Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀ Kẹ́ Ẹ Lè Túbọ̀ Ṣera Yín Lọ́kan

Ẹ Máa Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀ Kẹ́ Ẹ Lè Túbọ̀ Ṣera Yín Lọ́kan

“Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.”—ÒWE 25:11.

1. Àǹfààní wo ni àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa ti rí?

ARÁKÙNRIN kan ní Kánádà sọ pé, “Ó máa ń wù mí pé kí n wà pẹ̀lú ìyàwó mi ju kí n wà pẹ̀lú ẹlòmíì. Ńṣe ló máa ń dà bíi pé eéwo mi tú, ara á sì tù mí pẹ̀sẹ̀ bí èmi àtìyàwó mi bá ti wà pa pọ̀, inú mi sì máa ń dùn gan-an.” Ọkùnrin kan ní Ọsirélíà sọ nípa ìyàwó rẹ̀ pé: “Ọdún kọkànlá rèé tí èmi àtìyàwó mi ti ṣègbéyàwó, kò sì tíì ṣẹlẹ̀ rí pé kí ọjọ́ kan lọ, ká má jọ sọ̀rọ̀.” Ó tún sọ pé báwọn ṣe jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa ti mú kí àwọn fọkàn tán ara àwọn gan-an, ó sì ti mú kí àárín àwọn túbọ̀ gún régé. Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Costa Rica sọ ní tiẹ̀ pé: “Bí èmi àti ọkọ mi ṣe jọ máa ń sọ̀rọ̀ mú kí àárín wa gún. Yàtọ̀ síyẹn, kò jẹ́ ká ṣubú sínú ìdẹwò, ó mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, a mọ inú ara wa, ó sì tún mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa.”

2. Àwọn nǹkan wo ni kì í jẹ́ kí tọkọtaya ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó dán mọ́rán?

2 Ṣé ìwọ àti ọkọ́ tàbí aya rẹ jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa àbí ẹ kì í fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ ara yín yé? Kò sí àní-àní, ìwọ àti aya tàbí ọkọ rẹ lè má gbọ́ ara yín yé láwọn ìgbà míì. Ìdí ni pé aláìpé lẹ̀yin méjèèjì, ìwà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ ní, ilé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti tọ́ yín dàgbà, àṣà ìbílẹ̀ yín sì tún lè yàtọ̀ síra. (Róòmù 3:23) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, bí kálukú ṣe máa ń sọ̀rọ̀ yàtọ̀ síra. Abájọ tí John M. Gottman àti Nan Silver tí wọ́n ṣèwádìí nípa ìgbéyàwó fi sọ pé tọkọtaya gbọ́dọ̀ sapá gan-an, kí ó lè ṣeé ṣe fún wọn láti jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa, kí ìgbéyàwó wọn sì wà pẹ́ títí.

3. Kí ló mú kí àwọn tọkọtaya kan lè ṣera wọn lọ́kan?

3 Kò rọrùn kí tọkọtaya ṣera wọn lọ́kan, àmọ́ tí wọ́n bá sapá gidigidi, ìgbéyàwó wọn á ládùn á sì lóyin. (Oníw. 9:9) Àpẹẹrẹ kan ni ti ìgbéyàwó Ísákì àti Rèbékà. (Jẹ́n. 24:67) Bíbélì jẹ́ ka mọ̀ pé títí dọjọ́ ogbó wọn, ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ara wọn kò yingin. Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí fún ọ̀pọ̀ tọkọtaya lónìí náà nìyẹn. Kí ni wọ́n ṣe tí ọ̀rọ̀ wọn fi wọ̀ bẹ́ẹ̀? Wọ́n jẹ́ kó mọ́ àwọn lára láti máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn àti bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn, láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Àmọ́, wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Wọ́n tún máa ń lo ìjìnlẹ̀ òye, wọ́n máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ tìfẹ́tìfẹ́, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò báwọn ànímọ́ yìí ṣe lè mú kí tọkọtaya máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà.

Ẹ MÁA LO ÌJÌNLẸ̀ ÒYE

4, 5. Báwo ni ìjìnlẹ̀ òye ṣe lè mú kí tọkọtaya túbọ̀ lóye ara wọn? Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan.

