Mo Bọ́ Lọ́wọ́ Ìdààmú Ìgbà Ọ̀dọ́
Mo Bọ́ Lọ́wọ́ Ìdààmú Ìgbà Ọ̀dọ́
Gẹ́gẹ́ bí Eusebio Morcillo ṣe sọ ọ́
Ní September ọdún 1993, mo lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ògbólògbó ọ̀daràn. Ìdí tí mo fi lọ síbẹ̀ ni láti ṣe ìrìbọmi fún ẹlẹ́wọ̀n kan, ìyẹn àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Mariví. Díẹ̀ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n àtàwọn tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ń wò mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bí mo ṣe ń sọ àsọyé ìrìbọmi tí mo sì ṣe ìrìbọmi fún un. Àmọ́ kí n tó sọ ohun tó gbé èmi àti àbúrò mi débẹ̀, ẹ jẹ́ kí n sọ díẹ̀ nínú ìtàn ìgbésí ayé wa fún un yín.
Ọ JỌ́ karùn-ún oṣù karùn-ún, ọdún 1954, ni wọ́n bí mi ní ilẹ̀ Sípéènì. Èmi ni àkọ́bí nínú ọmọ mẹ́jọ táwọn òbí mi bí. Mariví ni ọmọ kẹta. Ìyá tó bí ìyá mi tọ́ wa ká lè gba ẹ̀sìn Kátólíìkì tọkàntọkàn. Mo rántí pé nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, mo máa ń rò ó pé tọkàntọkàn ni mo fi ń sin Ọlọ́run. Àmọ́, wọn ò ráyè ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn rárá nílé àwọn òbí mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni bàbá mi máa ń lu ìyá mi àtàwa ọmọ. Ojoojúmọ́ lẹ̀rù máa ń bà wá, ó sì máa ń dùn mí gan-an láti rí bí ìyá mi ṣe ń jìyà.
Mo tún dojú kọ àwọn nǹkan míì tó bà mí lọ́kàn jẹ́ nílé ìwé. Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́, tó jẹ́ àlùfáà máa ń fi orí wa gbá ògiri tá ò bá gba ìbéèrè tó bi wá. Àlùfáà míì máa ń bá àwọn ọmọbìnrin ṣèṣekúṣe nígbà tó bá ń wo iṣẹ́ àṣetiléwá wọn. Láfikún sí i, àwọn ẹ̀kọ́ Kátólíìkì, irú bí iná ọ̀run àpáàdì máa ń dẹ́rù bà mí ó sì tún máa ń dà mí lọ́kàn rú. Kò sì pẹ́ tí mo fi pa ìjọsìn Ọlọ́run tì.
Mo Dẹni Tó Yàyàkuyà
Nítorí mi ò rí ẹni tó máa kọ́ mi ní ohun tí Ọlọ́run fẹ́, mo dẹni tó ń bá àwọn oníwà ipá àtàwọn oníṣekúṣe kẹ́gbẹ́ nílé ijó. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìjà máa ń bẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì máa ń fi ọ̀bẹ, ẹ̀wọ̀n, ìgò àti àga jà. Èmi kì í sábà báwọn dá sí ìjà o, àmọ́ lọ́jọ́ kan wọ́n lù mí débi pé mo dá kú.
Nígbà tó yá, ibẹ̀ yẹn sú mi, ni mo bá wá ilé ijó tí kò láwọn oníjàgídíjàgan. Àmọ́, oògùn olóró pọ̀ lápọ̀jù láwọn ilé ijó yìí náà. Dípò tí máa fi gbádùn ara mi, kí ọkàn mi sì balẹ̀, ńṣe ni oògùn olóró ń mú mi ṣe ìrànrán, ó sì ń kó àníyàn bá mi.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé yẹn ò tẹ́ mi lọ́rùn, síbẹ̀ mo tan José Luis àbúrò mi ọkùnrin àti Miguel
ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ wọnú ìgbé ayé burúkú yẹn. Kì í ṣe àwa nìkan là ń gbé irú ìgbésí ayé yìí ní ilẹ̀ Sípéènì lásìkò yẹn, àwọn ọ̀dọ́ míì náà yàyàkuyà bíi tiwa. Kò sí nǹkan tí mi ò lè ṣe láti rí owó tí máa fi ra oògùn olóró. Mo wá di aláìlójútì gbáà.Jèhófà Kó Mi Yọ
Láàárín àkókò yìí, mo máa ń bá àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà pé Ọlọ́run wà, a sì tún máa ń sọ nípa ìdí tá a fi wà láàyè. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí máa ṣe mọ Ọlọ́run kiri. Mo ṣèyẹn nípa wíwá ẹni tí máa fọ̀rọ̀ lọ̀. Mo ti kíyè sí i pé Francisco ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ dá yàtọ̀ láàárín àwọn èèyàn tó kù. Ó dà bí i pé ó máa ń láyọ̀, ó sì tún jẹ́ aláìlábòsí àti onínúure, nítorí náà mo pinnu láti sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún un. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Francisco, ó sì fún mi ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa oògùn olóró.
