Ìfẹ́ Ìyá sí Ọmọ Ń Gbé Ìfẹ́ Ọlọ́run Yọ
Ìfẹ́ Ìyá sí Ọmọ Ń Gbé Ìfẹ́ Ọlọ́run Yọ
“Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé.”—AÍSÁYÀ 49:15.
ABIYAMỌ kan rọra gbé ọmọ jòjòló rẹ̀ sọ́wọ́ bó ṣe ń tọ́jú rẹ̀. Bí ìyá àtọmọ rẹ̀ jòjòló bá wà pa pọ̀ báyìí ńṣe ló ń fi àbójútó àti ìfẹ́ hàn. Ìyá kan tórúkọ rẹ̀ jẹ́ Pam sọ pé: “Ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ gbé ọmọ mi sọ́wọ́ ni mo mọ̀ ohun tí wọ́n ń pè ní ìfẹ́ ìyá sọ́mọ lọ́nà tó kàmàmà, mo sì wá rí i pé mo gbọ́dọ̀ bójú tó ọmọ jòjòló náà.”
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ìfẹ́ ìyá sọ́mọ máa ń kópa tó lágbára lórí ìdàgbàsókè ọmọ. Ìwádìí sì ti wá fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ dáadáa. Ìwé kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe jáde lórí Ètò Ìlera Ọpọlọ sọ pé: “Ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ìkókó táwọn òbí wọn pa tì tàbí tí wọ́n gbé kúrò lọ́dọ̀ ìyá wọn kì í láyọ̀, wọ́n máa ń ní ìdààmú ọkàn, ìyẹn sì tún máa ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn ọmọ náà.” Ìwé yìí tún sọ pé, ìwádìí fi hàn pé àwọn ọmọ tí wọ́n bá fìfẹ́ hàn sí tí wọ́n sì ń bójú tó láti kékeré sábà máa ń ní làákàyè tó pọ̀ ju tàwọn ọmọ tí wọ́n pa tì lọ.
Nígbà tí Alan Schore, ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó jẹ́ oníṣègùn ọpọlọ tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti Yunifásítì California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń ṣàlàyé lórí bí ìfẹ́ ìyá sọmọ ti ṣe pàtàkì tó, ó ní: “Ní gbàrà tí wọ́n bá bí ọmọ kan, àjọṣe tó wà láàárín ìyá náà àti ọmọ rẹ̀ ló máa ń jẹ́ ìpìlẹ̀ fún àjọṣe èyíkéyìí tí ọmọ náà máa ní pẹ̀lú àwọn èèyàn nígbà tó bá dàgbà.”
Ó ba ni nínú jẹ́ pé ipò ìbànújẹ́, àìsàn tàbí àwọn ìnira míì lè mú kí abiyamọ Aísáyà 49:15) Àmọ́, kì í sábà ṣẹlẹ̀ pé kí ìyá gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀. Kódà, ó jọ pé Ọlọ́run ti dá a mọ́ àwọn abiyamọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn. Ìwádìí kan táwọn èèyàn ṣe fi hàn pé omi ara kan tí wọ́n ń pè ní oxytocin máa ń pọ̀ gan-an lára àwọn obìnrin nígbà ìbímọ, omi ara yìí ló ń mú kí ilé ọmọ tètè padà sípò lẹ́yìn ìbímọ, òun ló tún ń mú kí ara abiyamọ mú wàrà jáde fún ọmọ jòjòló. Omi ara yìí tó wà lára ọkùnrin àtobìnrin ni wọ́n tún gbà pé ó ń kó ipa pàtàkì nínú bí abiyamọ ṣe máa ń fi ìfẹ́ àti ojú àánú tọ́jú ọmọ rẹ̀.
kan gbàgbé “ọmọ ẹnu ọmú” rẹ̀. (Ibo Ni Ìfẹ́ Ti Wá?
