Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Maa Fi Idurosinsin Ti Awon Arakunrin Kristi Leyin

Maa Fi Idurosinsin Ti Awon Arakunrin Kristi Leyin

“Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, ẹ ti ṣe é fún mi.”—MÁT. 25:40.

1, 2. (a) Àpèjúwe wo ni Jésù jíròrò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ló yẹ ká mọ̀ nípa àpèjúwe àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́?

JÉSÙ ti ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn àkókò kan, ìyẹn Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àpèjúwe ẹrú olóòótọ́ àti olóye, àwọn wúńdíá mẹ́wàá àti àwọn tálẹ́ńtì fún wọn ni. Jésù wá fi àpèjúwe kan parí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tí “Ọmọ ènìyàn” máa ṣèdájọ́ “gbogbo orílẹ̀-èdè.” Ó dájú pé àpèjúwe yìí á gbàfiyèsí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gan-an ni! Àpèjúwe Jésù yẹn dá lórí àwùjọ méjì, ó pe àwùjọ kan ní àgùntàn, ó sì pe àwùjọ kejì ní ewúrẹ́. Ó sì tún sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ pàtàkì kan tó jẹ́ ìkẹta, ó pè é ní “àwọn arákùnrin” “Ọba náà.”—Ka Mátíù 25:31-46.

2 Ọjọ́ pẹ́ tí àpèjúwe yìí ti gbàfiyèsí àwa èèyàn Jèhófà, ó sì yẹ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, torí pé inú àpèjúwe yẹn ni Jésù ti jẹ́ ká mọ ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn àwa èèyàn. Ó jẹ́ ká mọ ìdí tí àwọn kan fi máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun, nígbà tó jẹ́ pé àwọn tó kù máa pa run yán-án-yán-án. Tá a bá fẹ́ jogún ìyè àìnípẹ̀kun, ó ṣe pàtàkì pé ká lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Jésù kọ́ni, ká sì ṣiṣẹ́ lé wọn lórí. Torí náà, ó yẹ ká béèrè pé: Báwo ni Jèhófà ṣe ti jẹ́ kí òye wa nípa àpèjúwe yìí túbọ̀ ṣe kedere ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé? Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àpèjúwe yìí túbọ̀ jẹ́ ká mọ bí iṣẹ́ ìwàásù ti ṣe pàtàkì tó? Àwọn wo ló gba àṣẹ náà láti máa wàásù? Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àkókò yìí ló yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí “Ọba náà” àtàwọn tó pè ní “arákùnrin mi”?

BÁWO NI ÒYE TÁ A NÍ ṢE TÚBỌ̀ ṢE KEDERE?

3, 4. (a) Àwọn kókó pàtàkì wo la gbọ́dọ̀ mọ̀ ká tó lè lóye àpèjúwe àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́? (b) Báwo ni ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ṣe ṣàlàyé àpèjúwe yìí lọ́dún 1881?

3 Ká tó lè lóye àpèjúwe àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́ náà lọ́nà tó tọ́, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lóye kókó pàtàkì mẹ́ta nínú àpèjúwe náà, àwọn kókó náà ni: àwọn tá à ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, àkókò ìdájọ́ náà àti ìdí tí àwọn kan fi jẹ́ àgùntàn táwọn kan sì jẹ́ ewúrẹ́.

4 Lọ́dún 1881, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ṣàlàyé pé Jésù ni “Ọmọ ènìyàn,” tá a tún pè ní “Ọba náà.” Nígbà àtijọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà pé ọ̀rọ̀ náà “arakọnrin mi” tó wà nínú Bibeli Mimọ ń tọ́ka sí àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi, ó sì tún ń tọ́ka sí gbogbo aráyé lẹ́yìn tí wọ́n bá ti di pípé lórí ilẹ̀ ayé. Èrò wọn ni pé ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ni yíya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́ máa wáyé. Wọ́n sì tún gbà pé ìdí tí Jésù fi máa ka àwọn kan sí àgùntàn ni pé wọ́n pa òfin Ọlọ́run nípa ìfẹ́ mọ́.

