Ìṣẹ̀dá Ń Fi Ọgbọ́n Ọlọ́run Hàn
Ìṣẹ̀dá Ń Fi Ọgbọ́n Ọlọ́run Hàn
“Òun ni Ẹni tí ń kọ́ wa ju àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé, ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹ̀dá tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá.”—JÓÒBÙ 35:11.
ORÍṢIRÍṢI àrà làwọn ẹyẹ máa ń dá. Bí wọ́n ṣe máa ń dárà lójú ọ̀run máa ń jọ àwọn tó ṣe ọkọ̀ òfuurufú lójú gan-an. Àwọn ẹyẹ kan máa ń fo ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lórí agbami òkun láìsí ohun tó máa fi wọ́n mọ̀nà, wọ́n á sì dé ibi tí wọ́n ń lọ láìṣìnà.
Àrà mìíràn tó ta yọ táwọn ẹyẹ tún máa ń dá tó fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni Ẹni tó dá wọn ni pé, wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè fi ìró àti orin bára wọn sọ̀rọ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
Àwọn Ẹyẹ Máa Ń Bára Wọn Sọ̀rọ̀
Oríṣi àwọn ẹyẹ kan máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó jáde nínú ilé ẹyin. Bí àpẹẹrẹ, ó kéré tán, abo àparò máa ń yé ẹyin tó mẹ́jọ, ẹyin kan ló sì ń yé lóòjọ́. Bí ọmọ tó wà nínú ẹyin kọ̀ọ̀kan bá dàgbà bó ṣe yẹ, á jẹ́ pé ọjọ́ mẹ́jọ ló máa gbà kí gbogbo wọn tó jáde tán nínú ilé ẹyin wọn. Yóò wá di pé kí ìyá àwọn ọmọ ẹyẹ náà gba iṣẹ́ títọ́jú àwọn tó ti jáde nínú ẹyin wọn nígbà tí àwọn ọmọ yòókù kò tíì jáde. Àmọ́, dípò ìyẹn, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé gbogbo ẹyin mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ náà ló ń pamọ sọ́wọ́ kan náà láàárín wákàtí mẹ́fà. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe? Ìdí pàtàkì kan táwọn aṣèwádìí sọ pé ó fà á ni pé àwọn ọmọ ẹyẹ àparò tó wà nínú ilé ẹyin máa ń ta ara wọn lólobó, tí wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣètò láti jáde kúrò nínú ilé ẹyin wọn lákòókò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìgbà kan náà.
Nígbà táwọn ẹyẹ bá dàgbà, àwọn akọ ló sábà máa ń kọrin. Wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gùn, kí wọ́n bàa lè fàmì sí ibi tí wọ́n máa ń jẹ̀ dé, tàbí láti fa abo mọ́ra. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹyẹ ló wà lóríṣiríṣi, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ní ìró tirẹ̀.
Èyí ló máa ń jẹ́ káwọn abo mọ àwọn akọ tó jẹ́ irú tiwọn.Òwúrọ̀ kùtùkùtù àti ìrọ̀lẹ́ làwọn ẹyẹ sábà máa ń kọrin, ó sì nídìí tó fi jẹ́ pé àkókò yẹn ni wọ́n ń kọrin. Ìdí náà ni pé afẹ́fẹ́ àti ariwo tó lè di orin ẹyẹ lọ́wọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lákòókò yẹn. Àwọn aṣèwádìí ti wá rí i pé òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ làwọn ẹyẹ máa ń kọrin dáadáa ju ti ọ̀sán lọ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akọ ẹyẹ ló sábà máa ń kọrin, àti akọ àti abo ló ní oríṣiríṣi ìró tó ní ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, irú àwọn ẹyẹ ìbákà kan ní ìró ohùn mẹ́sàn-án tó yàtọ̀ síra wọn. Ìró kan wà fún ṣíṣe ìkìlọ̀ nípa ewu tó wà lójú ọ̀run, irú bí ìgbà tí ẹyẹ apẹyẹjẹ bá ń fò kiri, ó tún ní ìró mìíràn tó fi ń ṣèkìlọ̀ nígbà tí ewu bá wà lórí ilẹ̀.
Ẹ̀bùn Tó Dára Jù Lọ
Ọgbọ́n tí Ọlọ́run dá mọ́ àwọn ẹyẹ wúni lórí gan-an ni. Àmọ́ tó bá kan ti ọ̀rọ̀ sísọ, àwa èèyàn ló ta yọ. Jóòbù 35:11 sọ pé, Ọlọ́run dá àwa èèyàn lọ́nà tá a fi “gbọ́n ju àwọn ẹ̀dá tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá.” Ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àwa èèyàn ni pé a lè fi ohùn wa ṣàlàyé nǹkan tó díjú kó sì yéni yékéyéké, a sì tún máa ń fara ṣàpèjúwe nǹkan.
Ó jọ pé Ọlọ́run ti dá a mọ́ àwọn ọmọdé láti kọ́ àwọn èdè tó díjú, kò sì sí ẹ̀dá abẹ̀mí mìíràn tó nírú ẹ̀bùn yìí. Ìwé ìròyìn kan tó wà lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ American Scientist sọ pé: “Àwọn ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ máa ń kọ́ èdè báwọn òbí wọn ò bá tiẹ̀ bá wọn sọ ọ́ ní tààràtà; àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ adití tiẹ̀ máa ń hùmọ̀ èdè adití tiwọn fúnra wọn bí wọn ò bá tiẹ̀ kọ́ wọn ní èdè adití nílé wọn.”
Agbára táwa èèyàn ní láti fi ọ̀rọ̀ tàbí àmì sọ ohun tá à ń rò, tí a sì lè fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa hàn jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, ẹ̀bùn tó tóbi jù lọ tí Ọlọ́run fún àwa èèyàn ni pé a lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà. Kódà, Jèhófà Ọlọ́run ń rọ̀ wá pé ká máa bá òun sọ̀rọ̀. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.
Nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu tó le, Jèhófà fẹ́ ká wá ọgbọ́n lọ sínú ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì. Jèhófà sì tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe máa lo àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì. Jákọ́bù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.”—Jákọ́bù 1:5.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́?
Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nígbà tó o bá ń gbọ́ orin dídùn yùngbà táwọn ẹyẹ ń kọ? Tàbí tó o bá ń gbọ́ tí ọmọ kékeré kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bá a ṣe ń sọ̀rọ̀? Ǹjẹ́ o rí ọgbọ́n Ọlọ́run nínú àwọn ohun tó dá wọ̀nyí?
Lẹ́yìn tí Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù ti ṣàṣàrò lórí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá òun, ó sọ látọkàn wá fún Ọlọ́run pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.” (Sáàmù 139:14) Bó o ṣe ń mọrírì àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tó o sì ń ronú nípa bí wọ́n ṣe ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn, ó dájú pé ìgbàgbọ́ tó o ní pé Ọlọ́run á máa tọ́ ẹ sọ́nà yóò túbọ̀ máa lágbára sí i.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Agbára ọ̀rọ̀ sísọ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
© Dayton Wild/Visuals Unlimited