kí àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ènìyàn náà lè fi taratara wá Jèhófà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ènìyàn tí a fi orúkọ mi pè, ni Jèhófà wí, ẹni tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, tí a mọ̀ láti ìgbà láéláé.’”—Ìṣe 15:13-18.
2 “Àtíbàbà Dáfídì” túmọ̀ sí àwọn ọba tó wá láti inú ìdílé Dáfídì. Ọ̀kan lára àwọn ọba yìí ni Sedekáyà, òun ló sì jẹ kẹ́yìn ní ìlú Júdà. Àtíbàbà Dáfídì “wó lulẹ̀” nígbà tí wọ́n rọ Sedekáyà lóyè. (Ámósì 9:11) Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé Ọlọ́run máa tún àwókù àtíbàbà náà kọ́. Èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run máa fi ẹlòmíì tó wá láti ìdílé Dáfídì jọba, Jésù sì ni ẹni náà. (Ìsík. 21:27; Ìṣe 2:29-36) Jákọ́bù tún ṣàlàyé níbi ìpàdé yẹn pé ohun mìíràn tí àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì yìí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run máa fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí láti jọba pẹ̀lú Jésù lókè ọ̀run. Lónìí, àwọn tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé lára àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn àti àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” ni wọ́n jùmọ̀ ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn.—Jòh. 10:16.
ÀWỌN ARÁ BÁBÍLÓNÌ KÓ ÀWỌN JÚÙ LẸ́RÚ
3, 4. Kí ni kò jẹ́ káwọn Júù jìnnà sí Jèhófà nígbà tí wọ́n wà ní Bábílónì?
3 Nígbà tí wọ́n kó àwọn Júù lẹ́rú lọ sí Bábílónì, 1 Jòh. 5:19) Ibi yòówù kí àwa èèyàn Jèhófà wà, a ní ogún tẹ̀mí tó máa ń mú ká jẹ́ olóòótọ́!
ó dájú nígbà náà pé “àtíbàbà Dáfídì” ti wó lulẹ̀. Ìsìn èké pọ̀ gan-an ní ìlú Bábílónì. Kí ni kò jẹ́ káwọn Júù yẹn fi Jèhófà sílẹ̀ láàárín àádọ́rin [70] ọdún tí wọ́n lò ní Bábílónì? Ohun táwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń gbé nínú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí ń ṣe ká lè máa fi òótọ́ sin Ọlọ́run làwọn náà ṣe. (4 Bíbélì pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan lára ogún tẹ̀mí wa. Àwọn Júù tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí Bábílónì kò ní odindi Bíbélì, àmọ́ wọ́n mọ Òfin Mẹ́wàá àtàwọn òfin míì tí Jèhófà tipasẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n mọ “àwọn orin Síónì” àti ọ̀pọ̀ òwe. Wọ́n sì tún mọ ìtàn àwọn tó fòótọ́ sin Jèhófà nígbà àtijọ́. Àwọn Júù kò gbàgbé Jèhófà, ìgbàkigbà tí wọ́n bá sì ti rántí ìlú wọn, ńṣe ni wọ́n máa ń sunkún. (Ka Sáàmù 137:1-6.) Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni kò jẹ́ kí wọ́n jìnnà sí Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ èké àti àṣàkaṣà pọ̀ gan-an ní Bábílónì.
Ẹ̀KỌ́ MẸ́TALỌ́KAN TI BẸ̀RẸ̀ TIPẸ́
5. Kí ló fi hàn pé àwọn ará Bábílónì àtàwọn ará Íjíbítì ní ìgbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan?
5 Nígbà àtijọ́, àwọn èèyàn máa ń sin òrìṣà mẹ́ta pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, òrìṣà mẹ́ta táwọn ará Bábílónì máa ń sìn pa pọ̀ bí ẹyọ kan ni ọlọ́run òṣùpá, ọlọ́run oòrùn àti abo ọlọ́run ìbímọlémọ òun ogun. Àwọn ará Íjíbítì máa ń sin àwọn òrìṣà tí wọ́n gbà pé ìdílé kan ni wọ́n, ìyẹn ọlọ́run bàbá, ìyá àti ọmọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́run mẹ́ta tí wọ́n ń fi ojú ẹyọ kan ṣoṣo wò làwọn òrìṣà yìí, wọ́n gbà pé ìgbà míì wà tí wọ́n máa ń lágbára jura wọn lọ. Àpẹẹrẹ kan nílẹ̀ Íjíbítì ni ti Osiris tó jẹ́ ọlọ́run, Isis tó jẹ́ abo ọlọ́run àti Horus, tó jẹ́ ọmọ wọn ọkùnrin.