Lẹ́yìn tí mo ka àpilẹ̀kọ náà, mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́, mo ní: “Olúwa, mo mọ̀ pé o wà, nítorí náà mo fẹ́ mọ̀ ọ́, kí n lè máa ṣe ohun tó o fẹ́. Jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́!” Francisco àtàwọn Ẹlẹ́rìí míì fi ọ̀rọ̀ Bíbélì ràn mí lọ́wọ́, wọ́n tún fún mi láwọn ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí n lọ kà á. Àsìkò yìí ló wá yé mi pé àdúrà tí mo gbà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́ ló ti gbà yìí. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àbúrò mi José Luis sọ ohun tí mo ń kọ́ nìyẹn.
Lọ́jọ́ kan, bémi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi ti kúrò lágbo ijó tàka-súfèé, mo yọ ara mi kúrò láàárín wọn. Bí mo ti ta kété tí mo sì ń wò wọ́n, mo wá rí i pé ìwà tó ń ríni lára gbáà la ń hù, torí pé oògùn olóró tá a ń lò ti sọ wá dìdàkudà. Ìgbà yìí gan-an ni mo pinnu láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí mo sì yí bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi padà.
Mo sọ fún Francisco pé kó fún mi ní Bíbélì, ó fún mi, ó sì tún fún mi ní ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye. a Nígbà tí mo kà nípa ìlérí Ọlọ́run pé ó máa nu omijé gbogbo kúrò lójú àwọn èèyàn àti pé kò ní sí ikú mọ́, ó dá mi lójú pé mo ti rí òtítọ́ tó lè sọ èèyàn di òmìnira. (Jòhánù 8:32; Ìṣípayá 21:4) Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tó wú mi lórí jù ni bí gbogbo wọn ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ tí wọ́n sì ń kí ara wọn tọ̀yàyàtọ̀yàyà.
Bí ara mi ti wà lọ́nà láti sọ ohun tí mo rí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo pe José Luis àtàwọn ọ̀rẹ́ mi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo sì sọ gbogbo ohun tí mo rí fún wọn. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, gbogbo wa lọ sípàdé. Ọmọbìnrin tó jókòó sórí àga tó wà ní ìlà iwájú níbi tá a jókòó sí jí wa wò. Ẹnu ti ní láti ya ọmọbìnrin yìí bó ṣe déédéé rí àwọn èèyàn tí irun wọn gùn tí wọ́n sì dá yàtọ̀ láwùjọ, nítorí náà kò yíjú padà sẹ́yìn mọ́. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un láti tún rí wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí kóòtù la wọ̀ a sì tún de táì mọ́rùn.
Kò pẹ́ témi àti Miguel tún fi jọ lọ sí àpéjọ àyíká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A ò rírú ẹ̀ rí láyé wa, ńṣe ni gbogbo wọn àtọmọdé àtàgbà ń ṣe bí ọmọ ìyá. Ohun tó tún wá jẹ́ ìyàlẹ́nu ni pé, inú gbọ̀ngàn tá a ti lọ jó ijó tàka-súfèé láìpẹ́ sí àkókò yẹn ni wọ́n ti ṣe àpéjọ yìí. Àmọ́ lásìkò yìí, orin tá a gbọ́ àti àyíká náà tù wá lára gan-an ni.
Gbogbo ẹgbẹ́ wa bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn náà, ní July 26, ọdún 1974, èmi
àti Miguel ṣèrìbọmi. Ọmọ ogún ọdún ni wá nígbà náà. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà làwọn mẹ́rin lára ẹgbẹ́ wa tún ṣèrìbọmi. Àwọn ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì wá mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ran màmá mi tó ti ń lo ìfaradà látọjọ́ pípẹ́ lọ́wọ́, mo ń bá a ṣe iṣẹ́ ilé mo sì ń sọ ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà gbọ́ fún un. A wá sún mọ́ra gan-an. Mo sì tún sapá gan-an láti ran àwọn àbúrò mi ọkùnrin àtobìnrin lọ́wọ́.Nígbà tó yá, màmá mi àtàwọn àbúrò mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àyàfi àbúrò mi ọkùnrin kan. Lọ́dún 1977, mo gbé Soledad níyàwó. Òun ni ọmọbìnrin tí mo sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan pé ẹnu yà bó ṣe rí wa nígbà tá a kọ́kọ́ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà làwa méjèèjì di aṣáájú-ọ̀nà, báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń pe àwọn tó ń lo àkókò tó pọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù.
