Bá A Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Ọmọ Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Bàlágà Sọ̀rọ̀
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bá A Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Ọmọ Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Bàlágà Sọ̀rọ̀
“Nígbà kan, kì í ṣòro fún mi rárá láti bá ọmọkùnrin mi sọ̀rọ̀, àmọ́ ní báyìí tó tí di ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó ṣòro fún èmi àti ọkọ mi láti mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Ńṣe ló kàn máa ń dá wà nínú yàrá rẹ̀, agbára káká ló sì fi máa ń bá wa sọ̀rọ̀!”—ÌYÁÀFIN MIRIAM, LÁTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ MẸ́SÍKÒ.
“Nígbà kan, àwọn ọmọ mi máa ń fẹ́ gbọ́ ohunkóhun tí mo bá fẹ́ sọ fún wọn. Ńṣe ni ara wọn máa ń wà lọ́nà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi! Àmọ́, ní báyìí tí wọ́n ti ń bàlágà, ohun tí wọ́n máa ń sọ ni pé, bó ṣe ń ṣe àwọn kò lè yé mi rárá.”—Ọ̀GBẸ́NI SCOTT, LÁTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ ỌSIRÉLÍÀ.
TÓ O bá ní ọmọ tó ṣẹ̀sẹ̀ ń bàlágà, ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn òbí tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí lè máa ṣẹlẹ̀ síwọ náà. Bóyá nígbà kan rí, ńṣe ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín ìwọ pẹ̀lú ọmọ rẹ dà bí ojú pópó kan tó fẹ̀ dáadáa, tí ọkọ̀ ń lọ tó ń bọ̀ lórí rẹ̀ tí ọ̀kan kò sì kọ lu èkejì. Àmọ́ ní báyìí, ọ̀nà tó fẹ̀ dáadáa tẹ́lẹ̀ yẹn ti wá dí pa. Obìnrin kan tó ń dá tọ́ ọmọ lórílẹ̀-èdè Ítálì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Angela sọ pé: “Nígbà tí ọmọkùnrin mi ṣì kéré, ńṣe ló máa ń da ìbéèrè bò mí lóríṣiríṣi, àmọ́ ní báyìí, èmi ni mo máa ń dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀. Bí mi ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè wà bẹ́ẹ̀ ká má jọ sọ̀rọ̀ gidi kan fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.”
Bíi ti ìyáàfin Angela yìí, bóyá nígbà kan rí ọmọ rẹ máa ń bá ẹ sọ̀rọ̀ dáadáa, àmọ́ bó ṣe di pé ó ń bàlágà báyìí ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í dinú, tí kò fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀ mọ́. Pẹ̀lú gbogbo bó o ṣe ń sapá tó láti bá a sọ̀rọ̀, ó lè jẹ́ pé ńṣe ló kàn máa fèsì gán-ún. Bóyá o bi ọmọkùnrin rẹ pé, “Báwo lònìí ti rí?” àmọ́, tó kàn dáhùn ṣákálá pé, “Dáadáa ni.” Bóyá o sì bi ọmọbìnrin rẹ pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ níléèwé yín lónìí?” àmọ́ tó fèsì gán-ún pé, “Kò sí nǹkan kan.” Bóyá níbi tó o ti ń gbìyànjú kọ́mọ náà tiẹ̀ sọ̀rọ̀ díẹ̀ sí i, o sọ pé, “Ṣé o ò fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ ni?” Ló bá di wẹ́lo, ọmọ náà ò wá kúkú fèsì mọ́.
Lóòótọ́, àwọn ọmọ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Àmọ́, kì í ṣohun táwọn òbí wọn fẹ́ gbọ́ ni wọ́n sábà máa ń sọ. Obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Edna, ní Nàìjíríà sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, tí mo bá ní kí ọmọbìnrin mi bá mi ṣe nǹkan, ńṣe ló máa ń sọ fún mi pé ‘Ẹ fi mí sílẹ̀ jọ̀ọ́.’ Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ramón, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò náà nírú ìṣòro yìí pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Ó ní: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ la máa ń bára wa jiyàn. Nígbàkigbà tí mo bá ní kó bá mi ṣe nǹkan kan, ńṣe lá máa sọ-tibí-sọ-tọ̀hún-ún, tá ṣáà máa wá bí kò ṣe ní ṣe nǹkan ọ̀hún.”
Tí òbí bá ń bá ọmọ sọ̀rọ̀, tọ́mọ náà sì wá ń dágunlá, ó máa ń tán òbí ní sùúrù. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Obìnrin kan tó ń dá tọ́mọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, tó ń jẹ́ Anna sọ pé: “Nígbà tó di pé mi ò tiẹ̀ wá mọ ohun tó wà lọ́kàn ọmọkùnrin mi mọ́, inú bí mi burúkú-burúkú, débi pé ó ń ṣe mí bíi pé kí n jágbe mọ́ ọn.” Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìgbà tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì gan-an làwọn ọ̀dọ́ àtàwọn òbí wọn kì í lè bára wọn sọ̀rọ̀?
