Ilé Là Ń Wò Ká Tó Sọmọ Lórúkọ
Ilé Là Ń Wò Ká Tó Sọmọ Lórúkọ
Inú obìnrin ará Etiópíà kan ń dùn ṣìnkìn nígbà tó bímọ ọkùnrin làǹtì lanti. Àmọ́, ìbànújẹ́ dorí ẹ̀ kodò nígbà tó rí i pé ọmọ yẹn ò ta pútú. Nígbà tí ìyá bàbá ọmọ náà gbé ọmọ tí kò ta pútú yìí láti wẹ̀ fún un, ìgbà yẹn lọmọ náà tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra sọ, tó ń mí, tó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í ké! “Ìyanu” nìtúmọ̀ orúkọ bàbá ọmọ yẹn, torí náà, àwọn òbí ẹ̀ pa orúkọ bàbá rẹ̀ yìí pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ míì kan lédè Etiópíà, wọ́n sì wá sọ ọmọkùnrin náà ní Ọlọ́run Ti Ṣèyanu.
Lórílẹ̀-èdè Bùrúńdì, ọ̀dọ́mọkùnrin kan sá mọ́ àwọn sójà tó fẹ́ pa á lọ́wọ́. Níbi tó sá pa mọ́ sí nínú pápá kan ló ti gbàdúrà, tó sì wá jẹ́jẹ̀ẹ́ pé, tí Ọlọ́run bá gba òun sílẹ̀ nínú wàhálà yìí, Manirakiza, tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ni Olùgbàlà,” lòun máa sọ àkọ́bí òun. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn ìgbà yẹn, inú ọkùnrin náà dùn pé òún ṣì wà láàyè, ó sì wá sọ àkọ́bí ẹ̀ ní Manirakiza.
Ó LÈ dà bíi pé ó ṣàjèjì létí àwọn kan láti fáwọn ọmọ lórúkọ tó láwọn ìtumọ̀ pàtó kan, àmọ́ ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà ọgọ́rọ̀ọ̀rún irú àwọn orúkọ bẹ́ẹ̀ ló wà nínú Bíbélì. Wàá túbọ̀ jàǹfààní látinú Bíbélì kíkà tó o bá mọ ìtúmọ̀ orúkọ àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn. Jẹ́ ká kàn gbé díẹ̀ lára àwọn orúkọ wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Àwọn Orúkọ Tó Nítumọ̀ Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù
Sẹ́ẹ̀tì wà lára àwọn orúkọ tó o máa kọ́kọ́ rí kà nínú Bíbélì, ìtumọ̀ ẹ̀ sí ni “Ẹni Tí Ọlọ́run Yàn.” Éfà tó jẹ́ ìyá fún Sẹ́ẹ́tì ṣàlàyé ìdí tóun fi yan orúkọ yẹn, ó ní: ‘Ọlọ́run yan irú ọmọ mìíràn fún mi ní ipò Ébẹ́lì tí Kéènì pa.’ (Jẹ́nẹ́sísì 4:25, Bíbélì Mímọ́) Lámékì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Sẹ́ẹ́tì sọ ọmọ ẹ̀ ní Nóà, ìyẹn sì túmọ̀ sí “Ìsinmi” tàbí “Ìtùnú.” Nígbà tí Lámékì ń sọ ìdí tó fi sọ ọmọ ẹ̀ lórúkọ yẹn, ó ní: “Ẹni yìí ni yóò mú ìtùnú wá fún wa nínú iṣẹ́ wa àti nínú ìrora ọwọ́ wa tí ó jẹ́ àbáyọrí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.”—Jẹ́nẹ́sísì 5:29.
Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yí orúkọ àwọn àgbàlagbà kan pa dà kó lè fi sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ Ábúrámù tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Gbé Bàbá Ga” di Ábúráhámù tó túmọ̀ sí “Bàbá Ogunlọ́gọ̀.” Orúkọ yìí sì ro Ábúráhámù lóòótọ́ torí pé nígbà tó yá ó di bàbá fáwọn orílẹ̀-èdè tó pọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 17:5, 6) Tún wo orúkọ ìyàwó Ábúráhámù, ìyẹn Sáráì, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Àríyànjiyàn.” Ó dájú pé inú ẹ̀ máa dùn gan-an, nígbà tí Ọlọ́run sọ orúkọ ẹ̀ di “Sárà” tó túmọ̀ sí “Ìyá Ọba,” ìyẹn sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun ṣì máa di ìyá ńlá fáwọn ọba.—Jẹ́nẹ́sísì 17:15, 16.