Àbúrò Mi Àtàtà Ronú Pìwà Dà
Láti kékeré ni wọ́n ti bá àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Mariví ṣèṣekúṣe, nǹkan burúkú tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí ṣàkóbá fún gan-an. Kò tíì pé ọmọ ogún ọdún tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, tó ń jalè, tó sì tún ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún, ó ti dèrò ẹ̀wọ̀n, kò sì jáwọ́ nínú ìwàkíwà tó ń hù.
Nígbà yẹn, mo jẹ́ alábòójútó àyíká, ìyẹn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ òjíṣẹ́ tó ń rìnrìn àjò láti ìjọ kan sí òmíràn. Lọ́dún 1989, wọ́n gbé èmi àti Soledad ìyàwó mi lọ sí àdúgbò tí Mariví ti ń ṣẹ̀wọ̀n. Kò tíì pẹ́ táwọn aláṣẹ gba ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí bà á lọ́kàn jẹ́, ayé sì sú u. Lọ́jọ́ tí mo lọ wò ó, mo sọ fún un pé kó jẹ́ ká jọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì gbà. Lẹ́yìn oṣù kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó jáwọ́ nínú sìgá mímu àti oògùn olóró. Inú mi dùn gan-an láti rí bí Jèhófà ṣe fún un lágbára tó fi ṣàtúnṣe ìgbé ayé rẹ̀.—Hébérù 4:12.
Kò pẹ́ tí Mariví fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n àtàwọn tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó ń kọ́ nínú Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń gbé e láti ọgbà ẹ̀wọ̀n kan lọ sí òmíràn, kò dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró. Kódà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan, ńṣe ló ń wàásù láti yàrá ẹ̀wọ̀n kan sí òmíràn. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, Mariví ní àwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi tiẹ̀ tó ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ti gbé e lọ.
Lọ́jọ́ kan Mariví sọ fún mi pé òun fẹ́ ya ìgbésí ayé òun sí mímọ́ fún Jèhófà, kóun sì ṣe ìrìbọmi. Àmọ́ wọn ò fún un láyè láti jáde kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọn ò sì gbà kí ẹnikẹ́ni wá ṣe ìrìbọmi fún un lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ọdún mẹ́rin ló fi fara dà á ní àyíká ọgbà ẹ̀wọ̀n tí kò bára dé yẹn. Kí ló ràn án lọ́wọ́ tí kò fi pa ìgbàgbọ́ rẹ̀ tì ní gbogbo àkókò yìí? Ohun tó máa ń ṣe ni pé, nígbà táwọn ìjọ tó wà ní àdúgbò yẹn bá ń ṣe ìpàdé, òun náà máa ń ṣe tiẹ̀ nínú yàrá ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà. Ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì tún máa ń gbàdúrà déédéé.
Láìpẹ́, wọ́n gbé Mariví lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ògbólògbó ọ̀daràn tó ní odò ìlúwẹ̀ẹ́. Ó wò ó pé ibi tóun ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fóun láti ṣe ìrìbọmi. Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, wọ́n gbà á láyè láti ṣèrìbọmi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyí tó fi jẹ́ pé èmi ni mo sọ àsọyé ìrìbọmi rẹ̀. Mo wà pẹ̀lú ẹ̀ nígbà tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀.
Nítorí ìgbésí ayé burúkú tó ti gbé sẹ́yìn, Mariví wá dẹni tó lárùn éèdì. Àmọ́ ìwà rere tó ń hù báyìí jẹ́ kí wọ́n tètè dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ìyẹn ní March 1994. Ó padà sílé, ó wà lọ́dọ̀ Màmá ó sì ń gbé ìgbé ayé Kristẹni títí dìgbà tó fi kú ní ọdún méjì lẹ́yìn náà.
