Máa Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run —Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Yè!
“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—HÉB. 4:12.
1, 2. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé fún Mósè, ìdánilójú wo sì ni Jèhófà fún un?
BÁWO ló ṣe máa rí lára rẹ ká sọ pé o ní láti lọ síwájú ọba kan tó lágbára jù lọ nínú gbogbo ọba ayé, tó o sì fẹ́ gbèjà àwọn èèyàn Jèhófà níwájú rẹ̀? Ó ṣeé ṣe kí àyà ẹ já, kó o máa wò ó pé irú ẹ ò tó ẹni tó ń lọ síwájú irú ọba bẹ́ẹ̀. Báwo lo ṣe máa múra ohun tó o máa sọ? Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń ṣojú fún Ọlọ́run Olódùmarè, kí lo lè ṣe tọ́rọ̀ rẹ á fi tẹ̀wọ̀n?
2 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè gan-an nìyẹn. Jèhófà sọ fún Mósè tó jẹ́ “ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀” pé òun fẹ́ rán an lọ sọ́dọ̀ Fáráò kó lè lọ gba àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń fìyà jẹ wọ́n, kó sì kó wọn kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì. (Núm. 12:3) Bá a ṣe máa rí i nínú ohun tó ṣẹlẹ̀, Fáráò jẹ́ olóríkunkun àti agbéraga ẹ̀dá. (Ẹ́kís. 5:1, 2) Síbẹ̀, Jèhófà fẹ́ kí Mósè sọ fún Fáráò pé kó dá mílíọ̀nù bíi mélòó kan àwọn tó kó lẹ́rù sílẹ̀ lómìnira! Abájọ tí Mósè fi bi Jèhófà pé: “Ta ni èmi tí èmi yóò fi lọ bá Fáráò, tí n ó sì fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì?” Mósè ti ní láti wo ara rẹ̀ pé òun ò lẹ́mìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún òun yìí àti pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, Ọlọ́run fi dá a lójú pé òun kò ní dá a dá iṣẹ́ náà. Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ.”—Ẹ́kís. 3:9-12.
3, 4. (a) Kí làwọn nǹkan tó ń ba Mósè lẹ̀rù? (b) Báwo ni ìṣòro tó dojú kọ Mósè ṣe lè dojú kọ ìwọ náà?
3 Kí làwọn nǹkan tó ń ba Mósè lẹ́rù? Ó dájú pé ẹ̀rù bà á pé Fáráò lè máà tẹ́wọ́ gba ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rán tàbí kó tìẹ má fetí sí i. Mósè tún ń bẹ̀rù pé àwọn èèyàn òun pàápàá ò ní gbà gbọ́ pé Jèhófà ti rán òun láti kó wọn jáde kúrò ní Íjíbítì. Ìdí nìyẹn tí Mósè fi sọ fún Jèhófà pé: “Ṣùgbọ́n ká ní wọn kò gbà mí gbọ́ tí wọn kò sì fetí sí ohùn mi, nítorí wọn yóò wí pé, ‘Jèhófà kò fara hàn ọ́.’”—Ẹ́kís. 3:15-18; 4:1.
4 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì lára ìdáhùn tí Jèhófà fún Mósè àti nínú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e. Lóòótọ́, o lè má lọ síwájú aláṣẹ gíga èyíkéyìí. Àmọ́, ǹjẹ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí pé ó ṣòro fún ẹ láti sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ fáwọn èèyàn tó ò ń bá pàdé? Tó bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, wo ohun tó o lè kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè.
“KÍ NI Ó WÀ NÍ ỌWỌ́ RẸ YẸN?”
