Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìlú Kọ́ríńtì “Ń Jọlá Èbúté Méjì”

Ìlú Kọ́ríńtì “Ń Jọlá Èbúté Méjì”

Ìlú Kọ́ríńtì “Ń Jọlá Èbúté Méjì”

TÓ O bá wo àwòrán ilẹ̀ orílẹ̀-èdè Gíríìsì, wàá kíyè sí i pé omi ló yí ibi tó pọ̀ jù nínú orílẹ̀-èdè náà ká, ibì kan tó dà bí erékùṣù tó tóbi gan-an ló sì wà lápá gúúsù orílẹ̀-èdè náà. Ilẹ̀ tóóró kan tápá ibi tó ti tín-ín-rín jù lọ fẹ̀ tó nǹkan bíi kìlómítà mẹ́fà ló sì so apá méjèèjì pọ̀. Ọ̀nà Tóóró Ìlú Kọ́ríńtì ni wọ́n máa ń pe ilẹ̀ yẹn, òun ló so àgbègbè Peloponnesus tómi yí ká tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Gíríìsì pọ̀ mọ́ àríwá tó jẹ́ apá ibi táwọn èèyàn ń gbé jù lọ.

Ilẹ̀ tóóró yẹn tún ní iṣẹ́ pàtàkì míì tó ń ṣe. Afárá òkun ni wọ́n máa ń pè é, torí pé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ tóóró náà ni Òkun Aegean àti apá ìlà oòrùn Òkun Mẹditaréníà ti ya wọ àgbègbè Saronic, nígbà tó jẹ́ pé lápá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ tóóró náà ni Òkun Ionian, Òkun Adriatic àti apá ìwọ̀ oòrùn Òkun Mẹditaréníà ti ya wọ àgbègbè Kọ́ríńtì. Àárín gbogbo àwọn àgbègbè tá a mẹ́nu kàn yìí ni ìlú Kọ́ríńtì wà, ìlú yìí sì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sábà máa ń dúró láwọn ìgbà tó ń rìnrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀. Àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó wà nílùú náà, ìgbésí ayé afẹ́ táwọn èèyàn ibẹ̀ ń gbé àti ìwà pálapàla tó kún ìlú náà ló jẹ́ kó lókìkí láyé ìgbà yẹn.

Ìlú Tó Ṣe Pàtàkì

Ìpẹ̀kun ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ tóóró tó ṣe pàtàkì yìí nìlú Kọ́ríńtì wà. Èbúté tàbí etíkun méjì ló wà nìlú Kọ́ríńtì, ọ̀kan ni Lékíónì tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn, èkejì sì ni Kẹnkíríà tó wà lápá ìlà oòrùn. Abájọ tí ọ̀gbẹ́ni Strabo, ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àtàwọn ẹ̀dá tó ń gbénú ẹ̀, fi sọ pé ìlú Kọ́ríńtì ń “jọlá èbúté méjì.” Torí ọ̀gangan ibi tí ìlú Kọ́ríńtì wà, ojúkò ló jẹ́ fáwọn tó máa ń gba orí ilẹ̀ wá ṣòwò nílùú Kọ́ríńtì láti apá àríwá gúúsù àtàwọn tó ń gba orí omi wá ṣòwò láti apá ìlà oòrùn ìwọ̀ oòrùn ìlú náà.

Láyé àtijọ́, àwọn ọkọ̀ òkun tó máa ń wá láti ìlà oòrùn Kọ́ríńtì (ìyẹn láti Éṣíà Kékeré, Síríà, Fòníṣíà àti Íjíbítì) àtàwọn tó máa ń wá láti ìwọ̀ oòrùn (ìyẹn láti Ítálì àti Sípéènì) máa ń fàwọn ọkọ̀ òkun kó àwọn ọjà wọn wá sí èbúté kan, wọ́n á sì wá kó wọn gba orí ilẹ̀ lọ sí òdìkejì ilẹ̀ tóóró náà tó tó nǹkan bíi kìlómítà mélòó kan sí èbúté náà. Òdìkejì ilẹ̀ tóóró yìí ni wọ́n ti máa ń kó àwọn ọjà tí wọ́n bá gbé wá sínú àwọn ọkọ̀ òkun míì kí wọ́n lè máa bá ìrìn àjò wọn lọ. Àwọn ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kéékèèké ni wọ́n fi ń kó àwọn ọjà wọn gba ojú ọ̀nà tóóró kan tí wọ́n ń pè ní diolkos sọdá sódìkejì ilẹ̀ tóóró náà.—Wo  àpótí tó wà lójú ìwé 27.