4 Òwe 16:20 sọ pé, “Ẹni tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú ọ̀ràn yóò rí ire.” Èyí mú kó dáni lójú pé bí tọkọtaya bá ń lo ìjìnlẹ̀ òye, wọ́n á rí ire nínú ìdílé wọn. (Ka Òwe 24:3.) Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan la ti lè rí ojúlówó ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n. Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 2:18 sọ pé àṣekún ni aya jẹ́ sí ọkọ rẹ̀. Èyí fi hàn pé ànímọ́ ọkùnrin yàtọ̀ sí ti obìnrin, àmọ́ tí àwọn méjèèjì bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọ́n á ṣera wọn lọ́kan. Ọ̀nà táwọn obìnrin gbà ń sọ̀rọ̀ yàtọ̀ sí tọkùnrin. Àwọn obìnrin sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe rí lára wọn, wọ́n sì tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlòmíì. Wọ́n máa ń fẹ́ sọ tinú wọn fún ẹni tó máa lóye wọn, tó sì máa gba tiwọn rò. Ẹni tó bá ń fara balẹ̀ fetí sí wọn tó sì gba tiwọn rò ni wọ́n gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọkùnrin ni kì í fẹ́ sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe àtèyí tí wọ́n máa ṣe, àwọn ìṣòro tó yọjú àtohun tí wọ́n lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà. Bákan náà, àwọn ọkùnrin máa ń fẹ́ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn.

5 Arábìnrin kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé, “Ọkọ mi kì í jẹ́ kí n sọ gbogbo tinú mi délẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń já lu ọ̀rọ̀ mi, á sì ní ká sọ bá a ṣe máa yanjú ìṣòro náà. Èyí sì máa ń múnú bí mi gan-an. Ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó tẹ́tí sí mi, kí ó sì mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi.” Ọkùnrin kan sọ pé: “Nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, tí ìyàwó mi bá ń sọ ìṣòro ẹ̀ fún mi, mi ò kì í lè fara balẹ̀ tó láti gbọ́ gbogbo àlàyé rẹ̀, bí mo ṣe máa yanjú ìṣòro náà ló máa ń gbà mí lọ́kàn. Àmọ́, mo wá rí i pé ohun tó fẹ́ gan-an ni pé kí n máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí i.” (Òwe 18:13; Ják. 1:19) Ọkọ tó bá ní ìjìnlẹ̀ òye máa ń kíyè sí bọ́rọ̀ ṣé rí lára ìyàwó rẹ̀, ó sì máa ń hùwà lọ́nà tí ìyàwó náà á fi gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ òun. Ó máa ń jẹ́ kó dá ìyàwó rẹ̀ lójú pé òun gba tiẹ̀ rò àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ òun lógún. (1 Pét. 3:7) Bákan náà, ìyàwó tó ní ìjìnlẹ̀ òye á máa sapá láti lóye ọkọ rẹ̀. Bí tọkọtaya bá lóye ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ojúṣe wọn, tí wọ́n sì ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, wọ́n á láyọ̀, wọ́n á sì máa ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.

6, 7. (a) Báwo ni ìlànà tó wà nínú Oníwàásù 3:7 ṣe lè mú kí tọkọtaya máa lo ìjìnlẹ̀ òye? (b) Báwo ni aya ṣe lè máa fòye mọ bí nǹkan ṣe rí lára ọkọ rẹ̀? Ìsapá wo ló yẹ kí ọkọ ṣe?

6 Tọkọtaya tó ní ìjìnlẹ̀ òye mọ̀ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníw. 3:1, 7) Arábìnrin kan tó ti wà lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ fún ọdún mẹ́wàá sọ pé òun ti wá mọ̀ pé ó yẹ kí òun mọ ìgbà tó tọ́ láti máa bá ọkọ òun sọ ohun tó ń jẹ òun lọ́kàn. Tó bá kíyè sí pé iṣẹ́ ti wọ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn, ńṣe ló máa ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ dìgbà míì. Nígbà tí wọ́n bá wá ráyè sọ̀rọ̀, wọ́n máa ń gbádùn ìjíròrò wọn gan-an. Torí náà, tí aya kan bá ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń tuni lára, tó sì ń sọ ọ́ “ní àkókò tí ó tọ́,” inú ọkọ rẹ̀ á dùn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Ka Òwe 25:11.

Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn nǹkan tó dà bíi pé kò jọjú yìí máa ń ṣe nínú ìgbéyàwó

7 Ó yẹ kí ọkọ máa tẹ́tí sí ohun tí ìyàwó rẹ̀ ní láti sọ, ó sì yẹ kóun náà sapá láti máa sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ fún un. Alàgbà kan tó ti ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] sọ pé: “Kì í rọrùn fun mi rárá láti jẹ́ kí ìyàwó mi mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára mi, mo ní láti sapá gan-an.” Arákùnrin kan tóun àtìyàwó rẹ̀ ti wà pa pọ̀ fún ọdún mẹ́rìnlélógún [24] sọ pé òun kì í fẹ́ láti máa sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tí òun ní, torí pé ó gbà pé tó bá yá òun á gbàgbé rẹ̀. Àmọ́, ó sọ pé, “Mó ti wá gbà pé kò burú tí mo bá sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi fún ìyàwó mi. Tó bá ṣòro fún mi láti sọ̀rọ̀ náà, mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n mọ bí màá ṣe sọ ọ́. Lẹ́yìn náà, màá ṣọkàn gírí, màá wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀.” Ohun míì tó tún ṣe pàtàkì ni kí tọkọtaya mọ àkókò tó dáa láti sọ̀rọ̀, bóyá nígbà táwọn méjèèjì jọ ń jíròrò ẹsẹ ojoojúmọ́ tàbí tí wọ́n ń ka Bíbélì pa pọ̀.

8. Kí ni nǹkan tó lè mú kí tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ àtimáa bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà?

8 Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn tọkọtaya kan láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà torí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀. Torí náà, á dára kí tọkọtaya máa gbàdúrà fún ẹ̀mí Ọlọ́run, kí wọ́n sì jẹ́ kó túbọ̀ máa wù wọ́n gan-an láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà. Bí tọkọtaya bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n ń ṣe ohun tó wù ú, tí wọ́n sì ń fi ojú tó tọ́ wo ìgbéyàwó wọn, ó dájú pé ó máa wù wọ́n gan-an láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà. Arábìnrin kan tòun àtọkọ rẹ̀ ti wà pa pọ̀ fún ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] sọ pé: “Ojú tí Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó lèmi àti ọkọ mi fi ń wò ó, torí bẹ́ẹ̀, kò sígbà tá a ronú pé a fẹ́ pínyà. Nípa bẹ́ẹ̀, á máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wá àyè jíròrò nípa àwọn ìṣòro wa ká sì yanjú wọn.” Nítorí náà, bí àwọn tọkọtaya bá ń fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó wò ó, tí wọ́n sì ṣera wọn lọ́kan, wọ́n á múnú Ọlọ́run dùn. Ọlọ́run náà sì máa bù kún wọn.—Sm. 127:1.

Ẹ JẸ́ KÍ ÌFẸ́ YÍN MÁA LÁGBÁRA SÍ I

9, 10. Àwọn nǹkan pàtó wo ni tọkọtaya lè máa ṣe táá mú kí okùn ìfẹ́ wọn túbọ̀ lágbára?

9 Ìfẹ́ ni ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbéyàwó. Bíbélì sọ pé ìfẹ́ jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kól. 3:14) Ńṣe ni okùn ìfẹ́ tòótọ́ máa ń lágbára sí i bí tọkọtaya ṣe túbọ̀ ń gbé pọ̀, yálà nígbà dídùn tàbí nígbà kíkan. Wọ́n á túbọ̀ di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn, inú wọn sì máa ń dùn láti wà pa pọ̀. Irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n máa ń ṣe nínú fíìmù. Ní ti àwọn tọkọtaya inú fíìmù, ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ni wọ́n máa ń ṣe nǹkan fún ara wọn láti fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àmọ́, ní ti ìgbéyàwó àwọn Kristẹni, ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹnì kejì wọn, bó ti wù kó kéré mọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń dì mọ́ra, wọ́n máa ń gbóríyìn fún ara wọn, wọ́n máa ń di ara wọn lọ́wọ́ mú, wọ́n máa ń rẹ́rìn-ín síra tàbí kí wọ́n máa béèrè bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe rí lọ́wọ́ ara wọn. Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn nǹkan tó dà bíi pé kò jọjú yìí máa ń ṣe nínú ìgbéyàwó. Tọkọtaya kan tó ti wà pa pọ̀ fún ọdún mọ́kàndínlógún [19] máa ń pe ara wọn lórí fóònù tàbí kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra kí wọ́n lè béèrè àlàáfíà ara wọn.