Ọlọ́run tún fúnra ẹ̀ yan orúkọ tó fẹ́ kí wọ́n sọ àwọn ọmọdé kan. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún Ábúráhámù àti Sárà pé kí wọ́n sọ́ ọmọkùnrin wọn ní Ísákì, tó túmọ̀ sí “Ẹ̀rín.” Gbogbo ìgbà lorúkọ yìí á máa jẹ́ káwọn tọkọtaya olóòótọ́ wọ̀nyí rántí bó ṣe rí lára wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn máa bímọ lẹ́yìn táwọn ti darúgbó. Jẹ́nẹ́sísì 17:17, 19; 18:12, 15; 21:6.
Nígbà tí Ísákì sì wá dàgbà di olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kò sí àní-àní pé orúkọ ẹ̀ rò ó, ó sì ń bá a nìṣó láti múnú Ábúráhámù àti Sárá dùn bí wọ́n ṣe ń wojú ọmọkùnrin wọn ọ̀wọ́n bó ṣe ń dàgbà.—Ìdí tí Rákélì tó jẹ́ ìyàwó ọmọ Ísákì fi fún ọmọ ẹ̀ lórúkọ tó fún un tún yàtọ̀ pátápátá. Nígbà tó ń kú lọ lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, Rákélì pe orúkọ ọmọ rẹ̀ yìí ní Bẹni-Ónì, tó túmọ̀ sí “Ọmọ Ìbànújẹ́ Mi.” Jékọ́bù, ọkọ Rákélì yí orúkọ ọmọ náà sí Bẹ́ńjámínì, tó túmọ̀ sí “Ọmọ Lójú Òbí.” Ìtúmọ̀ orúkọ yìí jẹ́ ká rí i pé ọmọ táwọn òbí máa ṣojúure sí tí wọ́n sì máa tì lẹ́yìn ni.—Jẹ́nẹ́sísì 35:16-19; 44:20.
Àwọn orúkọ kan tún máa ń jẹ́ ká mọ bẹ́ni tó ń jẹ́ ẹ ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ, Ísákì àti Rèbékà bí ọmọkùnrin kan tó ní irun pupa lára, irun ọ̀hún sì wá dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú lára ẹ̀, torí náà, wọ́n pe orúkọ ẹ̀ ní Ísọ̀ lédè Hébérù, èyí sì túmọ̀ sí “Irun Bò Ó Lára.” (Jẹ́nẹ́sísì 25:25) Ìwé Rúùtù náà jẹ́ ká mọ̀ pé Náómì bímọ ọkùnrin méjì, ó sì pé orúkọ ọ̀kan nínú wọn ní Málónì, tó túmọ̀ sí “Aláìsàn tàbí Alárùn,” nígbà tó pe orúkọ ìkejì ní Kílíónì, tó túmọ̀ sí “Aláìlera.” Bíbélì ò sọ bóyá látìgbà tí wọ́n ti bí àwọn ọmọ wọ̀nyí ni wọ́n ti fún wọn lórúkọ yìí tàbí lẹ́yìn ìgbà yẹn, àmọ́ a rí i pé orúkọ yẹn rò wọ́n lóòótọ́ torí àwọn méjèèjì ló kú láìtọ́jọ́.—Rúùtù 1:5.
Àwọn èèyàn tún sábà máa ń yí orúkọ wọn pa dà tàbí kí wọ́n tún un ṣe. Nígbà tí Náómì pa dà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, tó sì wá ku òun nìkan lẹ́yìn tí ọkọ àtàwọn ọmọ ẹ̀ ti ṣaláìsí, kò fẹ́ káwọn èèyàn máa pe òun ní Náómì tó túmọ̀ sí “Adùn” mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ẹ má pè mí ní Náómì. Márà [tó túmọ̀ sí “Ìkorò”] ni kí ẹ máa pè mí, nítorí Olódùmarè ti mú kí ó korò gan-an fún mi.”—Rúùtù 1:20, 21.