5. Kí ni Jèhófà fi lé Mósè lọ́wọ́, báwo nìyẹn sì ṣe mú ẹ̀rù tó ń bà á kúrò? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
5 Nígbà tí Mósè sọ ohun tó ń bà á lẹ́rù pé wọn ò ní ka ọ̀rọ̀ òun sí, Ọlọ́run múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Ìtàn tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Ẹ́kísódù sọ pé: “Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún [Mósè] pé: ‘Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ yẹn?’ Ó dáhùn pé: ‘Ọ̀pá.’ Lẹ́yìn èyí, ó wí fún un pé: ‘Sọ ọ́ sí ilẹ̀.’ Nítorí náà, ó sọ ọ́ sí ilẹ̀, ó sì di ejò; Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí sá fún un. Wàyí o, Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Na ọwọ́ rẹ jáde, kí o sì gbá a ní ìrù mú.’ Nítorí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì gbá a mú, ó sì di ọ̀pá ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé, ‘Kí wọ́n bàa lè gbà gbọ́ pé Jèhófà . . . ti fara hàn ọ́.’” (Ẹ́kís. 4:2-5) Ọlọ́run tipa bẹ́ẹ̀ fi ohun tí Mósè máa fi mú káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ló rán an lé e lọ́wọ́. Ohun tó dà bí ọ̀pá lásán lójú àwọn èèyàn yí pa dà di nǹkan ẹlẹ́mìí nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run! Ẹ ò rí i pé irú iṣẹ́ ìyanu yìí máa mú kí ọ̀rọ̀ Mósè rinlẹ̀, èyí sì máa jẹ́ ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé Jèhófà wà lẹ́yìn rẹ̀! Torí náà, Jèhófà sọ fún un pé: “Ọ̀pá yìí ni ìwọ yóò sì mú ní ọwọ́ rẹ kí o lè máa fi ṣe iṣẹ́ àmì.” (Ẹ́kís. 4:17) Pẹ̀lú ẹ̀rí tó wà lọ́wọ́ Mósè pé Ọlọ́run ló rán an yìí, ó lè fìgboyà lọ ṣojú Ọlọ́run tòótọ́ níwájú àwọn èèyàn rẹ̀ àti níwájú Fáráò.—Ẹ́kís. 4:29-31; 7:8-13.
6. (a) Kí ló yẹ kó wà lọ́wọ́ wa tá a bá ń wàásù, kí sì nìdí? (b) Ṣàlàyé bí “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run [ṣe] yè” àti bó ṣe “ń sa agbára.”
6 Nígbà tá a bá lọ wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, Ọlọ́run lè béèrè lọ́wọ́ àwa náà pé: “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ yẹn?” Lọ́pọ̀ ìgbà, Bíbélì máa ń wà lọ́wọ́ wa láti lò lóde ẹ̀rí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn míì lè ka Bíbélì sí ìwé kan lásán, Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ tó fi ẹ̀mí mímọ́ mí sí. (2 Pét. 1:21) Nínú Bíbélì, a máa ń kà nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe nígbà tí Ìjọba rẹ̀ bá ń ṣàkóso. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Ka Hébérù 4:12.) Gbogbo ìlérí Jèhófà ló máa ṣẹ, torí pé Jèhófà ń ṣiṣẹ́ kó bàa lè mú wọn ṣẹ. (Aísá. 46:10; 55:11) Tí ẹnì kan bá mọ èyí nípa Ọ̀rọ̀ Jèhófà, ohun tó bá ń kà nínú Bíbélì á sa agbára nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
7. Báwo la ṣe lè “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́”?
7 Jèhófà ti gbé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó yè lé wa lọ́wọ́, èyí tá a lè fi ti ọ̀rọ̀ wa lẹ́yìn pé kò sírọ́ nínú ohun tí à ń sọ àti pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá. Abájọ tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Hébérù, ó rọ ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí, ìyẹn Tímótì pé kó “sa gbogbo ipá rẹ láti . . . fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tím. 2:15) Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò? Ká máa ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣe rẹ́gí táá wọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa lọ́kàn. Ọ̀nà tí a gbà ṣe àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tá a mú jáde lọ́dún 2013 lè mú ká ṣe èyí.
KA ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ TÓ ṢE RẸ́GÍ!
8. Kí ni alábòójútó iṣẹ́ ìsìn kan sọ nípa àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun náà?
8 Ọ̀nà kan náà la gbà ṣe gbogbo ìwé àṣàrò kúkúrú wa tuntun. Torí náà, tá a bá ti mọ bí a ṣe lè lo ọ̀kan nínú wọn, a ti mọ bá a ṣe máa lo gbogbo wọn nìyẹn. Ṣé wọ́n rọrùn láti lò? Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn kan ni ìpínlẹ̀ Hawaii, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “A ò mọ̀ pé àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun yìí máa wúlò gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé àti fún wíwàásù láwọn ibi táwọn èèyàn pọ̀ sí.” Arákùnrin yìí ti rí i pé ọ̀nà tá a gbà kọ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú yìí mú káwọn èèyàn lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde, èyí sì máa ń jẹ́ kó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó lárinrin lọ́pọ̀ ìgbà. Arákùnrin yìí gbà pé ìbéèrè àti onírúurú ìdáhùn tá a kọ sí iwájú àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà mú kí wọ́n rọrùn láti lò. Kò sí pé ẹni tá à ń wàásù fún á máa bẹ̀rù pé òun lè má gba ìdáhùn.
