Ipa Wo Ni Àwọn Obìnrin Ń Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ?
“Àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.”—SM. 68:11.
1, 2. (a) Àwọn ẹ̀bùn wo ni Ọlọ́run fún Ádámù? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fún Ádámù ní aya? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
Ó NÍDÌÍ tí Jèhófà fi dá ayé. Bíbélì sọ pé, Ọlọ́run “ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísá. 45:18) Ẹ̀dá pípé ni Ádámù ẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ó sì fún un ní ilé tó rẹwà, ìyẹn ọgbà Édẹ́nì. Ó dájú pé Ádámù á máa gbádùn ara rẹ̀ láàárín àwọn igi tó rẹwà, àwọn odò tó ń ṣàn àtàwọn ẹranko tó ń ṣeré kiri! Àmọ́, ó ṣì ku nǹkan pàtàkì kan tí kò ní. Jèhófà sọ ohun náà nígbà tó sọ pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” Ọlọ́run wá mú kí Ádámù sun oorun àsùnwọra, ó mú ọ̀kan nínú egungun ìhà rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í “fi egungun ìhà tí ó mú . . . mọ obìnrin.” Nígbà tí Ádámù jí, inú rẹ̀ dùn gan-an! Ó wá sọ pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi. Obìnrin ni a óò máa pe èyí, nítorí pé láti ara ọkùnrin ni a ti mú èyí wá.”—Jẹ́n. 2:18-23.
2 Ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ látọwọ́ Ọlọ́run ni obìnrin, torí pé olùrànlọ́wọ́ pípé ni obìnrin náà máa jẹ́. Bákan náà, obìnrin náà lè bímọ, àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ sì ni èyí jẹ́ pẹ̀lú. Kódà, “Ádámù pe orúkọ aya rẹ̀ ní Éfà, nítorí pé òun ni yóò di ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè.” (Jẹ́n. 3:20) Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye mà ni Ọlọ́run fún tọkọtaya àkọ́kọ́ yìí o! Wọ́n láǹfààní láti bí àwọn ọmọ tó jẹ́ ẹ̀dá pípé. Wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ mú kí gbogbo ayé di Párádísè tí àwọn èèyàn pípé kún inú rẹ̀, àwọn ohun alààyè yòókù á sì wà lábẹ́ àbójútó wọn.—Jẹ́n. 1:27, 28.
3. (a) Kí ni Ádámù àti Éfà gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run lè bù kún wọn, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?
3 Tí Ádámù àti Éfà bá fẹ́ gba àwọn ìbùkún yìí, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Jèhófà, kí wọ́n sì fi ara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀. (Jẹ́n. 2:15-17) Ìyẹn nìkan ló máa mú kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún wọn ṣẹ. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé Sátánì tó jẹ́ “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà” kó bá wọn, wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (Ìṣí. 12:9; Jẹ́n. 3:1-6) Ọ̀nà wo ni ọ̀tẹ̀ tó wáyé yìí gbà kan àwọn obìnrin? Kí ni àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà àtijọ́ gbéṣe? Kí nìdí tá a fi lè pe àwọn obìnrin Kristẹni òde òní ní “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá”?—Sm. 68:11.
OHUN TÍ Ọ̀TẸ̀ TÓ WÁYÉ YỌRÍ SÍ
4. Ta ni Ọlọ́run dá lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ tí tọkọtaya àkọ́kọ́ náà dá?
4 Nígbà tí Ọlọ́run ní kí Ádámù wá jẹ́jọ́ fún ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù, àwáwí kan tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ló ṣe, ó ní: “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi láti wà pẹ̀lú mi, òun ni ó fún mi ní èso láti ara igi náà, nítorí náà, mo sì jẹ.” (Jẹ́n. 3:12) Yàtọ̀ sí pé Ádámù ò fẹ́ gbà pé òun ṣẹ̀, ó tún dá obìnrin yẹn àti Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó fún un lẹ́bùn náà lẹ́bi. Lóòótọ́, Ádámù àti Éfà ló jọ dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ Ádámù ni Ọlọ́run dá lẹ́bi. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé “ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.