6. Kí ni Mẹ́talọ́kan? Kí nìdí tí àwa èèyàn Jèhófà ò fi gba Mẹ́talọ́kan gbọ́?
6 Lóde òní, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ àwọn èèyàn pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Wọ́n á ní Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́ ló para pọ̀ di Ọlọ́run. Ńṣe ni irú ẹ̀kọ́ yìí máa ń mú kó dà bíi pé agbára Jèhófà kò tó nǹkan torí pé ńṣe ló wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú ọlọ́run mẹ́ta tó para pọ̀ di ọ̀kan. Jèhófà ti gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké yìí. A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.” (Diu. 6:4) Jésù lo gbólóhùn yẹn léraléra. Àwa Kristẹni tòótọ́ sì gba ohun tó sọ gbọ́.—Máàkù 12:29.
7. Kí nìdí tí ẹni tó bá nígbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan kò fi lè ṣèrìbọmi?
7 Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ta ko àṣẹ tí Jésù pa fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” kí wọ́n sì “máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Mát. 28:19) Èyí túmọ̀ sí pé kí wọ́n tó lè ri ẹnì kan bọmi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́ kí ó sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ gbà pé Baba, ìyẹn Jèhófà, ní àṣẹ lórí Jésù, àti pé Jésù jẹ́ ọmọ Ọlọ́run tó rán wá sórí ilẹ̀ ayé láti wá rà wá pa dà. Kò ní ka ẹ̀mí mímọ́ sí ara Mẹ́talọ́kan. Ńṣe ló máa gbà pé agbára Ọlọ́run ló jẹ́. (Jẹ́n. 1:2) Torí náà, apá pàtàkì lára ogún tẹ̀mí wa ló jẹ́ láti mọ̀ pé ńṣe ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ń tàbùkù sí Jèhófà Ọlọ́run, kì í sì í ṣe ẹ̀kọ́ òtítọ́.
ÌBẸ́MÌÍLÒ
8. Kí ni àwọn ará Bábílónì gbà gbọ́ nípa àwọn òrìṣà àti àwọn ẹ̀mí èṣù?
8 Onírúurú nǹkan ni ẹ̀sìn àwọn ará Bábílónì fàyè gbà. Ó fàyè gba ẹ̀kọ́ èké, àwọn òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀mí èṣù àti ìbẹ́mìílò. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tiẹ̀ sọ pé àwọn ará Bábílónì
gbà pé àwọn ẹ̀mí èṣù lè fi àìsàn ṣe àwọn èèyàn. Torí náà, àwọn èèyàn máa ń bẹ àwọn òrìṣà tí wọ́n ń bọ pé kí wọ́n gba àwọn lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.9. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù ṣe kọ́ ẹ̀kọ́ èké nípa àwọn ẹ̀mí èṣù? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe gbà wá lọ́wọ́ ìbẹ́mìílò?
9 Ìgbà táwọn Júù wà ní Bábílónì ni ọ̀pọ̀ lára wọn ti kọ́ ẹ̀kọ́ èké nípa àwọn ẹ̀mí èṣù. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ọ̀pọ̀ lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fara mọ́ èrò àwọn Gíríìkì pé àwọn ẹ̀mí èṣù lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àmọ́, Ọlọ́run sọ fún wa pé ìbẹ́mìílò tàbí kéèyàn máa bá àwọn ẹ̀mí èṣù sọ̀rọ̀ léwu, kò sì dára. Ara ogún tẹ̀mí wa ni òye òtítọ́ yìí jẹ́. (Aísá. 47:1, 12-15) Torí náà, ohun tó ń mú kí Jèhófà dáàbò bò wá ni pé à ń ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ pé ká má ṣe lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò.—Ka Diutarónómì 18:10-12; Ìṣípayá 21:8.
10. Kí ni Bábílónì Ńlá? Ibo ni àṣàkaṣà àti ẹ̀kọ́ èké tó wà nínú ìsìn ti wá?
10 Bó ṣe rí ní Bábílónì ìgbàanì ló ṣe rí lóde òní pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn ló ń lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe gbogbo ìsìn èké tó wà lórí ilẹ̀ ayé ní Bábílónì Ńlá. (Ìṣí. 18:21-24) Ńṣe ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìsìn èké yìí dà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Bábílónì ìgbàanì, torí pé ibẹ̀ ni àwọn ẹ̀kọ́ èké àti àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ti ṣẹ̀ wá. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìbẹ́mìílò, ìbọ̀rìṣà àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì túbọ̀ ń gbilẹ̀ nínú Bábílónì Ńlá, Ọlọ́run máa pa á run láìpẹ́.—Ka Ìṣípayá 18:1-5.