10 Àwọn tọkọtaya tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn máa ń sapá láti túbọ̀ mọ ìwà ara wọn. (Fílí. 2:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ aláìpé, tí wọ́n bá ń sapá láti túbọ̀ mọ ara wọn, okùn ìfẹ́ wọn á túbọ̀ lágbára. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ni ìfẹ́ tó wà láàárín tọkọtaya tó mọwọ́ ara wọn máa ń lágbára sí i. Torí náà, tó o bá ti ṣègbéyàwó, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo mọ ọkọ tàbí aya mi dáadáa? Ṣé mo mọ bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ̀? Ṣé mo mọ ohun tó lè ṣe lábẹ́ ipò kan? Ǹjẹ́ mo ṣì máa ń ronú nípa àwọn ànímọ́ tó wù mí lára rẹ̀ kó tó di pé a fẹ́ra?’

Ẹ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÚN ARA YÍN

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn? Sọ àpẹẹrẹ kan.

11 A kì í mọ̀-ọ́n-rìn, kí orí ó má mì. Kódà àwọn tọkọtaya tí ìfẹ́ wọn jinlẹ̀ gan-an pàápàá máa ń ní èdèkòyédè. Ìgbà kan wà tí Ábúráhámù àti Sárà kò gbọ́ ara wọn yé. (Jẹ́n. 21:9-11) Àmọ́, ìyẹn ò mú kí àárín wọn dà rú. Kí ni wọ́n ṣe tí àárín wọn ò fi dà rú? Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “jọ̀wọ́,” fún Sárà. (Jẹ́n. 12:11, 13) Sárà náà sì máa ń gbọ́ràn sí ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó kà á sí “olúwa” rẹ̀. (Jẹ́n. 18:12) Àmọ́, bí tọkọtaya bá ń fìkanra bá ara wọn sọ̀rọ̀, ńṣe nìyẹn fi hàn pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún ara wọn. (Òwe 12:18) Tí wọn ò bá sì wá nǹkan ṣe sí ohun tó ń fa ìṣòro náà, àárín wọn lè dà rú.—Ka Jákọ́bù 3:7-10, 17, 18.

12. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó sapá gan-an láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀?

12 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó sapá láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kí wọ́n sì máa fi inú rere hàn síra wọn. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà. Ọkọ kan sọ pé fún ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn táwọn ṣègbéyàwó, òun àti ìyàwó òun ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ìwà ara àwọn, bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn àti ohun tí kálukú àwọn nífẹ̀ẹ́ sí. Torí bẹ́ẹ̀, nǹkan máa ń tojú sú wọn nígbà míì. Àmọ́, ní báyìí, wọ́n ti wá mọwọ́ ara wọn, torí pé wọ́n máa ń gba ti ara wọn rò, wọ́n jọ máa ń ṣàwàdà, wọ́n sì máa ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti sùúrù ṣe nǹkan. Láfikún, wọ́n máa ń gbára lé Jèhófà, wọ́n sì máa ń fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ ńlá lèyí jẹ́ fún wa!

Ẹ MÁA FI OJÚLÓWÓ Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀ HÀN

13. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bí wọ́n bá fẹ́ kí àárín wọn gún?

13 Ó ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kí wọ́n tó lè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà. (1 Pét. 3:8) Arákùnrin kan tó ti ṣègbéyàwó fún ọdún mọ́kànlá sọ pé ó máa ń rọrùn láti yanjú èdèkòyédè bí tọkọtaya bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Èyí á mú kí wọ́n lè bẹ ẹnì kejì wọn pé, “jọ̀ọ́ má bínú.” Alàgbà kan tó ti ṣègbéyàwó fún ogún [20] ọdún, tí òun àti ìyàwó rẹ̀ sì mọwọ́ ara wọn gan-an sọ pé: “Àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé gbólóhùn náà, ‘má bínú,’ ṣe pàtàkì ju ‘mo fẹ́ràn rẹ.’” Ó wá sọ bí àdúrà ṣe mú kí òun àtìyàwó rẹ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó sọ pé: “Tí èmi àti ìyàwó mi bá jọ gbàdúrà, ó máa ń jẹ́ ká rántí pé aláìpé ni wá àti pé a nílò àánú Ọlọ́run.” Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n kì í ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ, wọ́n sì tètè máa ń yanjú èdèkòyédè.

Ẹ rí i pé ẹ̀yin méjèèjì jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa

14. Báwo ni ẹ̀mí ìgbéraga ṣe lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó?

14 Ìgbéraga kì í jẹ́ kí tọkọtaya lè bára wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà, kì í sì í jẹ́ kí wọ́n lè yanjú èdèkòyédè. Onígbèéraga kì í lè tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹni tó ṣẹ̀. Dípò tó fi máa sọ pé: “Dákun, má bínú, dárí jì mí,” àwáwí nirú ẹni bẹ́ẹ̀ á máa ṣe. Kàkà kí ó gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi, àṣìṣe ẹnì kejì lá máa ránnu mọ́. Tẹ́nì kan bá ṣẹ agbéraga èèyàn, dípò tó fi máa wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀, ṣe ló máa bínú rangbandan. (Oníw. 7:9) Ó ṣe kedere pé ìgbéraga lè da ìgbéyàwó rú. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—Ják. 4:6.

15. Ṣàlàyé bí ìlànà tó wà nínú Éfésù 4:26, 27 ṣe lè mú kí tọkọtaya yanjú èdèkòyédè.

15 Bí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ẹ̀yin tọkọtaya, ẹ tètè wá nǹkan ṣe sí i dípò tẹ́ ẹ fi máa gba ẹ̀mí ìgbéraga láyè. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfé. 4:26, 27) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí tọkọtaya kò bá fi ìmọ̀ràn yìí sílò? Arábìnrin kan sọ pé, “Àwọn ọjọ́ tá ò bá ti fi ìmọ̀ràn yìí sílò ni mi kì í lè sùn dáadáa!” Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká tètè máa fi pẹ̀lẹ́tù yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé! Àmọ́ o, kó tó di pé ẹ máa yanjú ọ̀rọ̀ náà, ó lè gba pé kẹ́ ẹ ní sùúrù díẹ̀ kí inú tó ń bí yín fi rọlẹ̀. Ó sì tún dáa pé kẹ́ ẹ bẹ Jèhófà pé kó fún yín ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yìí ni kò ní jẹ́ kẹ́ ẹ máa ránnu mọ́ àṣìṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan yín, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fa ìṣòro náà ni kẹ́ ẹ yanjú.—Ka Kólósè 3:12, 13.

16. Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè mú kí tọkọtaya mọyì ànímọ́ rere tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní?

16 Bí tọkọtaya bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn, wọ́n á mọyì àwọn ànímọ́ rere tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní. Bí àpẹẹrẹ, aya kan lè ní àwọn ẹ̀bùn ara ọ̀tọ̀ kan tó fi ń ṣe ìdílé rẹ̀ láǹfààní. Bí ọkọ rẹ̀ bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, kò ní máa wo ìyàwó rẹ̀ bí ẹni tó fẹ́ gbapò mọ́ òun lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, á máa ṣe ohun táá jẹ́ kí aya rẹ̀ mọ̀ pé òun mọyì àwọn ànímọ́ rere tó ní, ìyẹn á sì wú ìyàwó náà lórí. (Òwe 31:10, 28; Éfé. 5:28, 29) Lẹ́sẹ̀ kan náà, ìyàwó tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ ò ní máa gapá tàbí kó máa fojú kéré ọkọ rẹ̀. Ẹ máa rántí pé ẹ̀mí ìgbéraga lè da ìgbéyàwó rú. Ó ṣe tán, ohun tó bá bá ojú, ó bá imú pẹ̀lú, torí pé “ara kan” ni ẹ̀yin méjèèjì.—Mát. 19:4, 5.

17. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí ìgbéyàwó láyọ̀, kí ó sí bọlá fún Ọlọ́run?

17 Ó dájú pé á wù ẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ ládùn kó lóyin, kó sì máa múnú Jèhófà dùn, bíi ti Ábúráhámù àti Sárà tàbí bíi ti Ísákì àti Rèbékà. Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó ni kó o máa fi wò ó. Máa kẹ́kọ́ọ̀ Bíbélì kó o lè ní ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye. Sapá láti mọyì ànímọ́ rere tí ẹnì kejì rẹ ní, tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á mú kí ẹ̀yín méjèèjì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín. (Orin Sól. 8:6) Jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ tàbí aya rẹ. Tó o bá ń fàwọn ìmọ̀ràn yìí sílò, ìgbéyàwó rẹ á láyọ̀, wàá sì mú inú Jèhófà dùn. (Òwe 27:11) Arákùnrin kan tó ti ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] sọ pé: “Mi ò mọ bí ayé mi ṣe máa rí láìsí ìyàwó mi. Ojoojúmọ́ ni okùn ìfẹ́ wa túbọ̀ ń lágbára. Ìdí ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, a sì máa ń bá ara wa sọ̀rọ̀ dáadáa.” Jẹ́ kó dá ọ lójú pé ìgbéyàwó tiẹ̀ náà lè ládùn kó sì lóyin!