5. Báwo ni òye wa ṣe túbọ̀ ṣe kedere lọ́dún 1923?

5 Lọ́dún 1923, Jèhófà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ túbọ̀ lóye àpèjúwe yìí. Ilé Ìṣọ́ October 15, 1923, ṣàlàyé pé Jésù ni “Ọmọ ènìyàn” náà. Àmọ́, ó ṣe àlàyé tó bọ́gbọ́n mu tá a gbé karí Ìwé Mímọ́ to fi hàn pé kìkì àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run, ìyẹn àwọn arákùnrin Kristi ni àwọn tá à ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, ó sì ṣàlàyé pé àwọn àgùntàn ni àwọn tó nírètí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Kristi. Àkókò wo ni Kristi máa ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́? Àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé tó bá fi máa di ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn arákùnrin Kristi á ti máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run, torí náà kò ní sí pé ẹnikẹ́ni ń ràn wọ́n lọ́wọ́ tàbí pa wọ́n tì. Fún ìdí yìí, ṣáájú ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ni yíya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́ máa wáyé. Nípa ìdí tá a fi máa ka àwọn kan sí àgùntàn, àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé ohun tó máa mú kí á ka àwọn kan sí àgùntàn ni pé wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Olúwa wọn, wọ́n sì gbà pé Ìjọba rẹ̀ nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé.

6. Báwo ni òye wa ṣe túbọ̀ ṣe kedere lọ́dún 1995?

6 Nítorí òye tuntun tá a ní yẹn, àwa èèyàn Jèhófà gbà pé jálẹ̀ àkókò òpin ètò àwọn nǹkan yìí ni Jésù ń ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́, àti pé èyí sinmi lé ìhà tí wọ́n bá kọ sí ìhìn rere náà. Àmọ́, lọ́dún 1995, òye wa túbọ̀ ṣe kedere. Àpilẹ̀kọ méjì nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 1995, sọ ìjọra tó wà láàárín ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 24:29-31 (kà á) àti Mátíù 25:31, 32. (Kà á.) * Kí wá la parí èrò sí? Àpilẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ sọ pé: “Ṣíṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò jẹ́ ní ọjọ́ ọ̀la.” Ìgbà wo gangan ni? “Yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ‘ìpọ́njú ńlá’ náà tí a mẹ́nu kàn ní Matteu 24:29, 30 bá bẹ́ sílẹ̀, tí Ọmọkùnrin ènìyàn sì ‘dé nínú ògo rẹ̀.‘ . . . Nígbà náà, nígbà tí ètò ìgbékalẹ̀ búburú látòkèdélẹ̀ bá ti lọ sí òpin rẹ̀, Jesu yóò pe àpèjọ ìdájọ́, yóò ṣèdájọ́, yóò sì múdàájọ́ ṣẹ.”

7. Òye tó ṣe kedere wo la ti wá ní báyìí?

7 Lóde òní, a ti wá ní òye tó ṣe kedere nípa àpèjúwe àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́. Nípa ti àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú àpèjúwe yìí, Jésù ni “Ọmọ ènìyàn,” ìyẹn Ọba náà. Àwọn tó pè ní “arákùnrin mi” ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Róòmù 8:16, 17) “Àwọn àgùntàn” àti “àwọn ewúrẹ́,” túmọ̀ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn yìí ò sí lára àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yan. Àkókò wo ni ìdájọ́ náà máa wáyé? Ìdájọ́ yìí máa wáyé ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá tó máa bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́. Kí wá ni ìdí tí Jésù máa fi ṣèdájọ́ àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́? Èyí sinmi lé bí wọ́n bá ṣe hùwà sí àwọn tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lára àwọn arákùnrin Kristi tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn. Bí òpin ètò nǹkan yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, a dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí àpèjúwe yìí àtàwọn àpèjúwe tó tan mọ́ ọn tó wà ní Mátíù orí 24 àti 25!

BÁWO NI ÀPÈJÚWE NÁÀ ṢE FI HÀN PÉ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ ṢE PÀTÀKÌ?

8, 9. Kí nìdí tá a fi pe àwọn àgùntàn ní “olódodo”?

8 Nínú àpèjúwe àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́, Jésù ò sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù ní tààràtà. Kí wá nìdí tá a fi lè sọ pé àpèjúwe yẹn jẹ́ ká mọ bí iṣẹ́ ìwàásù ti ṣe pàtàkì tó?

9 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ ká mọ̀ pé ńṣe ni Jésù ń fi àpèjúwe yẹn kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe yíya àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́ gidi sọ́tọ̀ ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bákan náà, kò sọ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí òun máa ṣèdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn gbọ́dọ̀ bọ́ àwọn arákùnrin òun, kí wọ́n da aṣọ bò wọ́n, kí wọ́n ṣètọ́jú wọn tàbí kí wọ́n lọ wò wọ́n lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń ṣàpèjúwe bí àwọn àgùntàn ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe máa hùwà sí àwọn arákùnrin rẹ̀. Ìdí tó fi pe àwọn àgùntàn náà ní “olódodo” ni pé wọ́n gbà pé Kristi ní àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn àgùntàn náà sì ń fi ìdúróṣinṣin ti àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko yìí.—Mát. 10:40-42; 25:40, 46; 2 Tím. 3:1-5.