Àwọn ẹlòmíì sì rèé, orúkọ tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa rántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan ni wọ́n máa ń sọmọ wọn. Bí àpẹẹrẹ, orúkọ wòlíì Hágáì túmọ̀ sí “A Bí I Nígbà Àjọ̀dún.” a
Àwọn Orúkọ Tó Nítumọ̀ Lákòókò Àwọn Kristẹni
Orúkọ Jésù nítumọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọlọ́run tipasẹ̀ ańgẹ́lì kan fáwọn òbí Jésù nítọ̀ọ́ni kí wọ́n tó bí i pé kí wọ́n “pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù,” èyí tó túmọ̀ sí “Ti Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Ìdí tí wọ́n sì fi fún un lórúkọ yìí ni pé “òun [ló máa] gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì tó bá Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ ṣe sọ fún un. (Mátíù 1:21) Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi tí Ọlọ́run sì fẹ̀mí mímọ́ yàn án, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti máa jẹ́ orúkọ oyè kan lédè Hébérù, ìyẹn sì ni “Mèsáyà.” Lédè Gíríìkì, “Kristi” ni wọ́n ń pe orúkọ oyè yìí. Ìtúmọ̀ orúkọ oyè méjèèjì wọ̀nyí ni “Ẹni Àmì Òróró.”—Mátíù 2:4.
Jésù pàápàá fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láwọn orúkọ kan tó ṣàpèjúwe irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ó fún Símónì ní orúkọ kan lédè Hébérù, ìyẹn Kéfà, tó túmọ̀ sí “Àpáta.” Ìtúmọ̀ Kéfà lédè Gíríìkì làwọn èèyàn wá tẹ̀ mọ́ Símónì lórí, ìtúmọ̀ rẹ̀ sì ni “Pétérù.” (Jòhánù 1:42) Jésù pe Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tó máa ń fìtara ṣe nǹkan, ní “Bóánágè,” tó túmọ̀ sí “Àwọn Ọmọ Ààrá.”—Máàkù 3:16, 17.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tún máa ń fúnra wọn láwọn orúkọ míì tó bá ìwà kálukú wọn mu. Ọ̀kan lára irú àwọn orúkọ bẹ́ẹ̀ ni Bánábà, táwọn àpọ́sítélì máa ń pe Jósẹ́fù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ìtumọ̀ ẹ̀ sì ni “Ọmọ Ìtùnú.” Orúkọ yẹn sì ro Bánábà torí pé ó fìwà ọ̀làwọ́ tó ní tu àwọn èèyàn nínú, ó sì fọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu ọ̀pọ̀ èèyàn nínú.—Ìṣe 4:34-37; 9:27; 15:25, 26.
Orúkọ Rere Ṣe Pàtàkì
Òótọ́ ni pé àwa kọ́ la máa ń sọra wa lórúkọ nígbà tí wọ́n bá bí wa, àmọ́ ìwà wa ló máa sọrú ojú táwọn èèyàn á máa fi wò wá. (Òwe 20:11) Wá bi ara ẹ pé: ‘Ká ló ṣeé ṣe fún Jésù tàbí àwọn àpọ́sítélì láti fún mi lórúkọ, orúkọ wo ni wọn ì bá fún mi? Orúkọ wo gan-an ló máa ṣàpèjúwe ìwà tí mò ń hù tàbí irú ẹni tí mo jẹ́?’