Kí nìdí táwọn atukọ̀ ojú omi fi fẹ́ láti máa gba orí ilẹ̀ sọdá ilẹ̀ tóóró náà? Torí pé ìyẹn máa ń pé wọn ju kí wọ́n lọ rìnrìn àjò ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogún [320] kìlómítà lórí òkun tó wà ní gúúsù Peloponnese, ìrìn àjò orí òkun yẹn máa ń léwu gan-an, ìjì sì sábà máa ń jà níbẹ̀. Àwọn atukọ̀ òkun máa ń dìídì sá fún ilẹ̀ tómi yí ká tó ń jẹ́ Malea, òwe ayé àtijọ́ kan sọ nípa Malea yìí pé: “Gba ọ̀nà Malea, kó o rá sájò.”

Wọ́n Ṣàwárí Èbúté Kẹnkíríà Tókun Ti Bò Mọ́lẹ̀

Èbúté Kẹnkíríà tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mọ́kànlá sílùú Kọ́ríńtì wà nípẹ̀kun ojú ọ̀nà orí omi tó lọ sí àgbègbè Éṣíà. Ní báyìí òkun ti fẹ́ẹ̀ bo èbúté náà mọ́lẹ̀ tán torí ìmìtìtì ilẹ̀ tó jà nígbà tí ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni ń parí lọ. Ọ̀gbẹ́ni Strabo sọ pé káràkátà kì í dá ní èbúté Kẹnkíríà, ó sì gbajúmọ̀ gan-an. Onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Róòmù kan tó ń jẹ́ Lucius Apuleius sì pe èbúté Kẹnkíríà ní “èbúté ńlá táwọn ọkọ̀ òkun láti onírúurú orílẹ̀-èdè máa ń wọ̀ tìrítìrí lọ.”

Nígbà tí ìjọba Róòmù ń ṣàkóso, wọ́n ṣe afárá orí omi méjì tó dà bí pátákò ẹṣin tó gùn láti èbúté náà sórí òkun, àlàfo tó wà láàárín àwọn afárá náà fẹ̀ tó àádọ́ta-lé-nírínwó [450] sí ẹgbẹ̀ta [600] ẹsẹ̀ bàtà, ó sì lè gba ọkọ̀ òkun tó fẹ́ẹ̀ẹ́ gùn tó bọ́ọ̀sì mẹ́sàn-án. Àwọn awalẹ̀pìtàn wú àwókù tẹ́ńpìlì kan jáde lápá gúúsù ìwọ̀ oòrùn èbúté náà, wọ́n sì sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú tẹ́ńpìlì yìí ni wọ́n ti máa ń jọ́sìn abo-ọlọ́run kan tó ń jẹ́ Isis. Ilé ràgàjì kan sì wà ní òdìkejì èbúté náà táwọn awalẹ̀pìtàn sọ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti máa jọ́sìn òòṣà kan tí wọ́n ń pè ní Áfúródáítì. Àwọn atukọ̀ òkun gbà gbọ́ pé àwọn abo-ọlọ́run méjèèjì yìí ló máa ń dáàbò bo àwọn.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí òwò káràkátà tó máa ń wáyé ní èbúté náà ni Pọ́ọ̀lù ṣe ń ṣe iṣẹ́ àgọ́ pípá nílùú Kọ́ríńtì. (Ìṣe 18:1-3) Ìwé In the Steps of St. Paul sọ pé: “Nígbà òtútù, iṣẹ́ máa ń pọ̀ gan-an lọ́wọ́ àwọn tó máa ń pàgọ́ àtàwọn tó máa ń ṣe aṣọ ìgbòkun ọkọ̀ òkun nílùú Kọ́ríńtì. Nígbà òtútù tá à ń wí yìí, àwọn èbúté méjèèjì máa ń kún fọ́fọ́ fáwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n ń dúró kí ojú ọjọ́ dára, wọ́n fẹ́ tètè lo àkókò yìí láti fi tún ọkọ̀ wọn ṣe kí wọ́n sì tún kó ọjà sínú ọkọ̀. Lásìkò yìí, àwọn aláròóbọ̀ tó wà ní èbúté Lékíónì àti Kẹnkíríà máa níṣẹ́ tí wọ́n máa gbé fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti lè gán aṣọ ọkọ̀ pọ̀.”

Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù lo ohun tó lé lọ́dún kan àtààbọ̀ nílùú Kọ́ríńtì, ìyẹn ní nǹkan bí ọdún 52 Sànmánì Kristẹni, ó wọkọ̀ òkun láti èbúté Kẹnkíríà lọ sílùú Éfésù. (Ìṣe 18:18, 19) Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà ni wọ́n dá ìjọ Kristẹni kan sílẹ̀ ní Kẹnkíríà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù pé kí wọ́n ran arábìnrin kan tó ń jẹ́ Fébè láti “ìjọ tí ó wà ní Kẹnkíríà” lọ́wọ́.—Róòmù 16:1, 2.

Lónìí, àwọn tó wá ń ṣèbẹ̀wò sí èbúté Kẹnkíríà máa ń lúwẹ̀ẹ́ nínú òkun tó mọ́ lóló tó ti bo èbúté àtayébáyé náà mọ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ wọn ni ò mọ̀ pé lọ́pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ibi tí wọ́n ti ń lúwẹ̀ẹ́ yìí máa ń kún fáwọn ọlọ́jà àtàwọn Kristẹni tó ń wàásù. Bí etíkun kejì tó wà nílùú Kọ́ríńtì sì ṣe rí náà nìyẹn, ìyẹn èbúté Lékíónì tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ tóóró náà.

Èbúté Lékíónì Lọ̀nà Tó Wọ̀lú Láti Ìwọ̀ Oòrùn

Ọ̀nà kan wà tí wọ́n da ọ̀dà ẹ̀, wọ́n ń pè é ní Òpópónà Lékíónì, kìlómítà méjì sì ni láti agora tàbí ọjà ìlú Kọ́ríńtì sí èbúté tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn, ìyẹn èbúté Lékíónì. Àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ gbẹ́lẹ̀ apá kan létí òkun náà kí wọ́n lè ríbi kọ́ èbúté náà sí, wọ́n wá kó pàǹtírí tí wọ́n gbẹ́ níbẹ̀ sí etí omi náà kó lè máa dáàbò bo àwọn ọkọ̀ òkun tó wà ní èbúté lọ́wọ́ ìjì alágbára tó máa ń fẹ́ wá láti ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ náà. Lákòókò kan, èbúté yìí wà lára àwọn èbúté tó tóbi jù lọ nínú gbogbo àwọn èbúté tó wà ní àgbègbè Òkun Mẹditaréníà. Àwọn awalẹ̀pìtàn hú àwọn àwókù ilé atọ́nà ọkọ̀ òkun tí wọ́n ṣe ère Poseidon tó mú iná dání sí, láti jẹ́ káwọn atukọ̀ rí jàǹbá tó bá wà lọ́ọ̀ọ́kán.

Téèyàn bá gba Òpópónà Lékíónì tí wọ́n mọ ògiri aláwẹ́ méjì sí lẹ́gbẹ̀ẹ́, èèyàn máa rí àwọn ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀, àwọn ilé ìjọba, àwọn tẹ́ńpìlì àtàwọn ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n kọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ títì. Kò sí àní-àní pé àdúgbò yìí máa dáa fún Pọ́ọ̀lù láti wàásù, torí ó ti máa báwọn tó wá rajà pà dé, àwọn ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́ tí ò rí kan ṣèkan, àwọn tó ń tajà ní ṣọ́ọ̀bù, àwọn ẹrú, àwọn oníṣòwò àtàwọn míì.

Yàtọ̀ sí pé èbúté Lékíónì jẹ́ ojúkò ọjà títà, wọ́n tún máa ń kó àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń jagun síbẹ̀. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé èbúté Lékíónì ni wọ́n ti ṣe ọkọ̀ òkun kan tí wọ́n ń pè ní trireme, ìyẹn ọkọ̀ òkun tí wọ́n máa ń lò láti fi jagun láyé àtijọ́. Wọ́n ní ọ̀gbẹ́ni Ameinocles ọmọ ìbílẹ̀ Kọ́ríńtì kan tó máa ń ṣe ọkọ̀ òkun ló ṣe é lọ́dún 700 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọkọ̀ òkun trireme yìí làwọn ọmọ ogun Áténì gbé lọ sójú ogun nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Páṣíà ní èbúté Sálámísì lọ́dún 480 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Èbúté tó máa ń kún fọ́fọ́ férò nígbà kan ti wá di omi adágún tó dúdú tí ewéko ti kún bò báyìí. Kò tiẹ̀ sóhun téèyàn fi lè mọ̀ pé ọkàn lára èbúté tó tóbi jù lọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún mélòó kan sẹ́yìn wà níbí yìí.