10. Báwo ni àwọn àgùntàn ṣe lè fi inú rere hàn sí àwọn arákùnrin Kristi?

10 Ohun kejì ni pé ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù ń sọ bọ̀ kó tó sọ àpèjúwe yìí. Ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan. (Mát. 24:3) Kò pẹ́ tí Jésù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó fi sọ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn àmì náà, ìyẹn ni pé, a ó “wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) Kó tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́, ó ti sọ àpèjúwe tálẹ́ńtì. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, Jésù sọ àpèjúwe yẹn láti fi tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, ìyẹn àwọn “arákùnrin” rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, ìwọ̀nba kéréje àwọn ẹni àmì òróró tó ṣì wà láyé nígbà wíwàníhìn-ín Jésù ní ìpèníjà ńlá kan, ìyẹn bí wọ́n ṣe máa wàásù lọ sí “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” kí òpin tó dé. Àpèjúwe àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹni àmì òróró máa ní olùrànlọ́wọ́. Torí náà, ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ọ̀nà tí àwọn tá a máa ṣèdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn lè gbà fi inú rere hàn sí àwọn arákùnrin Kristi ni pé kí wọ́n máa tì wọ́n lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni irú ìtìlẹ́yìn yẹn ní nínú? Ṣé kí wọ́n kàn ṣáà máa fi owó àtàwọn ohun ìní wọn ṣètìlẹ́yìn fún wọn, kí wọ́n sì máa tù wọ́n nínú ni?

ÀWỌN WO LÓ MÁA WÀÁSÙ?

11. Àwọn ìbéèrè wo la lè béèrè, kí sì nìdí?

11 Lóde òní, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn mílíọ̀nù mẹ́jọ tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù kì í ṣe ẹni àmì òróró. Wọn kò gba tálẹ́ńtì tí Jésù fún àwọn ẹrú rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. (Mát. 25:14-18) Torí náà, a lè béèrè pé, ‘Ṣé àṣẹ náà láti máa wàásù kan àwọn tí a kò fi ẹ̀mí mímọ́ yàn?’ Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìdí bíi mélòó kan tí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí fi jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni.

12. Kí la rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 28:19, 20?

12 Jésù fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa wàásù. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n máa kọ́ wọn láti máa pa “gbogbo” ohun tó pa láṣẹ fún wọn mọ́. Iṣẹ́ ìwàásù wà lára àwọn àṣẹ ti Jésù pa fún wọn yẹn. (Ka Mátíù 28:19, 20.) Torí náà, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ló yẹ kó máa wàásù, ì báà jẹ́ pé wọ́n nírètí láti ṣàkóso lọ́run tàbí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣe 10:42.

13. Kí ni ìran tí Jòhánù rí fi hàn, kí sì nìdí?

13 Ìwé Ìṣípayá fi hàn pé àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn tó kù ló máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Nínú ìran tí Jésù fi han àpọ́sítélì Jòhánù, ó rí “ìyàwó” náà, ìyẹn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run, tí wọ́n ń pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣí. 14:1, 3; 22:17) Omi ìṣàpẹẹrẹ yẹn túmọ̀ sí àwọn ìpèsè tí Jèhófà ṣe láti fi gba aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi. (Mát. 20:28; Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:9, 10) Ìràpadà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí à ń wàásù, àwọn ẹni àmì òróró náà sì ń múpò iwájú nínú kíkọ́ àwọn èèyàn nípa rẹ̀, kí wọ́n sì jàǹfààní látinú rẹ̀. (1 Kọ́r. 1:23) Àmọ́ nínú ìran yẹn, Jòhánù rí àwọn míì tí kì í ṣe ará ẹgbẹ́ ìyàwó náà. A sọ fún àwọn náà pé kí wọ́n sọ pé, “Máa bọ̀!” Wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn, àwọn náà sì ń pe àwọn míì pé kí wọ́n wá mu omi ìyè. Àwùjọ kejì yìí jẹ́ àwọn tí wọ́n nírètí láti wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé. Torí náà, ìran yìí fi hàn kedere pé gbogbo àwọn tó bá gba ìpè náà pé kí wọ́n “máa bọ̀” ló ní ojúṣe láti máa wàásù fún àwọn míì.

14. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti fi hàn pé à ń pa òfin Kristi mọ́”?