Bá A Ṣe Lè Mọ Àwọn Ohun Tó Máa Ń Dènà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ju pé kéèyàn kan ṣáà máa sọ̀rọ̀ nìkan. Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Lúùkù 6:45) Nípasẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dára, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ẹlòmíì, wọ́n sì lè mọ àwọn nǹkan kan nípa wa. Kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá fáwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde. Nítorí pé, táwọn ọmọ bá ti ń bàlágà, àwọn àyípadà kan máa n dédé ṣẹlẹ̀. Kódà ọmọ tó jẹ́ pé ara ẹ̀ yọ̀ mọ́ èèyàn tẹ́lẹ̀ lè ṣàdédé máa tijú. Àwọn ògbóǹkangí kan sọ pé ó máa ń ṣe àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà bíi pé wọ́n wà níwájú àwùjọ kan tó dajú bò wọ́n, bí ìgbà tí wọ́n wà lórí ìtàgé kan tí wọ́n wá tanná sí wọn. Nítorí pé ojú ń ti àwọn ọ̀dọ́ yìí, tí wọn ò sì fẹ́ káwọn èèyàn máa wò wọ́n, ńṣe ló máa ń dà bíi pé wọ́n kúkú wá fa aṣọ orí ìtàgé tá a fi ṣàpẹẹrẹ yẹn wálẹ̀ káwọn tó ń dajú bò wọ́n má bàa rí wọn mọ́. Wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀.
Ohun míì tó máa ń dènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà àtàwọn òbí wọn ni pé, àwọn ọ̀dọ́ yìí máa ń fẹ́ òmìnira. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé bọ́mọ ṣe ń dàgbà, ńṣe lá fẹ́ máa dá ṣe nǹkan tí kò sì ní fẹ́ kẹ́nì kankan dá sọ́rọ̀ òun. Èyí ò wá túmọ̀ sí pé ọmọ náà ti ṣe tán láti filé sílẹ̀ o. Ó ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà ìwọ òbí rẹ̀ lọ́pọ̀ ọ̀nà, àní ju tàtẹ̀yìnwá lọ pàápàá. Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà tó di àgbàlagbà ni ìgbà tó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ tá a sọ yìí o. Báwọn ọmọ ṣe ń bàlágà, ọ̀pọ̀ nínú wọn máa ń fẹ́ dá ronú lórí nǹkan, kí wọ́n sì pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe kó tó di pé wọ́n jẹ́ káwọn ẹlòmíì mọ̀ nípa rẹ̀.
Àmọ́, ohun kan ni pé, àwọn ọ̀dọ́ kì í sábà fi nǹkan pa mọ́ fáwọn ojúgbà wọn. Lórí ọ̀rọ̀ yìí, obìnrin kan tó ń jẹ́ Jessica lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Nígbà tí ọmọbìnrin mi ṣì kéré, ìgbà gbogbo ló máa ń sọ àwọn ìṣòro rẹ̀ fún mi, àmọ́ ní báyìí, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló ń lọ bá.” Tá a bá rí òbí èyíkéyìí tírú èyí ṣẹlẹ̀ sí, má ṣe rò pé ọmọ yẹn ti kọ̀ ẹ́ lóbìí o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ìwádìí sọ ni pé, bó bá tiẹ̀ dà bíi pé àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà ò gba ohun táwọn òbí wọn ń sọ fún wọn, wọ́n ṣì ka ìmọ̀ràn táwọn òbí wọn ń fún wọn sí pàtàkì ju tàwọn ọ̀rẹ́ wọn lọ. Báwo ni ìwọ òbí ṣe lè rí i dájú pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó mọ́yán lórí wà láàárín ìwọ àti ọmọ rẹ?
