Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́ Pé Àwọn Nìkan Làwọn Máa Nígbàlà?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé
Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́ Pé Àwọn Nìkan Làwọn Máa Nígbàlà?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé àwọ́n ti rí ìsìn tòótọ́. Ká ní kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni, wọn ì bá ti yí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ pa dà. Bíi tàwọn onísìn tó kù, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé àwọ́n máa nígbàlà. Àmọ́, wọ́n tún gbà pé ojúṣe àwọn kọ́ ni láti pinnu ẹni tó máa nígbàlà. Ọlọ́run ni Adájọ́ tó mọ ẹjọ́ dá. Òun ló máa pinnu ẹni tó bá máa nígbàlà.—Aísáyà 33:22.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé àwọn tó máa nígbàlà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàlà nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Olùgbàlà. Àpèjúwe kan rèé: Ká sọ pé arìnrìn-àjò kan sọ nù sínú aginjù. Ó ń wá bó ṣe máa pa dà sílé lójú méjèèjì. Ṣó máa rọ́nà àbáyọ, àbí ó máa kú síbẹ̀? Ìyẹn kù sọ́wọ́ ohun tó bá ṣe nígbà tẹ́nì kan bá fẹ́ ràn án lọ́wọ́. Tó bá ń gbéra ga, ó lè kọ̀ láti gba ìrànlọ́wọ́ tẹ́ni yẹn fẹ́ fún un. Ó sì lè fi hàn pé òún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nípa jíjẹ́ kẹ́ni yẹn ran òun lọ́wọ́ kóun lè délé láyọ̀.
Bákan náà, àwọn tó bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹni tó fẹ́ gba aráyé sílẹ̀, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run, nìkan ló máa nígbàlà. Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìgbàlà, àmọ́ gbogbo èèyàn kọ́ ló máa ní in. Jésù, Ọmọ Ọlọ́run sọ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.”—Mátíù 7:21.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé kìkì àwọn tó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, tí wọ́n sì ń fàwọn ohun tí Jésù kọ́ni ṣèwà hù dáadáa nìkan ni Ọlọ́run máa gbà là. (Ìṣe 4:10-12) Ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́ta tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè nígbàlà.
(1) Jésù sọ fáwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Bí Jésù ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ torí àwọn ẹlòmíì jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ ṣe ṣe pàtàkì tó. Àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ń fi hàn pé àwọn ní ànímọ́ kan tó ṣe pàtàkì fún ìgbàlà.
(2) Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀, ó sọ pé: “Mo . . . ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn.” (Jòhánù 17:26) Jésù mọ bí Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó sí Bàbá rẹ̀. Ó gbàdúrà pé kí orúkọ Bàbá òun di “sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Lára ohun téèyàn ní láti ṣe kó tó lè sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ ni pé kó mọ orúkọ yẹn, kó kà á sí pàtàkì, kó sì kà á sí mímọ́. Bíi ti Jésù, àwọn tó bá fẹ́ nígbàlà gbọ́dọ̀ máa lo orúkọ Ọlọ́run. Wọ́n tún gbọ́dọ̀ máa kọ́ àwọn èèyàn nípa orúkọ Ọlọ́run àtàwọn ànímọ́ rẹ̀. (Mátíù 28:19, 20) Ká sòótọ́, kìkì àwọn tó bá ń pe orúkọ Ọlọ́run nìkan ló máa nígbàlà.—Róòmù 10:13.
(3) Jésù sọ fún Pọ́ńtù Pílátù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Ìwọ̀nba làwọn èèyàn tó ń fi hàn pé àwọ́n nígbàgbọ́ nínú Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù jẹ́ Ọba rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àjọ táwọn èèyàn dá sílẹ̀ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé. Àmọ́, àwọn tí Ọlọ́run máa gbà là ń fi tọkàntọkàn gbárùkù ti Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìjọba yẹn ṣe máa sọ gbogbo àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ dòmìnira.—Mátíù 4:17.
Lẹ́yìn táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti mọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè nígbàlà, wọ́n béèrè pé: “Ta ni ó lè ṣeé ṣe kí a gbà là?” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún ènìyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 18:18-30) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi tọkàntọkàn ṣàwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ wọ̀nyí kí wọ́n lè ní ìgbàlà. Wọ́n sì tún máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, káwọn yẹn náà bàa lè ní ìgbàlà.