Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Máa Ṣera Wọn Lọ́kan
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Máa Ṣera Wọn Lọ́kan
Èyí obìnrin sọ pé: “Láìpẹ́ yìí ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé Michael, ọkọ mi, kì í sọ tinú ẹ̀ fún mi mọ́, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í jìnnà sáwọn ọmọ wa. a Ìwà rẹ̀ ti yí pa dà látìgbà tá a ti ní Íńtánẹ́ẹ̀tì, mo sì fura pé ó ti ń wo àwọn àwòrán ìṣekúṣe lórí kọ̀ǹpútà. Lálẹ́ ọjọ́ kan, mo sọ ọ́ kò ó lójú lẹ́yìn táwọn ọmọ wa ti lọ sùn, ó sì jẹ́wọ́ fún mi pé òun ti ń wo àwòrán ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Inú bí mi gan-an. Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ lè má gbà gbọ́ pé èmi lọ̀rọ̀ yìí ń ṣẹlẹ̀ sí. Àtìgbà yẹn ni mi ò ti fọkàn tán an mọ́. Bíi pé ìyẹn ò tíì burú tó, ìgbà yẹn náà ni ọkùnrin kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ níbì kan náà bẹ̀rẹ̀ sí í yọ mí lẹ́nu pé òun nífẹ̀ẹ́ mi.”
Èyí ọkùnrin sọ pé: “Láìpẹ́ yìí Maria, ìyàwó mi, rí àwòrán kan tí mo tọ́jú sórí Kọ̀ǹpútà wa, ó sì wá bi mí nípa ẹ̀. Nígbà tí mo jẹ́wọ́ fún un pé mo máa ń wo àwòrán ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ńṣe ló gbaná jẹ. Ojú gbà mí tì, ẹ̀rí ọkàn mi sì bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí láàmú. Ńṣe ni mo rò pé ọjọ́ yẹn la máa tú ká.”
KÍ LO rò pó ṣẹlẹ̀ sí ìgbéyàwó Michael àti Maria? O lè rò pé wíwo àwòrán ìṣekúṣe gan-an ni olórí ìṣòro Michael. Àmọ́ bí Michael fúnra ẹ̀ ṣe mọ̀ nígbà tó yá, ohun tó ń ṣe é jùyẹn lọ; ohun tó ń ṣe é gan-an ni pé kò ṣe tán láti mú àdéhùn ìgbéyàwó rẹ̀ ṣẹ. b Nígbà tí Michael àti Maria ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, ńṣe ni wọ́n ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ìfẹ́ tó wà láàárín wọn tún máa lágbára sí i táwọn méjèèjì á sì máa gbádùn ara wọn. Bó ṣe sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ tọkọtaya bọ́jọ́ bá ti ń gorí ọjọ́, okùn ìfẹ́ wọn ò lágbára bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, nígbà tó sì yá, àárín wọn ò gún mọ́.
Ṣó o ronú pé àárín ìwọ àti ọkọ tàbí ìyàwó ẹ ò gún tó bó ṣe rí nígbà tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó? Ṣé wàá fẹ́ kẹ́ ẹ pa dà sí bẹ́ ẹ ṣe wà tẹ́lẹ̀? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, o ní láti dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta wọ̀nyí: Kí ló túmọ̀ sí fún tọkọtaya láti ṣera wọn lọ́kan? Kí làwọn nǹkan tó lè da àárín tọkọtaya rú? Kí lo sì lè ṣe kẹ́yin méjèèjì lè túbọ̀ ṣera yín lọ́kan?
Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Ṣera Yín Lọ́kan?
Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé bí tọkọtaya ṣe lè ṣera wọn lọ́kan? Ọ̀pọ̀ ló máa sọ pé kò jú kéèyàn máa Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24) Àwọn ìdí wọ̀nyẹn tó bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, wọ́n sì lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Àmọ́, táwọn tọkọtaya bá fẹ́ láyọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ohun tó wà láàárín àwọn kọjá ṣíṣe ojúṣe tó yẹ káwọn ṣe síra àwọn.