Ó yẹ kó o ronú dáadáa lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Ọlọ́gbọ́n Ọba Solómónì ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: ‘Orúkọ rere sàn ní yíyàn ju ọrọ̀ púpọ̀ lọ.’ (Òwe 22:1, Bíbélì Mímọ́) Ká sòótọ́, béèyàn bá lórúkọ rere ládùúgbò, nǹkan àtàtà ló ní yẹn. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkí jù ni pé, tá a bá lórúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìṣúra ayérayé la ní yẹn. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa kọ orúkọ àwọn tó bá bẹ̀rù òun sínú “Ìwé ìrántí” òun, wọ́n sì máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun.—Málákì 3:16; Ìṣípayá 3:5; 20:12-15.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Áfíríkà ló láwọn orúkọ tó bá àkọlé àwọn àpéjọ táwa Ẹlẹ́rìí ṣe nígbà tí wọ́n bí wọ́n mu.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]
Táwọn èèyàn bá wo irú ẹni tí mo jẹ́, orúkọ wo ni wọ́n máa fún mi?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ta Ni Ìmánúẹ́lì?
Àwọn orúkọ kan wà nínú Bíbélì tó dà bí àsọtẹ́lẹ̀, tó sì ń sọ iṣẹ́ tẹ́ni tó ni orúkọ yẹn máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti kọ̀wé pé: “Wò ó! Omidan náà yóò lóyún ní tòótọ́, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, dájúdájú, yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.” (Aísáyà 7:14) Orúkọ yìí túmọ̀ sí “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.” Àwọn kan lára àwọn tó máa ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ti sọ pé ọ̀kan lára àwọn ọba Ísírẹ́lì tàbí ọ̀kan lára àwọn ọmọ Aísáyà ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ sí lára. Àmọ́ Mátíù, ọ̀kan lára àwọn tó kọ Ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí ṣẹ sí lára ní kíkún.—Mátíù 1:22, 23.
Àwọn kan ti sọ pé, nígbà tí Bíbélì pe Jésù ní Ìmánúẹ́lì, ohun tó fi ń kọ́ni ni pé Jésù ni Ọlọ́run. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Ọlọ́run ni Élíhù náà, ìyẹn ọ̀dọ́mọkùnrin tó tu Jóòbù nínú tó sì tọ́ ọ sọ́nà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ìtúmọ̀ orúkọ Élíhù ni “Òun Ni Ọlọ́run Mi.”
Jésù ò fìgbà kankan pera ẹ̀ ní Ọlọ́run. (Jòhánù 14:28; Fílípì 2:5, 6) Àmọ́ ó fàwọn ànímọ́ Bàbá rẹ̀ ṣèwà hù láìkù síbì kan, ó sì mú gbogbo ìlérí Ọlọ́run nípa Mèsáyà ṣẹ. (Jòhánù 14:9; 2 Kọ́ríńtì 1:20) Ìmánúẹ́lì, orúkọ tí Bíbélì pe Jésù yìí ṣàpèjúwe Jésù dáadáa, ó jẹ́ ká mọ ipa tó kó gẹ́gẹ́ bí Irú-ọmọ tó jẹ́ Mèsáyà, àtọmọdọ́mọ Dáfídì, ẹni tó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú gbogbo ẹni tó bá ń sìn ín.
[Àwòrán]
ÌMÁNÚẸ́LÌ “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Orúkọ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ
Orúkọ Ọlọ́run fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà nínú Bíbélì. Lédè Yorùbá, “Jèhófà” là ń pe orúkọ náà, ìyẹn sì bá àwọn lẹ́tà mẹ́rin tí wọ́n fi ń kọ ọ́ lédè Hébérù mu, ìyẹn יהוה. Báwo lorúkọ yìí ṣe ṣe pàtàkì tó? Nígbà tí Mósè béèrè pé kí lorúkọ Ọlọ́run, Jèhófà dá a lóhùn pé: “Èmi Yóò Di ohun tó bá wù mí.” (Ẹ́kísódù 3:14, The Emphasised Bible, tí J. B. Rotherham ṣe.) Ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run ń jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa sọra ẹ̀ di ohunkóhun tó bá gbà kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ. (Aísáyà 55:8-11) Tí Ọlọ́run bá ṣèlérí fún wa, ọkàn wa balẹ̀ pé ìlérí Ọlọ́run kì í yẹ̀. Kí nìdí tá a fi lè gbára lé àwọn ìlérí Ọlọ́run? Ìdí ni pé òun ni Jèhófà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
ÁBÚRÁHÁMÙ “Bàbá Ogúnlọ́gọ̀”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
SÁRÀ “Ìyá Ọba”