9, 10. (a) Báwo làwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa ṣe ń mú ká lè lo Bíbélì? (b) Ìwé àṣàrò kúkúrú wo lo ti lò lóde ẹ̀rí tó wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, kí sì nìdí?
9 Ìwé àṣàrò kúkúrú kọ̀ọ̀kan tọ́ka sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó bá a mu rẹ́gí tá a máa kà. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o fún ẹnì kan ní ìwé àṣàrò kúkúrú tó ní àkọlé náà Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? Ẹni tó ò ń wàásù fún lè sọ pé, “bẹ́ẹ̀ ni,” “bẹ́ẹ̀ kọ́,” tàbí “kò dá mi lójú.” Ohun yòówù kó sọ, ṣí ìwé náà, kó o wá sọ pé, “Ohun tí Bíbélì sọ nìyí.” Lẹ́yìn náà, ka Ìṣípayá 21:3, 4.
10 Bákan náà, tó o bá fẹ́ fi ìwé àṣàrò kúkúrú tó ní àkọlé náà Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì Jẹ́? lọni, ìdáhùn yòówù kí onítọ̀hún mú nínú ìdáhùn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà níwájú ìwé náà, kò ba nǹkan kan jẹ́. Ohun tó o kàn máa ṣe ni pé kó o ṣí ìwé náà, kó o sì sọ pé, “Bíbélì sọ pé ‘gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.’” O lè sọ síwájú sí i pé, “Ẹsẹ Bíbélì tó sọ ọ̀rọ̀ yìí ṣì tún sọ púpọ̀ sí i.” Lẹ́yìn náà, ṣí Bíbélì rẹ, kó o sì ka 2 Tímótì 3:16, 17.
11, 12. (a) Kí ló máa ń fún ẹ láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? (b) Báwo ni àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò?
11 Bí ẹni tó ò ń wàásù fún bá ṣe fèsì ló máa pinnu bí ohun tó o máa kà tó o sì máa jíròrò nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà ṣe máa pọ̀ tó. Bó ti wù kó rí, wàá láyọ̀, torí kì í ṣe pé o fún àwọn èèyàn ní ìwé àṣàrò kúkúrú nìkan, o tún ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì lo lè kà nígbà àkọ́kọ́ tó o pàdé ẹni náà. Ẹ máa bá ìjíròrò náà nìṣó nígbà míì.
12 Ní ẹ̀yìn pátápátá nínú ìwé àṣàrò kúkúrú kọ̀ọ̀kan, àkọlé kan wà níbẹ̀ tó sọ pé, “Rò Ó Wò Ná,” ìbéèrè kan àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wà níbẹ̀ tẹ́ ẹ lè jíròrò nígbà ìpadàbẹ̀wò. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé àṣàrò kúkúrú tó ní àkọlé náà, Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la? ìbéèrè tó wà níbẹ̀ tẹ́ ẹ máa jíròrò nígbà tẹ́ ẹ bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò ni, “Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ tún ayé yìí ṣe?” Ó tọ́ka sí Mátíù 6:9, 10 àti Dáníẹ̀lì 2:44. Ìbéèrè tó wà ní ẹ̀yìn ìwé àṣàrò kúkúrú tó ní àkọlé náà Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde? ni, “Kí nìdí tá a fi ń darúgbó tá a sì ń kú?” Ó tọ́ka sí Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19 àti Róòmù 5:12.
13. Ṣàlàyé bó o ṣe lè lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
13 Lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà láti fi nasẹ̀ bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tẹ́nì kan bá fi fóònù rẹ̀ wo àmì ìlujá tó wà lẹ́yìn ìwé náà, ó máa ṣí ibi kan fún un nínú Ìkànnì wa tó máa rọ̀ ọ́ pé kó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwé àṣàrò kúkúrú náà tún sọ nípa ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! ó sì tọ́ka sí orí kan pàtó nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú tó ní àkọlé náà Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí? tọ́ka sí orí 5 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà. Ìwé àṣàrò kúkúrú tó ní àkọlé náà Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀? tọ́ka sí orí 9. Tó o bá ń lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà bá a ṣe sọ, á mọ́ ẹ lára láti máa lo Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tó o wàásù fún ẹnì kan àti nígbà ìpadàbẹ̀wò. Ìyẹn á sì jẹ́ kó o ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀. Nǹkan míì wo lo tún lè ṣe táá jẹ́ kó o lè máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
SỌ̀RỌ̀ LÓRÍ KÓKÓ KAN TÓ Ń JẸ ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́KÀN
14, 15. Ọwọ́ wo ni Pọ́ọ̀lù fi mú iṣẹ́ ìwàásù, báwo lo sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
14 Ó wu Pọ́ọ̀lù gan-an pé kó ran “àwọn ènìyàn púpọ̀” lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Ka 1 Kọ́ríńtì 9:19-23.) Kíyè sí i pé ohun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ ni pé kó “jèrè àwọn Júù . . . , àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin . . . , àwọn tí wọ́n wà láìní òfin . . . , [àti] àwọn aláìlera.” Ó fẹ́ dé ọ̀dọ̀ “ènìyàn gbogbo, [kó] lè rí i dájú pé [òun] gba àwọn kan là.” (Ìṣe 20:21) Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù bá a ṣe ń múra sílẹ̀ láti kọ́ “gbogbo onírúurú ènìyàn” lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?—1 Tím. 2:3, 4.
15 Àwọn àbá lórí bá a ṣe lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí máa ń wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lóṣooṣù. Máa lo àwọn àbá yìí. Àmọ́, tí àwọn nǹkan kan bá wà tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, ronú lórí ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó bá ohun náà mu, tó sì máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Ronú nípa àgbègbè tó ò ń gbé, àwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀ àti àwọn ohun tó sábà máa ń jẹ wọ́n lọ́kàn jù lọ. Lẹ́yìn náà, ronú lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Alábòójútó àyíká kan sọ bí òun àti ìyàwó rẹ̀ ṣe máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn dá lé orí Bíbélì, ó ní: “Ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún ló máa ń gbà kí a ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún wọn tá a bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe ṣókí tó sì ṣe tààràtà. Ká a tó dé ọ̀dọ̀ wọn, a ti máa ń ṣí Bíbélì sọ́wọ́, lẹ́yìn tá a bá ti kí wọ́n, àá wá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà fún wọn.” Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa ohun tó o lè sọ̀rọ̀ lé lórí, àwọn ìbéèrè tó o lè bi ẹni tó ò ń wàásù fún àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o lè lò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín. Àwọn kan ti lò wọ́n lóde ẹ̀rí, wọ́n sì rí i pé ó gbéṣẹ́.
16. Ṣàlàyé bó o ṣe lè lo Aísáyà 14:7 lóde ẹ̀rí.
16 Tó o bá ń gbé ní àgbègbè tí rògbòdìyàn ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀, o lè bi ẹni tó o fẹ́ wàásù fún pé: “Báwo ló ṣe máa rí ká sọ pé ohun tó o gbọ́ nínú ìròyìn lọ́jọ́ kan ni pé: ‘Gbogbo ilẹ̀ ayé ti sinmi, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu. Àwọn ènìyàn ti tújú ká pẹ̀lú igbe ìdùnnú’? Ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn nínú Aísáyà 14:7. Kódà, Bíbélì sọ ọ̀pọ̀ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe tó fi hàn pé àlàáfíà máa jọba lọ́jọ́ iwájú.” Lẹ́yìn náà, ka ọ̀kan nínú àwọn ìlérí yẹn látinú Bíbélì.
17. Báwo lo ṣe lè lo Mátíù 5:3 lóde ẹ̀rí?
17 Ǹjẹ́ ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ ọkùnrin láti gbọ́ bùkátà ìdílé wọn ní àgbègbè rẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè fi ìbéèrè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, o lè sọ pé: “Èèló lo rò pé baálé ilé kan gbọ́dọ̀ ní tó máa mú kí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ láyọ̀?” Tó bá ti fèsì, fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ baálé ilé ni owó tó jù bẹ́ẹ̀ lọ ń wọlé fún, síbẹ̀ ìdílé wọn ò láyọ̀. Kí wá ni nǹkan tí wọ́n nílò gan-an?” Lẹ́yìn náà ka Mátíù 5:3, kó o sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́.