Mú Àwọn Ohun Ìdènà Kúrò Kó O Lè Ṣàṣeyọrí
Ká sọ pé ò ń wa ọ̀kọ̀ lọ lójú pópó kan tó lọ gbọnrangandan. Látìgbà tó o ti gbéra ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn yìí, ńṣe lo kàn rọra ń yí àgbá ìtọ́kọ̀ rẹ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Àmọ́, lójijì lo rí i pé ọ̀nà náà dédé yà. Tí o kò bá fẹ́ kí ọkọ̀ rẹ dà nù, ńṣe ni wàá yí àgbá ìtọ́kọ̀ rẹ síbi tí ọ̀nà ti yà yẹn. Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn bọ́mọ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, fún ọ̀pọ̀ ọdún, wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ báyìí ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ máa ń lọ láàárín ìwọ àti ọmọ rẹ, tí kò sì sí wàhálà kankan. Àmọ́ ní báyìí, ńṣe ló dà bíi pé ìgbé ayé ọmọ rẹ ṣàdédé yà, ìwọ òbí náà sì gbọ́dọ̀ yí ọwọ́ sí ọ̀nà tó yà yẹn, nípa ṣíṣe àyípadà nínú ọ̀nà tó o ń gbà bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀. Wàyí o, bi ara rẹ láwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
▪ ‘Bí ọmọ mi bá fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀, ṣé èmi náà ti múra tán láti bá a sọ̀rọ̀?’ Bíbélì sọ pé: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 25:11) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí mú kó ṣe kedere pé àsìkò tó tọ́ ló yẹ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wáyé. Wo àpèjúwe yìí ná: Kò sóhun tí àgbẹ̀ kan lè ṣe tá á fi mú kí ìgbà ìkórè yára ju ìgbà tó yẹ kó wáyé lọ, bákan náà ni kò lè ṣe nǹkan kan láti sún ìgbà ìkórè síwájú. Ohun tí àgbẹ̀ náà lè ṣe kò ju pé kó ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe tí ìgbà ìkórè bá dé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò kan pàtó wà tí ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà máa ń fẹ́ láti sọ̀rọ̀. Ńṣe ni kó o lo àǹfààní yẹn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Frances tó ń dá tọ́mọ lórílẹ̀ èdè Ọsirélíà, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọmọbìnrin mi máa ń wá sínú yàrá mi lálẹ́, tí á sì lò tó wákàtí kan pẹ̀lú mi. Lóòótọ́, kò rọrùn fún mi rárá láti bá ọmọ mi sọ̀rọ̀ nírú àkókò yìí, nítorí mo máa ń tètè sùn. Àmọ́, kò sóhun tá a kì í sọ tán tó bá wá sọ́dọ̀ mi láwọn àkókò yẹn.”
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà kò fẹ́ bá ẹ ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, gbìyànjú kẹ́ ẹ jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀. Ẹ lè jọ kẹ́sẹ̀ rìn lọ síbì kan, kẹ́ ẹ jọ wakọ̀ jáde lọ, kẹ́ ẹ jọ ṣeré àṣedárayá tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣe àwọn iṣẹ́ ilé kan. Lọ́pọ̀ ìgbà táwọn òbí bá bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ nírú àwọn àkókò yìí, tí kì í ṣe pé wọ́n dìídì pè wọ́n jókòó, àwọn ọmọ máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.
▪ ‘Ǹjẹ́ mo fòye mọ bí nǹkan ṣe rí lára ọmọ náà nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ń sọ?’ Jóòbù 12:11 sọ pé: “Etí kò ha ń dán ọ̀rọ̀ wò bí òkè ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò?” Ní báyìí, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, o gbọ́dọ̀ máa “dán” ohun tí ọmọ rẹ ń sọ “wò.” Àbùmọ́ sábà máa ń wà nínú ọ̀rọ̀ táwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà máa ń sọ. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ rẹ lè sọ pé, “Ìgbà gbogbo lẹ máa ń fojú ọmọdé tí kò mọ nǹkan kan wò mí!” tàbí kó sọ pé “Ẹ ò tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ mi rí láé!” Dípò tí wàá fi wá rinkinkin mọ́ àbùmọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ ọmọ náà, ìyẹn “ìgbà gbogbo” àti “láé,” ńṣe ni kó o mọ̀ pé kì í kúkú ṣe pé bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ohun tí ọmọ náà sọ ṣe rí, àmọ́ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ ló mú kó sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọmọ náà bá sọ pé, “Ìgbà gbogbo lẹ máa ń fojú ọmọdé tí kò mọ nǹkan kan wò mí,” ó lè jẹ́ ohun tó ní lọ́kàn ni pé, “ó dà bíi pé ẹ ò tiẹ̀ fọkàn tán mi rárá.” Nígbà tọ́mọ náà sì sọ pé, “Ẹ ò tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ mi rí láé!” ó lè jẹ́ pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé, “Ẹ jẹ́ kí n sọ bọ́rọ̀ yìí ṣe rí lára mi gan-an.” Gbìyànjú kó o fòye mọ bí nǹkan ṣe rí lára ọmọ náà nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ń sọ.
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà sọ ọ̀rọ̀ líle, o lè sọ pé: “Mo mọ̀ pé inú ló ń bí ẹ, mo sì fẹ́ gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ. Mo fẹ́ kó o sọ fún mi, ohun tó mú kó o rò pé mo ń fojú ọmọdé tí kò mọ nǹkan kan wò ẹ́.” Tí ọmọ náà bá ti wá ń sọ̀rọ̀, tẹ́tí sí i, má sì já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí yóò fi sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ tán.