Mo Borí Èrò Tó Ń Dà Mí Láàmú
Kì í ṣe pé èmi náà kò rí àbájáde ìgbésí ayé tí kò tọ́ tí mo ti gbé sẹ́yìn. Bí bàbá mi ṣe máa ń lù mí nílùkulù àti bí mo ṣe gbé ìgbé ayé mi nígbà Aísáyà 1:18 àti Sáàmù 103:8-13 tún ti ràn mí lọ́wọ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún wá tí mo fi ń dín bí mo ṣe ń ronú nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti dá sẹ́yìn kù.
tí mo wà lọ́mọdé ṣèpalára fún mi. Nígbà tí mo wá dàgbà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń kábàámọ̀ àwọn ohun tí mo ti ṣe, tí mo sì máa ń ronú pé mi ò wúlò fún nǹkan kan. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn máa ń bá mi. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ kí n lè borí àwọn èrò tó ń dà mí láàmú yìí. Bí mo tún ṣe máa ń ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì bíÀdúrà tún jẹ́ nǹkan míì tó ràn mí lọ́wọ́ láti borí èrò tí mo ní pé mi ò wúlò fún nǹkan kan. Gbogbo ìgbà ni omijé máa ń dà lójú mi tí mo bá ń gbàdúrà sí Jèhófà. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Jòhánù 3:19, 20 ti fún mi lágbára gan-an ni. Ó ní: “Nípa èyí ni àwa yóò mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti inú òtítọ́, a óò sì fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú níwájú rẹ̀ ní ti ohun yòówù nínú èyí tí ọkàn-àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi, nítorí Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.”
Nítorí pé mo ń sún mọ́ Ọlọ́run lóòótọ́ pẹ̀lú ọkàn-àyà “tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀,” mo wá rí i pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ mi burú tó. Bíbélì mú un dá àwọn tó ń wá Jèhófà lójú pé Jèhófà kì í tẹ́ńbẹ́lú àwọn tó fi tọkàntọkàn kábàámọ̀ ìwà tí wọ́n ti hù sẹ́yìn tí wọ́n sì ti wá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 51:17.
Ìgbàkigbà tí mo bá ti ń ṣiyèméjì nípa ara mi, ṣe ni mo máa ń gbìyànjú láti máa ro ohun tó tọ́, àtàwọn èrò tó mọ́, irú èyí tó wà nínú Fílípì 4:8. Mo ti há ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù ìkẹtàlélógún àti Ìwàásù Lórí Òkè sórí. Nígbà táwọn èrò tí kò tọ́ bá wá sí mi lọ́kàn, ńṣe ni mo máa ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo ti há sórí wọ̀nyí. Bí mo ṣe ń fìyẹn rọ́pò èrò burúkú tó ń wá sí mi lọ́kàn ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an láwọn ìgbà tí mi ò bá rí oorun sùn lóru.
Ohun tó tún ràn mí lọ́wọ́ ni bí ìyàwó mi àtàwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe máa ń fún mi níṣìírí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ó ṣòro fún mi láti gba àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ láti fi fún mi níṣìírí gbọ́, àmọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí n lóye pé ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:7) Àti pé, mo ti wá gbà pé mo ṣì láwọn ibi tí mo kù díẹ̀ káàtó sí.
Kì í ṣe pé àwọn ohun tí mo ń rò nípa ara mi kò ní àǹfààní tó ṣe, ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò tó láàánú. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n ọdún báyìí témi àti ìyàwó mi ti jẹ́ òjíṣẹ́ tó ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. Ayọ̀ tí mo ń ní nígbà tí mo bá ń ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì ti jẹ́ kí ìdààmú tí mo máa ń ní lórí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi tẹ́lẹ̀ rí dín kù.
Ní báyìí, tí mo bá ronú padà sẹ́yìn nípa ìgbésí ayé mi àti bí Jèhófà ṣe bù kún mi, ńṣe lọ̀rọ̀ onísáàmù yìí máa ń wá sí mi lọ́kàn, ó ní: “Fi ìbùkún fún Jèhófà, . . . ẹni tí ń dárí gbogbo ìṣìnà rẹ jì, ẹni tí ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn, ẹni tí ń gba ìwàláàyè rẹ padà kúrò nínú kòtò, ẹni tí ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú dé ọ ládé.”—Sáàmù 103:1-4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń kábàámọ̀ àwọn ohun tí mo ti ṣe, tí mo sì máa ń ronú pé mi ò wúlò fún nǹkan kan. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ kí n borí àwọn èrò tó ń dà mí láàmú yìí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àbúrò mi José Luis àti ọ̀rẹ́ mi Miguel tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú mi àti àpẹẹrẹ rere mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
Ìdílé Morcillo lọ́dún 1973
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Nígbà tí Mariví wà lẹ́wọ̀n
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Èmi àti Soledad ìyàwó mi