18. Báwo lo ṣe lè fi Jeremáyà 29:11 tu àwọn èèyàn nínú?
18 Ṣé àjálù kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ ń kó ìbànújẹ́ bá àwọn èèyàn lágbègbè rẹ? Ọ̀nà kan tó o lè gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ rèé, o lè sọ pé: “Mo wá sílé rẹ kí n lè tù ẹ́ nínú. (Ka Jeremáyà 29:11.) Ǹjẹ́ o kíyè sí ohun mẹ́ta tí Ọlọ́run fẹ́ ká ní? Ó fẹ́ ká ní ‘àlàáfíà,’ ‘ọjọ́ ọ̀la kan’ àti ‘ìrètí kan.’ Ṣé kò múnú wa dùn láti mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ ká gbádùn ayé wa? Àmọ́, ǹjẹ́ ìyẹn ṣeé ṣe?” Lẹ́yìn náà, tọ́ka sí orí tó bá a mu nínú ìwé pẹlẹbẹ Ìròyìn Ayọ̀.
19. Ṣàlàyé bó o ṣe lè lo Ìṣípayá 14:6, 7 láti fi wàásù fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn ẹ̀sìn.
19 Ṣé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn ẹ̀sìn ní àgbègbè tó ò ń gbé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ báyìí: “Tí áńgẹ́lì kan bá bá ẹ sọ̀rọ̀, ṣé wàá fetí sí ohun tó fẹ́ sọ? (Ka Ìṣípayá 14:6, 7.) Nígbà tí áńgẹ́lì yìí sì ti sọ pé ká ‘bẹ̀rù Ọlọ́run,’ ǹjẹ́ kò ṣe pàtàkì pé ká dá Ọlọ́run tó ń sọ mọ̀? Áńgẹ́lì náà sọ ohun tá a máa fi dá a mọ̀, ó sọ pé òun ni ‘Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.’ Ta ni Ọlọ́run náà?” Lẹ́yìn náà ka Sáàmù 124:8, tó ní: “Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ nínú orúkọ Jèhófà, Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Sọ fún onítọ̀hún pé tó bá fẹ́, wàá pa dà wá ṣàlàyé púpọ̀ sí i nípa Jèhófà Ọlọ́run.
20. (a) Báwo lo ṣe lè lo Òwe 30:4 láti fi kọ́ni ní orúkọ Ọlọ́run? (b) Ǹjẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtó kan wà tó o lò, tó sì ní àbájáde rere?
20 Tó o bá fẹ́ wàásù fún ọ̀dọ́ kan, o lè sọ pé: “Mo fẹ́ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún ẹ tó béèrè ìbéèrè pàtàkì kan. (Ka Òwe 30:4.) Ǹjẹ́ èèyàn kankan wà tó lè ṣe gbogbo nǹkan tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ? Ó dájú pé kò sí. A jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá wa ló ń sọ. * Báwo la ṣe lè mọ orúkọ rẹ̀? Inú mi á dùn láti fi hàn ẹ́ nínú Bíbélì.”
JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN MÚ KÍ IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ RẸ SUNWỌ̀N SÍ I
21, 22. (a) Báwo ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mú rẹ́gí ṣe lè yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà? (b) Kí lo pinnu láti máa ṣe bó o ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù rẹ nìṣó?
21 O ò lè mọ bó ṣe máa rí lára àwọn èèyàn tó o bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó ṣe rẹ́gí. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan ilẹ̀kùn ilé obìnrin kan. Nígbà tó ṣí ilẹ̀kùn, ọ̀kan nínú wọn bí i pé, “Ṣé o mọ orúkọ Ọlọ́run?” ó wá ka Sáàmù 83:18 fún un. Obìnrin náà sọ pé, “Ó yà mí lẹ́nu gan-an ni! Lẹ́yìn tí wọ́n lọ, mo wa ọkọ̀ lọ sí ilé ìtàwé kan tó jìn tó kìlómítà mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56 km] torí kí n lè wo orúkọ náà nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì àti nínú ìwé atúmọ̀ èdè. Nígbà tí mo rí i pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, mo tún wá ń rò ó lọ́kàn mi pé kí ló tún kù ti mi ò tíì mọ̀.” Kò pẹ́ sígbà náà, òun àti ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ṣèrìbọmi nígbà tó yá.
22 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń yí ìgbésí ayé àwọn tó ń kà á pa dà sí rere, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:13.) Ohun yòówù ká sọ torí kí ọ̀rọ̀ wa lè dénú ọkàn àwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ló ṣì lágbára jù lọ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbàkigbà tá a bá ti rí àǹfààní rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yè!
^ ìpínrọ̀ 20 Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 1987, ojú ìwé 31.