5. Kí ló ṣe kedere bí Ọlọ́run ti ṣe fàyè gbà á kí àwọn èèyàn máa ṣàkóso ara wọn?
5 Sátánì mú kí tọkọtaya àkọ́kọ́ máa ronú pé àwọn ò nílò kí Jèhófà jẹ́ Alákòóso àwọn. Èyí ló fa ìbéèrè pàtàkì kan nípa ipò Ọba Aláṣẹ: Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, Ọlọ́run fàyè gbà á káwọn èèyàn máa ṣàkóso ara wọn fún àwọn sáà àkókò kan láìbá wọn dá sí i rárá. Ó mọ̀ pé bópẹ́ bóyá, ẹ̀rí á fi hàn kedere pé ìṣàkóso èyíkéyìí tí èèyàn bá ṣe láìfi ti òun pè máa forí ṣánpọ́n. Ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá báyìí tí ìràn èèyàn ti ń dá ṣàkóso ara wọn, ńṣe ni wọ́n ń tinú àjálù kan bọ́ sí òmíràn. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún tí ó kọjá yìí nìkan, àwọn ọkùnrin àti obìnrin àtàwọn ọmọdé tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ tí ó bá ogun lọ tó nǹkan bíi mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000,000]. Torí náà, ẹ̀rí pelemọ ti wà nílẹ̀ báyìí tó fi hàn pé lóòótọ́, “kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jer. 10:23) Òótọ́ pọ́ńbélé tá a mọ̀ yìí jẹ́ ká gbà pé Jèhófà ni Alákòóso wa.—Ka Òwe 3:5, 6.
6. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, kí làwọn èèyàn máa ń fojú àwọn obìnrin rí?
6 Àtọkùnrin àtobìnrin lojú wọn ń rí màbo nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí. (Oníw. 8:9; 1 Jòh. 5:19) Lára ìwà ìkà tó burú jáì tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni bí wọ́n ṣe ń fojú àwọn obìnrin gbolẹ̀. Kárí ayé, nǹkan bíi mẹ́ta nínú mẹ́wàá àwọn obìnrin ló sọ pé ọkọ àwọn ń lu àwọn. Ní àwọn ilẹ̀ kan, olú ọmọ ni wọ́n ka àwọn ọkùnrin sí torí wọ́n gbà pé àwọn ni kò ní jẹ́ kí orúkọ ìdílé pa run, àwọn ló sì máa tọ́jú àwọn òbí àtàwọn òbí àgbà lọ́jọ́ ogbó. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, wọn ò ka àwọn ọmọbìnrin sọ́mọ gidi, wọ́n sì máa ń ṣẹ́ oyún ọmọbìnrin dànù ju ti ọkùnrin lọ.
7. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà mú kí ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn?
7 Inú Ọlọ́run kò dùn sí bí wọ́n ṣe ń fojú àwọn obìnrin gbolẹ̀. Ọlọ́run máa ń pọ́n àwọn obìnrin lé, kì í sì í fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n. Ọ̀nà tí Jèhófà gbà dá Éfà fi hàn pé ó ka àwọn obìnrin sí. Ẹ̀dá pípé ni Jèhófà dá a, ó sì tún jẹ́ kó ní àwọn ànímọ́ tó mú kó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Ádámù, tí kì í sì í ṣe ẹrú. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, ní òpin ọjọ́ kẹfà ìṣẹ̀dá, Ọlọ́run “rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Jẹ́n. 1: 31) Ní ti gidi, “gbogbo” ohun tí Jèhófà dá ló “dára gan-an.” Ó mú kí tọkùnrin tobìnrin náà bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó dára!
ÀWỌN OBÌNRIN TÍ JÈHÓFÀ TÌ LẸ́YÌN
8. (a) Ṣàlàyé bí ìwà àwọn èèyàn ṣe rí. (b) Jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn, àwọn wo ni Ọlọ́run ti fi ojúure hàn sí?
8 Lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í hùwàkiwà, ńṣe ni ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá yìí tiẹ̀ tún wá burú ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà ìkà máà gbilẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Ìwà ìkà tó gbòde yìí jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn àkókò lílekoko” la wà lóòótọ́. (2 Tím. 3:1-5) Àmọ́, jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn, “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ” ti fi ojúure hàn sí àtọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, tí wọ́n ń tẹ̀ lé òfin rẹ̀, tí wọ́n sì fi ara wọn sábẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alákòóso wọn.—Ka Sáàmù 71:5.
9. Èèyàn mélòó ló la Ìkún-omi náà já, kí sì nìdí?