11. Ìkìlọ̀ wo ni ètò Ọlọ́run ti fún wa nípa ìbẹ́mìílò nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa?
11 Jèhófà sọ pé òun “kò lè fara da lílo agbára abàmì.” (Aísá. 1:13) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò. Torí náà, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ti oṣù May, ọdún 1885 sọ pé: “Ẹ̀sìn táwọn èèyàn ń ṣe nígbà àtijọ́ kọ́ wọn pé àwọn òkú ṣì wà láàyè. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kárí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé ńṣe ni àwọn tó bá ti kú máa ń lọ gbé ní ayé míì.” Ìwé ìròyìn náà tún sọ síwájú sí i pé, àwọn ẹ̀mí èṣù tún máa ń dọ́gbọ́n ṣe bí ẹni tó ti kú, wọ́n á sì bá àwọn alààyè sọ̀rọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń pa irọ́ fún àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń mú wọn hùwà burúkú. Irú ìkìlọ̀ yìí tún wà nínú ìwé kékeré náà, What Say the Scriptures About Spiritism? àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde ẹnu àìpẹ́ yìí.
ṢÉ IBÌ KAN WÀ TÍ ÀWỌN ÒKÚ TI Ń JORÓ?
12. Kí ni Sólómọ́nì sọ nípa àwọn òkú?
12 Gbogbo àwọn tó ti “wá mọ òtítọ́” mọ̀ pé àwọn òkú kì í joró níbì kankan. (2 Jòh. 1) Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wà ní “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ipò òkú, ó sọ pé: “Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ. Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.”—Oníw. 9:4, 5, 10.
13. Ẹ̀kọ́ èké wo làwọn Júù gbà látọ̀dọ̀ àwọn Gíríìkì?
13 Jèhófà ti jẹ́ káwọn Júù mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá kú. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọ̀gágun ilẹ̀ Gíríìsì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ Júdà àti Síríà. Wọ́n gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn náà máa ṣe ẹ̀sìn àwọn Gíríìkì kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ wọn. Látàrí ìyẹn, àwọn Júù tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ èké àwọn Gíríìkì pé téèyàn bá kú ohun kan wà tó máa ń jáde nínú àgọ́ ara rẹ̀. Ohun tó bá jáde lára òkú yìí á wá máa lọ joró
nínú ayé míì. Àwọn Gíríìkì kọ́ ló kọ́kọ́ gbà gbọ́ pé ibì kan téèyàn ò lè fojú rí wà táwọn ọkàn ti máa ń joró. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé àwọn ará Bábílónì gbà pé ayé mìíràn kan wà tí àwọn ọlọ́run àtàwọn ẹ̀mí èṣù tó rorò gan-an ti máa ń dá àwọn èèyàn lóró. Ó ṣe kedere látinú èyí pé àwọn ará Bábílónì gbà gbọ́ pé ọkàn èèyàn kì í kú.—Ìwé The Religion of Babylonia and Assyria.14. Kí ni Jóòbù àti Ábúráhámù mọ̀ nípa ikú àti àjíǹde?
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì sí Bíbélì nígbà ayé Jóòbù, ó mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ipò táwọn òkú wà. Ó tún mọ̀ pé bí òun bá kú, Jèhófà Ọlọ́run máa jí òun dìde torí pé ó nífẹ̀ẹ́ òun. (Jóòbù 14:13-15) Ábúráhámù pẹ̀lú ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde. (Ka Hébérù 11:17-19.) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ẹni tó kú ló ṣeé jí dìde, wọn ò gbà gbọ́ nínú àìleèkú ọkàn. Ó dájú pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló mú kí Jóòbù àti Ábúráhámù mọ òtítọ́ nípa ipò táwọn òkú wà, tó sì tún mú kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú àjíǹde. Ara ogún tẹ̀mí wa lèyí jẹ́ pẹ̀lú.
A NÍLÒ “ÌTÚSÍLẸ̀ NÍPA ÌRÀPADÀ”
15, 16. Báwo ni Jèhófà ṣe gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?
