Ta Ló Fà Á?
Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìyà tó ń jẹ wá, ta ló wá fa ebi, ìṣẹ́ àti òṣì, ogun, àìsàn burúkú àti ìjábá tó ń han aráyé léèmọ̀? Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ ohun mẹ́ta tó gbawájú lára àwọn nǹkan tó ń mú kí ìyà máa jẹ aráyé:
Ìmọtara-ẹni-nìkan, Ojúkòkòrò àti Ìkórìíra. “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ìyà sábà máa ń jẹ àwọn èèyàn torí pé àwọn èèyàn aláìpé tó jẹ́ onímọ̀tara-ẹni-nìkan àti ìkà ń hàn wọ́n léèmọ̀.
Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀. Àwọn èèyàn sábà máa ń jìyà torí pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Ìyẹn ni pé, èèyàn lè ṣe kòńgẹ́ aburú, ìjàǹbá lè ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn lè hùwà àìbìkítà tàbí kí wọ́n ṣe àṣìṣe.
Ẹni Ibi Ló Ń Ṣàkóso Ayé. Bíbélì sọ ní kedere olórí ohun tó ń fìyà jẹ àwa èèyàn. Ó ní: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Sátánì Èṣù ni “ẹni burúkú” yẹn. Ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ni, àńgẹ́lì Ọlọ́run ló sì jẹ́ níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.’ (Jòhánù 8:44) Àwọn áńgẹ́lì míì tún dara pọ̀ mọ́ Sátánì, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan wọn mú kí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n sì sọ ara wọn di ẹ̀mí èṣù. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-5) Látìgbà tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù yìí ti ṣọ̀tẹ̀ ni wọ́n ti ń lo agbára wọn láti dá wáhálà ńlá sílẹ̀ láyé. Àkókò tá a wà yìí ló sì le jù. Ní báyìí, inú ń bí Èṣù burúkú-burúkú, ó sì ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà,” ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé “ègbé ni fún ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 12:9, 12) Apàṣẹwàá ni Sátánì, òǹrorò àti ìkà ẹ̀dá sì ni. Ńṣe ló ń yọ̀ ṣìnkìn bó ṣe ń rí i tí ìyà ń jẹ àwa èèyàn. Èṣù ló ń fìyà jẹ́ àwa èèyàn, kì í ṣe Ọlọ́run.
RÒ Ó WÒ NÁ: Ìkà àti olubi ẹ̀dá ló lè máa fìyà jẹ àwọn èèyàn láìṣẹ̀-láìrò. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Torí pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́, “kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú, àti pé kí Olódùmarè hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!”—Jóòbù 34:10.
Síbẹ̀ náà, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé bí Olọ́run á ṣe máa wo Sátánì níran rèé táá sì máa fìyà jẹ àwa èèyàn?’ A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kórìíra ìwà burúkú, ó sì máa ń dùn ún gan-an bá a ṣe ń jìyà. Bákan náà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé ká a ‘kó gbogbo àníyàn wa lé e, nítorí ó bìkítà fún wa.” (1 Pétérù 5:7) Olọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì tún lágbára láti mú gbogbo ìyà tó ń jẹ wá kúrò. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣàlàyé kókó yìí. a
a Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń jìyà lónìí, wo ẹ̀kọ́ 26 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, o tún lè wà á jáde lọ́fẹ̀ẹ́ lórí www.dan124.com/yo