ṣe ojúṣe ẹ̀ nínú ilé lọ. Bí àpẹẹrẹ, tàwọn ọmọ làwọn tọkọtaya kan ń rò tí wọ́n fi wà pa pọ̀, àwọn míì sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí wọ́n gbà pé ojúṣe tí Ọlọ́run, Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó gbé lé àwọn lọ́wọ́ nìyẹn. (Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ káwọn tọkọtaya máa láyọ̀ látọkàn wá, kẹ́ni tí wọ́n fẹ́ sì tẹ́ wọn lọ́rùn. Ohun tó fẹ́ gan-an ni pé kí ọkùnrin ‘máa yọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀,’ kí obìnrin nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀, kó sì máa rí i nínú ìwà ọkọ pé ó nífẹ̀ẹ́ òun gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. (Òwe 5:18; Éfésù 5:28) Kírú àjọṣe yìí tó lè wà láàárín ọkọ àti ìyàwó, àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ fọkàn tán ara wọn. Ó sì tún ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn kalẹ́. Tí tọkọtaya bá fọkàn tán ara wọn tí wọ́n sì ṣera wọn lọ́rẹ̀ẹ́ àtàtà, àwọn méjèèjì á fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti máa ṣera wọn lọ́kan. Ìgbà yẹn làárín wọn á tó lè gún débi pé, bí Bíbélì ṣe sọ, ńṣe ló máa dà bí ìgbà táwọn méjèèjì jẹ́ “ara kan.”—Mátíù 19:5.
Nítorí náà, a lè fi ṣíṣera ẹni lọ́kan nínú ìgbéyàwó wé àpòpọ̀ sìmẹ́ǹtì tẹ́ni tó ń mọlé fi ń há àwọn búlọ́ọ̀kù tó fi ń mọlé. Ó kéré tán, omi, sìmẹ́ǹtì àti yẹ̀pẹ̀ ni wọ́n máa ń pò pọ̀ láti mọlé. Bákan náà, tí tọkọtaya bá fẹ́ ṣera wọn lọ́kan, wọ́n ní láti máa ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, kí wọ́n máa fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n sì ṣera wọn lọ́rẹ̀ẹ́ àtàtà. Kí ló wá lè da àárín tọkọtaya rú?
Àwọn Nǹkan Tó Lè Da Àárín Tọkọtaya Rú
Tọkọtaya gbọ́dọ̀ sapá gan-an kí wọ́n tó lè ṣera wọn lọ́kan, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe tán láti máa yááfì àwọn nǹkan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Èyí túmọ̀ sí pé ẹ ní láti máa fàwọn nǹkan tẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ sí du ara yín kẹ́ ẹ lè tẹ́ ọkọ tàbí ìyàwó yín lọ́rùn. Àmọ́, láyé tá a wà yìí, àwọn èèyàn kì í ronú nípa ohun tó máa ṣàwọn ẹlòmíì láǹfààní ṣáájú tiwọn, wọn kì í sì í fẹ́ fún àwọn èèyàn ní nǹkan láì béèrè pé, ‘Kí ló máa yọ fún mi?’ Tí wọ́n bá sì rẹ́nì kan tó ń fi nǹkan táwọn ẹlòmíì fẹ́ràn ṣáájú tiẹ̀, sùẹ̀gbẹ̀ tí ò rọ́ọ̀ọ́kán ni wọ́n máa pe irú ẹni bẹ́ẹ̀. Àmọ́ bi ara ẹ pé, ‘Onímọtara-ẹni-nìkan mélòó ni mo mọ̀ tó ní ìdílé aláyọ̀?’ Ó dájú pé wọn ò tó nǹkan, ìyẹn tí wọ́n bá tiẹ̀ wà rárá. Kí nìdí? Kì í rọrùn fún tọkọtaya tó bá jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan láti ṣera wọn lọ́kan nígbà tó bá dọ̀ràn kí wọ́n fàwọn nǹkan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí du ara wọn, àgàgà tí wọn ò bá ní rí nǹkan kan gbà ńbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kò sí bí tọkọtaya ṣe lè yóòfẹ́ tó nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn, àjọṣe wọn ò lè kẹ́sẹ járí táwọn méjèèjì ò bá ṣe tán láti ṣera wọn lọ́kan.
Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an ni Bíbélì sọ nígbà tó sọ pé ojúṣe ńlá lọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Ó sọ pé, “ọkùnrin tí ó gbéyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé, bí òun ṣe lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀,” bẹ́ẹ̀ sì ni “obìnrin tí a gbé níyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé, bí òun ṣe lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà ọkọ rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:33, 34) Ó ṣeni láàánú pé àwọn tọkọtaya tí kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan pàápàá kì í mọ ohun tó ń jẹ ọkọ tàbí ìyàwó wọn lọ́kàn tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ mọyì àwọn nǹkan tẹ́nì kejì wọn nínú ìgbéyàwó ń yááfì nítorí tiwọn. Tí tọkọtaya ò bá mọyì ara wọn, “ìpọ́njú nínú ẹran ara” tí wọ́n máa ní nínú ìgbéyàwó wọn máa pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.—1 Kọ́ríńtì 7:28.
Tẹ́ ẹ bá fẹ́ kí nǹkan máa lọ dáadáa nínú ìdílé yín nígbà dídùn àti nígbà kíkan, àfi kẹ́ ẹ mọ̀ lọ́kàn ara yín pé èkùrọ́ lalábàákú ẹ̀wà. Báwo lẹ ṣe lè máa ronú lọ́nà yìí, kí lẹ sì lè ṣe láti ran ara yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè máa ṣera yín lọ́kan?
Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Túbọ̀ Ṣera Yín Lọ́kan
Ohun kan tó lè ràn yín lọ́wọ́ ni pé kẹ́ ẹ máa fàwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ máa “ṣe ara [yín] láǹfààní.” (Aísáyà 48:17) Àwọn nǹkan méjì tẹ́ ẹ lè ṣe rèé.
1. Jẹ́ kọ́rọ̀ ọkọ tàbí ìyàwó ẹ máa jẹ ẹ́ lógún. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ẹ . . . máa wádìí Fílípì 1:10) Bí ọkọ àti ìyàwó ṣe ń ṣe síra wọn ṣe pàtàkì gan-an lójú Ọlọ́run. Ọlọ́run máa mọyì ọkùnrin tó bá mọyì ìyàwó rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni obìnrin tó bá bọ̀wọ̀ fọ́kọ “níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.”—1 Pétérù 3:1-4, 7.
dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Báwo ni ìgbéyàwó ẹ ṣe ṣe pàtàkì tó lójú ẹ? Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó bá ń dunni ló ń pọ̀ lọ́rọ̀ ẹni. Bi ara ẹ pé: ‘Lóṣù bíi mélòó kan sẹ́yìn, wákàtí mélòó ni mo yà sọ́tọ̀ láti ṣe fàájì pẹ̀lú ọkọ tàbí ìyàwó mi? Kí làwọn nǹkan tí mo dìídì ṣe láti jẹ́ kí ọkọ tàbí ìyàwó mi mọ̀ pé ọ̀rẹ́ àtàtà la ṣì jẹ́ síra wa?’ Tó bá jẹ́ pé àkókò díẹ̀ lò ń lò láti jẹ́ kí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun, ó lè má rọrùn fún un láti gbà pé lóòótọ́ lọ̀rọ̀ òun jẹ ẹ́ lógún.
Ṣé ọkọ tàbí ìyàwó ẹ mọ̀ pé o kì í fọ̀rọ̀ òun ṣeré? Báwo lo ṣe lè mọ̀?