Àwọn kan wà tí wọ́n gbà pé èèyàn àti ayé òun ìsálú ọ̀run ṣàdédé wà ni, kò sẹ́ni tó dá wọn. Àwọn wọ̀nyí ń kọ́ni pé ńṣe ni ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan, irú èyí tó wà láàárín ìyá àtọmọ ṣàdédé wà ni. Wọ́n sọ pé nítorí pé ìfẹ́ náà ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní ni kò sì ṣe dópin. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn orí íńtánẹ́ẹ̀tì kan tó dá lórí ojúṣe ìyá, tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Mothering Magazine sọ pé: “Apá àkọ́kọ́ nínú ọpọlọ àwa èèyàn tó wà láfikún sí ọpọlọ tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn ẹranko afàyàfà ló máa ń jẹ́ kéèyàn mọ nǹkan lára. Apá yìí nínú ọpọlọ èèyàn ló máa ń mú kí ìyá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ gan-an.”
Lóòótọ́, ìwádìí fi hàn pé apá ibì kan wà nínú ọpọlọ èèyàn tó máa ń jẹ́ kéèyàn mọ nǹkan lára. Àmọ́ ǹjẹ́ o rò pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ọpọlọ tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn ẹranko afàyàfà ló ń mú kí ìfẹ́ wà láàárín ìyá àtọmọ?
Wá wo àlàyé mìíràn lórí kókó yìí. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, èyí túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn lè gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Ìfẹ́ ni olórí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run.” Kí nìdí? Ìdí ni pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yìí kò sọ pé Ọlọ́run ní ìfẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìfẹ́ ti wá.
Wo bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìfẹ́, ó ní: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (1 Kọ́ríńtì 13:4-8) Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbà pé nípasẹ̀ èèṣì ni ànímọ́ tó wúni lórí jù lọ yìí fi wà?
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́?
Nígbà tó o kà ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ ní ìpínrọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí yìí, ǹjẹ́ kò wù ọ́ pé kéèyàn kan fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí ọ? Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa yán hànhàn fún ìfẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé “àwa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọlọ́run.” (Ìṣe 17:29) Ọlọ́run dá wa lọ́nà tá a fi lè máa fìfẹ́ hàn síra wa. Ó sì dá wa lójú pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa jinlẹ̀ gan-an. (Jòhánù 3:16; 1 Pétérù 5:6, 7) Ẹsẹ Bíbélì tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa lágbára gan-an ni, ó sì wà pẹ́ títí, kódà, ó ju ìfẹ́ tí abiyamọ ní sọ́mọ rẹ̀ lọ!
Èyí lè mú kó o ṣe kàyéfì pé: ‘Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run gbọ́n, tó lágbára, tó sì nífẹ̀ẹ́ wa, kí ló dé tí kò fi fòpin sí ìyà tó ń jẹ́ àwa èèyàn? Kí ló dé tó fi ń wòran táwọn ọmọdé ń kú, tí ìnira ń pọ̀ sí i, táwọn ọ̀bàyéjẹ́ àtàwọn oníwọra ẹ̀dá sì ń bayé jẹ́?’ Àwọn ìbéèrè onílàákàyè nìwọ̀nyí, wọ́n sì ń fẹ́ ìdáhùn tó mọ́gbọ́n dáni.
Ohun yòówù káwọn tó sọ pé Ọlọ́run ò ṣeé mọ̀ sọ, a lè rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn, ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún orílẹ̀-èdè ló ti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn tó ń ṣe ìwé ìròyìn yìí rọ̀ ẹ́ pé kíwọ náà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ìmọ̀ tó o ní nípa Ọlọ́run bá ṣe túbọ̀ ń jinlẹ̀ sí i, látinú ohun tó o kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti lára àwọn nǹkan tó dá, wàá mọ̀ pé Ọlọ́run ò jìnnà sí wa rárá, kì í sì í ṣe Ọlọ́run tí kò ṣeé mọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á wá gbà pé Ọlọ́run “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:27.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa lágbára ju ìfẹ́ tí abiyamọ ní sọ́mọ rẹ̀ lọ