Ìlú Kọ́ríńtì Dìṣòro Fáwọn Kristẹni

Yàtọ̀ sí pé ìlú Kọ́ríńtì láwọn èbúté tí wọ́n ti máa ń ṣòwò, àwọn èbúté yìí tún dà bí ẹnu ọ̀nà táwọn ìwàkíwà tó ń ṣàkóbá fáwọn ará ìlú náà ń gbà wọlé. Ohun kan ni pé ojúkò ọrọ̀ ajé làwọn èbúté yìí jẹ́, wọ́n sì ń pa owó wọlé. Owó gọbọi tíjọba ìlú Kọ́ríńtì ń gbà lọ́wọ́ àwọn tí ọjà wọn ń dé sí èbúté, àtèyí tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn tó ń fọkọ̀ ọlọ́pọ́n kẹ́rù gba ojú ọnà tóóró, ìyẹn diolkos, ló sọ wọ́n dọlọ́rọ̀. Wọ́n tún máa ń gbowó orí lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ tó ń gba orí àwọn títì wọn kọjá. Níparí ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni, owó tó ń wọlé sápò ìjọba, látinú owó tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò àtèyí tí wọ́n ń rí láwọn èbúté, ti pọ̀ débi pé ìjọba ò ṣòpò gbowó orí mọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Kọ́ríńtì.

Owó tún ń wọlé sápò ìjọba ìlú Kọ́ríńtì látọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò tó ń gbé níbẹ̀, àmọ́ tí wọ́n kì í ṣe ọmọ ìbílẹ̀. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló máa ń jayé káyé tí wọ́n sì máa ń ṣèṣekúṣe láwọn ibi àríyá. Àwọn atukọ̀ ojú omi tún máa ń ya wọ ìlú Kọ́ríńtì, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ ìlú náà di ọlọ́rọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni Strabo sì ṣe sọ, wọ́n ò mọlà tówó kọ. Àwọn tó ń gbé nílùú náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n ń ṣe, lára ẹ̀ ni títún ọkọ̀ òkun ṣe.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà láyé, yàtọ̀ sílùú Róòmù, Alẹkisáńdíríà, Áńtíókù àti Síríà, ìlú Kọ́ríńtì làwọn èèyàn tún pọ̀ sí, torí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó [400,000] ló ń gbé níbẹ̀ nígbà yẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Gíríìsì, Róòmù, Síríà, Íjíbítì àtàwọn Júù ló fi ìlú Kọ́ríńtì ṣelé. Nítorí àwọn èbúté tó wà nílùú náà, gbogbo ìgbà nìlú náà máa ń kún fọ́fọ́ fáwọn arìnrìn àjò, àwọn àlejò tó wá ṣeré ìdárayá, àwọn ayàwòrán, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí, àwọn oníṣòwò àtàwọn míì. Àwọn àlejò yìí máa ń mú ẹ̀bùn wá sí tẹ́ńpìlì, wọ́n sì máa ń rúbọ sáwọn òrìṣà tó wà níbẹ̀. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló jẹ́ kí ìlú Kọ́ríńtì máa rọ̀ ṣọ̀mù kó sì máa dùn yùngbà, àmọ́ àkóbá kékeré kọ́ ni wọ́n ṣe fáwọn tó ń gbé ìlú náà.

Ìwé In the Steps of St. Paul sọ pé: “Èbúté méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nílùú Kọ́ríńtì jẹ́ kí onírúurú èèyàn máa wà síbẹ̀, òun ló sì fà á táwọn aráàlú náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ìṣekúṣe tí wọ́n rí lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò tó ń bá ọkọ̀ òkun wá sáwọn èbúté wọn.” Onírúurú ìwà pálapàla tó kún ọwọ́ àwọn èèyàn tó máa ń wá láti ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn ayé ló wá dàṣà ìgbàlódé nílùú Kọ́ríńtì. Abájọ tí ìwà rere fi pòórá nílùú Kọ́ríńtì, wọ́n wá ń jayé káyé, ó sì wá di ìlú tí ìwà pálapàla ẹ̀ pọ̀ jù ní orílẹ̀-èdè Gíríìsì àtijọ́. Àwọn èèyàn máa ń sọ pé ẹni tó bá ń ṣèṣekúṣe ń gbé ìgbésí ayé àwọn ará Kọ́ríńtì.