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ? Kọ àwọn nǹkan márùn-ún yìí sórí bébà: owó, iṣẹ́, ìgbéyàwó, fàájì, àtàwọn ọ̀rẹ́. Kó o wá kọ [1] síwájú èyí tó o rò pó ṣe pàtàkì jù sí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ, kó o kọ [2] síwájú èyí tó tẹ̀ lé e àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní kí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ìwọ náà. Nígbà tó o bá ṣe tán, fún ọkọ tàbí ìyàwó rẹ léyìí tó o kọ nípa rẹ̀, kó o sì gba èyí tóun náà kọ nípa rẹ. Tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ bá rò pé àkókò tó ò ń lò pẹ̀lú òun ò tó, ẹ jọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè ṣe láti túbọ̀ máa ṣera yín lọ́kan. Tún bi ara ẹ pé, ‘Kí ni mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa gbọ́ tọkọ tàbí tìyàwó mi?’
2. Ẹ má ṣe dalẹ̀ ara yín. Jésù Kristi sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28) Tẹ́nì kan bá lọ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí ìyàwó ẹ̀, ó ti wu àjọṣe tó wà láàárín òun àti ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ léwu, Bíbélì sì sọ pé èyí lè yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀. (Mátíù 5:32) Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú ẹsẹ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé èròkérò lè ti wà lọ́kàn ẹnì kan tipẹ́tipẹ́ kó tó ṣàgbèrè. Ọ̀dàlẹ̀ lẹni tó bá gba irú èròkérò bẹ́ẹ̀ láyè.
Tẹ́ ẹ bá fẹ́ máa ṣera yín lọ́kan, àfi kẹ́ ẹ pinnu pé ẹ ò ní wo àwòrán ìṣekúṣe. Ohun yòówù káwọn èèyàn máa sọ, ó dájú pé àwòrán ìṣekúṣe máa ń dalé rú. Gbọ́ ohun tí ìyàwó kan sọ nípa ohun tí ọkọ rẹ̀ sábà máa ń wò: “Ọkọ mi sọ pé ńṣe làwọn àwòrán ìṣekúṣe tóun ń wò yẹn túbọ̀ ń jẹ́ kọ́nà tá a gbà ń fìfẹ́ hàn síra wa túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Àmọ́, ńṣe lohun tó ń ṣe yẹn jẹ́ kí n máa ronú pé mi ò ja mọ́ nǹkan kan lójú ẹ̀ àti pé mi ò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ńṣe ni mo máa ń wa ẹkún mu títí tí oorun á fi gbé mi lọ tó bá ti lọ wo ìwòkuwò yẹn.” Kí lo máa sọ nípa ọkùnrin yìí, ṣé ó ń ṣe
gbogbo ohun tó lè ṣe kóun àti ìyàwó ẹ̀ lè ṣera wọn lọ́kan ni àbí ńṣe ló fẹ́ dalé ara ẹ̀ rú? Ṣó o rò pé ohun tó ń ṣe yẹn máa jẹ́ kó rọrùn fún ìyàwó ẹ̀ láti máa ṣòótọ́ sí i? Ṣé lóòótọ́ ló mú un bí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́?Ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Jóòbù jẹ́ ká mọ bí àdéhùn tó wà láàárín òun àti ìyàwò ẹ̀ àti Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó sọ pé ‘òun ti bá ojú òun dá májẹ̀mú.’ Ó pinnu pé ‘òun ò ní tẹjú mọ́ wúńdíá.’ (Jóòbù 31:1) Báwo lẹ ṣe lè fara wé Jóòbù?
