Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Títí Láé Ni Ayé Yìí Máa Wà?

Ṣé Títí Láé Ni Ayé Yìí Máa Wà?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣé Títí Láé Ni Ayé Yìí Máa Wà?

Àjálù kankan ò ní pa àgbáyé wa yìí run. Kí nìdí tí èyí fi dá wa lójú? Ìdí ni pé Ọlọ́run ṣèlérí pé: “A kì yóò mú kí [ayé] ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Bíbélì sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé, “iran kan lọ, iran kan si bọ̀: ṣugbọn aiye duro titi lai.”—Oníwàásù 1:4, Bibeli Mimọ.

Ọ̀rọ̀ Hébérù méjì tí wọ́n lò ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nínú Sáàmù 104:5 tá a fà yọ lókè yìí jẹ́ ká rí i pé mìmì kan ò ní mi ayé. Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ni ʽoh·lamʹ tó dúró fún “àkókò tí ó lọ kánrin” àti ʽadh tó dúró fún “títí láé.” A lè túmọ̀ ʽoh·lamʹ sí “ọ̀pọ̀ ọdún” tàbí “títí ayé.” Gẹ́gẹ́ bí Harkavy’s Students’ Hebrew and Chaldee Dictionary ṣe sọ, ʽadh túmọ̀ sí “àkókò gígùn, àìnípẹ̀kun, títí gbére, títí láé.” Àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù méjèèjì yìí túbọ̀ jẹ́ kó dájú gbangba pé mìmì kankan ò lè mi ayé yìí, ńṣe ni yóò máa wà títí lọ gbére. Jẹ́ ká tún ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí mìíràn tó wà nínú Bíbélì tá a fi lè gbà pé ayé yóò wà títí láé.

Àkọ́kọ́, Ọlọ́run dá ayé káwa èèyàn lè máa gbé inú rẹ̀. Kó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá, Párádísè ọ̀gbà ìdẹ̀ra tó kárí ayé, kì í ṣe ibi jákujàku tí kò ṣeé gbé. Aísáyà 45:18 sọ pé Jèhófà ni “Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ẹni tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.”

Ìkejì, tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti ṣèlérí pé ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ràn sóun lẹ́nu yóò máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé yìí lálàáfíà. Míkà orí kẹrin ẹsẹ kẹrin sọ pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.” Nítorí náà, níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn, ayé yìí gbọ́dọ̀ máa jẹ́ ibùgbé àwọn èèyàn títí láé. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, òtúbáńtẹ́ ni ìlérí Ọlọ́run.—Sáàmù 119:90; Aísáyà 55:11; 1 Jòhánù 2:17.

Ìkẹ́ta, Ọlọ́run ti gbé iṣẹ́ àbójútó ayé yìí lé àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sáàmù 115:16) Ṣé o rò pé bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ lè fún ọmọ náà ní ẹ̀bùn dáradára kan, kó sì wá ba ẹ̀bùn náà jẹ́ mọ́ ọn lọ́wọ́ nígbà tó yá? Láéláé! Bákan náà, Jèhófà ò ní ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún ayé àtàwọn tó ń gbénú rẹ̀, torí pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.

Jésù Kristi sọ ọ̀rọ̀ ìdánilójú yìí nípa Bàbá rẹ̀, pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Ọlọ́run tí kò sì lè parọ́ ṣèlérí pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29; Títù 1:2.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwòrán ayé: Inú fọ́tò NASA la ti rí i