Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ran Ara Rẹ Àti Àwọn Míì Lọ́wọ́
“Mo [ti] ka gbogbo àṣẹ ìtọ́ni nípa ohun gbogbo sí èyí tí ó tọ̀nà.”—SM. 119:128.
1. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣiyè méjì nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
KÍ ẸNÌ kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó bẹ̀rẹ̀ sí lọ sóde ẹ̀rí, ó gbọ́dọ̀ fi hàn pé òun gbà gbọ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. * Ó yẹ kí gbogbo wa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa pé a gba ohun tó wà nínú Bíbélì gbọ́. Tó bá jẹ́ pé a kì í ṣiyè méjì rárá nípa ohun tó wà nínú Bíbélì, tá a sì mọ̀ ọ́n lò dáadáa lóde ẹ̀rí, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kí wọ́n sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ‘bá a lọ nínú àwọn ohun tí a ti kọ́’?
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú kó ṣe kedere pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì. Ó sọ fún Tímótì pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́.” “Àwọn ohun” tí Tímótì ti kọ́ ni àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó mú kó ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere. Ohun tí àwa náà ti kọ́ nínú Bíbélì lè mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún lè mú ká jẹ́ “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” (2 Tím. 3:14, 15) Ohun tí Pọ́ọ̀lù tún sọ ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e fi hàn pé Ọlọ́run ló fún wa ní Bíbélì. Àmọ́, kí la tún lè rí kọ́ nínú 2 Tímótì 3:16. (Kà á.) Ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Bíbélì yẹn, èyí á sì mú kí ọkàn wa túbọ̀ balẹ̀ pé gbogbo ohun tí Jèhófà ń kọ́ wa ló “tọ̀nà.”—Sm. 119:128.
Ó “ṢÀǸFÀÀNÍ FÚN KÍKỌ́NI”
3-5. (a) Kí làwọn èèyàn ṣe lẹ́yìn tí Pétérù ti sọ àsọyé fún àwùjọ ńlá kan ní Pẹ́ńtíkọ́sì, kí sì nìdí? (b) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi di Kristẹni ní Tẹsalóníkà? (d) Kí ló máa ń wú àwọn èèyàn lórí nígbà tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́?
3 Jésù sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Èmi ń rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn àti àwọn olùkọ́ni ní gbangba jáde sí yín.” (Mát. 23:34) Àwọn tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn níbí ni àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tí wọ́n ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè máa lo Ìwé Mímọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pétérù tó jẹ́ ọ̀kan lára wọn sọ àsọyé fún àwùjọ ńlá kan ní Jerúsálẹ́mù. Inú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ló sì ti mú ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó sọ jáde. Nígbà táwọn èèyàn gbọ́ bí Pétérù ṣe ṣàlàyé àwọn ẹsẹ yẹn, ọ̀pọ̀ lára wọn kábàámọ̀ pé àwọn ti ṣe àwọn nǹkan tí kò tọ́. Torí náà, wọ́n ronú pìwà dà, wọ́n sì bẹ Ọlọ́run pé kó dárí ji àwọn. Lọ́jọ́ yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta lára wọn ló di Kristẹni.—Ìṣe 2:37-41.
4 A tún lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wàásù ìhìn rere láwọn ìlú mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń wàásù ní Makedóníà tó wà ní ìlú Tẹsalóníkà, ó bá àwọn Júù kan tó ń jọ́sìn nínú sínágọ́gù sọ̀rọ̀. Ní Sábáàtì mẹ́ta, Pọ́ọ̀lù “bá wọn fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́” kó lè fi dá wọn lójú pé “ó pọndandan kí Kristi jìyà, kí ó sì dìde kúrò nínú òkú.” Kí wá ni àbájáde ìwàásù Pọ́ọ̀lù? Àwọn kan lára àwọn Júù tó wàásù fún di onígbàgbọ́, títí kan ọ̀pọ̀ lára àwọn Gíríìkì.—Ìṣe 17:1-4.