9 Nígbà tí Ọlọ́run fi Ìkún-omi pa àwọn oníwà ipá run nígbà ayé Nóà, àwọn èèyàn díẹ̀ ló la ìparun yẹn já. Tí àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò Nóà bá wà láàyè nígbà yẹn, á jẹ́ pé àwọn náà pa run sínú Ìkún-omi náà. (Jẹ́n. 5:30) Àmọ́, bí ọkùnrin ṣe wà lára àwọn tó la Àkúnya Omi náà já náà làwọn obìnrin náà wà níbẹ̀. Àwọn tó là á já ni Nóà, ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tà àtàwọn ìyàwó wọn. Ọlọ́run dá wọn sí torí pé wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ àti pé wọ́n ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Látọ̀dọ̀ àwọn mẹ́jọ tí Jèhófà tì lẹ́yìn yìí ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ti ṣẹ̀ wá.—Jẹ́n. 7:7; 1 Pét. 3:20.
10. Kí nìdí tí Jèhófà fi wà lẹ́yìn àwọn obìnrin tó bẹ̀rù rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ìyàwó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́?
10 Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Ọlọ́run ṣì ń ti àwọn obìnrin tó bẹ̀rù rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ìyàwó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lẹ́yìn. Èyí lè máà rí bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ń ṣàròyé nípa ipò tí wọ́n bá ara wọn. (Júúdà 16) Ǹjẹ́ irú obìnrin bíi Sárà, tó ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ábúráhámù ọkọ rẹ̀ á máa ṣàròyé kíkan-kíkan nígbà tí wọ́n kúrò ní ìlú Úrì níbi tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù fún wọn, tí wọ́n sì di àtìpó tó ń gbé nínú àgọ́ ní ilẹ̀ àjèjì? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé, “Sárà . . . máa ń ṣègbọràn sí Ábúráhámù, ní pípè é ní ‘olúwa.’ “ (1 Pét. 3:6) Tún wo àpẹẹrẹ Rèbékà, ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ló jẹ́, ó sì di aya àtàtà. Abájọ tí Ísákì ọkọ rẹ̀ fi “kó sínú ìfẹ́ fún [un], . . . Ísákì sì rí ìtùnú lẹ́yìn tí ó ti pàdánù ìyá rẹ̀.” (Jẹ́n. 24:67) Inú wa mà dùn o, pé lónìí a ní àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run láàárín wa tí wọ́n fìwà jọ Sárà àti Rèbékà!
11. Báwo ni àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ agbẹ̀bí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ onígboyà?
11 Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ gan-an, Fáráò wá pàṣẹ pé kí wọ́n máa pa gbogbo ọmọdékùnrin Hébérù bí wọ́n bá ṣe ń bí wọn. Àmọ́, wo àpẹẹrẹ Ṣífúrà àti Púà tí wọ́n jẹ́ agbẹ̀bí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ni olórí nídìí iṣẹ́ agbẹ̀bí. Wọ́n fi hàn pé àwọn jẹ́ onígboyà bí wọ́n ṣe kọ̀ láti pa àwọn ọmọdékùnrin jòjòló tí wọ́n ń gbẹ̀bí wọn, torí pé wọ́n bẹ̀rù Jèhófà wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bù kún wọn, tó sì jẹ́ kí wọ́n ní ìdílé ti ara wọn.—Ẹ́kís. 1:15-21.
12. Kí ló gbàfiyèsí nípa Dèbórà àti Jáẹ́lì?
12 Ní ìgbà ayé àwọn onídàájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ọ̀kan nínú àwọn obìnrin tí Ọlọ́run wà lẹ́yìn rẹ̀ ni Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin. Ó fún Bárákì Onídàájọ́ ní ìṣírí, ó sì kó ipa ribiribi kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń fojú wọn gbolẹ̀, àmọ́ ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Bárákì kọ́ ló máa gba ògo ìṣẹ́gun lórí àwọn ará Kénáánì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa fi Sísérà tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Kénáánì lé “ọwọ́ obìnrin.” Bó sì ṣe ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn, Jáẹ́lì obìnrin kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ló pa Sísérà.—Oníd. 4:4-9, 17-22.
13. Kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa Ábígẹ́lì?
13 Obìnrin míì tó tún gbàfiyèsí ni Ábígẹ́lì tó gbé láyé ní ọ̀rúndún kọkànlá ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọlọ́gbọ́n obìnrin ni, àmọ́ èèyànkéèyàn ni Nábálì ọkọ rẹ̀, ó burú, kò wúlò fún nǹkan kan, kò sì gbọ́n. (1 Sám. 25:2, 3, 25) Nígbà kan, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ń bá Nábálì dáàbò bo ohun ìní rẹ̀, àmọ́ nígbà tí wọ́n sọ pé kí Nábálì fún àwọn ní nǹkan, ṣe ni “ó fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí wọn,” kò sì fún wọn ní nǹkan kan. Inú bí Dáfídì gan-an débi pé ó gbéra láti lọ pa Nábálì àti agboolé rẹ̀ run. Bí Ábígẹ́lì ṣe gbọ́ nípa ohun tí Dáfídì fẹ́ ṣe yìí, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó gbé oúnjẹ àti ohun mímu lọ pàdé Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, ohun tó ṣe yìí ni kò jẹ́ kí ìtàjẹ̀sílẹ̀ wáyé. (1 Sám. 25:8-14, 18) Dáfídì sọ fún un pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi!” (1 Sám. 25:32) Lẹ́yìn tí Nábálì kú, Dáfídì fẹ́ Ábígẹ́lì.—1 Sám. 25:37-42.
14. Iṣẹ́ wo ni àwọn ọmọbìnrin Ṣálúmù kópa nínú rẹ̀, báwo ni àwọn Kristẹni obìnrin ṣe ń kópa nínú irú iṣẹ́ yẹn lóde òní?
14 Ọ̀pọ̀ ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké ló kú nígbà tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì pa ìlú Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n tún ògiri ìlú náà kọ́ lábẹ́ ìdarí Nehemáyà. Àwọn ọmọbìnrin Ṣálúmù, ọmọ aládé ìdajì àgbègbè Jerúsálẹ́mù wà lára àwọn tó kópa nínú iṣẹ́ àtúnṣe náà. (Neh. 3:12) Tinútinú ni wọ́n fi ṣe iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ àtúnṣe náà. Ẹni ọ̀wọ́n ni ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni obìnrin tí wọ́n ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣe onírúurú iṣẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn ilé ìjọsìn lóde òní!
ÀWỌN OBÌNRIN TÓ BẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN NÍ Ọ̀RÚNDÚN KÌÍNÍ
15. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo ni Ọlọ́run fún Màríà?
15 Láwọn àkókò kan ṣáájú àti lẹ́yìn ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, Jèhófà fi àwọn àǹfààní pàtàkì kan dá àwọn obìnrin mélòó kan lọ́lá. Lára wọn ni wúńdíà kan tó ń jẹ́ Màríà. Òun àti Jósẹ́fù ń fẹ́ra sọ́nà nígbà tó lóyún lọ́nà ìyanu nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi yan Màríà pé kó di ìyá Jésù? Ó dájú pé ó ní àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tó máa jẹ́ kó lè tọ́ ọmọkùnrin Ọlọ́run láti kékeré títí táá fi dàgbà, torí pé ẹni pípé ni ọmọ náà. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ni Màríà ní láti jẹ́ ìyá fún ọkùnrin tó tóbi lọ́lá jù lọ tí kò sẹ́ni bíi tirẹ̀ tó gbé ayé rí!—Mát. 1:18-25.
16. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ irú ọwọ́ tí Jésù fi ń mú àwọn obìnrin.
16 Jésù máa ń fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn obìnrin. Wo àpẹẹrẹ obìnrin kan tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá. Àárín èrò ló ti fọwọ́ kan aṣọ Jésù láti ẹ̀yìn. Àmọ́, kàkà kí Jésù kàn án lábùkù, ṣe ló fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.”—Máàkù 5:25-34.
17. Ohun ìyanu wo ló ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni?
17 Àwọn obìnrin kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe ìránṣẹ́ fún òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Lúùkù 8:1-3) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nǹkan bí ọgọ́fà [120] ọkùnrin àti obìnrin ni ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Ka Ìṣe 2:1-4.) Ọlọ́run ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa títú ẹ̀mí rẹ̀ jáde, ó ní: “Èmi [Jèhófà] yóò tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ dájúdájú . . . Èmi yóò sì tú ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti sára àwọn ìránṣẹ́bìnrin pàápàá.” (Jóẹ́lì 2:28, 29) Ọlọ́run tipasẹ̀ ohun ìyanu tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì yẹn fi hàn pé òun ti pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n di apẹ̀yìndà tì, Òun sì ti yí àfiyèsí òun sọ́dọ̀ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tó ní nínú àwọn ọkùnrin àti obìnrin. (Gál. 3:28; 6:15, 16) Àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí Fílípì ajíhìnrere bí wà lára àwọn Kristẹni obìnrin tí wọ́n wàásù ní ọ̀rúndún kìíní.—Ìṣe 21:8, 9.
