“Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”
Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”
Ọ̀PỌ̀ nǹkan ló lè fa ìbànújẹ́, kó sì mú kéèyàn sọ̀rètí nù nígbèésí ayé. Lára wọn ni ìyà, ìjákulẹ̀, ìdánìkanwà. Nígbà tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa, a lè béèrè pé, ‘Ta ló máa ràn mí lọ́wọ́ báyìí?’ Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tá a rí nínú 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4 jẹ́ ká mọ ibi tá a ti lè rí ìtùnú tí kò lè jáni kulẹ̀, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run.
Ní ẹsẹ kẹta, ó pe Ọlọ́run ní “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Èrò tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” lè gbé síni lọ́kàn ni ìyọ́nú téèyàn ń ní sáwọn èèyàn nítorí ìyà tó ń jẹ wọ́n. a Ìwé kan tá a ṣèwádìí ọ̀rọ̀ Bíbélì nínú rẹ̀ sọ pé a lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn sí “àánú tó ń ṣeni” tàbí “bí ọ̀rọ̀ ṣe ń káni lára.” “Àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” Ọlọ́run ń mú kó gbégbèésẹ̀ lórí ọ̀ràn kan. Mímọ̀ tá a mọ ànímọ́ Ọlọ́run yìí ń fà wá sún mọ́ ọn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Pọ́ọ̀lù tún sọ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò níbí yìí nasẹ̀ dórí “títu ẹnì kan tó wà nínú ìdààmú tàbí ìbànújẹ́ nínú, ó tún ní èrò ṣíṣe ohun tó máa fún ẹni náà níṣìírí.” Bíbélì The Interpreter’s Bible ṣàlàyé pé: “À ń tu ẹni tíyà ń jẹ nínú nígbà tá a bá fún un nígboyà tó máa mú kó lè fara da ìrora rẹ̀.”
O lè wá béèrè pé: ‘Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń tù wá nínú tó sì ń fún wa ní ìgboyà láti fara da ìrora wa?’ Ohun pàtàkì tó ń lò ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà. Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé Ọlọ́run fi ìfẹ́ fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ “pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” Yàtọ̀ síyẹn, nípasẹ̀ àdúrà àtọkànwá, a lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Róòmù 15:4; Fílípì 4:7.
Báwo ni ìtùnú tí Jèhófà ń fáwọn èèyàn rẹ̀ ṣe pọ̀ tó? Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run “ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:4) Kò sí bí wàhálà, ìnira àti ìyà wa ṣe lè pọ̀ tó, Ọlọ́run lè fún wa ní ìgboyà àti okun tá a nílò láti lè fara dà á. Ẹ ò rí bíyẹn ṣe fini lọ́kàn balẹ̀ tó!
Ìtùnú tí Ọlọ́run ń fún wa kì í ṣe fún àwa nìkan. Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé Ọlọ́run ń tù wá nínú “kí àwa lè tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.” Ìtùnú tá a rí gbà nígbà tá a wà nínú ìpọ́njú lè mú ká ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, tó sì máa jẹ́ ká lè ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn tó wà nínú ìṣòro.
Kì í ṣe pé Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” ní láti ṣàdédé mú káwọn ìṣòro tàbí ìrora wa dàwátì. Síbẹ̀, ohun kan dá wa lójú: Tá a bá sá tọ̀ ọ́ pé kó tù wá nínú, ó máa fún wa lókun tó máa jẹ́ ká lè fara da ìbànújẹ́ tàbí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá wa láyé yìí débi tá a fi máa borí ẹ̀. Ó dájú pé irú Ọlọ́run oníyọ̀ọ́nú bẹ́ẹ̀ ló yẹ ká máa sìn, ká sì máa yìn lógo.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Pọ́ọ̀lù pe Ọlọ́run ní “Baba [tàbí orísun] àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àánú ti wá, ó sì jẹ́ ara ànímọ́ Ọlọ́run.