15 Ó yẹ ká máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run tún jẹ́ ká mọ bí òun ṣe máa gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12) A mọ̀ pé Jésù “wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́ kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Máàkù 10:45) Ẹ sì wo bó ṣe dára tó láti mọ̀ nípa “ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san”!—Róòmù 3:22-24.
16 Ní ọ̀rúndún kìíní, ó pọn dandan pé kí àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù bí wọ́n bá fẹ́ rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ohun tí àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn. (Jòh. 3:16, 36) Bí ẹnì kan bá ṣì gba àwọn ẹ̀kọ́ èké bíi Mẹ́talọ́kan àti àìleèkú ọkàn gbọ́, kò lè jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà náà. Ṣùgbọ́n àwa lè jàǹfààní nínú rẹ̀ torí pé a mọ ẹni tí Ọmọ Ọlọ́run jẹ́, nípasẹ̀ rẹ̀ la “gba ìtúsílẹ̀ wa nípa ìràpadà” tá a sì rí “ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—Kól. 1:13, 14.
Ẹ MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ
17, 18. Ibo la ti lè rí ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ìtàn wa?
17 Àwọn nǹkan míì ṣì wà tó jẹ́ ara ogún tẹ̀mí wa. Lára wọn ni àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti kọ́ wa, títí kan àwọn ọ̀nà tó ti gbà ràn wá lọ́wọ́ tó sì fi ìbùkún sí iṣẹ́ ìsìn wa. Àwọn ìwé ọdọọdún wa ti jẹ́ ká mọ bí àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé ṣe ń bá a nìṣó láti máa sin Ọlọ́run. Àwọn ìwé ìròyìn wa máa ń sọ ìtàn ìgbésí ayé àwọn ará wa lọ́nà tó wọni lọ́kàn. Ìtàn nípa wa sì tún wà ní onírúurú èdè nínú àwọn ìtẹ̀jáde bíi Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom àtàwọn fídíò wa náà, Faith in Action, Apá Kìíní àti Ìkejì.
18 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rántí bí Jèhófà ṣe dá wọn nídè lóko ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì. Bákan náà, ó yẹ kí àwa pẹ̀lú máa ka ìtàn nípa ètò Jèhófà nítorí pé ó máa ṣe wa láǹfààní. (Ẹ́kís. 12:26, 27) Lẹ́yìn tí Mósè ti di arúgbó, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Rántí àwọn ọjọ́ láéláé, ẹ ronú nípa àwọn ọdún tí ó ti kọjá láti ìran dé ìran; béèrè lọ́wọ́ baba rẹ, ó sì lè sọ fún ọ; àwọn àgbà rẹ, wọ́n sì lè sọ ọ́ fún ọ.” (Diu. 32:7) Gbogbo wa ń fi ayọ̀ yin Ọlọ́run a sì ń sọ fún àwọn èèyàn nípa àwọn ohun tó ti ṣe. (Sm. 79:13) Àwọn ẹ̀kọ́ tá a bá kọ́ nínú ìtàn wa á jẹ́ ká lè máa bá a nìṣó láti sin Ọlọ́run.
19. Níwọ̀n bá a ti mọ òtítọ́, kí ló yẹ ká ṣe?
19 Nínú ayé búburú yìí, a dúpẹ́ pé Ọlọ́run kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ òtítọ́. (Òwe 4:18, 19) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì máa wàásù fún àwọn èèyàn. Ká dà bí onísáàmù tó fìyìn fún Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, tó sì sọ pé: “Èmi yóò máa mẹ́nu kan òdodo rẹ, tìrẹ nìkan. Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá, títí di ìsinsìnyí, mo sì ń bá a nìṣó ní sísọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ. Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀, títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran náà, fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀, nípa agbára ńlá rẹ.”—Sm. 71:16-18.
20. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà? Níwọ̀n bó o ti mọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso wa, báwo ló ṣe rí lára rẹ?
20 Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Torí pé ó jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé òun nìkan ṣoṣo ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso wa àti pé òun ló yẹ ká máa sìn. (Ìṣí. 4:11) Jèhófà ń fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Ìhìn rere yìí ń tù wọ́n nínú ó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (Aísá. 61:1, 2) Bó ti wù kí Sátánì gbìyànjú tó láti ṣàkóso àwa èèyàn Ọlọ́run àti gbogbo aráyé, kò lè ṣàṣeyọrí. Ogún tẹ̀mí wa yìí ń mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, ó sì tún ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti máa sin Jèhófà ní báyìí àti títí láé.—Ka Sáàmù 26:11; 86:12.