ÀWỌN OBÌNRIN TÓ JẸ́ “ẸGBẸ́ ỌMỌ OGUN ŃLÁ”
18, 19. (a) Tó bá kan ọ̀ràn ìjọsìn tòótọ́, àǹfààní wo ni Ọlọ́run fún tọkùnrin tobìnrin? (b) Kí ni onísáàmù kan sọ nípa àwọn obìnrin tó ń polongo ìhìn rere?
18 Ní àwọn ọdún 1870, àwọn ọkùnrin àti obìnrin mélòó kan fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn tòótọ́. Àwọn náà ti ṣe nínú iṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ ń ṣe lóde òní, ìyẹn ni iṣẹ́ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ tó sì ti ní ìmúṣẹ, ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mát. 24:14.
19 Àwùjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n kéré níye tẹ́lẹ̀ ti wá gbèrú gan-an báyìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ti tó nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́jọ [8,000,000]. Lọ́dún 2013, àwọn tó ju mílíọ̀nù mọ́kànlá [11,000,000] lọ ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi tí à ń ṣe lọ́dọọdún tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ wa, tí wọ́n sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn obìnrin ló pọ̀ jù nínú àwọn tó ń wá síbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, nínú iye tó ju mílíọ̀nù kan àwọn tó ń fi àkókò-kíkún polongo Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé, àwọn obìnrin ló pọ̀ jù. Láìsí àní-àní, Ọlọ́run ti fún àwọn obìnrin olóòótọ́ láǹfààní láti kópa nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí onísáàmù kan sọ, ó ní: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó sọ àsọjáde náà; àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.”—Sm. 68:11.
ÌBÙKÚN ÀGBÀYANU TÍ ÀWỌN OBÌNRIN TÓ BẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN MÁA GBÁDÙN
20. Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?
20 A ò lè sọ̀rọ̀ nípa gbogbo obìnrin olóòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn tán nínú àpilẹ̀kọ yìí nìkan. Àmọ́, a lè rí ìtàn wọn kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn àpilẹ̀kọ tí à ń tẹ̀ jáde nínú àwọn ìwé wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣe àṣàrò nípa ìdúróṣinṣin Rúùtù. (Rúùtù 1:16, 17) Tí a bá ka àwọn àpilẹ̀kọ kan nípa Ayaba Ẹ́sítérì àti ìwé tí a fi orúkọ rẹ̀ pè nínú Bíbélì, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára. A máa jàǹfààní gan-an nínú irú àwọn ẹ̀kọ́ yìí, a tiẹ̀ tún lè ṣètò láti jíròrò wọn nígbà Ìjọsìn Ìdílé. Tí a kò bá tíì ní ìdílé, a lè ṣàyẹ̀wò irú ẹ̀kọ́ yìí nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa.
21. Báwo ni àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run ṣe fi hàn pé tọkàntọkàn làwọn fi ń sin Jèhófà kódà nígbà ìṣòro?
21 Kò sí àní-àní pé Jèhófà ń bù kún iẹ́ ìwàásù tí àwọn Kristẹni obìnrin ń ṣe, kò sì fi wọ́n sílẹ̀ nígbà ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run pa ìṣòtítọ́ wọn mọ́ nígbà tí ìjọba Násì àti ìjọba Kọ́múníìsì fìyà jẹ wọ́n gan-an, àwọn míì sì kú torí pé wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Ìṣe 5:29) Bíi ti ìgbà àtijọ́, àwọn arábìnrin wa àti àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà ń fi hàn pé àwọn fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà di ọwọ́ ọ̀tún wọn mú, tó sì ń sọ fún wọn bó ṣe sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “Má fòyà. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”—Aísá. 41:10-13.
22. Àǹfààní wo ni a lè máa fojú sọ́nà fún lọ́jọ́ iwájú?
22 Láìpẹ́ sí ìgbà tí a wà yìí, àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa mú kí ayé di ibi tó rẹwà láti gbé, wọ́n á sì kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó máa jíǹde lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ Jèhófà. Kó tó dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká mọyì àǹfààní tí a ní láti máa sin Jèhófà “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”—Sef. 3:9.