2. Fi Tọkàntọkàn Kà Á
Bó O Ṣe Lè Lóye Bíbélì
2. Fi Tọkàntọkàn Kà Á
Ṣé ọ̀rẹ́ ẹ kan ti sọ àwọn nǹkan tí kò dáa fún ẹ rí nípa ẹnì kan tó ò mọ̀ rí? Nígbà tó o wá rí ẹni yẹn, ṣáwọn nǹkan tó o ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀ ò wá gbà ẹ́ lọ́kàn débi pé o ò fiyè sáwọn ẹ̀bùn àbínibí àtàwọn ànímọ́ rere tẹ́ni yẹn ní? Irú ohun kan náà lè wáyé tó bá dọ̀rọ̀ lílóye Bíbélì.
ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ kìlọ̀ fún wa nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá fi tọkàntọkàn ka Bíbélì. Ó kọ̀wé nípa àwọn Júù kan tí wọ́n jọ gbé láyé nígbà náà lọ́hùn pé: “Mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.”—Róòmù 10:2.
Àwọn kan lára àwọn Júù tí wọ́n gbé láyé nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ò gbà pé Jésù ni Mèsáyà, láìka pé Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti sọ ọ́
lọ́nà tó ṣe kedere. Gbogbo àpèjúwe tí Ìwé Mímọ́ ṣe nípa ẹni tó máa jẹ́ Mèsáyà ló bá Jésù ará Násárétì mu, Jésù sì tún mú gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ṣẹ. Síbẹ̀, àwọn èrò òdì tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí wọ́n gbé láyé nígbà yẹn ní ò jẹ́ kí wọ́n lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi tọkàntọkàn ka Bíbélì. Téèyàn bá ní ẹ̀tanú tàbí àwọn èrò òdì kan nípa Bíbélì lọ́kàn tẹ́lẹ̀, ìyẹn lè gba onítọ̀hún lọ́kàn débi pé kò ní lè lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.
Bí àpẹẹrẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n kan láti ìpínlẹ̀ North Carolina lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsìn, ṣàpèjúwe Bíbélì gẹ́gẹ́ bí “ìwé táwọn èèyàn fi ọgbọ́n orí èèyàn kọ,” ó ní “ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ò bára mu, kò sì sọ ohunkóhun tó ṣeé gbára lé nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa.” Tẹ́nì kan bá ń ka Bíbélì pẹ̀lú èrò pé ó jẹ́ “ìwé táwọn èèyàn kọ,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èyí tó bá wu ẹni yẹn láá fẹ́ máa tẹ̀ lé nínú àwọn ìlànà tàbí àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì.
Àmọ́, Bíbélì fún wa níṣìírí pé ká máa fara balẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ará Bèróà, nígbà ayé Pọ́ọ̀lù pé: “Wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, . . . wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ [kí wọ́n lè rí i] bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.” (Ìṣe 17:11) Bíi tàwọn ará Bèróà yìí, ó lè gba pé kíwọ pẹ̀lú mú ẹ̀tanú tàbí lámèyítọ́ kúrò lọ́kàn ẹ, kó o lè lóye Bíbélì. Fi tọkàntọkàn ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bó o ṣe ń hára gàgà láti mọ ìsọfúnni tó ń mọ́kàn yọ̀ tí Ọlọ́run ní fún wa.