5 Lóde òní, ó máa ń wú ọ̀pọ̀ èèyàn lórí bí wọ́n ṣe ń kíyè sí i pé Bíbélì la fi ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ wa nígbà tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Arábìnrin wa kan ní orílẹ̀-èdè Switzerland ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nígbà tó wà lóde ẹ̀rí, ọkùnrin tó ń wàásù fún wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣọ́ọ̀ṣì wo ló ń lọ. Arábìnrin náà sọ fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. Ọkùnrin náà sọ pé: “Kò tiẹ̀ yẹ kí n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè. Ta ni ì bá tún wá ka Bíbélì fún mi nínú ilé mi bí kò ṣe ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà?”
6, 7. (a) Báwo ló ṣe yẹ káwọn tó ń kọ́ni nínú ìjọ máa lo Bíbélì? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo Bíbélì lọ́nà tó gbésẹ̀ nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
6 Báwo la ṣe lè máa lo Bíbélì lọ́nà tó gbéṣẹ́ nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Bó o bá ní àsọyé tàbí iṣẹ́ míì lórí pèpéle, pinnu àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtó tó o máa lò. Tó o bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ, má kàn fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ láti kín kókó tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí lẹ́yìn, ńṣe ni kó o kà á jáde. Dípò tí wàá fi ka ẹsẹ Bíbélì náà jáde látinú ìwé kan tó o kọ gbogbo rẹ̀ sí, tàbí látinú ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà kékeré kan, tàbí látorí fóònù, ńṣe ni kó o kà á jáde látinú Bíbélì. Sọ fún àwọn tó wà láwùjọ pé káwọn náà ṣí Bíbélì tiwọn. Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì náà àti bí wọ́n ṣe lè ran àwùjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Dípò tí wàá fi máa lo àwọn àpèjúwe tó ṣòro láti lóye tàbí àwọn ìrírí tó kàn ń pani lẹ́rìn-ín lásán, ńṣe ni kó o fi àkókò yẹn ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
7 Kí ló yẹ ká máa rántí nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́, kò yẹ ká máa gbójú fo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tọ́ka sí àmọ́ tí wọn kò fa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yọ. Ó yẹ ká jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, kó sì lóye rẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Kì í ṣe pé a óò wá bẹ̀rẹ̀ àlàyé rẹpẹtẹ o. Ṣùgbọ́n a óò jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ èrò rẹ̀. Dípò tí a ó fi sọ ohun tó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ gbà gbọ́ fún un tàbí ohun tó yẹ kó ṣe, ńṣe ni ká bi í láwọn ìbéèrè tó máa mú kó ronú jinlẹ̀, kó bàa lè ṣe ìpinnu tó tọ́. *
Ó ṢÀǸFÀÀNÍ FÚN “FÍFI ÌBÁWÍ TỌ́NI SỌ́NÀ”
8. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní láti bá jagun?
8 Ojúṣe àwọn alàgbà ìjọ ni láti bá àwọn tó bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà wí. (1 Tím. 5:20; Títù 1:13) Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí àwa fúnra wa máa bá ara wa wí. Kristẹni tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere ni Pọ́ọ̀lù, ó sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (2 Tím. 1:3) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù ní ohun kan tó ń bá a jagun. Ó sọ pé: “Mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.” Wàyí o, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Pọ́ọ̀lù ní láti ṣe kó bàa lè borí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń bá a jagun.—Ka Róòmù 7:21-25.
9, 10. (a) Àwọn àìlera wo ló ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ní? (b) Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù máa gbà kojú àìlera tó ń bá a jagun?
1 Tím. 1:13) Kí Pọ́ọ̀lù tó yí pa dà, ó ti hùwà tí kò dára sí àwọn Kristẹni. Ó sọ pé “orí” òun “gbóná sí wọn dé góńgó.” (Ìṣe 26:11) Pọ́ọ̀lù kọ́ bó ṣe lè kápá ìbínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kó ṣì máa ṣiṣẹ́ kára láti kápá ìmọ̀lára àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. (Ìṣe 15:36-39) Kí ló ràn án lọ́wọ́?