▪ ‘Ǹjẹ́ mo máa ń mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ṣòro láìmọ̀, nípa mímú kí ọmọ mi sọ̀rọ̀ tipátipá?’ Bíbélì sọ pé: “Èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.” (Jákọ́bù 3:18) Nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ mú kí “ipò tí ó kún fún àlàáfíà” wà, kí ó lè ṣeé ṣe fún ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Rántí pé ìwọ ni alágbàwí fún ọmọ rẹ. Nítorí náà, nígbà tẹ́ ẹ bá ń sọ̀rọ̀ lórí kókó kan, má ṣe sọ̀rọ̀ bí agbẹjọ́rò ìjọba kan tó jẹ́ pé ńṣe ló ń wá bó ṣe máa bẹnu àtẹ́ lu ẹlẹ́rìí kan nílé ẹjọ́. Bàbá kan tó ń jẹ́ Ahn lórílẹ̀-èdè Kòríà sọ pé: “Òbí tó bá mòye kì í sọ àwọn ọ̀rọ̀ bí, ‘Ọjọ́ wo ló máa gbọ́n láyé tìẹ ná?’ tàbí, ‘Ẹ̀ẹ̀melòó ni mo ti sọ fún ẹ?’ Lẹ́yìn tí mo ti ṣàṣìṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí ní ẹ̀ẹ̀melòó kan, mo ṣàkíyèsí pé, yàtọ̀ sí pé inú bí àwọn ọmọkùnrin mi sí ọ̀nà tí mo gbà báwọn sọ̀rọ̀ yìí, inú tún bí wọn sí ohun tí mo sọ pẹ̀lú.”
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Tó bá ṣẹlẹ̀ pé pẹ̀lú gbogbo ìsapá rẹ láti fi ìbéèrè mọ ohun tó wà lọ́kàn ọmọ rẹ, kò jọ pé ọmọ náà fẹ́ sọ ọ́ rárá. Tún gbìyànjú ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi bi ọmọbìnrin rẹ nípa bí ìgbòkègbodò rẹ̀ ọjọ́ yẹn ṣe rí, ńṣe ni kí ìwọ sọ bí ìgbòkègbodò tìrẹ fúnra rẹ ṣe rí lọ́jọ́ yẹn, kó o wá wò ó bóyá òun náà á sọ̀rọ̀. Tó bá sì jẹ́ pé ńṣe lo fẹ́ mọ èrò ọmọ rẹ lórí ọ̀rọ̀ kan, má ṣe dojú ìbéèrè kọ ọmọ náà tààràtà. Bi í pé, kí ni èrò ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan lórí ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn náà, wá bi í pé ìmọ̀ràn wo ló máa fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà àtàwọn òbí kì í ṣohun tí kò ṣeé ṣe. Máa ṣe àyípadà nínu ọnà tó ò ń gbà bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nígbàkigbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Fọ̀rọ̀ lọ àwọn òbí tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí nínú títọ́ ọmọ. (Òwe 11:14) Tó o bá ń bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀, “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, má ṣe dẹwọ́ nínú títọ́ àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.
BI ARA RẸ PÉ . . .
▪ Àwọn nǹkan wo ni mo ṣàkíyèsí pé ó yí padà nínú ìwà àti ìṣe ọmọ mi látìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà?
▪ Àwọn ọ̀nà wo ni mo lè gbà mú kí ọ̀nà tí mo ń gbà bá ọmọ mi sọ̀rọ̀ sunwọ̀n sí i?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Ohun Táwọn Òbí Kan Sọ
“Nígbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn èèyàn ni ọmọkùnrin mi máa ń sọ̀rọ̀ fàlàlà jù. Témi pẹ̀lú ẹ̀ nìkan bá jọ wà pa pọ̀, màá tún wá dá ọ̀rọ̀ tá à ń sọ pẹ̀lú àwọn èèyàn tẹ́lẹ̀ yẹn sílẹ̀.”—ANGELA, LÁTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ ÍTÁLÌ.
“Ohun tá a kíyè sí ni pé, àwọn ọmọ wa máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, tá a bá kọ́kọ́ gbóríyìn fún wọn fáwọn nǹkan dáadáa tí wọ́n ṣe, tá a sì sọ fún wọn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.”—Ọ̀GBẸ́NI DONIZETE, LÁTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ BRAZIL.
“Mo bá àwọn àgbàlagbà kan sọ̀rọ̀, ìyẹn àwọn tí wọ́n fi àwọn ìlànà Bíbélì tọ́ dàgbà. Mo bi wọ́n pé báwo ni nǹkan ṣe rí nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, báwo làwọn òbí wọn sì ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́. Ohun tí mo gbọ́ látẹnu wọn wúlò gan-an ni.”—DAWN, ÒBÌNRIN ANÌKÀNTỌ́MỌ LÁTI ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ.