Ọ̀rọ̀ Bẹ́yìn Yọ!
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Ọ̀rọ̀ Bẹ́yìn Yọ!
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bóhun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA DÁNÍẸ́LÌ 6:1-28.
Kí lèrò ẹ? Irú ọkùnrin wo ni Dáríúsì? Ṣàpèjúwe bó o ṣe rò pé ó máa rí? Báwo lo ṣe rò pé ohùn rẹ̀ ṣe máa rí nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀? (Tún ka ẹsẹ 14, 16 àti 18 sí 20.)
․․․․․
Báwo ni ihò yẹn ṣe rí, báwo lo sì ṣe máa ṣàpèjúwe àwọn kìnnìún wọ̀nyẹn?
․․․․․
Ṣàpèjúwe ohun tó o rò pé ó ṣẹlẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n ju Dáníẹ́lì sínú ihò náà tí wọ́n sì dé e pa.
․․․․․
ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Kí nìdí táwọn ìjòyè ọba Dáríúsì fi ń jowú Dáníẹ́lì? (Tún ka ẹsẹ 3.)
․․․․․
Kí nìdí tí Dáníẹ́lì fi gbàdúrà níbi táwọn èèyàn ti lè rí i dípò kó gbà á ní kọ̀rọ̀? (Tún ka ẹsẹ 10, 11.)
․․․․․
Kí nìdí tí òfin táwọn kan ṣe nípa àdúrà fi dùn mọ́ Dáríúsì nínú? (Tún ka ẹsẹ 7.)
․․․․․
MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Béèyàn ṣe lè jẹ́ onígboyà nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń ta kò ó.
․․․․․
Bí àdúrà ti ṣe pàtàkì tó.
․․․․․
Bí Jèhófà ṣe máa ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń fi tọkàntọkàn sìn ín.
․․․․․
KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN INÚ BÍBÉLÌ YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․