9 Pọ́ọ̀lù ò sọ ohun tó jẹ́ àìlera rẹ̀, àmọ́ ó sọ pé òun jẹ́ “aláfojúdi.” Ìyẹn ni pé ó jẹ́ aláìlọ́wọ̀. (10 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó ṣàlàyé bí òun ṣe máa ń bá ara òun wí. (Ka 1 Kọ́ríńtì 9:26, 27.) Pọ́ọ̀lù ò gbà lẹ́rọ̀ fún àwọn àìlera tó ń mú un dẹ́ṣẹ̀. Ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ló máa ń wá àwọn ìtọ́ni tó lè ràn án lọ́wọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Ó máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kóun lè fi àwọn ìtọ́ni náà sílò. Lẹ́yìn náà, á wá ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà tó rí gbà. * A lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù torí pé àwa náà ní àwọn àìlera kan tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀, èyí tó yẹ ká máa sapá láti ṣẹ́pá rẹ̀.
11. Báwo la ṣe lè “máa dán ara [wa] wò” ká lè mọ̀ bóyá à ń rìn nínú òtítọ́?
11 A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa wá nǹkan ṣe sí àwọn àìlera tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. A gbọ́dọ̀ “máa dán ara [wa] wò” ká lè rí i dájú pé à ń rìn nínú òtítọ́. (2 Kọ́r. 13:5) Tá a bá ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Kólósè 3:5-10, a lè bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mò ń sa gbogbo ipá mi kí n lè máa borí àwọn àìlera tó lè mú mi dẹ́ṣẹ̀? Ṣé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tí Jèhófà sọ pé kò dára? Bí àpẹẹrẹ, bí mo bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, tí mo sì ṣàdédé bá ara mi lórí ìkànnì tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ, ǹjẹ́ mo máa ń kúrò lórí ìkànnì náà àbí ńṣe ni mo máa ń tú u wò?’ Tá a bá ń ronú nípa bá a ṣe lè máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú gbogbo nǹkan tá a bá ń ṣe, a máa “wà lójúfò” a ó sì lè “pa agbára ìmòye wa mọ́.”—1 Tẹs. 5:6-8.
Ó ṢÀǸFÀÀNÍ FÚN “MÍMÚ ÀWỌN NǸKAN TỌ́”
12, 13. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti mú àwọn nǹkan tọ́? Bíi ti Jésù, báwo la ṣe lè máa mú àwọn nǹkan tọ́? (b) Tá a bá fẹ́ mú àwọn nǹkan tọ́ pẹ̀lú ẹnì kan, irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ni kò yẹ ká máa sọ?
12 Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa “mímú àwọn nǹkan tọ́,” ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn mú kí nǹkan wà bó ṣe yẹ kó rí tàbí kéèyàn tún ohun tí kò tọ́ ṣe. Nígbà míì, ó lè gba pé ká mú nǹkan tọ́ bí ẹnì kan bá ṣì wá lóye tàbí tó ṣì wá gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ń ṣàròyé pé ńṣe ló yẹ kí Jésù máa le koko mọ́ “àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Jésù wá sọ fún wọn pé: “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀. Ẹ lọ, nígbà náà, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí èyí túmọ̀ sí, ‘Àánú ni èmi fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ.’” (Mát. 9:11-13) Jésù fi sùúrù àti ìwà pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Èyí sì wá mú káwọn èèyàn náà mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, pé ó jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹ́kís. 34:6) Látàrí ìyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.
13 A gbọ́dọ̀ fìwà jọ Jésù tá a bá fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Òótọ́ ni pé 2 Tímótì 3:16 sọ pé Ìwé Mímọ́ ṣàǹfààní fún mímú àwọn nǹkan tọ́. Ṣùgbọ́n a ò gbọ́dọ̀ máa sọ̀rọ̀ líle sáwọn èèyàn nígbà tá a bá fẹ́ mú àwọn nǹkan tọ́ pẹ̀lú wọn. Ìwé Mímọ́ ò sọ pé ká kàn máa sọ̀rọ̀ gbàùgbàù sí àwọn èèyàn láìbìkítà nípa bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn. Tá a bá sọ̀rọ̀ sí ẹni kan lọ́nà líle koko, ọ̀rọ̀ wa lè dà bí “ìgúnni idà.” A lè ba irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́kàn jẹ́, ìyẹn ò sì ní ṣe é láǹfààní kankan.—Òwe 12:18.
14-16. (a) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè mú àwọn nǹkan tọ́ lọ́nà tí àwọn ẹlòmíì á fi lè yanjú àwọn ìṣòro wọn? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn òbí máa lo Ìwé Mímọ́ láti mú àwọn nǹkan tọ́ nínú ìdílé?
14 Báwo la ṣe lè máa fi sùúrù àti ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ mú àwọn nǹkan tọ́? Jẹ́ ká sọ pé tọkọtaya kan máa ń bára wọn jiyàn lemọ́lemọ́. Wọ́n wá ní kí alàgbà kan ran àwọn lọ́wọ́. Kí ló yẹ kí alàgbà náà ṣe? Kò yẹ kó gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni nínú àwọn méjèèjì, kò sì yẹ kó sọ èrò tiẹ̀ nípa ìṣòro wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kó fi àwọn ìlànà Bíbélì ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe máa fòpin sí iyàn jíjà náà. Ó lè lo àwọn ìlànà tó wà ní orí kẹta nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Bí alàgbà yìí bá ṣe ń jíròrò àwọn ìlànà náà pẹ̀lú wọn, tọkọtaya náà lè bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé ó yẹ káwọn ṣe àwọn ìyípadà kan. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, alàgbà náà lè béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ sí lọ́wọ́ tọkọtaya náà. Ó tún lè ràn wọ́n lọ́wọ́ síwájú sí i, tó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.
15 Báwo làwọn òbí ṣe lè mú nǹkan tọ́ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́? Jẹ́ ká sọ pé ọmọ rẹ obìnrin ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ọ̀rẹ́ kan, tó o sì ń kọminú nípa ọ̀rẹ́ tuntun náà. Ńṣe ló yẹ kó o kọ́kọ́ wádìí irú ẹni tí ọ̀rẹ́ náà jẹ́. Tó o bá wá rí i pé ó léwu tí ọmọ rẹ bá ń bá onítọ̀hún ṣọ̀rẹ́, o lè bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀. O lè lo àwọn ìlànà Bíbélì tó wà nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì. Lẹ́yìn náà, rí i dájú pé o tún bá a sọ̀rọ̀ dáadáa. O lè máa kíyèsí bó ṣe ń ṣe tẹ́ ẹ bá jọ wà lóde ẹ̀rí tàbí bó ṣe máa ń ṣe sí àwọn míì nínú ilé. Tó o bá ń fi sùúrù àti ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ bá ọmọ náà sọ̀rọ̀, á mọ̀ pé o fẹ́ràn òun àti pé ọ̀rọ̀ òun jẹ ọ́ lógún. Èyí lè mú kó tẹ̀ lé ohun tó o sọ fún un, kò sì ní ṣe àwọn ìpinnu tó lè ṣàkóbá fún un.
16 Ta ló tún lè nílò ìrànlọ́wọ́ wa? A tún lè fi sùúrù àti ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ mú àwọn nǹkan tọ́ nígbà táwọn míì bá ń ṣàníyàn jù nípa ìlera wọn, bí wọ́n bá soríkọ́ torí pé iṣẹ́ bọ́
lọ́wọ́ wọn, tàbí tó bá ṣòro fún wọn láti fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ kan nínú Bíbélì. Tá a bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú àwọn nǹkan tọ́, gbogbo wa la máa jàǹfààní tó pọ̀.Ó ṢÀǸFÀÀNÍ FÚN “BÍBÁNIWÍ NÍNÚ ÒDODO”
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ìbáwí tí wọ́n bá fún wa?
17 Bíbélì sọ pé: “Kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Héb. 12:11) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú òtítọ́ lè jẹ́rìí sí i pé ìbáwí táwọn òbí wọn fún wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an ni. Tá a bá sì gba ìbáwí tí Jèhófà ń tipasẹ̀ àwọn alàgbà fún wa, a ò ní yà kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè.—Òwe 4:13.
18, 19. (a) Kí àwọn alàgbà lè báni wí nínú òdodo, kí nìdí tí ìtọ́ni inú Òwe 18:13 fi ṣe pàtàkì? (b) Bí àwọn alàgbà bá ń ṣe pẹ̀lẹ́ tí wọ́n sì ń fìfẹ́ hàn nígbà tí wọ́n bá ń báni wí, kí ló sábà máa ń yọrí sí?
18 Báwo ni àwọn alàgbà àtàwọn òbí ṣe lè máa báni wí lọ́nà tó gbéṣẹ́? Jèhófà sọ fún wa pé ká máa báni wí “nínú òdodo.” (2 Tím. 3:16) Èyí túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ máa lo àwọn ìlànà Bíbélì nígbà tá a bá ń báni wí. Ọ̀kan lára irú ìlànà bẹ́ẹ̀ wà nínú Òwe 18:13 tó sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.” Torí náà, bí ẹnì kan bá sọ fún alàgbà pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn rídìí òkodoro òtítọ́ kí wọ́n tó bá onítọ̀hún wí. (Diu. 13:14) Ìgbà yẹn ni wọ́n tó lè báni wí “nínú òdodo.”
19 Bíbélì tún sọ pé káwọn alàgbà máa báni wí “pẹ̀lú ìwà tútù.” (Ka 2 Tímótì 2:24-26.) Òótọ́ ni pé ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan dá lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà tàbí kó ṣèpalára fáwọn ẹlòmíì. Síbẹ̀, bí alàgbà kan bá fìbínú bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ wí, kò ní lè ràn án lọ́wọ́. Bí alàgbà kan bá fìwà jọ Ọlọ́run, tó sì sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù, ìyẹn lè mú kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà.—Róòmù 2:4.
20. Àwọn ìlànà wo ló yẹ káwọn òbí máa fi sílò tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí?
20 Ó yẹ káwọn òbí náà máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí. (Éfé. 6:4) Bí àpẹẹrẹ, kí ló yẹ kí òbí kan ṣe bí ẹnì kan bá wá fẹjọ́ ọmọ rẹ̀ sùn? Bàbá náà gbọ́dọ̀ rí i pé òun rí àrídájú ọ̀rọ̀ náà kó tó fìyà jẹ ọmọ náà. Àwa Kristẹni ò sì gbọ́dọ̀ máa bínú débi tí a ó fi na ọmọ ṣe léṣe tàbí ká lù ú bí ẹni máa pa á. “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú,” ó sì yẹ káwọn òbí fìwà jọ ọ́ nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí.—Ják. 5:11.
BÍBÉLÌ JẸ́ Ẹ̀BÙN IYEBÍYE LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN
21, 22. Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 119:97-104 lo máa fi ṣàlàyé ojú tó o fi ń wo Ọ̀rọ̀ Jèhófà??
21 Nígbà kan, ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan sọ ìdí tó fi fẹ́ràn òfin Jèhófà. (Ka Sáàmù 119:97-104.) Bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó di ọlọgbọ́n, ó sì tún ní òye tó jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan. Nígbà tó tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́, kò ṣe irú àṣìṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe. Inú rẹ̀ máa dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bó sì ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà níbẹ̀ máa ń ṣe é láǹfààní. Ó pinnu pé níwọ̀n ìgbà tí òun bá ṣì wà láàyè, òfin Ọlọ́run lòun á máa pa mọ́.
22 Ṣé ìwọ náà gbà pé ẹ̀bùn iyebíye ni Bíbélì? Ó lè mú kó o ní ìgbàgbọ́ tó lágbára pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà fún wa nínú Bíbélì, o ò ní sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, èyí tó lè yọrí sí ikú. Wàá tún lè fi Bíbélì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá sójú ọ̀nà ìyè, kí wọ́n má sì ṣe yà kúrò nínú rẹ̀. Torí náà, bá a ṣe ń sin Jèhófà Ọlọ́run wa tó jẹ́ ọlọgbọ́n àti onífẹ̀ẹ́, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti lo Bíbélì ní gbogbo ọ̀nà tá a jíròrò yìí.
^ ìpínrọ̀ 1 Wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 79.
^ ìpínrọ̀ 7 Bí Jésù bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ó sábà máa ń bi wọ́n pé: “Kí ni ẹ̀yin rò?” Lẹ́yìn náà, á wá gbọ́ èrò wọn.—Mát. 18:12; 21:28; 22:42.
^ ìpínrọ̀ 10 Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìyànjú ló wà nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù nípa bá a ṣe lè sá fún àwọn ohun tó lè mú wa dẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 6:12; Gál. 5:16-18) Ó bọ́gbọ́n mu fún wa láti gbà pé òun tó ń sọ fáwọn ẹlòmíì lòun náà ń ṣe.—Róòmù 2:21.