14 Gbogbo àwọn tó bá wà lábẹ́ “òfin Kristi” gbọ́dọ̀ máa wàásù. (Gál. 6:2) Jèhófà kò ní ọ̀pá ìdiwọ̀n méjì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Òfin kan ni kí ó wà fún ọmọ ìbílẹ̀ àti fún àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní àárín yín.” (Ẹ́kís. 12:49; Léf. 24:22) Àwa Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin Mósè. Àmọ́, à báà jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí a kì í ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo wa la wà lábẹ́ “òfin Kristi.” Gbogbo ohun tí Jésù kọ́ni pátá ló wà nínú òfin yẹn. Èyí tó ga jù lọ nínú ẹ̀kọ́ Jésù ni èyí tó sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa fi ìfẹ́ hàn. (Jòh. 13:35; Ják. 2:8) Ọ̀kan pàtàkì lára ọ̀nà tá à ń gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, Kristi àtàwọn èèyàn ni pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Jòh. 15:10; Ìṣe 1:8.

15. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àṣẹ Jésù kan gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?

15 Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwùjọ kékeré kan tún lè kan ọ̀pọ̀ èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ́kànlá péré ló bá dá májẹ̀mú Ìjọba, àmọ́ gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni májẹ̀mú yẹn kàn. (Lúùkù 22:29, 30; Ìṣí. 5:10; 7:4-8) Bákan náà, ìwọ̀nba àwọn ọmọlẹ́yìn tí Jésù fara hàn lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ ló pàṣẹ fún pé kí wọ́n máa wàásù. (Ìṣe 10:40-42; 1 Kọ́r. 15:6) Àmọ́, gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jésù ní ọ̀rúndún kìíní ló mọ̀ pé àṣẹ yẹn kan àwọn náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kọ́ ni Jésù bá sọ̀rọ̀ ní tààràtà. (Ìṣe 8:4; 1 Pét. 1:8) Bákan náà lónìí, àwọn mílíọ̀nù mẹ́jọ èèyàn tó ń fìtara wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run kọ́ ni Jésù fún ní àṣẹ yẹn ní tààràtà. Àmọ́, gbogbo wa la gbà pé ojúṣe wa ló jẹ́ láti lo ìgbàgbọ́ nínú Kristi ká sì fi ìgbàgbọ́ yìí hàn nípa jíjẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run.—Ják. 2:18.

ÀKÓKÒ TÓ YẸ KÁ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN NÌYÍ

16-18. Báwo làwọn tó fẹ́ wà lára àwọn àgùntàn ṣe lè máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin Kristi, kí sì nìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí?

16 Sátánì ń gbéjà ko àwọn tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé lára àwọn arákùnrin Kristi tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn, ó sì máa túbọ̀ fínná mọ́ wọn bí “sáà àkókò kúkúrú” tó ṣẹ́ kù fún un ṣe ń tán lọ. (Ìṣí. 12:9, 12, 17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ní láti fara da àdánwò ńláǹlà, wọ́n ń bá a nìṣó láti múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó gbòòrò jù lọ nínú ìtàn. Kò sí àní-àní pé Jésù wà pẹ̀lú wọn, ó sì ń darí wọn bí wọ́n ṣe ń sapá lẹ́nu iṣẹ́ yìí.—Mát. 28:20.

17 Awọn tó nírètí láti wà lára àwọn ẹni bí àgùntàn náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i, wọ́n sì kà á sí àǹfààní ńlá pé àwọn ń ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn, kì í ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nìkan àmọ́ láwọn ọ̀nà pàtàkì míì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń fowó ṣètìlẹ́yìn, wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, wọ́n sì máa ń fi ìdúróṣinṣin ṣègbọràn sí àwọn tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” yàn láti máa mú ipò iwájú.—Mát. 24:45-47; Héb. 13:17.

Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn ẹni-bí-àgùntàn ń gbà ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn (Wo ìpínrọ̀ 17)

18 Láìpẹ́, àwọn ańgẹ́lì máa tú ẹ̀fúùfù ìpọ́njú ńlá tí ń pani run dà sórí ayé yìí. Èyí máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí gbogbo àwọn tó bá ṣẹ́ kù sáyé lára àwọn arákùnrin Kristi bá ti gba èdìdì ìkẹyìn wọn. (Ìṣí. 7:1-3) Kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró a ti wà ní ọ̀run. (Mát. 13:41-43) Torí náà, àkókò yìí ló yẹ kí àwọn tó nírètí láti wà lára àwọn tí Jésù máa ṣèdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn máa fi ìdúróṣinṣin ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn.

^ ìpínrọ̀ 6 Fún àlàyé síwájú sí i nípa àpèjúwe yìí, wo àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dúró Níwájú Ìtẹ́ Ìdájọ́?” àti “Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?” nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 1995.