Yàtọ̀ sí pé ẹ ò gbọ́dọ̀ máa wo àwòrán ìṣekúṣe, ẹ tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kẹ́ ẹ má lọ máa fìfẹ́ hàn lọ́nà tí ò bójú mu sẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya yín. Ká sòótọ́ títage pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí ìyàwó yín lè kó bá ìgbéyàwó yín. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremáyà 17:9) Ṣé ọkàn ẹ ti tàn ẹ́ rí? Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ọ̀dọ̀ ọkọ tàbí ìyàwó mi lọ́kàn mi máa ń fà sí jù àbí ọ̀dọ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin míì? Ṣé ọkọ tàbí ìyàwó mi ni mo máa ń kọ́kọ́ sọ ìròyìn ayọ̀ tí mo bá gbọ́ fún àbí ẹlòmíì? Tí ọkọ tàbí ìyàwó mi bá sọ pé òun fẹ́ kí n dín àjọṣe mi pẹ̀lú ọkùnrin tàbí obìnrin míì kù, báwo ló ṣe máa rí lára mi? Ṣé mo máa sọ ọ́ dìjà ni àbí inú mi á dùn láti ṣàtúnṣe?’
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ? Tó o bá rí i pé ọkàn ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí ìyàwó ẹ, yáa dín àjọṣe tó wà láàárín yín kù séyìí tó pọn dandan. Má máa ronú nípa ohun tẹ́ni yẹn fi dáa ju ọkọ tàbí ìyàwó ẹ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ànímọ́ rere tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ ní ni kó o máa ronú lé ni gbogbo ìgbà. (Òwe 31:29) Máa ronú lórí ohun tó mú kó o yóòfẹ́ fún ọkọ tàbí ìyàwó ẹ nígbà tẹ́ ẹ kọ́kọ́ mọra. Wá bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ọkọ tàbí ìyàwó mi ò láwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn mọ́ ni àbí èmi ni mi ò fara balẹ̀ kíyè sí wọn mọ́?’
Ẹ Lo Ìdánúṣe
Michael àti Maria tá a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan pinnu láti béèrè ìmọ̀ràn lórí bí wọ́n ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro tí wọ́n ní. Òótọ́ ni pé ohun àkọ́kọ́ ṣì ni wíwá ìmọ̀ràn. Àmọ́, torí pé Michael àti Maria ṣe tán láti gbà pé àwọn níṣòro tí wọ́n sì ṣe tán láti wá ìrànlọ́wọ́, wọ́n fi hàn pé lóòótọ́ làwọn fẹ́ ṣera àwọn lọ́kan, àwọn sì ṣe tán láti ṣiṣẹ́ kára kí ìgbéyàwó àwọn lè kẹ́sẹ járí.
Bóyá àárín ìwọ àtí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ gún tàbí ẹ láwọn ìṣòro kan, ọkọ tàbí ìyàwó ẹ ní láti mọ̀ pé lóòótọ́ ló wù ẹ́ pé kẹ́ ẹ ṣera yín lọ́kan, kí ìgbéyàwó yín bàa lè kẹsẹ járí. Gbogbo ohun tó bá gbà ni kó o ṣe láti jẹ́ kí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ mọ̀ pé lóòótọ́ lo fẹ́ kẹ́ ẹ ṣera yín lọ́kan. Ṣó o ti ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀?
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.
b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpẹẹrẹ ọkùnrin tó ń wo àwòrán ìṣekúṣe la lò nínú àpilẹ̀kọ yìí, ńṣe lobìnrin tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ náà ń fi hàn pé mímú àdéhùn ìgbéyàwó òun ṣẹ ò jẹ òun lógún.
BI ARA Ẹ PÉ . . .
▪ Àwọn nǹkan wo ni mo lè dín àkókò tí mò ń lò nídìí wọn kù kí n lè ráyè gbọ́ tọkọ tàbí tìyàwó mi?
▪ Kí ni mo lè ṣe láti fi dá ọkọ tàbí ìyàwó mi lójú pé lóòótọ́ ló wù mí pé ká ṣera wa lọ́kan?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Wáyè láti máa gbọ́ tọkọ tàbí tìyàwó ẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Inú ọkàn nìwà ọ̀dàlẹ̀ ti máa ń bẹ̀rẹ̀