Irú àyíká táwọn èèyàn ti ń lépa owó lójú méjèèjì, tí wọ́n sì ń hùwà pálapàla bẹ́ẹ̀ léwu fáwọn Kristẹni, ó lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó wà nílùú Kọ́ríńtì nílò ìyànjú kí wọ́n lè máa hùwà tó máa múnú Ọlọ́run dùn. Lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Kọ́ríńtì sì bọ́ sákòókò torí ó sọjú abẹ níkòó pé ìwà ìwọra jìbìtì àti ìwà àìmọ́ ò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Bó o ṣe ń ka àwọn lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí yẹn, ìwọ náà á rí i páwọn nǹkan táwọn Kristẹni tó wà nílùú náà ń kojú lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ lóòótọ́.—1 Kọ́ríńtì 5:9, 10; 6:9-11, 18; 2 Kọ́ríńtì 7:1.

Síbẹ̀, bó ṣe jẹ́ pé onírúurú èèyàn láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fi ìlú Kọ́ríńtì ṣelé ní rere tó ń ṣe fún ìlú náà. Gbogbo ìgbà làwọn tó ń gbé nílùú náà máa ń dá oríṣiríṣi àbá tó mọ́gbọ́n dání téèyàn lè fi ṣe nǹkan. Àwọn tó ń gbébẹ̀ lọ́pọlọ ju àwọn tó ń gbé láwọn ìlú míì tí Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò sí. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé: “Àwọn èèyàn láti ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn ń pàdé nílùú àtijọ́ tó ní èbúté yìí, èyí sì jẹ́ káwọn tó ń gbébẹ̀ ní oríṣiríṣi òye, ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti onírúurú ìsìn táwọn èèyàn ń ṣe ní gbogbo ayé.” Ìdí nìyẹn tí oríṣiríṣi ìsìn fi wà nílùú náà, ó sì ṣe kedere pé èyí jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe rọrùn.

Àwọn èbúté méjèèjì tó wà nílùú Kọ́ríńtì, ìyẹn Kẹnkíríà àti Lékíónì jẹ́ kí ìlú náà lọ́rọ̀ kí òkìkí ẹ̀ sì kàn. Àwọn èbúté yìí sì tún jẹ́ ìṣòro fáwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Kọ́ríńtì. Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Àwọn ohun tó lè ṣàkóbá fáwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run pọ̀ gan-an láyé yìí, lára ẹ̀ ni ìfẹ́ ọrọ̀ àti ìwà pálapàla. Nítorí náà, ó máa dáa káwa náà fiyè sáwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù fáwọn Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

 DIOLKOS—Ọ̀NÀ TÓÓRÓ TÍ WỌ́N MÁA Ń KẸ́RÙ GBÀ

Nígbà tí ètò tí wọ́n ṣe láti kọ́ ipadò sí ìlú Kọ́ríńtì forí ṣánpọ́n ní ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Periander tó jẹ́ alákòóso ìlú Kọ́ríńtì nígbà náà fọgbọ́n ṣe ọ̀nà tóóró kan sórí ilẹ̀ káwọn èèyàn lè máa gbé àwọn ẹrù wọn gbabẹ̀. a Diolkos, tó túmọ̀ sí “ti nǹkan kọjá,” ni wọ́n ń pe ọ̀nà yìí, ọ̀nà tóóró kan tí wọ́n gbẹ́, tí wọ́n sì fàwọn òkúta pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ ṣe ni, ọ̀nà náà da fírì lọ sísàlẹ̀, pákó tí wọ́n fi gíríìsì pa ni wọ́n sì fi ṣe àwọn ògiri ẹ̀. Àwọn akẹ́rù máa já ẹrù látinú ọkọ̀ òkun ní èbúté kan sínú ọmọlanke, wọ́n á wá tì í gba ojú ọ̀nà yẹn lọ sí òdìkejì. Nígbà míì, wọ́n máa ń ti àwọn ọkọ̀ ọlọ́pọ́n tẹ́rù wà nínu wọn gba ọ̀nà tóóró yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ ka ìtàn bí wọ́n ṣe kọ́ ipadò ìgbàlódé sí ìlú Kọ́ríńtì, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Odò Tí A Lànà Fún ní Kọ́ríńtì àti Ìtàn Rẹ̀,” nínú Jí! June 8, 1986, ojú ìwé 25 sí 27.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ORÍLẸ̀-ÈDÈ GÍRÍÌSÌ

Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ìlú Kọ́ríńtì

Èbúté Lékíónì

Ìlú Kọ́ríńtì Àtijọ

Èbúté Kẹnkíríà

Ilẹ̀ Tóóró Ìlú Kọ́ríńtì

Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Saronic

Peloponnese

ÒKUN IONIAN

Malea

ÒKUN AEGEAN

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń kó ọjà máa ń kọjá ní Ipadò Kọ́ríńtì lóde òní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èbúté Lékíónì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èbúté Kẹnkíríà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Látọwọ́: Todd Bolen/Bible Places.com