Báwo Ló Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó Láti Di Àtúnbí?
Báwo Ló Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó Láti Di Àtúnbí?
NÍNÚ ọ̀rọ̀ tí Jésù bá Nikodémù sọ látòkè délẹ̀, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn kan di àtúnbí. Báwo ló ṣe sọ ọ́?
Jésù sọ pé: “Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:3) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí “láìjẹ́” àti “kò lè” jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó fáwọn kan láti di àtúnbí. Wo àpèjúwe yìí ná: Bẹ́nì kan bá sọ pé, “Láìjẹ́ pé oòrùn ràn, ojú ọjọ́ kò lè mọ́lẹ̀,” ohun tó ń sọ ni pé ìmọ́lẹ̀ ṣe pàtàkì kójú ọjọ́ tó lè mọ́lẹ̀. Ohun tí Jésù náà ń sọ ni pé kéèyàn di àtúnbí ṣe pàtàkì kéèyàn tó lè rí Ìjọba Ọlọ́run.
Níkẹyìn, ńṣe ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tẹ̀ lé e mú iyèméjì kúrò lórí kókó yìí, ó sọ pé: “A gbọ́dọ̀ tún yín bí.” (Jòhánù 3:7) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù sọ, ẹni tó bá fẹ́ “wọ ìjọba Ọlọ́run” gbọ́dọ̀ di àtúnbí.—Jòhánù 3:5.
Ní báyìí tá a ti rí i pé Jésù ka dídi àtúnbí sóhun tó ṣe pàtàkì gan-an, ó yẹ káwa Kristẹni rí i dájú pé ọ̀rọ̀ dídi àtúnbí yé wa dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, ṣó o rò pé Kristẹni kan lè pinnu láti di àtúnbí?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Láìjẹ́ pé oòrùn ràn, ojú ọjọ́ kò lè mọ́lẹ̀”